ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 12/15 ojú ìwé 4-7
  • Keresimesi—Ó Ha Bá Ìsìn Kristian Mu Nítòótọ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Keresimesi—Ó Ha Bá Ìsìn Kristian Mu Nítòótọ́ Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpilẹ̀ṣẹ̀ “Keresimesi” Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Abọ̀rìṣà
  • Ìṣẹ̀lẹ̀ Aláyọ̀
  • Àwọn Ẹ̀bùn Keresimesi
  • Bọlá fún Jesu Gẹ́gẹ́ Bí Ọba!
  • Ṣé Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Ṣe Ọdún Kérésìmesì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Nípa Kérésìmesì
    Jí!—2011
  • Kí Nìdí Tí Àwọn Kan Kì Í Fi í Ṣe Kérésìmesì?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Orísun Kérésìmesì Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 12/15 ojú ìwé 4-7

Keresimesi—Ó Ha Bá Ìsìn Kristian Mu Nítòótọ́ Bí?

GẸ́GẸ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ti sọ, “Keresimesi jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Kristian máa ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́-ìbí Jesu Kristi.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, gbédègbẹ́yọ̀ náà tún sọ pẹ̀lú pé: “Àwọn Kristian ìjímìjí kò ṣayẹyẹ ìbí [Jesu] nítorí pé wọ́n ka ayẹyẹ ìbí ẹnikẹ́ni sí àṣà ìbọ̀rìṣà.”

Ìwé náà The Making of the Modern Christmas, láti ọwọ́ Golby àti Purdue, gbà pé: “Àwọn Kristian ìjímìjí kò ṣayẹyẹ ìbí Kristi. Àwọn ọjọ́-ìbí fúnraawọn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà ìbọ̀rìṣà; àwọn ìwé Ìhìnrere kò sọ ohunkóhun nípa déètì ọjọ́-ìbí Kristi gan-⁠an.”

Bí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yí àwọn ayẹyẹ ọjọ́-ìbí ká kì í bá ṣe ti Kristian, báwo ni ọjọ́-ìbí Kristi ṣe wá di àjọ̀dún tí ó lókìkí láàárín àwọn “Kristian”?

Ìpilẹ̀ṣẹ̀ “Keresimesi” Láti Ọ̀dọ̀ Àwọn Abọ̀rìṣà

“Gbogbo ènìyàn jàsè wọ́n sì yọ̀, iṣẹ́ àti ọrọ̀-ajé mọ́wọ́ dúró pátápátá fún sáà díẹ̀, àwọn ilé ni a fi ewé laurel àti ewé atutùkádún ṣe lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn ọ̀rẹ́ lọ kí araawọn wọ́n sì ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ẹ̀bùn, àwọn tí a ń rajà lọ́wọ́ wọn sì fún àwọn tí ń bá wọn rajà ní ẹ̀bùn. Gbogbo sáà náà jẹ́ ti yíyọ ayọ̀ ìdùnnú àti ti ìfẹ́ inúrere, àwọn ènìyàn sì fi ara wọn fún onírúurú àwọn ohun tí ń panilẹ́rìn-⁠ín.”​—⁠Paganism in Christian Festivals, láti ọwọ́ J. M. Wheeler.

Àpèjúwe yìí ha bá àwọn àjọ̀dún Keresimesi kan tí ìwọ mọ̀ mu bí? Lọ́nà tí ó yanilẹ́nu èyí kì í ṣe Keresimesi! Kàkà bẹ́ẹ̀, àpèjúwe yẹn jẹ́ ti Saturnalia​—⁠àjọ̀dún ọlọ́sẹ̀ kan ti àwọn abọ̀rìṣà Romu èyí tí ó níí ṣe pẹ̀lú òpin ìgbà òtútù (tí a fi àwòrán rẹ̀ hàn ní ojú-ìwé òdìkejì). Ọjọ́-ìbí oòrùn tí a kò ṣẹ́gun ni a ṣayẹyẹ rẹ̀ ní December 25, ọjọ́ àjọyọ̀ pàtàkì fún ìsìn Mithra ti Romu.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ti sọ, “December 25, ọjọ́-ìbí Mithra, ọlọrun ìmọ́lẹ̀ ti àwọn ará Iran àti . . . ọjọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn tí kò ṣeé ṣẹ́gun, àti ọjọ́ tí ó tẹ̀lé Saturnalia, ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí i Keresimesi, ìbí Kristi, láti fi júujùu bo àwọn ìyọrísí àjọ̀dún náà lójú.” Nítorí náà ayẹyẹ ọjọ́-ìbí ti àwọn abọ̀rìṣà ń bá a nìṣó pẹ̀lú ìyípadà ráńpẹ́ nínú orúkọ tí a ń pè é, láti Mithra sí Kristi!

Bí ó ti wù kí ó rí, ìwọ lè ní ìmọ̀lára pé ìbí Jesu, Ọmọkùnrin Ọlọrun, jẹ́ ohun àkànṣe kan, tí ó yẹ láti rántí. Wíwo ohun tí Bibeli sọ nípa èyí yóò túbọ̀ lani lóye gidigidi.

Ìṣẹ̀lẹ̀ Aláyọ̀

Orí kejì nínú Ìhìnrere ti Luku sọ bí ọ̀ràn ti rí látilẹ̀wá. Luku sọ nípa bí àwọn áńgẹ́lì ọ̀run, àwọn olùṣọ́ àgùtàn rírẹlẹ̀, àwọn olùfọkànsìn ìránṣẹ́ Ọlọrun, àti Maria fúnraarẹ̀ ṣe hùwàpadà sí ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó yẹ fún àfiyèsí yìí.

Kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò “awọn olùṣọ́ àgùtàn . . . tí wọ́n ń gbé ní ìta” tí wọ́n “ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí awọn agbo-ẹran wọn ní òru,” èyí tí wọn kì bá tí ṣe nínú otútù nini. Nígbà tí “áńgẹ́lì Jehofa” farahàn tí ògo Ọlọrun sì tàn yí wọn ká, àwọn olùṣọ́ àgùtàn náà kọ́kọ́ bẹ̀rù. A fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nígbà tí áńgẹ́lì náà ṣàlàyé pé: “Ẹ má bẹ̀rù, nitori, wò ó! emi ń polongo fún yín ìhìnrere ti ìdùnnú-ayọ̀ ńlá kan tí gbogbo awọn ènìyàn yoo ní, nitori pé a bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Oluwa.” Nígbà tí “ògìdìgbó ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” ti àwọn áńgẹ́lì sì farahàn lójijì, àwọn olùṣọ́ àgùtàn náà mọ̀ pé ìbí yìí yàtọ̀ sí gbogbo èyí tí ó kù. Lọ́nà tí ó dùnmọ́ni, àwọn áńgẹ́lì náà kò mú ẹ̀bùn kankan wá fún ọmọdé jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn áńgẹ́lì náà yin Jehofa, ní sísọ pé: “Ògo fún Ọlọrun ní awọn ibi gíga lókè, ati lórí ilẹ̀-ayé àlàáfíà láàárín awọn ènìyàn ìfẹ́rere.”​—⁠Luku 2:​8-⁠14, NW.

Lọ́nà tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu, àwọn olùṣọ́ àgùtàn náà fẹ́ láti rí ọmọ-ọwọ́ náà fúnraawọn, nítorí pé Jehofa ni ó kéde ìṣẹ̀lẹ̀ aláyọ̀ náà. Nígbà tí wọ́n rí ọmọdé jòjòló náà níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí ní ibùjẹ ẹran, wọ́n sọ ohun tí áńgẹ́lì náà wí fún àwọn òbí rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni àwọn olùṣọ́ àgùtàn náà lọ kúrò níbẹ̀, “wọ́n ń fi ògo fún Ọlọrun wọ́n sì ń yìn ín,” kì í ṣe ọmọ-ọwọ́ náà.​—⁠Luku 2:​15-18, 20, NW.

Kò sí iyèméjì pé Maria, ìyá Jesu yọ̀ nítorí tí ó bí àkọ́bí rẹ̀ láyọ̀. Ṣùgbọ́n ó tún dé “ìparí èrò ninu ọkàn-àyà rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, òun àti ọkọ rẹ̀, Josefu, rìnrìn-àjò lọ sí Jerusalemu ní ìṣègbọràn sí Òfin Mose. Èyí kì í ṣe ayẹyẹ ọjọ́-ìbí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ àkókò láti fi ọmọdé jòjòló náà fún Ọlọrun, “gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ ninu òfin Jehofa pé: ‘Gbogbo akọ tí ó ṣí ilé ọlẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ pè ní mímọ́ fún Jehofa.’”​—⁠Luku 2:​19, 22-⁠24, NW.

Ní tẹ́ḿpìlì tí ó wà ní Jerusalemu, Maria àti Josefu bá Simeoni pàdé, ẹni tí Luku ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “olódodo ati ẹni tí ó ní ọ̀wọ̀ onífọkànsìn, tí ń dúró de ìrẹ̀lẹ́kún Israeli.” Lábẹ́ ìmísí, a ti sọ fún un pé kì yóò kú títí tí yóò fi rí “Kristi ti Jehofa.” Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tẹ̀lé e tún jẹ́ “lábẹ́ agbára ẹ̀mí [Ọlọrun].” Simeoni gbé ọmọdé jòjòló náà sọ́wọ́, rárá, kì í ṣe láti fún un ní ẹ̀bùn, ṣùgbọ́n, láti fi ìbùkún fún Ọlọrun, ní sísọ pé: “Nísinsìnyí, Oluwa Ọba-Aláṣẹ, iwọ ń jẹ́ kí ẹrú rẹ lọ lómìnira ní àlàáfíà ní ìbámu pẹlu ìpolongo rẹ; nitori ojú mi ti rí ohun àmúlò rẹ fún gbígbanilà tí iwọ ti pèsè sílẹ̀ lójú gbogbo awọn ènìyàn.”​—⁠Luku 2:​25-⁠32, NW.

Lẹ́yìn náà, Anna wòlíì obìnrin, arúgbó náà wá sí itòsí. Òun pẹ̀lú “bẹ̀rẹ̀ sí í dá ọpẹ́ padà sọ́dọ̀ Ọlọrun ó sì ń sọ̀rọ̀ nipa ọmọ naa fún gbogbo awọn wọnnì tí ń dúró de ìdáǹdè Jerusalemu.”​—⁠Luku 2:​36-⁠38, NW.

Maria, Simeoni, Anna, àwọn olùṣọ́ àgùtàn, àti àwọn áńgẹ́lì ọ̀run, ni gbogbo wọn yọ̀ nítorí tí a bí Jesu. Bí ó ti wù kí ó rí, jọ̀wọ́ kíyèsi pé wọn kò fi ara wọn fún àríyá aláriwo ti ọjọ́-ìbí, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lọ́wọ́ nínú fífúnni ní ẹ̀bùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n yin Jehofa lógo, Olùpèsè ti òkè ọ̀run tí ó pèsè ọ̀nà àti rí ìgbàlà fún wọn.

Síbẹ̀, àwọn kan lè ronú pé, ‘Dájúdájú fífúnni ní ẹ̀bùn ní ìgbà Keresimesi kò lè lòdì, ṣe “àwọn amòye mẹ́ta” náà kò fi ẹ̀bùn bọlá fún Jesu ni?’

Àwọn Ẹ̀bùn Keresimesi

Ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ inú Bibeli lẹ́ẹ̀kan sí i. Ìwọ yóò rí i bí a ti kọ ọ́ sínú Ìhìnrere ti Matteu, orí 2 (NW). A kò mẹ́nukan ayẹyẹ ọjọ́-ìbí kankan, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò fúnni ní déètì pàtó kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó farahàn pé ó jẹ́ ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ìbí Jesu. Ní ẹsẹ̀ 1, Matteu pe àwọn àlejò náà ní “awọn awòràwọ̀ [Griki, maʹgoi] lati awọn apá ìlà-oòrùn wá,” nípa bẹ́ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ abọ̀rìṣà tí kò ní ìmọ̀ Jehofa Ọlọrun. Ìràwọ̀ tí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tẹ̀lé kò darí wọn tààràtà lọ sí ibi tí a bí Jesu sí ní Betlehemu, bíkòṣe ibi tí Ọba Herodu ti ń ṣàkóso ní Jerusalemu.

Nígbà tí alákòóso búburú yìí gbọ́ tí wọ́n ń béèrè nípa “ẹni naa tí a bí ní ọba awọn Júù,” ó fọ̀rànlọ àwọn àlùfáà láti wádìí “ibi tí a óò ti bí Kristi” ní pàtó kí ó baà lè pa ọmọ náà. Àwọn àlùfáà náà dáhùn nípa fífa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Mika yọ èyí tí ó fihàn pé Betlehemu ni a óò bí Messia sí. (Mika 5:2) Herodu fi ìwà àgàbàgebè fún àwọn àlejò rẹ̀ ní ìtọ́ni pé: “Ẹ lọ fẹ̀sọ̀ wá ọmọ kékeré naa káàkiri, nígbà tí ẹ bá sì ti rí i kí ẹ padà ròyìn fún mi, kí emi naa lè lọ kí n sì wárí fún un.” Àwọn awòràwọ̀ náà ń bá ọ̀nà wọn lọ, ìràwọ̀ náà sì “ń lọ níwájú wọn, títí ó wá fi dúró lókè ibi tí ọmọ kékeré naa wà.” Kíyèsi pé a ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ọmọ kékeré,” kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ-ọwọ́ àṣẹ̀ṣẹ̀bí.​—⁠Matteu 2:​1-⁠10, NW.

Gẹ́gẹ́ bí ohun yíyẹ fún àwọn ẹni-ọlá ará Gábàsì tí ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ alákòóso kan, àwọn awòràwọ̀ abọ̀rìṣà náà wólẹ̀ wọ́n sì “fún [ọmọ kékeré náà] ní awọn ẹ̀bùn, wúrà ati oje igi tùràrí ati òjíá.” Matteu fikún un pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, nitori a fún wọn ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá ninu àlá lati máṣe padà sọ́dọ̀ Herodu, wọ́n fi ibẹ̀ sílẹ̀ gba ọ̀nà mìíràn lọ sí ẹkùn-ìpínlẹ̀ wọn.”​—⁠Matteu 2:​11, 12, NW.

Láti inú ìròyìn Ìwé Mímọ́ ṣókí yìí, àwọn ènìyàn kan lè gbìdánwò láti wá ìtìlẹ́yìn fún ẹ̀bùn tí wọ́n ń fi fúnni nígbà Keresimesi. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìwé náà Discovering Christmas Customs and Folklore ṣàlàyé pé àṣà lọ́wọ́lọ́wọ́ náà ti fífúnni ní àwọn ẹ̀bùn fi gbòǹgbò rẹ̀ múlẹ̀ nínú ẹ̀bùn Saturnalia tí àwọn ará Romu ń fifún àwọn aládùúgbò wọn tí wọ́n tòṣì. “Ṣọ́ọ̀ṣì ìjímìjí . . . fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lọ́ ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ mọ́ rírántí ẹ̀bùn àwọn Afìràwọ̀mòye lọ́nà ààtò-àṣà lọ́rùn.” Ẹ wo bí èyí ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ tó​—⁠irú bí àwọn olùṣọ́ àgùtàn rírẹlẹ̀ náà⁠—​tí wọ́n wulẹ̀ fi ìyìn fún Ọlọrun nígbà ìbí Jesu!

Bọlá fún Jesu Gẹ́gẹ́ Bí Ọba!

Jesu kì í tún ṣe ọmọdé mọ́ lónìí. Òun jẹ́ alágbára Ọba Olùṣàkóso, Ọba Ìjọba Ọlọrun lókè ọ̀run, a sì níláti bọlá fún un lọ́nà bẹ́ẹ̀.​—⁠1 Timoteu 6:​15, 16.

Bí ìwọ bá ti dàgbà nísinsìnyí, a ha ti mú ara tì ọ́ rí nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi fọ́tò ìgbà tí ó wà ní ọmọ-ọwọ́ hàn, níṣojú rẹ? Lóòótọ́, irú àwòrán bẹ́ẹ̀ ń rán àwọn òbí rẹ létí ayọ̀ wọn nígbà tí wọ́n bí ọ. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ìwọ jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀ kan, ìwọ kì yóò ha fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn rí ọ gẹ́gẹ́ bí o ṣe jẹ́ bí? Ní ọ̀nà kan náà, ronú nípa bí ó ṣe jẹ́ àìfi ọ̀wọ̀ hàn fún Kristi Jesu tó nígbà tí àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́wọ́ jíjẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bá fi ara fún àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ abọ̀rìṣà ti Keresimesi tóbẹ́ẹ̀ lọ́dọọdún àti fún bíbọlá fún ọmọdé jòjòló kan tí wọ́n kùnà láti bọlá fún gẹ́gẹ́ bí Ọba. Họ́wù, àní ní ọ̀rúndún kìn-⁠ín-ní pàápàá, Kristian aposteli Paulu ronú lórí bí ó ṣe jẹ́ ohun yíyẹ tó láti máa ronú nípa Kristi gẹ́gẹ́ bí òun ti wà nísinsìnyí​—⁠Ọba kan ní ọ̀run. Paulu kọ̀wé pé: “Bí awa tilẹ̀ ti mọ Kristi nipa ti ẹran-ara, dájúdájú awa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́ nísinsìnyí”!​—⁠2 Korinti 5:16, NW.

Kò ní pẹ́ mọ́ tí Kristi, gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọrun, yóò fi mú kí ìlérí alásọtẹ́lẹ̀ náà láti mú ìrora, ìjìyà, òkùnrùn àti ikú kúrò di ṣíṣẹ. Òun ni Ẹni náà tí yóò rí sí i pé ilé gbígbé àti iṣẹ́ tí ń mú èrè wá wà fún gbogbo ènìyàn lábẹ́ àwọn ipò Paradise níhìn-⁠ín lórí ilẹ̀-ayé. (Isaiah 65:​21-⁠23; Luku 23:43; 2 Korinti 1:20; Ìṣípayá 21:​3, 4) Dájúdájú, ìwọ̀nyí ti tó ìdí tí a fi níláti yẹra fún títa àbùkù sí Jesu!

Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ ti Kristi fúnraarẹ̀, àwọn Kristian tòótọ́ ń làkàkà láti fún àwọn aládùúgbò wọn tòótọ́ ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn dídára jùlọ tí ẹnikẹ́ni lè fifúnni​—⁠òye nípa ète Ọlọrun, èyí tí ó lè sinni lọ sí ìyè ayérayé. (Johannu 17:3) Irú ẹ̀bùn fífúnni yìí ń mú ìdùnnú púpọ̀ wá fún wọn, àní gẹ́gẹ́ bí Jesu pàápàá ti ṣe: “Ayọ̀ púpọ̀ wà ninu fífúnni ju èyí tí ó wà ninu rírígbà lọ.”​—⁠Iṣe 20:35; Luku 11:​27, 28, NW.

Kò ṣòro rárá fún àwọn Kristian tí wọ́n ní ojúlówó ọkàn-ìfẹ́ nínú araawọn láti fi ìfẹ́ wọn hàn nígbàkigbà nínú ọdún. (Filippi 2:​3, 4) Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ rírọrùn kan, ẹ wo bí yóò ti gbádùnmọ́ni tó láti rí àwòrán kan gbà láti ọwọ́ ọ̀dọ́ Kristian kan ẹni tí ó yà á lẹ́yìn fífetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀-àsọyé Bibeli kan gẹ́gẹ́ bíi fífi ìdúpẹ́ hàn! Èyí tí ó tún ń fúnni ní ìṣírí bí èyí ni ti ẹ̀bùn àìròtẹ́lẹ̀ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ ìdílé kan gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìfẹ́ ẹni náà. Bákan náà, àwọn Kristian òbí tún ń jèrè ìdùnnú púpọ̀ nígbà tí wọ́n bá yan àwọn àkókò tí ó yẹ nínú ọdún láti fún àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀bùn. Irú ẹ̀mí-ọ̀làwọ́ Kristian yìí ni a kì í kó èérí bá nípasẹ̀ ìfojúsọ́nà fún ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ojúṣe ẹni ní àwọn ọjọ́ ayẹyẹ tàbí nípasẹ̀ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ abọ̀rìṣà.

Nítorí náà, lónìí iye tí ó rékọjá million mẹ́rin àti ààbọ̀ àwọn Kristian láti orílẹ̀-èdè gbogbo wá kì í ṣe ayẹyẹ Keresimesi. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, tí wọ́n máa ń mú ọwọ́ araawọn dí déédéé nípa jíjẹ́rìí fún àwọn aládùúgbò wọn nípa ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun. (Matteu 24:14) Ó ṣeé ṣe kí o bá wọn pàdé nígbà tí wọ́n bá ṣèbẹ̀wò sí ilé rẹ, bóyá láìpẹ́. Ǹjẹ́ kí fífi tí o bá fí ìháragàgà gba ohun tí wọ́n bá mú wá fún ọ ṣamọ̀nà ìdílé rẹ sí ìdùnnú ńlá, bí o ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí o ṣe lè fi ìyìn fún Jehofa Ọlọrun ní gbogbo ọjọ́ tí ń bẹ nínú ọdún.​—⁠Orin Dafidi 145:​1, 2.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Kristian ń fún àwọn aládùúgbò wọn ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀bùn títóbi jùlọ tí a lè fúnni​—⁠òye nípa ète Ọlọrun tí ń sinni lọ sí ìyè ayérayé

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Culver Pictures

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́