Ìtan Ìgbésí Ayé
A Ò Jẹ́ Kí Ohunkóhun Dí Wa Lọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
Gẹ́gẹ́ bí Lena Davison ṣe sọ ọ́
“Ojú mi ń ṣe bàìbàì. Mi ò ríran mọ́.” Ohun tí ẹni tó ń wa ọkọ̀ òfuurufú tá a wà nínú rẹ̀ sọ nìyẹn, agbára káká la sì fi ń gbọ́ ohun tó ń sọ. Nígbà tó yá, ọwọ́ rẹ̀ yẹ̀ kúrò lára ohun tó fi ń darí ọkọ̀ òfuurufú kékeré tá a wọ̀ náà, ó ṣubú lórí ìjókòó rẹ̀, ò sì dákú. Ọkọ mi tí ò mọ nǹkan kan nípa bí wọ́n ṣe ń wa ọkọ̀ òfuurufú sa gbogbo ipá rẹ̀ láti jí i. Kí n tó sọ bí Ọlọ́run ṣe kó wa yọ nínú ewu yẹn, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ ṣàlàyé ohun tó gbé wa dénú ọkọ̀ òfuurufú ní orílẹ̀-èdè Papua New Guinea, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tó jìnnà jù lọ láyé.
ORÍLẸ̀-ÈDÈ Ọsirélíà ni wọ́n ti bí mi lọ́dún 1929, wọ́n sì tọ́ mi dàgbà nílùú Sydney, tó jẹ́ olú ìlú New South Wales. Kọ́múníìsì ni bàbá mi tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bill Muscat, àmọ́ ó yani lẹ́nu pé ó gba Ọlọ́run gbọ́. Kódà, lọ́dún 1938, ó gbà láti fọwọ́ sí ìwé tí wọ́n fi ni kí ìjọba fún Joseph F. Rutherford, tó wá láti orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti wá wàásù ní Gbọ̀ngàn Ìlú Sydney.
Ohun tí bàbá mi sọ fún wa nígbà yẹn ni pé: “Ó ní láti ní ohun pàtàkì kan tí Joseph F. Rutherford fẹ́ sọ.” Ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn ìyẹn la wá rí kókó inú ọ̀rọ̀ tí bàbá mi sọ yẹn. Bàbá mi pe Norman Bellotti, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò-kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sílé wa láti wá sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Kíákíá ni ìdílé wa di olùjọsìn Jèhófà, kò sì pẹ́ tá a fi wá dẹni tọ́wọ́ rẹ̀ dí gan-an nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.
Ní àárín àwọn ọdún 1940, mo fi ilé ìwé sílẹ̀ kí n lè wá ṣèrànwọ́ fún màmá mi tó ń ṣàìsàn kan tó lágbára nígbà yẹn. Mo tún ń ránṣọ láti fi gbọ́ bùkátà ara mi. Láwọn ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Sátidé, èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ń jẹ́ Rose máa ń bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà jáde, a sì máa ń wàásù lójú pópó níwájú Gbọ̀ngàn Ìlú Sydney. Lọ́dún 1952, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ John kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́ ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì ní kó lọ sìn lórílẹ̀-èdè Pakistan. Èmi náà nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìwàásù gan-an, mo sì fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Nítorí bẹ́ẹ̀, ọdún tó tẹ̀ lé e ni mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.
Ìgbéyàwó àti Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì
Kété lẹ́yìn ìyẹn ni mo bá John Davison pàdé, ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ọsirélíà ló ti ń ṣiṣẹ́. Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní, bó ṣe jẹ́ ẹni tó mọ ohun tó ń ṣe, tí ìwà rẹ̀ sì dáa gan-an ló wú mi lórí. Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n nígbà Ogun Àgbáyé Kejì nítorí pé ó kọ̀ láti lọ́wọ́ sógun. Àwa méjèèjì pinnu pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ni iṣẹ́ tá a máa fi ìgbésí ayé wa ṣe.
Èmi àti John ṣègbéyàwó lóṣù June, ọdún 1955. A rá ọkọ̀ bọ́ọ̀sì kan tá a fẹ́ fi ṣe ilé alágbèérìn. Ohun tá a ní lọ́kàn ni pé inú rẹ̀ la ó máa gbé bá a ti ń wàásù láwọn eréko ilẹ̀ Ọsirélíà. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni ètò Jèhófà sọ pé káwọn Ẹlẹ́rìí yọ̀ǹda ara wọn láti lọ sílùú New Guinea, tó jẹ́ apá àríwá ìlà oòrùn erékùṣù ńlá kan tó wà ní àríwá Ọsirélíà.a Àwọn tó wà ní apá ibi yìí kò tíì gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run rí. Ojú ẹsẹ̀ la yọ̀ǹda ara wa láti lọ.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ohun kan ṣoṣo tó lé mú kí wọ́n jẹ́ kéèyàn wọ ìlú New Guinea ni pé kéèyàn gbaṣẹ́ síbẹ̀. Bí John ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wáṣẹ́ síbẹ̀ nìyẹn. Kò pẹ́ tó fi ríṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń la pákó nílùú New Britain, ìyẹn erékùṣù kan tó kéré gan-an, tó jẹ́ ara New Guinea. Ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn la gbéra tá a forí lé ibi tí wọ́n yàn fún wa yìí, a sì gúnlẹ̀ sílùú Rabaul, New Britain, lóṣù July, ọdún 1956. Ibẹ̀ la ti fi odindi ọjọ́ mẹ́fà dúró de ọkọ̀ tó máa gbé wa lọ sí erékùṣù Waterfall Bay.
Iṣẹ́ Ìwàásù Wa Nílùú Waterfall Bay
Lẹ́yìn ọjọ́ bíi mélòó kan tá a fi bá pákáǹleke ojú omi yí, a gúnlẹ̀ sí Waterfall Bay, tó jẹ́ nǹkan bí igba ó lé ogójì [240] kìlómítà lápá gúúsù ìlú Rabaul. Ilé iṣẹ́ ńlá kan tí wọ́n ti ń la pákó wà níbì kan tó rí gbalasa tí wọ́n ro nínú aginjù. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, bí gbogbo òṣìṣẹ́ ṣe jókòó yí tábìlì oúnjẹ ká ni ọ̀gá wọn sọ pé: “Ṣé ẹ rí i, Ọ̀gbẹ́ni àti Ìyáàfin Davison, òfin ilé iṣẹ́ yìí ni pé kí gbogbo òṣìṣẹ́ sọ ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe.”
Ó dá wa lójú pé kò sí òfin kankan tó sọ bẹ́ẹ̀, àmọ́ nígbà tá a ti sọ pé a kì í mu sìgá ni wọ́n ti ń fura sí wa. Lọ́rọ̀ kan, John fèsì pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá.” Gbogbo wọn kọ́kọ́ dákẹ́ lọ. Àwọn ọkùnrin náà wà lára àwọn tó ja Ogun Àgbáyé Kejì, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí nítorí pé wọn ò báwọn lọ́wọ́ sógun lákòókò yẹn. Látìgbà yẹn ni wọ́n ti ń wá gbogbo ọ̀nà táwọn fi lè mú nǹkan nira fún wa.
Lákọ̀ọ́kọ́, ẹni tó jẹ́ ọ̀gá ibẹ̀ kọ̀ láti fún wa ní fìríìjì àti sítóòfù tá a ó fi máa dáná oúnjẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé méjèèjì ló yẹ kí wọ́n fún wa. Àwọn oúnjẹ wa bà jẹ́, ó sì di ọ̀ràn-an-yàn fún wa láti máa fi sítóòfù kan tó ti bà jẹ́ tá a rí he nínú aginjù náà dáná. Nígbà tó yá, wọ́n ní àwọn ará abúlé náà ò gbọ́dọ̀ ta irè oko fún wa, ìwọ̀nba ewébẹ̀ tá a bá sì rí já la máa ń jẹ. Wọ́n tún pè wá ní amí, wọ́n sì ń ṣọ́ wa lójú méjèèjì láti rí i bóyá a máa kọ́ ẹnikẹ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbà yẹn ni mo wá ní àrùn ibà.
Síbẹ̀síbẹ̀, a ó jẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A wá ní káwọn ọmọkùnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìlú yẹn máa kọ́ wa ní èdè Melanesian Pidgin tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Iléeṣẹ́ tí wọ́n ti ń la pákó náà láwọn ọmọkùnrin méjì ọ̀hún ti ń ṣiṣẹ́, wọ́n sì gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àwa náà sì kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láwọn òpin ọ̀sẹ̀, a máa ń rìnrìn àjò lọ káàkiri bíi pé a fẹ́ mọ àgbègbè náà dáadáa. Bá a bá ṣe ń lọ lọ́nà la máa ń fọgbọ́n wàásù fáwọn ara abúlé tá a bá rí, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló sì máa ń bá wa túmọ̀ èdè. A máa ń kọjá lórí àwọn omi tó ń ru gùdù tó sì máa ń ní àwọn ọ̀nì ńláńlá tó ń yá oòrùn lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò. Àwọn ọ̀nì tó léwu wọ̀nyí kì í sábà dà wá láàmú, yàtọ̀ sí ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, Ọlórun sì kó wa yọ.
A Ṣe Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ṣe ń tẹ̀ síwájú, a pinnu láti tẹ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó lè tètè yéni sínú àwọn ìwé kan ká lè máa pín in fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́. Àwọn tá a ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé iṣẹ́ pákó náà ràn wá lọ́wọ́ láti túmọ̀ àwọn tá a kọ́kọ́ tẹ̀ jáde. Ọ̀pọ̀ òru la ò sùn tá à ń tẹ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé àṣàrò kúkúrú, tá a sì ń pín wọn fún àwọn ará abúlé náà àtàwọn òṣìṣẹ́ inú àwọn ọkọ̀ ojú omi tó ń kọjá lọ.
Lọ́dún 1957, Arákùnrin John Cutforth, tó ti pẹ́ gan-an lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò wá sọ́dọ̀ wa láti fún wa níṣìírí.b Ó dámọ̀ràn pé lílo àwòrán lè jẹ́ ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ gan-an láti kọ́ àwọn èèyàn tí kò mọ̀wé kà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òun àti ọkọ mi ya àwọn àwòrán bíi mélòó kan tó rọrùn gan-an láti fi ṣàlàyé àwọn ohun téèyàn kọ́kọ́ ń mọ̀ nínú Bíbélì. Nígbà tó yá, a lo àìmọye wákàtí láti tún àwọn àwòrán tá a fi ń wàásù yìí yà sínú àwọn ìwé kan. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kọ̀ọ̀kan sì gba ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan kó lè máa fi wàásù fáwọn èèyàn. Ọgbọ́n tá a dá láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ yìí ló wá di èyí tá à ń lò jákèjádò orílẹ̀-èdè náà nígbà tó yá.
Lẹ́yìn tá a ti lo ọdún méjì àtààbọ̀ nílùú Waterfall Bay, àkókò tá a sọ pé a máa fi bá ilé iṣẹ́ pákó yẹn ṣiṣẹ́ pé, wọ́n sì fún wa láyè láti máa gbé ní orílẹ̀-èdè náà. A wá gbà láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe níbẹ̀.
A Padà Sílùú Rabaul
Bá a ṣe ń wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí àríwá Rabaul, ọkọ̀ wa dúró, a sì sùn sí oko àgbọn àti oko kòkó kan tó wà ní Wide Bay mọ́jú. Àwọn tọkọtaya arúgbó tó ni oko náà fẹ́ fi iṣẹ́ sílẹ̀ kí wọ́n sì padà sí Ọsirélíà, wọ́n wá sọ pé kí John wá báwọn máa bójú tó oko náà. Ohun tí wọ́n fi lọ wá yìí fani mọ́ra gan-an, àmọ́ nígbà táwa méjèèjì ronú lórí ọ̀rọ̀ náà lóru yẹn, a fohùn ṣọ̀kan pé kì í ṣe ọrọ̀ la wá wá sí ìlú New Guinea. A ò sì fẹ́ kí ohunkóhun dí wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tá à ń ṣe. Nígbà tó di ọjọ́ kejì, a sọ èrò ọkàn wa fún tọkọtaya náà, a sì padà sínú ọkọ náà.
Nígbà tá a dé ìlú Rabaul, a dara pọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí kékeré kan tí wọ́n wá sí àgbègbè yẹn láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn ará ìlú náà nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run gan-an, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láàárín àkókò náà, gbọ̀ngàn kan tá a háyà la ti máa ń ṣe àwọn ìpàdé wa, àwa bí àádọ́jọ èèyàn la sì ń wá sípàdé ọ̀hún. Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn wọ̀nyí ló di olùjọsìn Jèhófà tí wọn sì ṣèrànwọ́ láti mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé àwọn apá ibòmíràn ní orílẹ̀-èdè yẹn.—Mátíù 24:14.
A tún lọ sí Vunabal, ìyẹn abúlé kan tó wà ní nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà sílùú Rabaul, níbi táwọn èèyàn kan ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ rárá tí ọmọ ìjọ Kátólíìkì kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún fi dájú sọ wọ́n. Bí òun àtàwọn kan tí wọ́n jọ ń ṣe ẹ̀sìn kan náà ṣe wá da ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ rú nìyẹn, tí wọ́n sì lé wa kúrò lábúlé náà. Nígbà tá a gbọ́ pé wàhálà yẹn tún máa pọ̀ sí i lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, a bẹ àwọn ọlọ́pàá pé kí wọ́n bá wa lọ.
Lọ́jọ́ yẹn, àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tó ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tò sí gbogbo ojú pópó, kódà àìmọye kìlómítà ni ibi tí wọ́n tò sí. Ọ̀pọ̀ múra tán láti sọ̀kò lù wá. Ní gbogbo àkókò yìí, àlùfáà kan ti kó ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará abúlé náà jọ. Àwọn ọlọ́pàá ti mú un dá wa lójú pé a lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìpàdé wa, bí wọ́n ṣe mú wa la àárín àwọn èrò náà kọjá nìyẹn. Àmọ́, bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ ìpàdé wa báyìí ni àlùfáà náà ní káwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í fa wàhálà. Àwọn ọlọ́pàá ò lè kápá àwọn èrò náà, ọ̀gá ọlọ́pàá tó wà níbẹ̀ wá ní ká fibẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì yára sìn wá dé ìdí ọkọ̀ wa.
Àwọn èèyànkéèyàn náà yí wa ká, báwọn kan ti ń ṣépè, làwọn kan ń tutọ́ lù wá, bẹ́ẹ̀ làwọn kan ń yọwọ́ ẹ̀ṣẹ́ sí wa. Ńṣe ni àlùfáà yẹn kan káwọ́ máyà ní tiẹ̀ tó rọra ń rẹ́rìn-ín. Lẹ́yìn tá a jàjà bọ́, ọ̀gá ọlọ́pàá náà sọ pé òun ò tíì rí nǹkan tó burú tó báyìí rí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn èèyànkéèyàn wọ̀nyẹn ṣe kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn fara mọ́ òtítọ́ nílùú Vunabal, síbẹ̀ ọ̀kan lára àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lo ìgboyà, ó sì fara mọ́ òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Látìgbà náà títí di ìsinsìnyí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn jákèjádò New Britain ló ti di olùjọ́sìn Jèhófà.
Iṣẹ́ Ìwàásù Dé Ìlú New Guinea
Ní oṣù November, ọdún 1960, wọ́n tún ní ká lọ sílùú Madang, ìyẹn ìlú ńlá kan tó wà ní etíkun lápá àríwá New Guinea, tó jẹ́ erékùṣù. Ibí yìí làwọn èèyàn ti ń fi oríṣiríṣi iṣẹ́ lọ èmi àti John. Ilé iṣẹ́ kan ní kí n wá máa báwọn bójú tó ṣọ́ọ̀bù ti wọ́n ti ń taṣọ. Àwọn kan fẹ́ kí n máa bá wọn tún aṣọ ṣe. Àwọn obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tiẹ̀ sọ pé àwọn á ṣí ṣọ́ọ̀bù fún mi, kí n máa ránṣọ níbẹ̀. Nítorí pé ohun tá a wá ṣe níbẹ̀ ló jẹ wá lọ́kàn jù lọ, a sọ fún wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé a ò ní lè ṣe àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí àtàwọn iṣẹ́ mìíràn tí wọ́n tún fi lọ̀ wá.—2 Tímótì 2:4.
Ìpínlẹ̀ Madang yẹn méso jáde gan-an, kó sì pẹ́ rárá tí ìjọ kan tó ń gbèèrú fi wà níbẹ̀. A máa ń fẹsẹ̀ rìn, a sì máa ń fi alùpùpù rìnrìn àjò, tá a ó lọ wàásù fún ọjọ́ bíi mélòó kan láwọn abúlé tó jìnnà gan-an. Inú àwọn abà táwọn èèyàn ò lò mọ́ la máa ń sùn sí, lórí àwọn koríko tá a gé nínú igbó. Kìkì àwọn oúnjẹ inú agolo, bisikíìtì, àti àpò ẹ̀fọn la máa ń kó dání lọ sáwọn ìrìn àjò náà.
Nígbà kan, a ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn kan tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ ní Talidig, ìyẹn abúlé kan tó jẹ́ nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà lápá àríwá Madang. Báwọn èèyàn náà ṣe ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí ni ọ̀gá ilé ìwé kan níbẹ̀ sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ilẹ̀ tó jẹ́ ti gbogbo gbòò mọ́. Nígbà tó yá, ó ní káwọn ọlọ́pàá ba ilé wọn jẹ́, kí wọ́n sì lé wọn lọ sínú igbó. Àmọ́ ìjòyè kan tó múlé gbe abúlé wọn ni kí wọn wá máa gbé lórí ilẹ̀ tòun. Láìpẹ́, ìjòyè tó jẹ́ onínúure yìí di olùjọsìn Jèhófà, a sì kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó bóde mu sí àgbègbè náà.
Iṣẹ́ Ìtúmọ̀ Èdè àti Ti Arìnrìn-Àjò
Ọdún méjì péré lẹ́yìn tá a dé sílùú New Britain lọ́dún 1956 ni wọ́n ní kí èmi àti John wá máa túmọ̀ onírúurú ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Melanesian Pidgin. A ṣe iṣẹ́ yìí fún ọ̀pọ̀ ọdún. Nígbà tó wá di ọdún 1970, wọ́n pè wá sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa tó wà nílùú Port Moresby, tó jẹ́ olú ìlú Papua New Guinea, pé ká kúkú wá máa ṣe iṣẹ́ atúmọ̀ èdè. A tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn lédè níbẹ̀.
Lọ́dún 1975, a padà sí New Britain láti ṣe iṣẹ́ arìnrìn-àjò. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má síbì kan tá ò dé lórílẹ̀-èdè yẹn láàárín ọdún mẹ́tàlá tó tẹ̀ lé e. A wọkọ̀ òfuurufú, a wọkọ̀ ojú omi, a wọkọ̀ ilẹ̀, a sì fẹsẹ̀ rìn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run kó wa yọ nínú ewu bá a ṣe ń lọ káàkiri, títí kan èyí tí mo mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Lọ́jọ́ tá à ń wí yìí, ọgbẹ́ inú kan tó lágbára gan-an ló ń ṣe ẹni tó ń darí ọkọ̀ òfuurufú tá a wọ̀, ìyẹn ló jẹ́ kó dákú bá a ṣe ń sún mọ́ ibi gbalasa kan tí ọkọ̀ òfuurufú lè balẹ̀ sí nílùú Kandrian tó wà ní New Britain. Nítorí pé wọ́n ṣe ohun kan sára ọkọ̀ náà tó fi lè máa dá wa ara rẹ̀ fúngbà díẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ sí í pòòyì kiri ojú òfuurufú, ọkọ mi sì ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti jí ẹni tó ń darí ọkọ̀ náà. Nígbà tó yá, ó jí, ojú rẹ̀ sì wálẹ̀ díẹ̀, èyí tó mú kó lè darí ọkọ̀ náà wálẹ̀ lọ́nà kan ṣá. Bó ṣe ń gúnlẹ̀ báyìí ló tún dákú.
Iṣẹ́ Ìsìn Mìíràn Tún Yọjú
Lọ́dún 1988, wọ́n ní ká padà sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó wà nílùú Port Moresby, nítorí pé wọ́n nílò èèyàn sí i níbi iṣẹ́ ìtumọ̀. Àwa èèyàn bí àádọ́ta ló ń gbébẹ̀ tá a sì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ bí ìdílé kan ní ẹ̀ka náà, a tún máa ń dá àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń di atúmọ̀ èdè lẹ́kọ̀ọ́. Gbogbo wa ni wọ́n fún ní yàrá kọ̀ọ̀kan tó mọ níwọ̀nba. Ńṣe lèmi àti John máa ń ṣílẹ̀kùn yàrá wa sílẹ̀ káwọn tá a jọ ń gbébẹ̀ àtàwọn àlejò lè máa yà kí wa ká lè di ojúlùmọ̀ ara wa. Ìyẹn ló wá jẹ́ ká mojú àwọn tá a jọ wà nínú ìdílé wa yìí dáadáa tó sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti nífẹ̀ẹ́ ara wa tá a sì máa ń ran ara wa lọ́wọ́.
Nígbà tó wá di ọdún 1993, àrùn ọkàn pa John ọkọ mi. Ńṣe ló dà bíi pé apá kan nínú ara mi ti kú. Ọdún méjìdínlógójì la fi jọ jẹ́ tọkọtaya, gbogbo àkókò yẹn la sì jọ lò pa pọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Síbẹ̀, mo pinnu láti máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi lọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Mo ṣì máa ń ṣílẹ̀kùn mi sílẹ̀, àwọn ọ̀dọ́ sì máa ń wá sọ́dọ̀ mi dáadáa. Irú ìbákẹ́gbẹ́ tó gbámúṣé bẹ́ẹ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe máa banú jẹ́.
Lọ́dún 2003, wọ́n ní kí n lọ máa sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti ìlú Sydney tó wà ní Ọsirélíà nítorí pé ara mi ò le bíi ti tẹ́lẹ̀. Lónìí, tí mo ti dẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, mo ṣì ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìtúmọ̀ Èdè, mo sì tún máa ń wàásù déédéé. Àwọn ọ̀rẹ́ mi, àwọn ọmọ mi, àtàwọn ọmọ ọmọ mi nípa tẹ̀mí máa ń fún mi láyọ̀ gan-an ní gbogbo ìgbà.
Ilẹ̀kùn yàrá mi ní Bẹ́tẹ́lì ṣì máa ń wà ní ṣíṣí sílẹ̀, bóyá la sì fi rí ọjọ́ kan tí mi ò kì í gbàlejò. Kódà, bí mo bá ti ilẹ̀kùn mi, àwọn èèyàn sábà máa ń kanlẹ̀kùn láti mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ṣì ń mí, mi ò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí mi lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi, màá sì máa sin Jèhófà Ọlọ́run títí lọ.—2 Tímótì 4:5.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lákòókò yẹn, ńṣe ni wọ́n pín apá ìlà oòrùn erékùṣù náà sí méjì, Papua ní ìhà gúúsù àti New Guinea ní ìhà àríwá. Lóde òní, Papua ni wọ́n ń pe apá ìwọ̀ oòrùn erékùṣù yìí tó jẹ́ apá kan ilẹ̀ Indonesia, wọ́n sì ń pe apá ìlà oòrùn rẹ̀ ní Papua New Guinea.
b Ìtàn ìgbésí ayé John Cutforth wà nínú Ile-Iṣọ Na ti June 1, 1958, ojú ìwé 333 sí 336 (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 18]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
NEW GUINEA
ỌSIRÉLÍÀ
Sydney
INDONESIA
PAPUA NEW GUINEA
Talidig
Madang
PORT MORESBY
NEW BRITAIN
Rabaul
Vunabal
Wide Bay
Waterfall Bay
[Credit Line]
Map and globe: Based on NASA/Visible Earth imagery
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Èmi àti John rèé nípàdé àgbègbè kan tá a ṣe nílùú Lae, New Guinea, lọ́dún 1973
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Nígbà ti mo wà ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti ìlú Papua New Guinea lọ́dún 2002