ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 3
  • O Lè Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Tọ́jú Ara Rẹ!
  • Máa Ṣe Àwọn Nǹkan Tó Máa Jẹ́ Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I
    Jí!—2011
  • 1 | Tọ́jú Ara Rẹ
    Jí!—2022
  • Aráyé Ń Fẹ́ Ìlera Tó Jíire!
    Jí!—2007
  • Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Ìlànà Ìwé Mímọ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Ìtọ́jú Ara
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 3

O Lè Mú Kí Ìlera Rẹ Dára Sí I

ORÍLẸ̀-ÈDÈ Rọ́ṣíà ni Rustam ń gbé, ọwọ́ rẹ̀ sì máa ń dí gan-an. Nígbà kan, ó ń dá àwọn àṣà kan tí kò dáa ó sì wá rí i pé ó ń ṣèpalára fún ìlera òun. Ó jáwọ́ nínú sìgá mímu àti ọtí àmujù. Síbẹ̀ bó ṣe máa ń jókòó pẹ́ nídìí kọ̀ǹpútà lójoojúmọ́ kì í jẹ́ kí ara rẹ̀ yá gágá.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aago mẹ́jọ àárọ̀ ni Rustam máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó máa ń tó nǹkan bí aago mẹ́wàá àárọ̀ kí ara rẹ̀ tó yá gágá, ó sì sábà máa ń ṣàìsàn. Torí náà, ó yí àwọn nǹkan kan tó máa ń ṣe pa dà. Kí ló wá jẹ́ àbájáde rẹ̀? Rustam ṣàlàyé pé: “Láti ọdún méje sẹ́yìn, kò tíì ju ìgbà méjì tí mo pa ibi iṣẹ́ jẹ nítorí àìsàn. Ara mi le, ó yá gágá, mo sì ń gbádùn ara mi!”

Orílẹ̀-èdè Nepal ni Ram, ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn méjì ń gbé. Àdúgbò wọn dọ̀tí, torí náà ẹ̀fọn àti eṣinṣin kún ibẹ̀ fọ́fọ́. Ìgbà kan wà tí Ram àti ìdílé rẹ̀ sábà máa ń ní àrùn kan tí kì í jẹ́ kí wọ́n lè mí dáadáa àti àrùn ojú. Àwọn náà ṣe àwọn ìyípadà kan tó mú kí ìlera wọn túbọ̀ dára sí i.

Máa Tọ́jú Ara Rẹ!

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé ohun tí àwọn ti sọ dàṣà lè nípa lórí ìlera àwọn, yálà wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì. Wọ́n lè máa wò ó pé níní tí àwọn ní ìlera tó dáa kàn ṣèèṣì ni tàbí kí wọ́n rò pé kò sóhun tí àwọn lè ṣe sí ọ̀rọ̀ ìlera àwọn. Irú èrò yìí ni kì í jẹ́ kí ọ̀pọ̀ ṣe ohun tó máa mú kí ìlera wọn sunwọ̀n sí i, kí wọ́n sì máa gbé ìgbé ayé tó máa ṣe wọ́n láǹfààní.

Ká sòótọ́, yálà o jẹ́ olówó tàbí tálákà, àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ, kó o sì mú kí ìlera rẹ àti ti ìdílé rẹ dára sí i. Ṣé àǹfààní tiẹ̀ wà nínú ṣíṣe àwọn nǹkan yìí? Bẹ́ẹ̀ ni! O lè mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbé ayé rẹ dára sí i, kó o má sì dá ẹ̀mí rẹ légbodò.

Àwọn òbí lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu wọn àti àpẹẹrẹ wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àṣà tó dára, èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n ní ìlera tó jí pépé. Àkókò tó o máa lò àti owó tó o máa ná láti dènà àìsàn kò tó àkókò tó o máa lò nígbà tí àìsàn bá dé àti owó tó o máa san nílé ìwòsàn. Bí wọ́n ṣe máa ń sọ, igi ganganran máà gún mi lójú, àtòkèèrè la ti ń lọ̀ ọ́.

Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa ṣàgbéyẹ̀wò ohun márùn-ún tó ran Rustam, Ram àti ọ̀pọ̀ èèyàn míì lọ́wọ́. Àwọn nǹkan yìí lè ran ìwọ náà lọ́wọ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Rustam

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ram ń ra omi tó mọ́ tí ìdílé rẹ̀ máa lò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́