ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 28-29
  • Ǹjẹ́ Ìgbàgbọ́ àti Àròjinlẹ̀ Bára Tan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ìgbàgbọ́ àti Àròjinlẹ̀ Bára Tan?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbàgbọ́ Tá A Gbé Karí Àròjinlẹ̀
  • Bó O Ṣe Lè Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Bíbélì
  • Ìgbàgbọ́ Tòótọ́—Kí Ló Jẹ́?
    Jí!—2000
  • Lo Igbagbọ Ti A Gbekari Otitọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìgbàgbọ́
    Jí!—2016
  • Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 28-29

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Ìgbàgbọ́ àti Àròjinlẹ̀ Bára Tan?

ỌMỌ ilẹ̀ Britain kan tó jẹ́ onímọ̀ ọgbọ́n orí tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ A.  C. Grayling, sọ pé: “Kò sí àròjinlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣàkópọ̀ èrò ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn òǹkọ̀wé àti àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tí wọ́n gbà láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn pé ìgbàgbọ́ àti àròjinlẹ̀ kò bára tan.

Ohun táwọn onísìn kan gbà gbọ́ kò bọ́gbọ́n mu rárá. Àmọ́ gbé èyí yẹ̀ wò ná: Ọ̀pọ̀ nǹkan tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà gbọ́ nígbà kan rí ti wá di ohun tí kò tọ̀nà mọ́ báyìí. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé gbogbo ohun tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà gbọ́ ni kò tọ̀nà tàbí tí wọn kò ro àròjinlẹ̀ nípa rẹ̀? Kí ló wá dé tá a fi wá ń fi ojú tó yàtọ̀ wo ohun tí àwọn ẹ̀sìn fi ń kọ́ni? Ká sòótọ́, èèyàn kò lè ní ìgbàgbọ́ tí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ láìjẹ́ pé ó ní ìmọ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ìmọ̀ àti àròjinlẹ̀ ló máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ yẹn lágbára. Bó o ṣe ń gbé àwọn ẹ̀rí náà yẹ̀ wò, wo bí ìgbàgbọ́ tòótọ́ àti àròjinlẹ̀ ṣe bára wọn tan.

Ìgbàgbọ́ Tá A Gbé Karí Àròjinlẹ̀

Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé bó o bá fẹ́ kí ìjọsìn rẹ “ṣe ìtẹ́wọ́gbà” lójú Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ ṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò” rẹ. A tún lè sọ ọ́ báyìí pé o gbọ́dọ̀ jọ́sìn Ọlọ́run “ní ọ̀nà tó yẹ ẹ̀dá tó nírònú.” (Róòmù 12:1; The Jerusalem Bible) Torí náà, ìgbàgbọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ rẹ̀ kì í ṣe ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí kò sì bọ́gbọ́n mu tàbí ìgbàgbọ́ tí kò ṣeé fi ẹ̀rí tì lẹ́yìn, bí àwọn kan ṣe pè é. Kì í sì í ṣe ìgbàgbọ́ oréfèé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ohun kan tó o ti fara balẹ̀ ronú nípa rẹ̀, tó sì jẹ́ kó o fọkàn tán Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àròjinlẹ̀ ló sì jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe.

Lóòótọ́ o, tó o bá máa ronú lọ́nà tó tọ́, o nílò ìsọfúnni tó péye. Kódà, kọ̀ǹpútà tó lágbára jù lọ tí wọ́n ti fi àwọn ìlànà gidi tó gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé sínú rẹ̀ lè yọ ọwọ́kọ́wọ́ bí wọ́n bá fi ìsọfúnni tí kò péye sórí rẹ̀. Bákan náà, bí ìgbàgbọ́ rẹ ṣe máa jinlẹ̀ tó sinmi lórí ohun tó o bá gbọ́ tàbí bí ìsọfúnni tó o gbọ́ ṣe jẹ́ èyí tó ṣeé gbára lé tó. Ó bá a mu bí Bíbélì ṣe sọ pé, “ìgbàgbọ́ ń tẹ̀ lé ohun tí a gbọ́.”—Róòmù 10:17.

Ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn tó lè ní ìgbàgbọ́ ni “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:4) “Òtítọ́” nìkan ni Bíbélì sọ pé ‘yóò dáni sílẹ̀,’ lómìnira kúrò nínú àwọn ìgbàgbọ́ tó ń ṣini lọ́nà, yálà èyí tó dá lórí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tàbí ti ẹ̀sìn. (Jòhánù 8:32) Bíbélì kìlọ̀ pé kó o má ṣe ní ìgbàgbọ́ “nínú gbogbo ọ̀rọ̀.” (Òwe 14:15) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé kó o “wádìí ohun gbogbo dájú” tàbí kó o dán ohun tó o gbọ́ wò kó tó di pé o gbà á gbọ́. (1 Tẹsalóníkà 5:21) Kí nìdí tó o fi ní láti ṣe ìwádìí, kó o sì tún dán ohun tó o gbà gbọ́ wò? Ìdí ni pé ìgbàgbọ́ tó dá lórí ẹ̀tàn máa ń ṣini lọ́nà. Àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn títọ́ ní ìlú Bèróà láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tó bá dọ̀rọ̀ ká gba ohun kan gbọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn yìí fẹ́ láti gba ohun tí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì kọ́ wọn gbọ́, wọ́n fi ṣe àfojúsùn wọn láti máa “ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.”—Ìṣe 17:11.

Bó O Ṣe Lè Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Bíbélì

Tó bá wá jẹ́ pé kò dá ẹ lójú bóyá Bíbélì ṣe é gbára lé ńkọ́? Báwo lo ṣe lè jẹ́ kó túbọ̀ dá ẹ lójú pé inú Bíbélì lo ti lè rí ìmọ̀ pípéye? Báwo lo ṣe máa ń mọ̀ pé àwọn èèyàn kan ṣeé fọkàn tán? Ó dájú pé nípa mímọ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dáadáa ni, ìyẹn ni pé wàá wo bí wọ́n ṣe ń hùwà fún àwọn àkókò kan, wàá sì rí bí ìwà wọn ṣe rí. Kí ló dé tí o kò fi ṣe ohun kan náà nípa Bíbélì?a

Bíbélì sọ pé ìgbàgbọ́ jẹ́ “ìfojúsọ́nà tí ó dáni lójú nípa àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba-gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” (Hébérù 11:1) Ó ṣe kedere pé, ẹni tó ní ìgbàgbọ́ tòótọ́ kì í ṣe òpè, kàkà bẹ́ẹ̀ ó ti gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ karí àwọn ìwádìí tó fara balẹ̀ ṣe nípa àwọn ìsọfúnni tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Téèyàn bá ronú lórí irú àwọn ìsọfúnni yẹn, ó máa jẹ́ kí èèyàn ní ìdánilójú pé àwọn nǹkan téèyàn ò lè fi ojú rí pàápàá jẹ́ ohun gidi.

Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé, ó jọ pé àwọn nǹkan tó o kọ́ ta ko àwọn ohun tó o ti gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ ńkọ́? Ṣé ó wá yẹ kó o fojú pa á rẹ́ ni? Rárá o. Àwọn ìgbà míì máa wà tó jẹ́ pé ó mọ́gbọ́n dání gan-an pé kó o gbé àwọn ẹ̀rí lílágbára tó jọ pé ó ta ko ohun tó o gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ yẹ̀ wò. Nínú Bíbélì, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa san èrè fún àwọn tó wá òtítọ́ nípa jíjẹ́ kí wọ́n ní ìmọ̀, ìfòyemọ̀ àti agbára láti ronú.—Òwe 2:1-12.

Ìgbàgbọ́ tá a gbé karí ohun tí Bíbélì kọ́ni àti àròjinlẹ̀ bára tan. Irú ìgbàgbọ́ wo lo ní? Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé ohun tí wọ́n bá lọ́wọ́ àwọn òbí wọn ni wọ́n gbà gbọ́, wọn ò sì tíì fìgbà kan rí ṣàyẹ̀wò rẹ̀ nípa ríro àròjinlẹ̀. Síbẹ̀, kì í ṣe ìwà ọ̀yájú láti ṣàyẹ̀wò ohun tó o gbà gbọ́, kó o lè “ṣàwárí fúnra” rẹ pé ìrònú rẹ bá ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. (Róòmù 12:2) Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé ká “dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (1 Jòhánù 4:1) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà tí àwọn èèyàn bá wá béèrè ìbéèrè nípa ohun tó o gbà gbọ́ lọ́wọ́ rẹ, á ṣeé ṣe fún ẹ “láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ [rẹ] ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú” rẹ.—1 Pétérù 3:15.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́ lórí bí wàá ṣe rí àwọn ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé nípa Bíbélì, kọ̀wé sí àwọn tó ṣe ìwé ìròyìn yìí.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Ǹjẹ́ Bíbélì dẹ́bi fún ríro àròjinlẹ̀?—Róòmù 12:1, 2.

● Irú ìmọ̀ wo ló ṣe pàtàkì láti ní, tó o bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ tòótọ́?—1 Tímótì 2:4.

● Kí la lè rí kọ́ látinú ìtumọ̀ tí Bíbélì fún ìgbàgbọ́?—Hébérù 11:1.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

Ọlọ́run máa ń san èrè fún àwọn tó bá ń fi taratara wá òtítọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́