Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ṣíṣẹ́pá Ìpèníjà ní “Ilẹ̀ Ìyanu”
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù bi àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ní Kọ́ríńtì pé: “Bí kàkàkí bá mú ìpè kan tí kò dún ketekete jáde, ta ni yóò gbára dì fún ìjà ogun? Ní ọ̀nà kan náà pẹ̀lú, láìjẹ́ pé ẹ̀yin sọ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn láti lóye jáde nípasẹ̀ ahọ́n, báwo ni a óò ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ?”—Kọ́ríńtì Kíní 14:8, 9.
Ní Papua New Guinea, tí a máa ń pè ní Ilẹ̀ Ìyanu nígbà míràn, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣalábàápàdé ìdènà tí ń páni láyà ní kíkéde ìhìn iṣẹ́ ṣíṣe ketekete nípa Bíbélì. Wọ́n ń wàásù fún àwọn ènìyàn tí ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ó lé ní 700, tí wọ́n sì ní onírúurú àṣà ìbílẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà tún máa ń dojú kọ ìṣòro àwọn òkè gíga, àìsí títì, àti ìwà ọ̀daràn tí ó túbọ̀ ń ga sí i. Yàtọ̀ sí gbogbo ìnira wọ̀nyí, àtakò máa ń wá láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ ìsìn kan àti ní àwọn ìgbà míràn, láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ pàápàá.
Síbẹ̀síbẹ̀, ìtọ́ni tẹ̀mí jíjíire àti onírúurú àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ń pọ̀ sí i ní àwọn èdè ìbílẹ̀, ń mú Àwọn Ẹlẹ́rìí gbára dì láti sọ ìhìn rere náà gẹ́gẹ́ bí ìpè kàkàkí dídún ketekete. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń dáhùn pa dà lọ́nà rere, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn tí ó tẹ̀ lé e yìí ti fi hàn:
• Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ilé ẹ̀kọ́ tuntun, olùkọ́ kan fẹ́ mọ ìdí tí àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í kí àsíá tàbí kọ orin orílẹ̀-èdè. Ó darí ìbéèrè rẹ̀ sí Maiola, akẹ́kọ̀ọ́ tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 13, tí ó sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí ó ti ṣe ìrìbọmi. Maiola ṣàlàyé tí ó ṣe kedere, tí a gbé karí Ìwé Mímọ́. Olùkọ́ náà tẹ́wọ́ gba àlàyé rẹ̀ níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé orí Bíbélì ni ó gbé e kà. A tún ṣàjọpín àlàyé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ yòó kù ní ilé ẹ̀kọ́.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí a sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti kọ àròkọ, Maiola yan kókó ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Àròkọ rẹ̀ ni ó gba máàkì tí ó ga jù lọ ní kíláàsì náà, olùkọ́ náà sì béèrè ibi tí ó ti rí ìsọfúnni náà. Ó fi ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lédè Gẹ̀ẹ́sì hàn án. Olùkọ́ náà tẹ̀ síwájú láti fi ìwé náà han gbogbo kíláàsì náà, ọ̀pọ̀ sì ń fẹ́ láti gba ẹ̀dà tiwọn. Ní ọjọ́ kejì, Maiola fi ìwé ńlá 14 àti ìwé ìròyìn 7 síta fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú mẹ́ta nínú wọn. Góńgó Maiola jẹ́ láti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún kan.
• Láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970 ni àwùjọ àdádó kan ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní abúlé etíkun kan nítòsí Port Moresby ti dojú kọ àtakò. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ yìí, wọ́n rí ìrànwọ́ gbà láti orísun kan tí wọn kò retí. Ní ọjọ́ kan, bíṣọ́ọ̀bù Ṣọ́ọ̀ṣì United tí ó wà níbẹ̀, ọmọ ilẹ̀ Papua New Guinea tí ó kẹ́kọ̀ọ́ nílẹ̀ òkèèrè, ké sí àwùjọ tí ń bẹ nínú ṣọ́ọ̀ṣì láti béèrè ìbéèrè. Ọkùnrin kan béèrè pé: “Ẹ̀sìn méjì ni ó wà ní abúlé wa—Ṣọ́ọ̀ṣì United àti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí ni kí a ṣe nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí bá wá sí ẹnu ọ̀nà wa?” Lẹ́yìn dídákẹ́ fún àkókò gígùn, bíṣọ́ọ̀bù náà fèsì pé: “Ṣé ẹ rí i, n kò mọ ohun tí ó yẹ kí n sọ fún yín. Láìpẹ́ yìí, àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí méjì kan wá sí ẹnu ọ̀nà mi. Wọ́n béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ mi, n kò mọ ìdáhùn rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ní yunifásítì. Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn ìbéèrè náà nírọ̀rùn láti inú Bíbélì. Nítorí náà, n kò ní í sọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe fún yín—n óò fi í sílẹ̀ fún yín. Kò pọn dandan fún yín láti fetí sílẹ̀ bí ẹ kò bá fẹ́ fetí sílẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ máà bá wọn fàjọ̀ngbọ̀n.”
Arìnrìn-àjò aṣojú Watch Tower Society tí ó bẹ àwùjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí wò lẹ́yìn ìgbà náà ròyìn pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn tí ń bẹ ní abúlé náà ni ó ń fetí sí Àwọn Ẹlẹ́rìí nígbà tí wọ́n bá lọ wàásù. Àwọn kan tilẹ̀ fọ̀yàyà ké sí wọn wọlé. Ìgbádùn ńlá ni ó jẹ́ láti wàásù níbẹ̀ nísinsìnyí.”