ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 13-15
  • Ohun Tó Dára Jù Lọ Ni Mo Fi Ayé Mi Ṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Dára Jù Lọ Ni Mo Fi Ayé Mi Ṣe
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Wàásù Nílùú Sumatra
  • A Wàásù ní Erékùṣù Java
  • Erékùṣù Kalimantan Níbi Táwọn Ẹ̀yà Dayak Ń Gbé
  • A Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Papua New Guinea
  • Ìrìn Àjò Tó Nira Jù Lọ fún Mi
  • Inú Mi Dùn Pé Ohun Tó Nítumọ̀ Ni Mo Fayé Mi Ṣé
    Ìtàn Ìgbésí Ayé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • A Ò Jẹ́ Kí Ohunkóhun Dí Wa Lọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • “Mo Dá Wà, àmọ́ Jèhófà Wà Pẹ̀lú Mi”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • A Wàásù “Ìhìn Rere” Ní Àwọn Erékùṣù Jíjìnnà Réré Ní Àríwá Ọsirélíà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 13-15

Ohun Tó Dára Jù Lọ Ni Mo Fi Ayé Mi Ṣe

Gẹ́gẹ́ bí Herawati Neuhardt ṣe sọ ọ́

Ìlú Cirebon lórílẹ̀-èdè Indonesia ni wọ́n ti bí mi. Ìlú yìí gbajúmọ̀ gan-an tó bá dọ̀rọ̀ ká pa aṣọ láró ká sì fọwọ́ ṣiṣẹ́ ọnà sára aṣọ. Láwọn ọ̀nà kan, ńṣe ni ìgbé ayé mi gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì dà bí aṣọ tí a pa láró tá a sì ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ ọ̀nà sí lára, torí pé mo ti rí ọ̀kan-kò-jọ̀kan àṣà ìbílẹ̀ tó wuni lápá Gúúsù Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Éṣíà àti Gúúsù Òkun Pàsífíìkì. Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé.

LỌ́DÚN 1962, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó yá, àwọn àti bàbá mi tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Ṣáínà tí wọ́n bí lórílẹ̀-èdè Indonesia di Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ̀lú àwa ọmọ wọn márùn-ún.

Ilé wa ni àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn alábòójútó arìnrìn-àjò tó máa ń bẹ ìjọ wa wò kí wọ́n lè fún wa ní ìṣírí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń dé sí. Àpẹẹrẹ rere wọn àti ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró tí wọ́n máa ń bá wa sọ ní ipa rere lórí mi. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo pinnu láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni alákòókò kíkún. Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà èmi àti Josef Neuhardt tó jẹ́ míṣọ́nnárì láti orílẹ̀-èdè Jámánì ṣègbéyàwó, ọdún 1968 ló dé sórílẹ̀-èdè Indonesia. Lẹ́yìn tá a dé láti ìsinmi lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, a lọ sí erékùṣù Sumatra, èyí tó jẹ́ erékùṣù tó tóbi ṣìkejì lára erékùṣù tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000] tó wà lórílẹ̀-èdè Indonesia. Ibẹ̀ ni mo ti dara pọ̀ mọ́ Josef lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, iṣẹ́ tó gba pé ká máa ṣèbẹ̀wò sí àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

A Wàásù Nílùú Sumatra

Àyíká tí wọ́n yàn wá sí bẹ̀rẹ̀ láti ìlú Padang ní West Sumatra, ìlú olóoru kan tí èrò ti máa ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀, títí dé adágún rírẹwà kan tí wọ́n ń pè ní Toba, adágún yìí wà níbi òkè ayọnáyèéfín kan ní ilẹ̀ olókè kan ní North Sumatra. Nígbà tó yá, a tún wàásù dé gúúsù erékùṣù náà. Ọkọ̀ ìjàpá wa là ń gbé kiri, à máa ń já sí kòtò já sí gegele nínú igbó, a kọjá lórí afárá tí wọ́n fi igi àgbọn ṣe tó ń mì jẹ̀gẹ̀jẹ̀gẹ̀. A tún máa ń wakọ̀ gba ẹ̀gbẹ́ àwọn òkè ayọnáyèéfín gíga fíofío, àwọn kan lára àwọn òkè yìí ṣì ń yọ èéfín nígbà táwọn kan kò yọ èéfín mọ́. Ní alẹ́, a máa ń sùn sílẹ̀ nínú ahéré. Kò sí iná, kò sí omi tàbí ilé ìwẹ̀. Inú adágún odò la ti máa ń fọ nǹkan tá a sì máa ń wẹ̀. Ìgbé ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì la gbé níbẹ̀, a sì fẹ́ràn àwọn aráàlú náà. Wọ́n gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n fún wa lóúnjẹ, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àwọn kan wà nítòsí ìlú Padang tí wọ́n ń pè ní Minangkabau, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ló jẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an, inú wọn sì dùn nígbà tá a fi hàn wọ́n látinú Bíbélì pé ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́run, kì í ṣe Mẹ́talọ́kan, gẹ́gẹ́ bí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń kọ́ni. (Diutarónómì 6:4) Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, àwọn kan tó sì fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ dẹni tó tẹ̀ síwájú dáadáa. Ní Adágún Toba, àwọn tó ń sọ èdè Batak nílùú Sumatra, tí èyí tó pọ̀ jù nínú wọn pe ara wọn ní Kristẹni mọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, torí pé wọ́n rí i nínú Bíbélì wọn lédè Batak. (Sáàmù 83:18) Síbẹ̀, wọ́n ṣì nílò láti mọ ohun tó pọ̀ sí i nípa Ọlọ́run àti ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Ọ̀pọ̀ nínú wọn la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì di Kristẹni tó ń fìtara wàásù.

A Wàásù ní Erékùṣù Java

Lọ́dún 1973, wọ́n rán èmi àti Josef lọ sí erékùṣù Java, erékùṣù yìí tó ìdajì Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, iye àwọn tó ń gbé ìlú náà lé ní ọgọ́rin [80] mílíọ̀nù.a A wàásù ìhìn rere fún àwọn tó ń sọ èdè Javanese, Sundanese àti èdè Chinese.

Torí pé ọmọ Ṣáínà tí wọ́n bí sí orílẹ̀-èdè Indonesia ni mí, mo lè sọ àwọn èdè mélòó kan, tó fi mọ́, Javanese, Sundanese àti Indonesian, mo tún lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Torí náà, mo máa ń gbádùn jíjíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn ní èdè ìbílẹ̀ wọn.

Ní Jakarta tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Indonesia, tó wà ní erékùṣù Java, mo bá ọmọbìnrin ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tí ojú rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì sọ̀rọ̀ nípa ìrètí ìwàláàyè nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Bí mo ṣe ka Bíbélì fún un, ńṣe ló bú sẹ́kún. Ó wá sọ̀rọ̀ tìfẹ́tìfẹ́ àti tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé: “Ẹ ṣeun gan-an fún ohun tẹ́ ẹ sọ fún mi yìí. Mo máa nílò mílíọ̀nù kan ààbọ̀ owó rupiah [nǹkan bíi ₦23,680] lọ́la, kí n lè san owó iléèwé gíga mi, mo sì ń ronú pé bóyá kí n lọ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kan kí n lè rí owó náà, bẹ́ẹ̀ mi ò ṣerú ẹ̀ rí láyé mi. Kẹ́ ẹ tó dé, ńṣe ni mò ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tọ́ mi sọ́nà. Mo ti wá mọ ohun tí màá ṣe báyìí. Mo ti pinnu pé mi ò ní wọ iléèwé mọ́ lásìkò yìí, kí n lè wà ní mímọ́ lójú Ọlọ́run.” Inú ọmọbìnrin náà dùn láti gba ìrànlọ́wọ́ púpọ̀ sí i látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Láti ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Javanese, Sundanese àti Chinese, ló ti mú ìgbé ayé wọn bá ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mu. Èyí sì ti mú kí wọ́n ní ojúlówó ìbàlẹ̀ ọkàn àti ayọ̀, bí Ọlọ́run ti ṣèlérí.—Aísáyà 48:17, 18.

Erékùṣù Kalimantan Níbi Táwọn Ẹ̀yà Dayak Ń Gbé

Nígbà tá a kúrò ní erékúṣù Java, èmi àti Josef lọ sí erékùṣù Kalimantan, tó jẹ́ ẹkùn ilẹ̀ Borneo lórílẹ̀-èdè Indonesia, òun ni erékùṣù kẹta tó tóbi jù lọ láyé (lẹ́yìn erékùṣù Greenland àti New Guinea). Ẹkùn ilẹ̀ Borneo kún fún igbó kìjikìji, òkè gbágungbàgun àtàwọn odò ńláńlá, àwọn tó ń sọ èdè Chinese, àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí tó ń sọ èdè Malays àtàwọn Dayak tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ló sì pọ̀ jù níbẹ̀. Etí odò ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ń gbé, ìgbà kan sì wà tó jẹ́ pé òkú òǹrorò ni wọ́n, tí wọ́n máa ń gé orí àwọn ọ̀tá fi ṣe ife ẹ̀yẹ.

Ká tó lè dé àwọn ìgbèríko tí àwọn ẹ̀yà Dayak ń gbé, a máa ń wa ọkọ̀ ojú omi gba àwọn odò tó la àárín igbó kìjikìji kọjá. Àwọn ọ̀nì ńláńlá máa ń ṣeré ní etídò, àwọn ọ̀bọ máa ń wò wá látorí igi, àwọn ẹyẹ sì máa ń fi ìyẹ́ wọn fífanimọ́ra dárà. Ká sòótọ́, ńṣe ni iṣẹ́ míṣọ́nnárì níbẹ̀ dà bí ìgbà téèyàn ń rin ìrìn àjò afẹ́.

Inú àwọn ahéré tí wọ́n fi igi àti koríko kọ́, tí wọ́n sì fi igi gígùn gbé dúró ni ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé Dayak ń gbé. Àwọn ilé kan wà tó kéré; àwọn míì sì wà tó tóbi tó sì gùn tó láti gba àwọn ìdílé mélòó kan. Ọ̀pọ̀ wọn ni kò rí èèyàn tó wá láti ilẹ̀ Yúróòpù rí, èyí mú kí gbogbo wọn fẹ́ rí Josef. Àwọn ọmọdé lè sáré yíká gbogbo abúlé tí wọ́n á máa pariwo, “Pásítọ̀! Pásítọ̀!” Gbogbo wọn á wá máa rọ́ wá gbọ́ ohun tí òjíṣẹ́ aláwọ̀ funfun fẹ́ sọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ ló máa ń ṣe ògbufọ̀ fún Josef, tí wọ́n á sì ṣètò láti kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́.

A Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Papua New Guinea

Ní December ọdún 1976, ìjọba orílẹ̀-èdè Indonesia fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí pé àwọn ẹlẹ́sìn tó ń ṣàtakò àwọn Ẹlẹ́rìí fúngun mọ́ wọn. Èyí ló mú kí wọ́n rán èmi àti Josef lọ sí orílẹ̀-èdè Papua New Guinea.

Lẹ́yìn tá a dé sí Port Moresby, olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, a lọ gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù méjì ní Hiri Motu, ibẹ̀ la ti kọ́ èdè tí wọ́n ń fi ṣòwò. Lẹ́yìn náà, a lọ sí erékùṣù Daru, ní ìgbèríko tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ẹkùn ilẹ̀ náà. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé Eunice, obìnrin kan tó lómi lára tó jẹ́ akíkanjú tó sì níwà tó wuni. Àwọ̀ pupa àti dúdú ti dápàá sí eyín rẹ̀ nítorí pé ó máa ń jẹ ẹ̀pà bẹ́tẹ́lì nígbà kan. Nígbà tí Eunice kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun jẹ́ mímọ́ nípa ti ara, nínú ìwà wọn àti nípa tẹ̀mí, ó jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó ti sọ di bárakú, ó sì di Kristẹni olùṣòtítọ́. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Gbogbo ìgbà tá a bá ti rí irú àwọn tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ń fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sílò, a máa ń túbọ̀ mọyì ohun tó wà nínú Sáàmù 34:8 tó sọ pé: “Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé Jèhófà jẹ́ ẹni rere.”

Nígbà tó yá, wọ́n tún yan Josef gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àgbègbè orílẹ̀-èdè Papua New Guinea la ṣèbẹ̀wò sí. Èdè tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè náà tó okòó lé lẹ́gbẹ̀rin [820]. Kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti wàásù fún ọ̀pọ̀ èèyàn, a tún kọ́ òmíràn lára àwọn èdè náà mọ́ èyí tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, wọ́n ń pe èdè náà ní Tok Pisin, òun ni èdè tí wọ́n ń sọ jù lọ ní ìlú náà. Tá a bá fẹ́ lọ sí àwọn ìlú àti abúlé, a máa ń fẹsẹ̀ rìn, a máa ń wọ mọ́tò, ọkọ̀ ojú omi, ọkọ̀ tí wọ́n ń fi àjẹ̀ wà àti ọkọ̀ òfúrufú kékeré, ooru máa ń mú wa gan-an, ẹ̀fọn máa ń jẹ wá, a sì tún máa ń ṣàìsàn ibà.

Lọ́dún 1985, wọ́n tún rán wa lọ sí Solomon Islands ní ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Papua New Guinea láti máa ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa lọ níbẹ̀. Nígbà tá a débẹ̀, a ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì tún rin ìrìn àjò jákèjádò àwọn erékùṣù náà ká lè fún àwọn ìjọ tó wà níbẹ̀ ní ìṣírí, a sì tún lọ sí àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A tún ní láti kọ́ èdè tuntun nígbà tá a débẹ̀, ìyẹn èdè Solomon Islands Pidgin. Àmọ́, ó máa ń dùn mọ́ wa láti bá àwọn ará Solomon Islands tó nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì sọ̀rọ̀.

Ìrìn Àjò Tó Nira Jù Lọ fún Mi

Lọ́dún 2001, ìjọba orílẹ̀-èdè Indonesia gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tí wọ́n fi de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èmi àti Josef sì pa dà sí Jakarta olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Kò pẹ́ tí àyẹ̀wò fi jẹ́ ká mọ̀ pé ọkọ mi ti ní àrùn kan tí wọ́n ń pè ní malignant melanoma, ìyẹn àrùn jẹjẹrẹ kan tó máa ń ṣèèyàn nínú ẹran ara. A wá lọ sí orílẹ̀-èdè Jámánì níbi tí Josef ti wá, kó lè lọ gba ìtọ́jú. Àmọ́, ó bà mí nínú jẹ́ pé ọjọ́ tó pé ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n tá a ṣègbéyàwó ló sùn nínú ikú, ó ń retí àjíǹde sínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 11:11-14) Ẹni ọdún méjìlélọ́gọ́ta [62] ni, ó sì lo ogójì [40] ọdún lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

Mo dúró sí ìlú Jakarta, mo sì ń bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì mi lọ. Àárò ọkọ mi máa ń sọ mí gan-an. Àmọ́ bí mo ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló jẹ́ kí n lè máa mú un mọ́ra, torí pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ ti jẹ́ kí n ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn, ó sì jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ pé mo ti fayé mi ṣe nǹkan rere. Dájúdájú, mo lè fi gbogbo ẹnu sọ pé Jèhófà ti jẹ́ kí ìgbésí ayé mi ládùn, ó sì lárinrin, àti pé mo ti fi ayé mi ṣe nǹkan tó dáa.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Iye èèyàn tó ń gbé erékùṣù Java báyìí lé ní ọgọ́fà [120] mílíọ̀nù.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

INDONESIA

Java

JAKARTA

Cirebon

Sumatra

Padang

Adágún Toba

Borneo

PAPUA NEW GUINEA

PORT MORESBY

Daru

SOLOMON ISLANDS

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Herawati àti ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Solomon Islands

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Èmi àti Josef rèé lórílẹ̀-èdè Holland, lọ́dún 2005 nígbà tó kù díẹ̀ kó kú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́