ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/10 ojú ìwé 31
  • Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé
  • Jí!—2010
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ló Ṣe Iṣẹ́ Yìí?
  • KÍ LO MỌ̀ NÍPA ÀPỌ́SÍTÉLÌ ÁŃDÉRÙ?
  • NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
  • ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ
  • Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé
    Jí!—2011
  • Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
    Jí!—2009
  • Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
    Jí!—2008
  • Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé
    Jí!—2010
Àwọn Míì
Jí!—2010
g 10/10 ojú ìwé 31

Àtúnyẹ̀wò Fún Ìdílé

Ta Ló Ṣe Iṣẹ́ Yìí?

1. Àwọn ọmọ Sébédè méjì wo ni wọ́n jẹ́ apẹja tí wọ́n sì tún jẹ́ àpọ́sítélì Jésù?

Kọ ìdáhùn rẹ sórí ìlà tó wà nísàlẹ̀ yìí.

AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 4:21, 22.

․․․․․

2. Kí ni orúkọ àwọn àpọ́sítélì méjì yòókù tí wọ́n jẹ́ apẹja?

AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 4:18.

․․․․․

FÚN ÌJÍRÒRÒ:

Kí nìdí tí Jésù fi sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa di “apẹja ènìyàn”? (Mátíù 4:19) Ọ̀nà wo lo rò pé pípẹja gidi àti pípẹja ènìyàn gbà jọra, kí sì ni ìyàtọ̀ méjèèjì?

KÍ LO MỌ̀ NÍPA ÀPỌ́SÍTÉLÌ ÁŃDÉRÙ?

3. Ọmọ ẹ̀yìn ta ni Áńdérù tẹ́lẹ̀ kó tó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?

AMỌ̀NÀ: Ka Máàkù 1:4; Jòhánù 1:35-40.

․․․․․

4. Ta ni Áńdérù sọ̀rọ̀ nípa Jésù fún, kí ló sì wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà?

AMỌ̀NÀ: Ka Jòhánù 1:40-42.

․․․․․

FÚN ÌJÍRÒRÒ:

Kí nìdí tó fi dára pé kó o sọ àwọn ohun tó o mọ̀ nípa Jésù fún àwọn ìbátan rẹ? Ṣùgbọ́n, báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe lè rí lára àwọn kan nínú wọn?

AMỌ̀NÀ: Ka Mátíù 10:32-37.

NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ

Dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, kó o sì kọ (àwọn) ẹsẹ Bíbélì tó yẹ sínú àlàfo.

OJÚ ÌWÉ 3 Kí ni afọgbọ́nhùwà máa ń ṣe? Òwe 14:․․․

OJÚ ÌWÉ 8 Orúkọ wo ni Ọlọ́run fún ara rẹ̀? Sáàmù 83:․․․

OJÚ ÌWÉ 18 Kí ni “fífún ìbínú jáde” máa ń yọrí sí? Òwe 30:․․․

OJÚ ÌWÉ 22 Kí ló ṣẹlẹ̀ sáwọn ańgẹ́lì tó dẹ́sẹ̀? Júúdà:․․․

ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ

1. Jákọ́bù àti Jòhánù.

2. Pétérù àti Áńdérù.

3. Jòhánù Olùbatisí.

4. Pétérù arákùnrin rẹ̀, ó sì di ọmọ ẹ̀yìn Jésù lẹ́yìn náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́