Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Títẹ́ Awọn ti Ebi Tẹmi Ń Pa Lọ́rùn—Ni Ile-ẹkọ
“ALAYỌ ni awọn ti aini wọn nipa tẹmi jẹ lọkan,” ni Jesu sọ ninu Iwaasu rẹ̀ lori Oke. (Matteu 5:3, NW) Ọpọ awọn ọmọ ile-ẹkọ ni oungbẹ ń gbẹ fun ìmọ̀ Ọlọrun ati awọn ète rẹ yiyanilẹnu. Wọn fẹ́ awọn idahun si awọn ibeere nipa igbesi-aye, wọn sì fẹ́ mọ bi wọn ṣe nilati gbé ki wọn baa lè rí itẹwọgba Ọlọrun ki wọn si layọ. Eyi ni ó hàn gbangba ni ile-ẹkọ kan ni Erekuṣu Virgin ti Britain. Ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nibẹ sọ bayii:
◻ “Mo lọ si ipade awọn òbí ati olukọ ni ilẹ-ẹkọ adugbo, pupọ ni a si sọ nipa oògùn líle, ọti mimu, dida ọjọ ajọrode, wiwo tẹlifiṣọn, ipò, ati awọn ọ̀ràn miiran, nitori naa, mo pinnu lati mu iwe naa Questions Young People Ask—Answers That Work ki n sì fifun ọ̀gá obinrin ile-ẹkọ naa. Lẹhin ti o ṣayẹwo iwe naa, o sọ pe ohun ti wọn nilo gan-an ni ó si beere bi ile-ẹkọ naa ba lè gba ẹ̀dà kan fun ọkọọkan awọn 120 akẹkọọ naa. Ọ̀ràn naa ni a jiroro pẹlu awọn alagba ijọ, wọn si pinnu lati fi awọn iwe naa tọrẹ fun ile-ẹkọ naa. Nigba ti a mẹnukan eyi, awọn olukọ naa ni ki a fun awọn akẹkọọ ni iwe naa. Awọn Ẹlẹ́rìí meji lọ, iyàrá naa si kún fun awọn akẹkọọ ti wọn ń duro dè wọn. Awọn ara naa sọrọ fun ọgbọ́n iṣẹju, awọn iriri ti ń fihàn bi iwe naa ti ṣe ran tọmọde tagba lọwọ ni a sì kà lati inu awọn iwe irohin Watch Tower Society. Lẹhin naa ni a fi iwe naa fun awọn akẹkọọ oniharagaga naa.”
O jẹ́ ohun ayọ lati mọ pe ile-ẹkọ naa ti pinnu lati lo iwe naa gẹgẹ bi apakan ilana-ẹkọ fun awọn kilaasi ọlọdun kẹrin ati ikarun un ni ile-ẹkọ alakọọbẹrẹ. Nitootọ ni yoo dahun ọpọ awọn ibeere ti awọn akẹkọọ wọnyi ní nipa igbesi-aye ati ọjọ-ọla.
Títẹ́ Awọn Ti Ebi Tẹmi Ń Pa Lọrun—Ni Papua New Guinea
Iriri ti o tẹle e yii ni a rigba lati ọwọ́ alaboojuto arinrin-ajo kan. O ṣapejuwe bi ebi tẹmi ti ṣe ń pa awọn eniyan tó ni orilẹ-ede yẹn ati bi awọn itẹjade wa ti a gbekari Bibeli ti gbeṣẹ tó ni títẹ́ ebi wọn lọrun.
◻ “Bi o ti jẹ pe kò ṣeeṣe fun mi lati ṣebẹwo si abule Kamberatoro,” ni alaboojuto naa sọ, “mo lo akoko mi lati ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọ kekere ti o wà ni Vanimo. Wọn fi ifẹ pupọ hàn nibẹ. Iye awọn eniyan kan lati Bewani gba awọn iwe ikẹkọọ. Ọkunrin kan késí mi lati wa bẹ abule yii wò, ó sì ṣetan lati pese ibùwọ̀ fun mi. Ọpọ eniyan ti di ojulumọ pẹlu awọn iwe ikẹkọọ wa. Ni gbogbo ìgbà ti a ba ti lọ si ilu Vanimo, ni awọn iwe ikẹkọọ wa kìí tó, bi o tilẹ jẹ pe a lọ pẹlu awọn apoti iwe mẹta. Iwe Itan Bibeli Mi ni a kà si eyi ti o niyelori gan-an gẹgẹ bi goolu. Awọn eniyan ń wá iwe naa. Awọn iwe ti mo kó dani ni mo fi sode ni kiakia. Nigba ti a bá fi awọn iwe ikẹkọọ wa han awọn eniyan, awọn kan yoo beere pe: ‘Iwe alawọ ìyeyè yẹn ń kọ́?’ Ọkunrin kan beere fun mẹfa. O fun mi ni orukọ ati adirẹsi rẹ̀ o sì ni ki n ṣe ikede lori redio nigba ti mo ba ti ri wọn gbà. Oun nigba naa yoo si wá lati abule rẹ̀ lati gbà wọn.” Alaboojuto arinrin-ajo naa fikun un pe: “Mo rii pe ọpọ eniyan ni Vanimo tẹwọgba awọn iwe naa Mankind’s Search for God ati Questions Young People Ask—Answers That Work.”
Eyi ṣapejuwe bi ebi ti ṣe ń pa awọn eniyan alailaboosi ọkàn tó fun ounjẹ tẹmi ti a ri ninu Bibeli ati awọn itẹjade ti Jehofa ti pese nipasẹ “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa.” (Matteu 24:45-47, NW) Ẹ wo bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti layọ tó lati lè ran awọn ẹni ti ebi otitọ ń pa wọnyi lọwọ!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Jijẹrii ni Papua New Guinea