ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 21-23
  • Ohun Tó Lè Dáàbò Bo Àwọn Àgbàlagbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Lè Dáàbò Bo Àwọn Àgbàlagbà
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Ní Okun àti Ìlera Tó Dára
  • Mú Kí Ilé Rẹ Jẹ́ Ibi Tí Kò Séwu
  • Ohun Tí Àwọn Ẹlòmíì Lè Ṣe
  • Jèhófà Ń Ṣìkẹ́ Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Tó Jẹ́ Àgbàlagbà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ṣé O Máa Ń Ṣe Eré Ìmárale Tó Bó Ṣe Yẹ?
    Jí!—2005
  • Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Àgbàlagbà Tó Wà Láàárín Yín
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Àwọn Ìdílé Kristian Ń Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 21-23

Ohun Tó Lè Dáàbò Bo Àwọn Àgbàlagbà

BÍ ỌMỌBÌNRIN kan ṣe fẹ́ gun pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, ó fẹsẹ̀ kọ, ó sì ṣubú. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ó ti dìde ó sì gbọnra nù. Gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ kò ju pé ojú kàn tì í díẹ̀ lọ. Màmá àgbàlagbà kan yọ̀ ṣubú nínú ilé rẹ̀, ìbàdí rẹ̀ sì yẹ̀. Ó ní láti ṣe iṣẹ́ abẹ, ó sì lo ọ̀pọ̀ oṣù nibi tí wọ́n ti ń to ara. Ní báyìí, ẹ̀rù wá túbọ̀ ń bà á, kò fẹ́ ṣe nǹkan tó lágbára, kò sì lókun mọ́.

Ní ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ayé, lọ́dọọdún, ó ju ìdá mẹ́ta àwọn tó ti tó ẹni ọdún márùndínláàádọ́rin [65] àtàwọn tọ́jọ́ orí wọn jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n máa ń ṣubú. Láfikún sí i, ṣíṣubú tí àwọn tó wà lọ́jọ́ orí yẹn máa ń ṣubú ló ń fa ìpalára tó máa ń yọrí sí ikú fún wọn. Abájọ tí Bíbélì fi sọ nípa àwọn àgbàlagbà pé: “Wọ́n ti fòyà ohun tí ó ga, àwọn ohun ìpayà sì wà ní ọ̀nà.”—Oníwàásù 12:5.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ogbó máa ń jẹ́ kéèyàn ní àwọn ìṣòro kan, síbẹ̀ o lè ṣe àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kó o máa fara pa, táá sì jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ dára sí i. Lọ́nà kan, o lè sapá láti ní ìlera àti okun tó dára dé ìwọ̀n àyè kan. Lọ́nà kejì, o lè ṣe àwọn ohun tí kò ní jẹ́ kí àwọn ohun tó lè ṣeni léṣe wà ní ilé rẹ.

Bó O Ṣe Lè Ní Okun àti Ìlera Tó Dára

Bá a ṣe ń dàgbà sí i, àwọn ẹ̀yà ara wa lè má ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́, ojú lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bàìbàì, kéèyàn má sì rántí nǹkan dáadáa mọ́. Àárẹ̀ ara lè túbọ̀ máa pọ̀ sí i nítorí ìṣàn àti eegun tó ti ń daṣẹ́ sílẹ̀. Àmọ́, èèyàn lè má tètè darúgbó tó bá ń ṣe eré ìmárale déédéé, tó sì ń jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore. Dókítà kan tó máa ń to ara tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nita sọ pé: “Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe àwọn eré ìmárale tó máa jẹ́ kára èèyàn le, tó máa jẹ́ kí ìrísí ẹni dáa, kéèyàn lókun nínú, kí ara èèyàn sì rọ̀.

Ìwé kan tí Iléeṣẹ́ Ìjọba Amẹ́ríkà Tó Ń Bójú Tó Ìlera àti Ìpèsè fún Aráàlú ṣe sọ pé: “Láìka bí ìlera àwọn àgbàlagbà àti okun wọn ṣe rí, wọ́n lè jàǹfààní gan-an tí wọn kì í bá jókòó sójú kan. Kódà tó bá ṣòro fún ẹ láti dúró tàbí láti máa rìn kiri, ṣíṣe eré ìmárale ṣì lè ṣe ẹ́ láǹfààní. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ìgbà tí o kò bá ṣe eré ìmárale lò ń ṣe ìpalára tó pọ̀ fún ara rẹ.”a Láfikún sí i, tí o kì í bá jókòó gẹlẹtẹ sójú kan, ìyẹn lè gbà ẹ́ lọ́wọ́ àrùn ọkàn, kí oríkèé ara máa roni, àrùn tí ń sọ egungun di hẹ́gẹhẹ̀gẹ àti ìsoríkọ́. Ó lè mú kí ẹ̀jẹ̀ túbọ̀ máa ṣàn kiri lára rẹ, kí oúnjẹ tètè máa dà, kó o máa sùn dáadáa, kó o túbọ̀ lè máa ṣe nǹkan láìbẹ̀rù, kó o sì wà lójúfò.

Tó bá jẹ́ pé o kì í ṣe eré ìmárale tẹ́lẹ̀, ó máa dáa kó o rí dókítà rẹ kó o tó bẹ̀rẹ̀. Bákan náà, kó o sọ fún un tó bá ń rẹ̀ ẹ́ wá látinú tàbí tí àyà ń dùn ẹ́ nígbà tó o bá ń ṣe eré ìmárale. Kódà, tọ́rọ̀ bá rí i bẹ́ẹ̀, ó máa mọ́gbọ́n dání tó o bá pe fóònù iléeṣẹ́ tó máa ń rí sí ọ̀ràn pàjáwìrì. Má fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ọ̀ràn náà o, torí pé ó lè ṣàkóbá fún ìlera rẹ! Ó sì tún dáa pé kó o máa ṣàyẹ̀wò ojú rẹ lọ́dọ̀ àwọn dókítà tó ń tọ́jú ojú lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.

Tó bá di ọ̀ràn oúnjẹ, máa yẹra fún àwọn oúnjẹ tí kò ní àwọn èròjà fítámì àti mínírà, ìbáà tiẹ̀ jẹ́ oúnjẹ téèyàn lè yára sè. Àwọn àgbàlagbà ní pàtàkì jù lọ ní láti máa jẹ àwọn oúnjẹ tó ní èròjà fítámì D àti káṣíọ́mù, àwọn èròjà méjèèjì yìí lè mú kí eegun èèyàn le dáadáa tàbí kó máà jẹ́ kó tètè di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Torí náà, máa jẹ àwọn oúnjẹ oníhóró, wàrà, èso àti ewébẹ̀. Bákàn náà, kó o sọ fún dókítà rẹ kó o tó ṣe àyípadà nínú ọ̀nà tó ò ń gbà jẹun. Ó lè fún ẹ láwọn àbá lórí irú oúnjẹ tó o lè máa jẹ àti èyí tó yẹ kó o yẹra fún, nítorí ìlera rẹ.

Síwájú sí i, o ní láti máa mu omi dáadáa. Àìpọ̀tó omi nínú ara, èyí tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn àgbàlagbà, pàápàá jù lọ àwọn tó ń dá gbé tàbí tó wà ní ibi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn àgbàlagbà lè mú kí wọ́n máa ṣubú, kí nǹkan máa tojú sú wọn, kí wọ́n má ṣe rí ìgbẹ́ yà, kí ara wọn hun jọ, kí wọ́n kó àrùn, ó sì lè yọrí sí ikú pàápàá.

Mú Kí Ilé Rẹ Jẹ́ Ibi Tí Kò Séwu

Inú ilé ni ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ti máa ń ṣubú. Àmọ́, tó o bá ṣe àwọn nǹkan kan, ó lè mú kí ewu náà dín kù. Máa ronú nípa ilé rẹ bó o ṣe ń ka àwọn kókó tó kàn yìí.

Ilé ìwẹ̀:

● Ilẹ̀ ilé ìwẹ̀ rẹ kò gbọ́dọ̀ máa yọ̀ nígbà tí omi bá dà sí i.

● Kí ilẹ̀ ilé ìwẹ̀ tó ní ẹ̀rọ tó ń fọ́n omi tàbí èyí tó ní ọpọ́n ńlá má ṣe jẹ́ èyí tó ń yọ̀, bí àga téèyàn lè jókòó lé nígbà tó ń wẹ̀ bá sì wà níbẹ̀, má ṣe jẹ́ kó jìnnà sí ẹnu ẹ̀rọ. Ó tún máa ṣàǹfààní tó o bá ní orí ẹ̀rọ téèyàn lè mú dání, kó o lè wà lórí ìjókòó nígbà tó o bá ń wẹ̀.

● Ó dára kó o ní nǹkan téèyàn lè dì mú nígbà tó bá fẹ́ wọ inú ọpọ́n ńlá tí wọ́n fi ń wẹ̀ tàbí tó o bá jáde nínú rẹ̀ tàbí nígbà tó o bá fẹ́ lo ilé ìgbọ̀nsẹ̀. Àmọ́ ó gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó lágbára, tí wọ́n sì dè mọ́lẹ̀ dáadáa. Bákan náà, rí i dájú pé ibi téèyàn ń jókòó lé tó bá fẹ́ ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ kò ga jù kò sì lọ sílẹ̀ jù, kó lè rọrùn láti jókòó tàbí dìde láìsí ìnira.

● Rí i dájú pé ó tan iná ibẹ̀, tàbí kó o lo tọ́ọ̀ṣì.

Àtẹ̀gùn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì:

● Kò gbọ́dọ̀ sí ohun tó lè gbé èèyàn ṣubú lórí àtẹ̀gùn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì, kó dúró sán-ún, kó má sì dọ̀tí.

● Ó yẹ kí àtẹ̀gùn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ní ohun téèyàn lè dì mú lọ́tùn-ún àti lósì, kó má ṣe jẹ́ èyí tó ń yọ̀, kí ohun tí èèyàn lè fi tan iná ẹ̀lẹ́tíríìkì sì wà lókè àti nísàlẹ̀.

● Gígun òkè àti sísọ̀ kalẹ̀ lè jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn àgbàlagbà lókun. Àmọ́ bí ara rẹ kò bá ró dáadáa, má ṣe máa dá nìkan gun àtẹ̀gùn pẹ̀tẹ́ẹ̀sì.

Inú yàrá:

● Jẹ́ kí àyè tó o ti lè rìn wà láàárín bẹ́ẹ̀dì àtàwọn nǹkan míì tó wà nínú yàrá rẹ.

● Ní àga tó o lè jókòó lé nígbà tó o bá fẹ́ múra.

● Jẹ́ kí àtùpà tàbí tọ́ọ̀ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ nígbà tó o bá wà lórí ibùsùn.

Ilé ìdáná:

● Jẹ́ kí orí káńtà wà létòlétò, kó o lè ráyè kó àwọn ohun èlò oúnjẹ àtàwọn nǹkan míì sí.

● Kò yẹ kí ilẹ̀ ilé ìdáná máa yọ̀, kó má sì ṣe máa dán gbinrin.

● Àwọn nǹkan tó wà nínú kọ́bọ́ọ̀dù kò gbọ́dọ̀ ga jù tàbí kó lọ sílẹ̀ jù, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ wà níbi tí ọwọ́ rẹ á ti tó o láìjẹ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá ẹni tó máa bá ẹ gbé e. Ṣọ́ra fún lílo àtẹ̀gùn tàbí ohun ìtìsẹ̀, má sì ṣe gun orí àga!

Àwọn ohun mìíràn:

● Jẹ́ kí iná wà lójú ọ̀nà tó o máa ń gbà lọ sí ilé ìwẹ̀ àti ní àwọn ọ̀nà míì tó o máa ń gbà lálẹ́.

● Ó máa ń ṣàǹfààní téèyàn bá fi ọ̀pá rìn ní òru, nígbà tí oorun kò bá tíì dá lójú èèyàn.

● Àga tó o fi ń jókòó gbọ́dọ̀ dúró sán-ún (kó má ṣe jẹ́ èyí tó ní táyà), kó ní ibi téèyàn lè gbé apá lé, kó má sì ga tàbí lọ sílẹ̀ jù, kó lè rọrùn láti jókòó tàbí dìde.

● Kó o má bàa máa ṣubú, máa tètè pààrọ̀ ohun tó bá bà jẹ́ tàbí kó o tún un ṣe, àwọn nǹkan bíi kápẹ́ẹ̀tì tó ti fàya tàbí tó ṣí, tàbí àwo tí wọ́n ń lẹ̀ mọ́ ilẹ̀. Gbé àwọn wáyà iná gba igun ara ògiri dípò tí wàá fi nà án gba àárín ọ̀nà.

● Àwọn rọ́ọ̀gì kéékèèké téèyàn lè tẹ́ sílẹ̀ láti fi ṣe ilé lọ́ṣọ̀ọ́ lè gbé èèyàn ṣubú, torí náà kò ní dáa kó o tẹ́ ẹ sórí kápẹ́ẹ̀tì. Tó bá wà lórí ilẹ̀ tó ń dán, irú bíi lórí àwo tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ilẹ̀ tàbí pákó, kó o fi nǹkan lẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kó má bàa máa sún kiri.

● Má ṣe máa wọ bàtà tí kì í ṣe alábọ̀tán, èyí tó ti já, èyí tí kò lókùn lẹ́yìn tàbí èyí tí kò lè di ilẹ̀ mú. Má sì ṣe wọ bàtà tí ìtẹ̀lẹ̀ rẹ̀ ga.

● Àwọn oògùn kan wà tó máa ń jẹ́ kó rẹ èèyàn. Tó o bá lo oògùn èyíkéyìí tó o sì rí i pé ó rẹ̀ ọ́ lẹ́yìn tó o lò ó, rí i dájú pé o sọ fún dókítà rẹ. Dókítà náà lè dín iye tí wàá máa lò kù, tàbí kó wá oògùn míì fún ẹ.

Tó o bá kíyè sí ohun kan tó ń fẹ́ àbójútó, tí o kò sì lè ṣe é fúnra rẹ, o lè ní kí ẹnì kan nínú ìdílé rẹ, ọ̀rẹ́ tàbí àwọn tó ń tún irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe wá ràn ẹ́ lọ́wọ́. Má sì máa fòní dónìí fọ̀la dọ́la.

Ohun Tí Àwọn Ẹlòmíì Lè Ṣe

Tó o bá ní òbí, òbí àgbà tàbí ọ̀rẹ́ tó ti dàgbà, báwo lo ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọn kò fi ní máa ṣubú? O lè fọgbọ́n jíròrò àwọn ohun tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí pẹ̀lú wọn, kó o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe àwọn ibi tó nílò àbójútó nínú ilé. O tún lè máa bá wọn ṣe oúnjẹ tó dáa bóyá lẹ́ẹ̀kàn tàbí ẹ̀ẹ̀méjì lọ́sẹ̀, bí wọ́n bá nílò rẹ̀. Ó tún yẹ kí àwọn àgbàlagbà máa ṣe eré ìmárale déédéé. Ǹjẹ́ o lè máa mú wọn jáde, bóyá nígbà tó o bá fẹ́ lọ ṣe àwọn nǹkan kan? Inú àwọn àgbàlagbà máa ń dùn láti jáde kúrò nílé bí wọ́n bá rẹ́ni tí wọ́n fọkàn tán tó máa tẹ̀ lé wọn jáde. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ìjọba máa ń pèsè ìrànwọ́, nípa títọ́jú àwọn àgbàlagbà ní ilé wọn, pípèsè ìtọ́jú tí kò la oògùn lọ àti bíbójú tó wọn nílé kí wọ́n má bàa fara pa. Ó yẹ kí dókítà rẹ lè sọ bó o ṣe lè rí irú àǹfààní bẹ́ẹ̀ gbà.

Ẹlẹ́dàá wa, tí Bíbélì pè ní “Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé,” fẹ́ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà, ní pàtàkì àwọn òbí wa tó ti darúgbó. (Dáníẹ́lì 7:9) Ó pàṣẹ pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:12) Ó tún fún wa ní ìtọ́ni pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó, kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ.” (Léfítíkù 19:32) Bẹ́ẹ̀ ni, bíbọ̀wọ̀ fún àwọn àgbàlagbà ń fi hàn pé a ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run! Bí àwọn àgbàlagbà bá sì wá dúpẹ́ lọ́wọ́ wa nítorí ìrànlọ́wọ́ tá a ṣe fún wọn, ńṣe ni wọ́n ń fi hàn pé àwọn mọyì ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tá a ní fún àwọn. Ká má ṣe máa wo ríran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìnira, ó jẹ́ ohun tó máa ń gbádùn mọ́ni!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jí! June 8, 2005 ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe eré ìmárale.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

OHUN ÈLÒ ABÁNÁṢIṢẸ́ KAN TÓ O LÈ LÒ NÍGBÀ ÌṢẸ̀LẸ̀ PÀJÁWÌRÌ

Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ṣe ohun èlò abánáṣiṣẹ́ kékeré kan tí àwọn àgbàlagbà lè lò nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì bá wáyé. Irú bíi nígbà tí wọ́n bá ṣubú. Bọ́tìnnì kékeré kan wà lára ohun èlò náà tí wọ́n máa tẹ̀ láti pe àwọn èèyàn fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n lè so ohun èlò yìí mọ́ ọrùn tàbí ọrùn ọwọ́. Bí ohun èlò yìí bá wà ní àgbègbè rẹ, wò ó bóyá o lè jàǹfààní rẹ̀, pàápàá tó bá jẹ́ pé ńṣe lò ń dá gbé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́