Kí Nìdí Tí Àwọn Tó Ń Ṣọdún Kérésì Fi Ń Pọ̀ Sí I?
ṢÉ Ò ń fojú sọ́nà láti ṣe ọdún Kérésìmesì? Àbí ńṣe ni ẹ̀rù ń bà ọ́ bó o ṣe ń retí ìgbà tí ọdún Kérésìmesì máa wáyé? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń béèrè pé: ‘Àwọn wo ni màá fún lẹ́bùn? Kí ni kí n rà? Ṣé owó mi á ká a? Ìgbà wo ni màá tó san gbèsè tí n bá jẹ tán?’
Pẹ̀lú bí ọdún Kérésìmesì ṣe máa ń kó àníyàn bá àwọn èèyàn tó, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣì máa ń ṣe é. Kódà, wọ́n ti ń ṣọdún Kérésìmesì ní àwọn ilẹ̀ tí kì í ṣe ti àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni pàápàá. Ní orílẹ̀-èdè Japan, ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń ṣe ọdún Kérésìmesì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe torí pé ọdún yìí ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn wọn ni wọ́n ṣe ń ṣe é, àmọ́ torí pé ó kàn jẹ́ àkókò àríyá. Ìwé ìròyìn The Wall Street Journal sọ pé: “Ńṣe ni wọ́n máa ń gbé àwòrán Bàbá Kérésì síbi tí àwọn èèyàn ti lè rí i ní àwọn ilé ìtajà tó wà láwọn ìlú ńláńlá lórílẹ̀-èdè Ṣáínà. Àwọn mẹ̀kúnnù tó ń gbé ní ìgboro ìlú náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọdún Kérésì, wọ́n máa ń rajà, wọ́n máa ń jẹun, wọ́n sì máa ń ṣe àríyá nígbà pọ̀pọ̀ṣìnṣìn Kérésì.”
Ọdún Kérésì ti mú kí ọrọ̀ ajé túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lágbàáyé. Orílẹ̀-èdè Ṣáìnà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára irú àwọn orílẹ̀-èdè bẹ́ẹ̀. Ìwé ìròyìn Journal tún sọ pé orílẹ̀-èdè Ṣáínà “máa ń kó àwọn igi àtọwọ́dá, àwọn ọ̀rá tó ń dán gbinrin, àwọn iná Kérésì àti ọ̀pọ̀ àwọn ohun tí wọ́n fi ń ṣe ọ̀ṣọ́ nígbà Kérésì ránṣẹ́ sáwọn orílẹ̀-èdè míì.”
Kódà, láwọn ilẹ̀ tó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí ló pọ̀ jù níbẹ̀, wọ́n máa ń ṣe àwọn ọdún tó fara jọ ọdún Kérésì, bí wọn ò tiẹ̀ ṣe é ní December 25. Ní ìlú Áńkarà, lórílẹ̀-èdè Turkey àti ìlú Beirut, lórílẹ̀-èdè Lẹ́bánónì, wọ́n máa ń ta àwọn igi Kérésì àtàwọn ẹ̀bùn tí wọ́n fi ọ̀rá tó ń dán gbinrin wé. Lórílẹ̀-èdè Indonesia, àwọn òtẹ́ẹ̀lì àtàwọn ilé ìtajà ńláńlá máa ń ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn àpèjẹ níbi tí àwọn ọmọdé ti máa ń jẹun pẹ̀lú Bàbá Kérésì tàbí kí wọ́n ya fọ́tò pẹ̀lú rẹ̀.
Ìwé ìròyìn Royal Bank Letter lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, Kérésìmesì kì í tún ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn mọ́, àmọ́ ó ti di ìṣòwò, wọ́n máa ń polówó ọjà “láti fa àwọn ọmọdé mọ́ra.” Òótọ́ ni pé àwọn kan ṣì máa ń lọ ṣe ọdún Kérésìmesì ní ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ àwọn ilé ìtajà níbi tí wọ́n ti ń kọ àwọn orin Kérésì làwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí jù lọ torí pé ríra ẹ̀bùn àti fífúnni lẹ́bùn ló jẹ wọ́n lógún jù lọ. Kí ló fa ìyípadà yìí? Ǹjẹ́ ìyípadà yìí ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú bí ọdún Kérésìmesì ṣe bẹ̀rẹ̀? Báwo ni ọdún Kérésìmesì ṣe bẹ̀rẹ̀ gan-an?
Ká tó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, á dára kí a ka ìtàn Bíbélì tí àwọn èèyàn sọ pé àwọn fi ń ya àwòrán ìbí Jésù nígbà tí wọ́n bá ń ṣọdún Kérésìmesì.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
OHUN TÍ ÀWỌN TÓ KỌ ÌWÉ ÌHÌN RERE SỌ
Àpọ́sítélì Mátíù: “Lẹ́yìn tí a bí Jésù ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà ní àwọn ọjọ́ Hẹ́rọ́dù Ọba, wò ó! àwọn awòràwọ̀ láti àwọn apá ìlà-oòrùn wá sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n wí pé: ‘Ibo ni ẹni tí a bí ní ọba àwọn Júù wà? Nítorí a rí ìràwọ̀ rẹ̀ nígbà tí a wà ní ìlà-oòrùn, a sì ti wá láti wárí fún un.’ Ní gbígbọ́ èyí, ṣìbáṣìbo bá Hẹ́rọ́dù Ọba.” Torí náà, Hẹ́rọ́dù béèrè lọ́wọ́ “àwọn olórí àlùfáà . . . ibi tí a ó ti bí Kristi.” Nígbà tí Hẹ́rọ́dù gbọ́ pé “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù” ni, ó sọ fún àwọn awòràwọ̀ pé: “Ẹ lọ fẹ̀sọ̀ wá ọmọ kékeré náà káàkiri, nígbà tí ẹ bá sì ti rí i, kí ẹ padà ròyìn fún mi.”
“Wọ́n bá ọ̀nà wọn lọ; sì wò ó! ìràwọ̀ tí wọ́n ti rí nígbà tí wọ́n wà ní ìlà-oòrùn ń lọ níwájú wọn, títí tí ó fi wá dúró lókè ibi tí ọmọ kékeré náà wà. . . . Nígbà tí wọ́n sì wọ ilé náà, wọ́n rí ọmọ kékeré náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀.” Lẹ́yìn tí wọ́n fún Jésù ní ẹ̀bùn, “a fún wọn ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nínú àlá láti má padà sọ́dọ̀ Hẹ́rọ́dù, [torí náà] wọ́n fi ibẹ̀ sílẹ̀ gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ilẹ̀ wọn.”
“Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ibẹ̀ sílẹ̀ lọ, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà fara han Jósẹ́fù nínú àlá, ó wí pé: ‘Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀, kí o sì sá lọ sí Íjíbítì . . . ’ Bẹ́ẹ̀ ni ó dìde, ó sì mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀ lọ́wọ́ ní òru, ó sì fi ibẹ̀ sílẹ̀ . . . Nígbà náà Hẹ́rọ́dù, ní rírí i pé àwọn awòràwọ̀ náà ti gbọ́n já òun, kún fún ìhónú ńláǹlà, ó sì ránṣẹ́ jáde, ó sì mú kí a pa gbogbo ọmọdékùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní gbogbo àgbègbè rẹ̀, láti ọmọ ọdún méjì sí ìsàlẹ̀.”—Matíù 2:1-16.
Lúùkù ọmọ ẹ̀yìn sọ pé: Jósẹ́fù “gòkè lọ láti Gálílì, kúrò ní ìlú ńlá Násárétì, lọ sí Jùdíà, sí ìlú ńlá Dáfídì, èyí tí a ń pè ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, . . . láti forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú Màríà . . . Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, . . . Ó sì bí ọmọkùnrin rẹ̀, àkọ́bí, ó sì fi àwọn ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran kan, nítorí pé kò sí àyè fún wọn nínú yàrá ibùwọ̀.”
“Àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú wà ní ìgbèríko kan náà, tí wọ́n ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru. Lójijì, áńgẹ́lì Jèhófà dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, . . . ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà wí fún wọn pé: ‘Ẹ má bẹ̀rù, nítorí, wò ó! èmi ń polongo fún yín ìhìn rere ti ìdùnnú ńlá kan tí gbogbo ènìyàn yóò ní, nítorí pé a bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa, ní ìlú ńlá Dáfídì.’” Nígbà náà ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn “lọ pẹ̀lú ìṣekánkán, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù, àti ọmọdé jòjòló tí ó wà ní ìdùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.”—Lúùkù 2:4-16.