ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 4/11 ojú ìwé 16-17
  • Ǹjẹ́ Fífi Ìyà Jẹ Ara Ẹni Lè Múni Sún Mọ́ Ọlọ́run?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Fífi Ìyà Jẹ Ara Ẹni Lè Múni Sún Mọ́ Ọlọ́run?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Ṣìkẹ́ Ara Rẹ
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Fi Irú Ìyà Tí Jésù Jẹ Dánra Wò?
  • Àṣà Yìí Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu
  • Ìjọsìn Ta Ni Ọlọrun Tẹ́wọ́gbà?
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Má Ṣe Ya Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Lẹ́yìn Tí Jésù Jíǹde, Ṣé Ara Èèyàn Ló Ṣì Ní àbí Ó Ti Di Ẹ̀dá Ẹ̀mí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 4/11 ojú ìwé 16-17

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ǹjẹ́ Fífi Ìyà Jẹ Ara Ẹni Lè Múni Sún Mọ́ Ọlọ́run?

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ni kò fara mọ́ kéèyàn máa fìyà jẹ ara rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn èèyàn ka àwọn olùjọsìn tó ń lọ́wọ́ nínú àṣà kéèyàn máa fìyà jẹ ara rẹ̀ sí àpẹẹrẹ àwọn tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, irú bíi kí wọ́n máa fi pàṣán na ara wọn, gbígba ààwẹ̀ àgbàyípo tàbí wíwọ àwọn aṣọ onírun tó máa ń gúnni lára. Àwọn àṣà náà kì í wulẹ̀ ṣe àṣà àtijọ́ o. Ìròyìn kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ pé, kódà àwọn tó jẹ́ èèkàn nínú àwọn aṣáájú ẹ̀sìn lóde òní ti lọ́wọ́ nínú àṣà kéèyàn máa fi ìyà jẹ ara rẹ̀.

Kí ló ń mú kí àwọn èèyàn máa jọ́sìn ní irú ọ̀nà yẹn? Nínú ọ̀rọ̀ kan tí agbẹnusọ fún àjọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan sọ, ó ní: “Bí èèyàn bá ń dìídì ṣe ohun tó máa ni ín lára, ọ̀nà kan ló jẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ Kristi àti ìyà tó dìídì jẹ kó bàa lè rà wá pa dà.” Láìka ohun tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn sọ sí, kí ni Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn yìí?

Máa Ṣìkẹ́ Ara Rẹ

Bíbélì kò fìgbà kankan fọwọ́ sí àṣà pé kéèyàn torí pé òun fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run, kó wá máa fìyà jẹ ara rẹ̀. Kódà, Bíbélì fún àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ní ìṣírí pé kí wọ́n máa tọ́jú ara wọn. Ṣàyẹ̀wò bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ìfẹ́ tó wà láàárín ọkọ àti ìyàwó. Ó tọ́ka sí ọ̀nà tí ọkùnrin kan ń gbà ṣìkẹ́ ara rẹ̀, ó wá rọ àwọn ọkọ pé: “Ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. . . . Kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.”—Éfésù 5:28, 29.

Ǹjẹ́ àṣẹ tí Bíbélì pa pé kí àwọn ọkọ nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn á ní ìtumọ̀ kankan tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run retí pé kí àwọn olùjọ́sìn òun máa fìyà jẹ ara wọn nígbà ìjọsìn? Ó hàn gbangba pé Ọlọ́run retí pé kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ìlànà rẹ̀ máa ṣìkẹ́ ara wọn, kódà ó fẹ́ kí wọ́n ní ìfẹ́ ara àwọn fúnra wọn, èèyàn sì gbọ́dọ̀ máa fi irú ìfẹ́ tó ní sí ara rẹ̀ hàn sí ọkọ tàbí aya rẹ̀.

Ó bá a mu pé Bíbélì ní àwọn ìlànà tó máa ran àwọn tó ń kà á lọ́wọ́ láti máa ṣìkẹ́ ara wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa ṣe eré ìmárale tó mọ níwọ̀n. (1 Tímótì 4:8) Ó jẹ́ ká mọ bí àwọn oúnjẹ kan ti ṣe pàtàkì tó fún ìlera wa, ó sì sọ àkóbá tí jíjẹ oúnjẹ tí kò ṣara lóore máa ń ṣe fún ara wa. (Òwe 23:20, 21; 1 Tímótì 5:23) Ìwé Mímọ́ fún àwọn èèyàn ní ìṣírí pé kí wọ́n máa ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n ní ìlera tó dáa, torí pé ìyẹn ló máa jẹ́ kí wọ́n lókun láti ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. (Oníwàásù 9:4) Bí a bá retí pé kí àwọn tó ń ka Bíbélì máa tọ́jú ara wọn lọ́nà yìí, ṣé a tún wá lè rétí pé kí wọ́n máa fìyà jẹ ara wọn?—2 Kọ́ríńtì 7:1.

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Fi Irú Ìyà Tí Jésù Jẹ Dánra Wò?

Síbẹ̀, àwọn kan máa ń ṣàṣìṣe nípa títọ́ka sí ìyà tí Kristi àti àwọn ọmọlẹ́yìn ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní jẹ, tí wọ́n á sì máa fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn ní ìṣírí láti máa fìyà jẹ́ ara wọn lóde òní. Àmọ́ kì í ṣe pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wọ̀nyẹn ló ń fìyà jẹ ara wọn. Nígbà tí àwọn Kristẹni tó kọ Bíbélì bá tọ́ka sí ìyà tí Kristi jẹ, ńṣe ni wọ́n kàn fi ń fún àwọn Kristẹni ní ìṣírí láti fara da inúnibíni, kì í ṣe kí wọ́n lè ṣe inúnibíni sí ara àwọn fúnra wọn. Torí náà, kì í ṣe àpẹẹrẹ Jésù Kristi ni àwọn tó ń dá ara wọn lóró ń tẹ̀ lé.

Bí àpẹẹrẹ: Ká sọ pé o rí i tí àwọn jàǹdùkú kan ń bú ọ̀rẹ́ rẹ tó o fẹ́ràn gan-an tí wọ́n sì ń lù ú. Àmọ́, o wá ṣàkíyèsí pé gbogbo bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ ọ̀rẹ́ rẹ yìí, ńṣe ló dákẹ́, kò tiẹ̀ bá wọn fa nǹkan kan, kò sì bú wọn. Tó o bá fẹ́ fara wé ọ̀rẹ́ rẹ yìí, ǹjẹ́ ńṣe ni wàá máa lu ara rẹ tí wàá sì máa bú ara rẹ? Rárá o! Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn jàǹdùkú lò ń fara wé yẹn. Ohun tó o kàn máa ṣe ni pé o kò ní gbẹ̀san bí wọ́n bá gbéjà kò ẹ́.

Ó ṣe kedere nígbà náà pé, a ò retí pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa dá ara wọn lóró, bíi pé wọ́n fẹ́ máa fara wé àwọn jàǹdùkú tínú ń bí, tí wọ́n dá Jésù lóró tí wọ́n sì fẹ́ pa á. (Jòhánù 5:18; 7:1, 25; 8:40; 11:53) Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbàkigbà tí wọ́n bá ń ṣe inúnibíni sí wọn, wọ́n ní láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tó fi ìwà pẹ̀lẹ́ àti ẹ̀mí aláàfíà fara da ìnira.—Jòhánù 15:20.

Àṣà Yìí Kò Bá Ìwé Mímọ́ Mu

Kódà kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, Ìwé Mímọ́ tó ń darí ìgbésí ayé àwọn Júù àti ìjọsìn wọn kò gbà wọ́n láyè láti máa ṣe ohunkóhun tó máa ṣe ìpalára fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, Òfin dìídì kà á léèwọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ fi abẹ ya ara wọn lára, èyí sì jẹ́ àṣà tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ìgbàanì tí kì í ṣe Júù. (Léfítíkù 19:28; Diutarónómì 14:1) Bí Ọlọ́run kò bá fẹ́ ká máa fi abẹ ya ara wa lára, ṣé ó máa wá fẹ́ kí á máa fi ẹgba na ara wa. Ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn yìí ṣe kedere, Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba kéèyàn máa mọ̀ọ́mọ̀ dá ọgbẹ́ sí ara rẹ̀ lára lọ́nàkọnà.

Bí oníṣẹ́ ọnà kan kò ṣe ní fẹ́ káwọn èèyàn ba iṣẹ́ ọwọ́ òun jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá, kò ṣe fẹ́ ká máa ṣèpalára fún ara wa tó jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. (Sáàmù 139:14-16) Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, fífi ìyà jẹ ara ẹni kò ní kí àjọṣe àwa èèyàn pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló máa sọ àjọṣe náà di ahẹrẹpẹ, táá sì gbé àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé Ìhìn Rere gbòdì.

Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé nípa àwọn ẹ̀kọ́ àwọn èèyàn lásán-làsàn yìí, pé: “Ohun wọnnì gan-an, ní tòótọ́, ní ìrísí ọgbọ́n nínú ọ̀nà ìjọsìn àdábọwọ́ ara ẹni àti ìrẹ̀lẹ̀ ẹlẹ́yà, ìfìyàjẹ ara; ṣùgbọ́n wọn kò níye lórí rárá nínú gbígbógunti títẹ́ ẹran ara lọ́rùn.” (Kólósè 2:20-23) Ká sòótọ́, àṣà kéèyàn máa dá ara rẹ̀ lóró kò ní nǹkan ṣe rárá pẹ̀lú sísún mọ́ Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Ọlọ́run retí nínú ìjọsìn tòótọ́ máa ń tuni lára, ó jẹ́ onínúure, ó sì fúyẹ́.—Mátíù 11:28-30.

KÍ LÈRÒ RẸ?

● Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo ara èèyàn?—Sáàmù 139:13-16.

● Ṣé fífìyàjẹ ara rẹ lè mú kó o mú àwọn èrò tí kò dáa kúrò lọ́kàn?—Kólósè 2:20-23.

● Ṣé ó yẹ kí ìsìn tòótọ́ jẹ́ ìnira tàbí kí ó le koko?—Mátíù 11:28-30.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

Ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn yìí ṣe kedere, Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gba kéèyàn máa mọ̀ọ́mọ̀ dá ọgbẹ́ sí ara rẹ̀ lára lọ́nàkọnà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Arìnrìn-àjò ẹ̀sìn kan ń rá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì kan

[Credit Line]

© 2010 photolibrary.com

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́