Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Kérésìmesì
ṢÉ Ó máa ń wù ẹ́ láti mọ òtítọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ àtàwọn ayẹyẹ ìsìn? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o ti béèrè àwọn ìbéèrè yìí rí: (1) Ṣé December 25 ni wọ́n bí Jésù lóòótọ́? (2) Àwọn wo ni “àwọn amòye” náà, ṣé mẹ́ta ni wọ́n lóòótọ́? (3) Irú “ìràwọ̀” wo ló mú wọn lọ sọ́dọ̀ Jésù? (4) Kí ni Bàbá Kérésì ní í ṣe pẹ̀lú ìbí Jésù? (5) Irú ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àṣà fífúnni lẹ́bùn nígbà Kérésì tàbí ṣíṣe pàṣípààrọ̀ ẹ̀bùn?
Jẹ́ ká fi Bíbélì àtàwọn ohun tá a mọ̀ nínú ìtàn dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.
(1) Ṣé December 25 ni wọ́n bí Jésù?
Ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe: Àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé December 25 ni wọ́n bí Jésù, ọjọ́ yẹn ni wọ́n sì máa ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopedia of Religion ṣàlàyé pé Kérésìmesì túmọ̀ sí ‘ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Kristi.’
Bí àṣà náà ṣe bẹ̀rẹ̀: Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Christmas Encyclopedia sọ pé, “àṣà ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù ní December 25 kò sí nínú Bíbélì, àmọ́ ó wá látinú àwọn ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà táwọn ará Róòmù máa ń ṣe ní ìparí ọdún,” èyí tó sábà máa ń bọ́ sí ìgbà òtútù ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà níhà àríwá. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà tún jẹ́ ká mọ̀ pé lára àwọn ayẹyẹ náà ni àjọ̀dún tí wọ́n fi ń bọlá fún òrìṣà Saturn, ìyẹn ọlọ́run nǹkan ọ̀gbìn “àti àjọ̀dún oríṣi ọlọ́run méjì tó jẹ́ ọlọ́run oòrùn, ìyẹn Sol ti ilẹ̀ Róòmù àti Mithra ti ilẹ̀ Páṣíà.” December 25 ni wọ́n máa ń ṣe ọjọ́ ìbí àwọn òrìṣà méjèèjì, ìyẹn ní ìgbà òtútù lórí Kàlẹ́ńdà Júlíọ́sì.
Ọdún 350 ni wọ́n mú ayẹyẹ àwọn abọ̀rìṣà yìí wọnú ẹ̀sìn Kristẹni nígbà tí Pope Julius Kìíní kéde pé December 25 ni ọjọ́ ìbí Kristi. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopedia of Religion sọ pé: “Bí ọdún ti ń gorí ọdún, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ayẹyẹ ìbí Jésù rọ́pò àwọn ayẹyẹ míì tí wọ́n máa ń ṣe nígbà òtútù. Wọ́n túbọ̀ ń fi àwòrán oòrùn ṣàpèjúwe bí Kristi (tí wọ́n tún máa ń pè ní Sol Invictus) ṣe jí dìde, àwòrán oòrùn . . . sì wá di ohun tí wọ́n máa ń yà sí ibi orí àwọn ẹni mímọ́.”
Ohun tí Bíbélì sọ: Bíbélì kò sọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù. Àmọ́ a lè fi ìdánilójú sọ pé kì í ṣe December 25 ni wọ́n bí i. Kí nìdí tá a fi lè sọ bẹ́ẹ̀? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn “ń gbé ní ìta,” wọ́n sì ń tọ́jú àwọn agbo ẹran wọn ní alẹ́ nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. (Lúùkù 2:8) Oṣù October ni òjò àti òtútù sábà máa ń bẹ̀rẹ̀, tó bá sì fi máa di oṣù December, òtútù náà máa ń pọ̀ gan-an débi pé yìnyín máa ń já bọ́, àwọn olùṣọ́ àgùntàn sì máa ń kó àwọn àgùntàn wọn sí inú ilé ní alẹ́ lásìkò náà, pàápàá ní àwọn ilẹ̀ olókè tó máa ń tutù gan-an bí àwọn tó wà nítòsí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.a
Ó gbàfiyèsí pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, tí ọ̀pọ̀ nínú wọn wà pẹ̀lú Jésù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, kò ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù ní ọjọ́ èyíkéyìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìrántí ikú rẹ̀ nìkan ni wọ́n máa ń ṣe, gẹ́gẹ́ bó ṣe pa á láṣẹ fún wọn. (Lúùkù 22:17-20; 1 Kọ́ríńtì 11:23-26) Síbẹ̀ àwọn kan lè sọ pé, ‘Kí ló wá burú nínú pé ayẹyẹ Kérésì wá látinú ẹ̀sìn àwọn abọ̀rìṣà?’ Ìdáhùn ìbéèrè yìí ni pé, ó burú lójú Ọlọ́run. Jésù Kristi sọ pé “àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́.”—Jòhánù 4:23.
(2) Mélòó Ni “Àwọn Amòye” Náà? Irú Èèyàn Wo sì Ni Wọ́n?
Ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe: Àwọn èèyàn máa ń ṣàpèjúwe bí àwọn amòye mẹ́ta tí “ìràwọ̀” láti ìlà oòrùn ṣamọ̀nà ṣe lọ sọ́dọ̀ Jésù láti fún un lẹ́bùn ní ibùjẹ ẹran tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nínú ilé ẹran. Nígbà míì wọ́n tún máa ń sọ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú wà níbẹ̀.
Bí àṣà náà ṣe bẹ̀rẹ̀: Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The Christmas Encyclopedia sọ pé, yàtọ̀ sí àlàyé díẹ̀ tí Bíbélì ṣe nípa àwọn amòye, “ìtàn àròsọ ni gbogbo àwọn nǹkan míì táwọn èèyàn sọ nípa Àwọn Amòye náà.”
Ohun tí Bíbélì sọ: Bíbélì kò sọ iye “àwọn amòye” tó lọ sọ́dọ̀ Jésù. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ méjì, mẹ́tà, mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan pè wọ́n ní “àwọn amòye,” ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò lédè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni magoi, ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni àwọn awòràwọ̀ tàbí àwọn oníṣẹ́ oṣó. Bíbélì sì sọ pé “ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú Jèhófà” ni àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí. (Diutarónómì 18:10-12) Torí pé ọ̀nà jíjìn ni àwọn awòràwọ̀ yẹn ti wá, ìyẹn láti ìlà oòrùn, nígbà tí wọ́n fi máa dé ilé ẹran tí wọ́n bí Jésù sí, wọ́n ti gbé e kúrò níbẹ̀. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lẹ́yìn tí wọ́n ti rìnrìn àjò fún ọ̀pọ̀ oṣù ni wọ́n “wọ ilé náà” níbi tí Jésù wà. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rí “ọmọ kékeré náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀.”—Mátíù 2:11.
(3) Irú Ìràwọ̀ Wo Ló Ṣamọ̀nà Àwọn Awòràwọ̀ Náà?
Ohun tí ìràwọ̀ náà ṣe jẹ́ ká mọ irú ìràwọ̀ tó jẹ́. Ohun kan ni pé, ìràwọ̀ náà kò ṣamọ̀nà àwọn awòràwọ̀ yẹn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní tààràtà, àmọ́ ṣe ló ṣamọ̀nà wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù, èyí ló sì mú kí Hẹ́rọ́dù Ọba gbọ́ pé wọ́n ń ṣèwádìí nípa ibi tí Jésù wà. Hẹ́rọ́dù wá “fi ọlá àṣẹ pe àwọn awòràwọ̀ náà ní bòókẹ́lẹ́,” wọ́n sì ṣàlàyé ohun tí wọ́n mọ̀ nípa “ọba àwọn Júù” tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà fún un. Hẹ́rọ́dù wá sọ pé: “Ẹ lọ fẹ̀sọ̀ wá ọmọ kékeré náà káàkiri, nígbà tí ẹ bá sì ti rí i, kí ẹ padà ròyìn fún mi.” Hẹ́rọ́dù kò ro Jésù ro ire rárá. Ṣe ni alákòóso tó jẹ́ agbéraga àti aláìláàánú yìí fẹ́ pa Jésù!—Mátíù 2:1-8, 16.
Ohun tó gbàfiyèsí ni pé, “ìràwọ̀” náà ṣamọ̀nà àwọn awòràwọ̀ yẹn lọ sí gúúsù Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Orí ilé tí Jésù wà ni ‘ó wá dúró’ sí.—Mátíù 2:9, 10.
Ó hàn gbangba pé ìràwọ̀ yìí kì í ṣe ìràwọ̀ lásán! Kí sì nìdí tí Ọlọ́run tó lo àwọn áńgẹ́lì láti sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn nípa ìbí Jésù fi máa lo ìràwọ̀ láti darí àwọn awòràwọ̀ tó jẹ́ abọ̀rìṣà sọ́dọ̀ ọ̀tá Jésù lákọ̀ọ́kọ́, kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá darí wọn lọ sọ́dọ̀ ọmọ náà? Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti parí èrò sí pé Sátánì tó jẹ́ alárèékérekè ló fẹ́ fi ìràwọ̀ yẹn ṣe iṣẹ́ ibi. (2 Tẹsalóníkà 2:9, 10) Àmọ́ ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé wọ́n máa ń fi ohun kan tí wọ́n ń pè ní ìràwọ̀ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ṣe ọ̀ṣọ́ sórí igi Kérésì.
(4) Kí Ni Bàbá Kérésì Ní Í Ṣe Pẹ̀lú Jésù àti Ìgbà Tí Wọ́n Bí I?
Ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe: Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, Bàbá Kérésì ni wọ́n sọ pé ó máa ń mú ẹ̀bùn wá fáwọn ọmọdé. Àwọn ọmọdé sábà máa ń kọ̀wé sí Bàbá Kérésì pé kó fún àwọn ní ẹ̀bùn, ohun tí ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ sì sọ ni pé àwọn ẹ̀dá abàmì kan ló máa ń bá a ṣe àwọn ẹ̀bùn náà ní ìpẹ̀kun àríwá ayé, níbi tó fi ṣe ibùjókòó rẹ̀.
Bí àṣà náà ṣe bẹ̀rẹ̀: Ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ ni pé ọ̀dọ̀ Níkólásì Mímọ́, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà ìlú Máírà ní Éṣíà Kékeré, tá a wá mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Tọ́kì báyìí ni ìtàn àròsọ nípa Bàbá Kérésì ti bẹ̀rẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The Christmas Encyclopedia sọ pé, “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé inú ìtàn àròsọ ni wọ́n ti mú gbogbo nǹkan tí wọ́n sọ nípa Níkólásì Mímọ́.” Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ náà, “Santa Claus,” ìyẹn Bàbá Kérésì wá látinú ọ̀rọ̀ náà “Sinterklaas,” tó jẹ́ ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà pe “Níkólásì Mímọ́” ní èdè Dutch. Èyí fi hàn pé nínú ìtàn àti nínú Bíbélì, Bàbá Kérésì kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú Jésù Kristi.
Ohun tí Bíbélì sọ: “Nísinsìnyí tí ẹ ti fi èké ṣíṣe sílẹ̀, kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara tí ó jẹ́ ti ara wa lẹ́nì kìíní-kejì ni wá.” Àwọn tó wà nínú ìdílé wa ni “aládùúgbò” wa tó sún mọ́ wa jù lọ. (Éfésù 4:25) Bíbélì tún sọ pé a gbọ́dọ̀ “nífẹ̀ẹ́ òtítọ́,” ká sì máa “sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà [wa].” (Sekaráyà 8:19; Sáàmù 15:2) Lóòótọ́, téèyàn bá sọ fún àwọn ọmọdé pé Bàbá Kérésì ló ń pín ẹ̀bùn lọ́jọ́ Kérésì, ó lè dà bí ohun téèyàn kàn fi ṣeré lásán, àmọ́ ṣé ó dárá, ṣé ó sì bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn máa tan àwọn ọmọdé jẹ, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tó dáa lèèyàn ní lọ́kàn? Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó yani lẹ́nu pé àkókò táwọn èèyàn sọ pé àwọn fi ń bọlá fún Jésù ti wá di àkókò tí wọ́n fi ń tan àwọn ọmọdé jẹ?
(5) Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Fífúnni Lẹ́bùn àti Ṣíṣe Àríyá Nígbà Kérésì?
Ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe: Ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Kérésìmesì ni pé, ìgbà yẹn ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn sábà máa ń fún ara wọn ní ẹ̀bùn tí wọ́n sì máa ń ṣe àríyá.
Bí àṣà náà ṣe bẹ̀rẹ̀: Ayẹyẹ bíbọ òrìṣà Saturn tí wọ́n máa ń ṣe nílùú Róòmù àtijọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀ ní December 17, ó sì máa ń parí ní December 24, ìgbà yẹn sì làwọn èèyàn máa ń fún ara wọn lẹ́bùn. Wọ́n sábà máa ń filé pọntí fọ̀nà rokà, wọ́n máa ń mu ọtí àmuyíràá, wọ́n sì máa ń hùwà jàgídíjàgan. Lẹ́yìn tí wọ́n bá parí ayẹyẹ bíbọ òrìṣà Saturn, ayẹyẹ ọjọ́ kìíní oṣù January ló máa ń tẹ̀ lé e. Nǹkan bí ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n sábà máa fi ń ṣe ayẹyẹ yìí. Ó jọ pé ayẹyẹ bíbọ òrìṣà Saturn àti ayẹyẹ ọjọ́ kìíní oṣù January máa ń wọnú ara wọn.
Ohun tí Bíbélì sọ: Ìdùnnú àti ìwà ọ̀làwọ́ wà lára ohun tá a fi ń dá ìjọsìn tòótọ́ mọ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ . . . kún fún ìdùnnú, ẹ̀yin olódodo; kí ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde.” (Sáàmù 32:11) Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ sábà máa ń jẹ́ kéèyàn ní irú ìdùnnú yìí. (Òwe 11:25) Jésù Kristi sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ó tún sọ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà” tàbí lédè míì, ẹ jẹ́ kó mọ́ ọn yín lára láti máa fúnni.—Lúùkù 6:38.
Irú fífúnni tí Jésù ń sọ yìí kì í ṣe èyí tí wọ́n fi ń ṣe ààtò ẹ̀sìn tàbí èyí téèyàn ń ṣe tipátipá, bóyá nítorí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ojúlówó ẹ̀mí ọ̀làwọ́, ó ní: “Kí olúkúlùkù ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn-àyà rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú ìlọ́tìkọ̀ tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Àwọn tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì títayọ yìí máa ń fúnni látọkàn wá, ìgbàkigbà ni wọ́n sì máa ń fúnni lẹ́bùn láàárín ọdún. Ká sòótọ́, Ọlọ́run máa ń bù kún irú fífúnni yìí, kì í sì í ṣe ẹrù ìnira.
Ẹ̀tàn Ni O!
Bá a bá ṣàyẹ̀wò ayẹyẹ Kérésìmesì níbàámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ni gbogbo àṣà tó máa ń wáyé nígbà Kérésìmesì ti wá tàbí kó jẹ́ èrò òdì nípa ohun tí Bíbélì sọ. Èyí fi hàn pé, ńṣe ni wọ́n kàn ń fẹnu lásán pe Kérésìmesì ní ayẹyẹ ẹ̀sìn Kristẹni. Báwo ni wọ́n ṣe mú Kérésìmesì wọnú ẹ̀sìn Kristẹni? Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀ olùkọ́ èké dìde ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ikú Kristi. (2 Tímótì 4:3, 4) Ohun tó gba àwọn oníwàkiwà yìí lọ́kàn ni bí wọ́n ṣe máa mú kí ẹ̀sìn Kristẹni fa àwọn abọ̀rìṣà lọ́kàn mọ́ra, kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi mú oríṣiríṣi ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà wọnú ẹ̀sìn Kristẹni.
Bíbélì kìlọ̀ pé irú àwọn “olùkọ́ èké” bẹ́ẹ̀ “yóò fi àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀ kó yín nífà. Ṣùgbọ́n ní tiwọn, ìdájọ́ náà láti ìgbà láéláé kò falẹ̀, ìparun wọn kò sì tòògbé.” (2 Pétérù 2:1-3) Ọwọ́ pàtàkì ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi mú ọ̀rọ̀ yìí àti gbogbo ọ̀rọ̀ yòókù nínú Bíbélì, wọ́n sì mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́rùn ni. (2 Tímótì 3:16) Torí náà, wọn kì í lọ́wọ́ sí àwọn àṣà tó wá látinú ẹ̀sìn èké, bákan náà wọn kì í ṣe àwọn ayẹyẹ ẹ̀sìn èké. Ǹjẹ́ èyí mú kí wọ́n pàdánù ayọ̀ wọn? Rárá o! Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i báyìí, wọ́n mọ̀ dájú pé ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ń sọni dòmìnira!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó jọ pé oṣù Ethanim (ìyẹn oṣù September–October) lórí Kàlẹ́ńdà àwọn Júù ayé ìgbàanì ni wọ́n bí Jésù.—Wo ìwé Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ Kejì, ojú ìwé 56. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
OHUN TÍ WỌ́N FÚNRÚGBÌN NI WỌ́N Ń KÁ
Ìwé Christmas Customs and Traditions—Their History and Significance sọ pé, ìgbà kan wà tí àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì jà “fitafita láti fòpin sí àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà.” Àmọ́ bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ẹ̀kọ́ òtítọ́ kò jẹ wọ́n lógún mọ́, bí wọ́n ṣe fẹ́ mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa rọ́ wá sí ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n gbájú mọ́. Bó ṣe di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í “gbójú fo” àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà nìyẹn. Nígbà tó sì yá, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí ìbọ̀rìṣà.
Bíbélì sọ pé, ‘ohun tó o bá fúnrúgbìn lo máa ká.’ (Gálátíà 6:7) Lẹ́yìn tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti fúnrúgbìn àṣà ìbọ̀rìṣà, kò yẹ kó yà wọ́n lẹ́nu láti rí i pé “àṣàkaṣà” ń pọ̀ sí i. Ayẹyẹ tí wọ́n sọ pé àwọn fi ń bọlá fún Jésù ni wọ́n sọ di ìgbà tí wọ́n máa ń mu àmuyíràá, tí wọ́n sì máa ń ṣe àríyá aláriwo, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń lọ sí àwọn ilé ìtajà dípò ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn ìdílé máa ń jẹ gbèsè rẹpẹtẹ torí kí wọ́n lè ra ẹ̀bùn, àwọn ọmọdé kò mọ ìyàtọ̀ láàárín ìtàn àròsọ àti ohun tó jẹ́ òótọ́, wọn ò sì mọ ìyàtọ̀ láàárín Bàbá Kérésì àti Jésù Kristi. Abájọ tí Ọlọ́run fi sọ pé kí a “jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.”—2 Kọ́ríńtì 6:17.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn èèyàn máa ń ṣe àríyá nígbà Kérésì, gẹ́gẹ́ bó ṣe máa ń rí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ayẹyẹ bíbọ òrìṣà Saturn nígbà àtijọ́
[Credit Line]
© Àwòrán Ibi Ìkówèésí Mary Evans