Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
‘Alayọ Ni Awọn Ẹni Ti Ebi Npa Nipa Tẹmi’
JESU wi pe: “Alayọ ni awọn wọnni ti aini wọn nipa tẹmi njẹ lọkan.” (Matiu 5:3, NW) Iru awọn bẹẹ yoo wá isọfunni ti nfunni ni iye lati inu Ọrọ Ọlọrun, Bibeli, gbigba imọ yii sinu yoo sì ṣamọna wọn si iye ainipẹkun.—Matiu 4:4; Johanu 17:3.
◻ Ẹnikan ti ebi tẹmi npa ni ilẹ Africa kan rin fun wakati mẹrin ninu otutu ati okunkun ki o baa le ri ẹda Iwe Itan Bibeli Mi kan gbà. Ni dide abule ibi ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti nwaasu, a ja a kulẹ lọna ti o ba a ninu jẹ́ lati rii pe iwe ti o ṣẹku ni a ti fi sode. O duro ni abule naa fun ọjọ mẹta titi di igba ti wọn le ri afikun ipese iwe naa gba, inu rẹ sì dun nigbẹhin-gbẹhin lati ni isọfunni rere tẹmi yii lọwọ.
Laaarin oṣu ti wọn fi wà ni agbegbe àdádó yii, awọn Ẹlẹrii naa pin 55 iwe nla, 365 iwe pẹlẹbẹ, ati 145 iwe irohin kiri, wọn si gba asansilẹ-owo 5. A ru wọn soke gidigidi gẹgẹ bi wọn ti nlọ, nigba ti tagbatewe nke tẹle wọn lẹhin ni ede Kpelle pe: “Njẹ ki Jehofa wa pẹlu yin!” Awọn isapa ni a nṣe lati ṣiṣẹ lori ifẹ naa.
Ẹlomiran ní ilu yii kan naa ni ebi tẹmi tun npa. Oun jẹ akapo fun ṣọọṣi rẹ̀ ati oṣiṣẹ ere ìnàjú fun ẹkùn rẹ̀. Nigba ti awọn Ẹlẹrii ke sii, o fi tẹkuntẹkun jẹwọ pe ṣọọṣi ko kájú awọn ohun ti Bibeli nbeere fun isin Kristẹni rárá. Awọn Ẹlẹrii naa fi bi yoo ti dá isin tootọ mọ han an lati inu Bibeli tirẹ funraarẹ. Nigba naa o lọ si awọn ipade ni Gbọngan Ijọba ati lẹhin naa o sọ pe: “Ohun ti mo ri ti mo sì gbọ́ mu un dá mi loju pe eyi ni otitọ naa.” A wu u lori nipa awọn ipade ati ihuwasi awọn wọnni ti wọn wa nibẹ. O rii pe ohun ti awọn Ẹlẹrii naa ti o kesi i ti sọ kii ṣe ohun kan ti wọn ti humọ ṣugbọn ohun kan ti o jẹ otitọ. Oun ti gbe igbesẹ lati igba naa lati já ibatan rẹ̀ pẹlu ṣọọṣi kuro, eyi si ti yọrisi ẹ̀rí rere ni awujọ naa.
◻ Katikiisi ọdọ ara Melanesia kan ni New Caledonia ni ebi npa nipa tẹmi. O ri ẹda iwe naa Otitọ ti Nsinni Lọ si Iye Aiyeraiye lori tabili ninu ile iya rẹ̀, o si ka ori keji ati ikẹta. Awọn ẹsẹ iwe Bibeli Ẹkisodu 20:4, 5 ati Johanu 4:23, 24 ti a jiroro nibẹ wọ ọ lọkan. Loju iwoye ohun ti iwe mimọ wọnyi sọ, o beere lọwọ alufaa rẹ̀ idi ti Ṣọọṣi Katoliki fi faye gba ìlò ere ninu ijọsin. Alufaa naa yẹ ibeere naa silẹ. Ọkunrin naa lọ sọdọ awọn isin “Kristẹni” melookan miiran, ṣugbọn wọn ko fun un ni awọn idahun ti ntẹnilọrun si ibeere rẹ̀. Nikẹhin o pinnu lati lọ si ipade awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa pẹlu iya rẹ̀, ẹni ti o ti fi ifẹ han ninu otitọ. Ifẹ ti o rí laaarin awọn Ẹlẹrii naa ati awọn ẹkọ wọn ti a gbekari Bibeli wu u lori gan an.
Laika ọna jinjin si, oun nwọ awọn ọkọ ajawọ lọ si awọn ipade deedee, o yara mu iduro fun otitọ, a si baptisi rẹ̀. Nisinsinyi oun jẹ iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kan. Iya rẹ̀ ati meji lara awọn arabinrin rẹ̀ nipa ti ara tun di Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ọdọkunrin naa waasu fun awọn ara ilu tirẹ funraarẹ o si bẹrẹ ọpọlọpọ ikẹkọọ Bibeli. Nisinsinyi lara wọn nwa si awọn ipade ni agbegbe yii—gbogbo rẹ nitori pe o ṣẹlẹ pé ọdọkunrin kan ṣakiyesi iwe kan ti nṣalaye Bibeli lori tabili, o kẹkọọ rẹ, o si fọwọ pataki mu ohun ti ó kọ́.
Jehofa ní itolẹsẹẹsẹ nla ti ìfoúnjẹ tẹmi bọ́ni ti nlọ lọwọ lonii, ogunlọgọ si njanfaani lati inu rẹ̀. Aisaya sọtẹlẹ lọna ti o ṣe wẹku nipa rẹ̀ nigba ti o sọ pe: “Sawo o! awọn iranṣẹ mi yoo jẹun, ṣugbọn ẹyin funraayin [awọn mẹmba isin eke] yoo kébi.” (Aisaya 65:13, NW) Alayọ ni wa bi awa ba janfaani lati inu awọn ipese Jehofa fun pipa ebi wa tẹmi.