‘Òtítọ́ Yóò Dá Yín Sílẹ̀ Lómìnira’!
ÒTÍTỌ́ tí kò ṣeé já ní koro ni ọ̀rọ̀ tí Jésù Kristi sọ yìí, tó wà ní Jòhánù 8:32. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí máa ń dá wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àtàwọn àṣà tí kò múnú Ọlọ́run dùn tó sì lè ṣàkóbá fún wa. Àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé e yìí láti onírúurú ilẹ̀ jẹ́ ká mọ bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe dá àwọn èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àṣà tó jẹ́ ẹrù ìnira tó máa ń wáyé nígbà ọdún Kérésì.
Ẹ̀kọ́ Bíbélì Sọ Wọ́n Di Òmìnira
Ajẹntínà Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Oscar sọ pé: “Ẹ̀kọ́ Bíbélì ti sọ ìdílé wa dòmìnira lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó máa ń wá látinú jíjẹ àjẹjù àti mímu ọtí àmuyíràá, ó sì tún gbà wá lọ́wọ́ gbèsè nítorí àtira ẹ̀bùn tí owó wa kò ká.”
Ará tu Mario gan-an nígbà tó wá mọ àṣírí irọ́ tí wọ́n ti máa ń pa fún un nípa ọdún Kérésìmesì. Ó sọ pé: “Ní báyìí, inú mi máa ń dùn pé mo lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé mo mọyì wọn nípa fífún wọn lẹ́bùn nígbàkigbà láàárín ọdún lásìkò tí agbára mi bá gbé e.”
Kánádà Obìnrin kan tó ń jẹ́ Elfie kọ̀wé pé: “Mo fẹ́ràn kí n máa fún àwọn èèyàn ní ẹ̀bùn, mo sì máa ń fẹ́ láti gba ẹ̀bùn, àmọ́ mi ò rí sí ká máa fi tipátipá fúnni lẹ́bùn. Nígbà tó di pé a ò ṣọdún Kérésì mọ́ nínú ìdílé wa, ńṣe ni ìtura dé bá gbogbo wa!”
Ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Elfie tó ń jẹ́ Ulli sọ pé: “Nígbà tí àwọn òbí mi kò ṣe ọdún Kérésì mọ́, wọ́n máa ń ṣe oríṣiríṣi nǹkan amóríyá fún wa tàbí kí wọ́n fún wa lẹ́bùn nígbà tá ò tiẹ̀ rò rárá láàárín ọdún, a sì máa ń gbádùn rẹ̀ gan-an! Bí àwọn ọmọ kíláàsì wa bá béèrè lọ́wọ́ wa pé kí ló dé táwọn òbí wa fi fún wa lẹ́bùn, inú wa máa ń dùn láti sọ fún wọn pé, ‘Wọ́n kàn fún wa ni!’ Àmọ́, nígbà táwọn òbí wa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n sì yí ìgbésí ayé wọn pa dà, nǹkan ò rọrùn rárá, torí pé àwọn èèyàn ṣe inúnibíni sí wọn, wọ́n sì fínná mọ́ wọn. Ṣùgbọ́n wọn kò torí ìyẹn yí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ pa dà. Bí wọ́n ṣe rọ̀ mọ́ ìpinnu wọn láti sin Jèhófà Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ mú kó wu èmi náà láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn.”
Nígbà tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Silvia jáwọ́ nínú ṣíṣe ọdún Kérésì, ó sọ pé: “Ara tù mí gan-an ni. Látìgbà náà, inú mi máa ń dùn gan-an! Mo mọ̀ pé ohun tí inú Jèhófà Ọlọ́run dùn sí ni mò ń ṣe, ìyẹn sì ń mú ayọ̀ wá fún mi ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún Kérésì lọ.”
Kẹ́ńyà Ọkùnrin kan tó ń jẹ Peter kọ̀wé pé: “Nígbà tí mo ṣì máa ń ṣọdún Kérésì, mo máa ń yáwó gan-an kí n lè ra àwọn ẹ̀bùn, kí n sì lè sanwó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tí mo bá rà. Torí èyí, ó di dandan kí n máa ṣe àfikún iṣẹ́, èyí sì máa ń mú kí n fi ìdílé mi sílẹ̀. Àmọ́, inú mi dùn gan-an pé mo ti bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ìyẹn báyìí!”
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Carolyne sọ pé: “Ìgbàkigbà ni mo máa ń fún tẹbí tọ̀rẹ́ lẹ́bùn, àwọn náà sì máa ń fún mi lẹ́bùn. Mo gbà gbọ́ pé irú ẹ̀bùn téèyàn ò retí bẹ́ẹ̀, tó ti ọkàn wá, ló dára jù lọ.”
Japan Tọkọtìyàwó kan tó ń jẹ́ Hiroshi àti Rie sọ pé: “A dúpẹ́ pé àwọn ọmọ wa kì í retí ẹ̀bùn, wọn kì í sì í gba ẹ̀bùn láì mọyì rẹ̀. Inú wa dùn pé a ti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé fífúnni lẹ́bùn gbọ́dọ̀ jẹ́ látọkàn wá.”
Obìnrin kan tó ń jẹ́ Keiko sọ pé: “Nígbà kan, a máa ń ṣọdún Kérésì nínú ìdílé wa. Bá a bá ti rí i pé ọmọ wa ọkùnrin ti sùn, èmi àti ọkọ mi á rọra fi ẹ̀bùn kan sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùsùn rẹ̀. Tó bá wá di àárọ̀ ọjọ́ kejì, a máa ń sọ fún un pé: ‘Bàbá Kérésì ló fún ẹ lẹ́bùn yìí, torí pé ọmọ dáadáa ni ẹ́.’ Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí mo sì sọ ohun tí mo kọ́ fún ọmọ mi, ẹnú yà á gan-an, ó sì sunkún. Ìgbà yẹn gan-an ni mo wá mọ̀ pé Kérésìmesì kì í ṣe ohun dáadáa táwọn èèyàn rò pé ó jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, irọ́ lásán ni. Ńṣe ni mo sì ń tan ọmọ mi jẹ́ bí mo ṣe ń gbé irọ́ yẹn lárugẹ.”
Philippines Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Dave sọ pé: “Ìdùnnú tí Jèhófà ń fún wa nítorí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá à ń kọ́ látinú Bíbélì kọjá àfẹnusọ. Nínú ìdílé wa, tá a bá fún àwọn kan lẹ́bùn, a kì í retí ohunkóhun pa dà látọ̀dọ̀ wọn mọ́. Bákan náà, tọkàntọkàn la fi ń fún àwọn èèyàn lẹ́bùn.”
Àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí wulẹ̀ jẹ́ díẹ̀ lára ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tí wọ́n ti rí i látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn fúnra wọn pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì máa ń sọni dòmìnira. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, tá a bá jẹ́ kí òtítọ́ yẹn máa darí ìgbésí ayé wa, a ó máa múnú Jèhófà dùn. (Òwe 27:11) Jésù Kristi sọ pé: “Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Bí Ọlọ́run bá ṣàyẹ̀wò ọkàn rẹ, ǹjẹ́ ó máa rí i pé ó wù ẹ́ gan-an láti mọ òtítọ́? A nírètí pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìfẹ́ máa ń mú káwọn Kristẹni fúnni lẹ́bùn nígbàkigbà láàárín ọdún