ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/11 ojú ìwé 22-23
  • Kí Nìdí Tí Wọ́n fi Kórìíra Ojúlówó Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Nìdí Tí Wọ́n fi Kórìíra Ojúlówó Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù?
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Lè Jẹ́ Pé Àìmọ̀kan Ló Ń Ṣe Wọ́n
  • Ìlara Ló Mú Kí Àwọn Kan Máa Ṣàtakò
  • Wọ́n Kórìíra Wọn Nítorí Pé Wọn “Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”
  • Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Padà?
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Jésù Yan Sọ́ọ̀lù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Èé Ṣe Tí Sọ́ọ̀lù Fi Ṣenúnibíni Sáwọn Kristẹni?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • ‘Máa Kó Ara Rẹ Níjàánu Lábẹ́ Ibi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 7/11 ojú ìwé 22-23

Ojú Ìwòye Bíbélì

Kí Nìdí Tí Wọ́n fi Kórìíra Ojúlówó Àwọn Ọmọlẹ́yìn Jésù?

“Àwọn ènìyàn yóò fà yín lé ìpọ́njú lọ́wọ́, wọn yóò sì pa yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” —Mátíù 24:9.

ỌJỌ́ mélòó kan ṣáájú kí wọ́n tó pa Jésù ní ìpa ìkà ló sọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn. Lálẹ́ ọjọ́ tó kú ọ̀la kí wọ́n pà á, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:20, 21) Àmọ́ kí nìdí táwọn èèyàn á fi kórìíra àwọn tó ń ṣègbọràn sí Jésù, tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jésù lo ara rẹ̀ fún àwọn èèyàn, ó tu àwọn òtòṣì nínú, ó sì fi àwọn tí à ń ni lára lọ́kàn balẹ̀.

Bíbélì sọ àwọn nǹkan pàtó tó mú kí wọ́n kórìíra àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. Tá a bá gbé àwọn nǹkan náà yẹ̀ wò, a máa mọ ohun tó fà á tí wọ́n fi ń ṣe àtakò sí àwọn tó ń tọ Jésù lẹ́yìn lónìí, bí wọ́n ti ṣe sí Jésù.

Ó Lè Jẹ́ Pé Àìmọ̀kan Ló Ń Ṣe Wọ́n

Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa yín yóò lérò pé òun ti ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n wọn yóò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí pé wọn kò mọ Baba tàbí èmi.” (Jòhánù 16:2, 3) Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ṣe inúnibíni ló ń sọ pé Ọlọ́run tí Jésù ń sìn làwọn náà ń sìn, àmọ́ ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn èké àti àṣà ìbílẹ̀ ló ń darí wọn. Òótọ́ ni pé wọ́n ní “ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye.” (Róòmù 10:2) Ọ̀kan lára irú àwọn alátakò bẹ́ẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù ará Tásù, tó wá di Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù.

Sọ́ọ̀lù jẹ́ ara ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní àwọn Farisí, wọ́n lẹ́nu gan-an nínú ọ̀ràn ìṣèlú, wọ́n sì tún jẹ́ ẹ̀ya ìsìn àwọn Júù tó lẹ́nu láwùjọ, wọ́n sì máa ń ṣàtakò sí ẹ̀sìn Kristẹni. Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo jẹ́ asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi. Ó tún sọ pé: “Mo jẹ́ aláìmọ̀kan, tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ nínú àìnígbàgbọ́.” (1 Tímótì 1:12, 13) Àmọ́, nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, ó yí ìwà rẹ̀ pa dà láìjáfara.

Ohun kan náà ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ alátakò. Láfikún sí i, àwọn kan lára wọn bíi ti Sọ́ọ̀lù, ti wá dẹni tí wọ́n ń ṣe inúnibíni sí. Àmọ́ ṣá o, wọn kò fi ibi san ibi fún ẹnikẹ́ni, àmọ́ wọ́n tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:44) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sapá láti fi àwọn ọ̀rọ̀ yẹn sílò, wọ́n sì nírètí pé, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára àwọn tó ń ta kò wọ́n yíwà pa dà, bí Sọ́ọ̀lù ti ṣe.

Ìlara Ló Mú Kí Àwọn Kan Máa Ṣàtakò

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ṣàtakò sí Jésù ló jẹ́ pé ìlara ló mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Gómìnà Róòmù náà, Pọ́ńtù Pílátù “mọ̀ pé nítorí ìlara ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fi [Jésù] lé òun lọ́wọ́” láti kàn án mọ́gi. (Máàkù 15:9, 10) Kí nìdí tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù fi ń ṣe ìlara Jésù? Ọ̀kan lára àwọn ìdí náà ni bí Jésù ṣe fẹ́ràn àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ gbáàtúù, bẹ́ẹ̀ ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń tẹ́ńbẹ́lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Àwọn Farisí ṣàròyé pé: “Ayé ti wọ́ tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.” (Jòhánù 12:19) Bákan náà, nígbà tí àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sí ìwàásù àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, ńṣe ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n jẹ́ alátakò tún “kún fún owú,” tí wọ́n ń fìbínú sọ̀rọ̀ sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ajíhìnrere náà.—Ìṣe 13:45, 50.

Àwọn ọ̀tá mìíràn ń bínú nítorí ìwà rere àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa àwọn Kristẹni tòótọ́ pé: “Nítorí ẹ kò bá a lọ ní sísáré pẹ̀lú wọn ní ipa ọ̀nà yìí sínú kòtò ẹ̀gbin jíjìnwọlẹ̀ kan náà tí ó kún fún ìwà wọ̀bìà, ó rú wọn lójú, wọ́n sì ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ yín tèébútèébú.” (1 Pétérù 4:4) Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ lóde òní pẹ̀lú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ ń yẹra fún àwọn ìwà búburú, síbẹ̀ wọn kò ṣe bí olódodo lójú ara wọn, tàbí kí wọ́n máa ṣe bí ẹni tó sàn ju àwọn èèyàn yòókù lọ. Irú ìwà bẹ́ẹ̀ ta ko ìlànà Kristẹni, torí pé gbogbo èèyàn ni ẹlẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì nílò àánú Ọlọ́run.—Róòmù 3:23.

Wọ́n Kórìíra Wọn Nítorí Pé Wọn “Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé”

Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.” (1 Jòhánù 2:15) Ayé wo ni àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ? Ìyẹn ni àwọn èèyàn tí wọn ti sọ ara wọn di àjèjì sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì wà lábẹ ìdarí Sátánì, tó jẹ́ “ọlọrun aiye yi.”—2 Kọ́ríńtì 4:4, Bibeli Mimọ; 1 Jòhánù 5:19.

Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ayé àti àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ ń ta ko àwọn tó ń fi àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣèwàhù. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí ẹ̀yin bá jẹ́ apá kan ayé, ayé yóò máa ní ìfẹ́ni fún ohun tí í ṣe tirẹ̀. Wàyí o, nítorí pé ẹ kì í ṣe apá kan ayé, ṣùgbọ́n mo ti yàn yín kúrò nínú ayé, ní tìtorí èyí ni ayé fi kórìíra yín.”—Jòhánù 15:19.

Ó dun ni pé àwọn èèyàn kórìíra àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà torí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ ayé tí ìwà ìbàjẹ́, ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ipá kúnnú rẹ̀ yìí, tó sì jẹ́ pé Sátánì ló ń darí rẹ̀! Ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn fẹ́ sọ ayé yìí di ibi tó dùn-ún gbé, àmọ́ kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe sí alákòóso ayé yìí tí kò ṣeé fojú rí. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló lè mú Sátánì kúrò, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa pa á run yán-án-yán, bí ìgbà téèyàn bá fi iná sun nǹkan!—Ìṣípayá 20:10, 14.

Ìrètí àgbàyanu yìí ni kókó pàtàkì lára “ìhìn rere ìjọba,” tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀ jákèjádò ayé. (Mátíù 24:14) Bẹ́ẹ̀ ni o, ó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú pé Ìjọba Ọlọ́run, nípasẹ̀ Kristi nìkan, ló máa mú aláàfíà àti ayọ̀ tí kò lópin wá sórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9, 10) Torí náà, wọn kò ní jáwọ́ nínú pípolongo Ìjọba náà, torí pé ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì lójú wọn ju ti èèyàn lọ.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù ará Tásù fi ṣe àtakò sí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi?—1 Tímótì 1:12, 13.

● Irú ìwà wo ló mú kí àwọn kan lára àwọn ọ̀tá Jésù ṣàtakò sí i?—Máàkù 15:9, 10.

● Ojú wo làwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń wo ayé?—1 Jòhánù 2:15.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Lọ́dún 1945, àwọn jàǹdùkú hùwà ipá sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Quebec, lórílẹ̀-èdè Canada, nítorí pé wọ́n ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Canada Wide

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́