Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .
Kí Nìdí Tí Àwọn Kan Kì Í Fi í Ṣe Kérésìmesì?
▪ Kárí ayé, àwọn èèyàn tí ó tó nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì ló ń ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì lọ́dọọdún ní December 25. Igba [200] mílíọ̀nù ó kéré tán ń ṣe ọjọ́ ìbí Jésù Kristi ní January 7 lọ́dọọdún. Síbẹ̀, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni kì í ṣe ọdún Kérésìmesì rárá. Kí nìdí?
Àwọn kan lára wọn lè máà jẹ́ ẹni tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè jẹ́ ẹlẹ́sìn Júù, Híńdù tàbí Ṣintó. Àwọn míì sì gbà pé ìtàn àròsọ lásán ni Kérésì, irú bí àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà àti àwọn tó gbà pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀.
Àmọ́ ṣá o, àwùjọ èèyàn kan ṣì wà tó gba Jésù gbọ́ síbẹ̀ tí wọn kò fara mọ́ ṣíṣe ayẹyẹ Kérésì. Kí nìdí? Wọ́n máa ń tọ́ka sí ìdí mẹ́rin ó kéré tán.
Ìdí àkọ́kọ́, wọn kò gbà pé oṣù December tàbí January ni wọ́n bí Jésù. Ṣé ẹ rí i, Bíbélì kò sọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù gan-an. Ohun tó kàn sọ ni pé: “Àwọn olùṣọ́ àgùntàn pẹ̀lú wà ní ìgbèríko kan náà, tí wọ́n ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru. Lójijì, áńgẹ́lì Jèhófà dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn . . . áńgẹ́lì náà wí fún wọn pé: ‘. . . A bí Olùgbàlà kan fún yín lónìí, ẹni tí í ṣe Kristi Olúwa.’”—Lúùkù 2:8-11.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí fi hàn pé ìbẹ̀rẹ̀ oṣù October, nígbà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń wà nínú pápá pẹ̀lú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lóru mọ́jú, ló jọ pé wọ́n bí Jésù. Oṣù December àti January tí yìnyín máa ń bolẹ̀ ní gbogbo àgbègbè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni òtútù máa ń mú jù. Lásìkò yìí, inú ilé ẹran ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń kó ẹran ọ̀sìn wọn sí dípò ìta gbangba kí òtútù máa bàa pa wọ́n dà nù.
Ìdí kejì: Ohun tí Jésù dìídì sọ pé kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣe ni ìrántí ikú rẹ̀, kì í ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ohun tó ní kí wọ́n ṣe kò sì la afẹfẹyẹ̀yẹ̀ lọ, búrẹ́dì àti wáìnì nìkan ló ní kí wọ́n máa lò. (Lúùkù 22:19, 20) Tún kíyè sí i pé, ìwé Ìhìn Rere Máàkù àti Jòhánù kò sọ nǹkan kan nípa bí wọ́n ṣe bí Jésù.
Ìdí kẹta: Kò sí ẹ̀rí kankan nínú ìtàn tó fi hàn pé àwọn Kristẹni ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Kristi. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe ìrántí ikú rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:23-26) Ó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bí Jésù kí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì ní December 25. Kódà, ní nǹkan bí irínwó ọdún sẹ́yìn, ìjọba fòfin de ṣíṣe ayẹyẹ Kérésìmesì ní ilẹ̀ England. Ní Amẹ́ríkà, ìgbìmọ̀ aṣòfin orílẹ̀-èdè náà, tó wà ní Massachusetts ṣe ohun kan náà. Kí nìdí? Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa Kérésìmesì, ìyẹn The Battle for Christmas, sọ pé: “Kò sí ìdí kankan tó bá ìtàn tàbí Bíbélì mu tí ẹnikẹ́ni fi lè sọ pé December 25 ni wọ́n bí Jésù.” Ìwé yẹn tún ṣàlàyé pé, ṣe ni àwọn tó ń ṣe àfọ̀mọ́ ẹ̀sìn láyé àtijọ́ gbà pé “Kérésìmesì jẹ́ ọdún àwọn abọ̀rìṣà tí wọ́n kàn dọ́gbọ́n pè ní ọdún àwọn Kristẹni.”
Ìdí kẹrin sì ni pé: Ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ni àjọ̀dún náà ti bẹ̀rẹ̀. Tí a bá tọ ipasẹ̀ rẹ̀, a ó rí i pé ọ̀dọ̀ àwọn abọ̀rìṣà ilẹ̀ Róòmù ni ó ti ṣẹ̀ wá. Àjọ̀dún tí wọ́n fi ń júbà òrìṣà àwọn àgbẹ̀, ìyẹn Sátọ̀n àti èyí tí wọ́n fi ń júbà òrìṣà oòrùn, ìyẹn Mithra, ni wọ́n sọ di ọdún Kérésì. Àwọn méjì kan tó jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn, Christian Rätsch àti Claudia Müller-Ebeling, sọ nínú ìwé tí wọ́n jọ kọ láti fi ṣàlàyé pé Kérésìmesì jẹ́ ọdún abọ̀rìṣà, wọ́n ní: “Ohun tí wọ́n ṣe sí ọ̀pọ̀ àṣà ìbílẹ̀ àti ìsìn tó ti wà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé náà ni wọ́n tún ṣe, wọ́n sọ àjọ̀dún àtijọ́ tí wọ́n fi ń ṣe ọdún ìgbà tí oòrùn máa ń pa dà yọjú lẹ́yìn ìgbà òtútù di àjọ̀dún ọjọ́ ìbí Kristi.”—Pagan Christmas.
Nítorí náà, ṣé o ti wá rí ìdí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
Ohun tí Jésù dìídì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa ṣe ni ìrántí ikú rẹ̀, kì í ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀
Àṣeyẹ kan ṣoṣo tí Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa rántí ní ikú rẹ̀, kìí ṣe ìbí rẹ̀