ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 8
  • Ohun 5—Ran Ara Rẹ àti Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun 5—Ran Ara Rẹ àti Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́
  • Jí!—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Tí Àìsàn Bá Dé Láìròtẹ́lẹ̀
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìlera Tó Dáa
    Jí!—2019
  • 1 | Tọ́jú Ara Rẹ
    Jí!—2022
  • Ẹ Máa Tẹ̀ Lé Ìlànà Ìwé Mímọ́ Lórí Ọ̀rọ̀ Ìtọ́jú Ara
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 8

Ohun 5​—Ran Ara Rẹ àti Ìdílé Rẹ Lọ́wọ́

“Ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà.” (Òwe 13:16) Tó o bá mọ àwọn ìsọfúnni pàtó nípa ọ̀ràn ìlera, ó máa jẹ́ kó o lè ṣe àwọn àtúnṣe pàtàkì sí ọ̀ràn ìlera rẹ àti ti ìdílé rẹ.

◯ Máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Àwọn àjọ kan tó jẹ́ ti ìjọba àti èyí tí àwọn kan dá sílẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn ìwé tó dá lórí onírúurú ọ̀ràn ìlera. Tó o bá lo àǹfààní tó wà nínú irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀, wàá lè mọ àwọn ọ̀nà pàtó tó o lè gbà mú kí ìlera rẹ sunwọ̀n sí i, kó o má sì máa fi ẹ̀mí ara rẹ wewu. Múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́, kó o sì ṣe àwọn àtúnṣe pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tó bá yẹ.

Àwọn àṣà rere tó o bá kọ́ tó o sì fi sílò lè ṣe ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ àtàwọn ọmọ ọmọ rẹ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú. Bí àwọn òbí bá fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa jíjẹ oúnjẹ tó ṣara lóore, ìmọ́tótó, oorun sísùn, eré ìmárale àti dídènà àrùn, ó ṣeé ṣe kó ṣe àwọn àtọmọdọ́mọ wọn láǹfààní.—Òwe 22:6.

◯ Kí làwọn nǹkan míì tá a tún nílò? Kéèyàn tó lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbé ayé tó máa jẹ́ kó ní ìlera tó dáa kó sì máa bá a lọ bẹ́ẹ̀, ó kọjá ohun tó kàn wu èèyàn láti ṣe. Ó máa ń ṣòro gan-an láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà kan tó ti mọ́ni lára, ṣíṣe àtúnṣe kékeré pàápàá máa ń gba pé kéèyàn rẹ́ni fún òun ní ìṣírí. Kódà, pé èèyàn lè ṣàìsàn tó le koko tàbí pé èèyàn lè kú pàápàá kò ní kí àwọn ẹlòmíì ṣe ohun tí wọ́n mọ̀ pé ó dára. Kí ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́? Gbogbo wa pátá ló yẹ kó máa rántí ìdí tí Ọlọ́run fi dá àwa èèyàn.

Àwọn tọkọtaya ní láti ní ìlera tó dáa kí wọ́n lè máa ran ara wọn lọ́wọ́ nìṣó. Àwọn òbí fẹ́ máa bá a nìṣó láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n sì máa tọ́ wọn. Àwọn ọmọ tó ti dàgbà ní láti máa ṣàbójútó àwọn mọ̀lẹ́bí tó ti dàgbà. Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan tó tọ́ tá a nífẹ̀ẹ́ sí yìí, gbogbo wa la fẹ́ ṣe ìlú wa láǹfààní dípò ká jẹ́ bùkátà sí wọn lọ́rùn. Èyí sì gba pé ká nífẹ̀ẹ́, kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn sì jẹ wá lógún.

Ohun míì tó tún yẹ kó ràn wá lọ́wọ́ ni ìmọrírì àti ìfọkànsin tá a ní fún Ẹlẹ́dàá wa. Àwọn tó gba Ọlọ́run gbọ́ máa ń fẹ́ dáàbò bo ẹ̀bùn pàtàkì tó fún wa yìí, ìyẹn ìwàláàyè wa. (Sáàmù 36:9) Tí ara wa bá le, á ṣeé ṣe fún wa láti sin Ọlọ́run dáadáa. Kò sí ohun míì tó lè fún wa ní ìṣírí láti bójú tó ìlera wa ju ìyẹn lọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Jẹ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn gbé ìgbé ayé tó máa mú kó ní ìlera tó dáa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́