Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mú Káwọn Èèyàn Ní Èrò Tó Dáa Nípa Mi Nígbà Tí Wọ́n Bá Kọ́kọ́ Rí Mi?
“Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yìí ń lọ dáadáa! Ọ̀gá yìí gbọ́dọ̀ ti rí i pé ara tù mí; orúkọ rẹ̀ ni mo sì fi ń pè é látìgbà tí mo ti wọlé. Ó dá mi lójú pé ó máa gbà mí síṣẹ́!”
“Ṣé ọmọkùnrin tó kọ̀wé ìwáṣẹ́ tó wúni lórí gan-an yẹn náà nìyí? Kò sóhun tó lè mú kí n gba ọmọ yìí síṣẹ́! Tó bá ń ṣe báyìí nígbà tá ò tíì gbà á síṣẹ́, tó bá wá ríṣẹ́ náà tán ń kọ́?”
Wo àwòrán yìí, kó o sì ka ọ̀rọ̀ tó wà lókè rẹ̀. Ǹjẹ́ o lè sọ ohun mẹ́tà tí ẹni tó ń wá iṣẹ́ yìí ṣe tí ẹni tó fẹ́ gbà á síṣẹ́ kò fi ní èrò tó dáa nípa rẹ̀?
1 ․․․․․
2 ․․․․․
3 ․․․․․
● Ìdáhùn wà nísàlẹ̀
1. Aṣọ tí ọ̀dọ́kùnrin yìí wọ̀ kò bójú mu láti wọ̀ lọ sí ibi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún iṣẹ́. 2. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ (ó la orúkọ mọ́ ẹni tó fẹ́ gbà á sí iṣẹ́ lórí) kò buyì kún ni. 3. Ìṣesí rẹ̀ fi hàn pé alárìífín ni.
KÁ SỌ pé o tọ́ oúnjẹ kan wò fún ìgbà àkọ́kọ́, báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kó o tó mọ̀ bóyá o fẹ́ràn rẹ̀? Èyí tó o bá kọ́kọ́ bù sẹ́nu ló máa pinnu bóyá wàá tún jẹ oúnjẹ náà nígbà míì, tàbí ńṣe lo máa rọ́jú jẹ èyí tí wọ́n gbé síwájú rẹ tán.
Irú nǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn tó o bá pàdé ẹnì kan fún ìgbà àkọ́kọ́. Láàárín àkókò kúkúrú, wàá ti ní ohun kan lọ́kàn nípa ẹni yẹn. Ohun kan tó gba àròjinlẹ̀ rèé: Láàárín àkókó kúkúrú yẹn kan náà ni ẹni yẹn máa ní ohun kan lọ́kàn nípa ìwọ náà.
Ṣé iṣẹ́ lò ń wá? Ṣé ọ̀rẹ́ ni? àbí ẹni tó o máa fẹ́? Ohun tí ẹni yẹn bá rò nípa rẹ nígbà tó kọ́kọ́ rí ẹ ló máa pinnu bóyá wàá ṣe àṣeyọrí. Jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀nà mẹ́ta tó o ti lè nílò láti ṣàtúnṣe sí bí o ṣe máa ń ṣe nígbà tó o bá wà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, kí wọ́n lè ní èrò tó dáa nípa rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí ẹ.
1. Ìrísí Rẹ
Bóyá èrò wọn tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà, ohun kan ni pé ohun táwọn èèyàn bá kọ́kọ́ rí, ìyẹn ìrísí rẹ ló máa pinnu èrò tí wọ́n máa ní nípa rẹ nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí ẹ. Àwọn èèyàn kì í sì í ka ìrísí wọn sí pàtàkì, bẹ́ẹ̀ òun ló ń pinnu bóyá àwọn èèyàn máa ní èrò tó dáa nípa ẹnì kan nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí i. Ọ̀dọ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Clarissaa sọ pé: “Lóde òní, ó jọ pé téèyàn bá lọ sílé oúnjẹ, o ò lè mọ báwọn tó máa wá síbẹ̀ ṣe máa múra, bóyá ńṣe ni wọ́n á ki àṣejù bọ ìmúra wọn tàbí ìmúra wọn kò tiẹ̀ ní bójú mu rárá!”
Ó yẹ kí aṣọ tó o bá wọ̀ bá irú òde tó o fẹ́ lọ mu. Bí àpẹẹrẹ, o kò ní wọ irú aṣọ tó o lè wọ lọ gbafẹ́ ní etíkun lọ sí ibi tó o ti fẹ́ lọ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún iṣẹ́! Tí o kò bá mọ irú aṣọ tó bójú mu fún ibi tó o fẹ́ lọ ńkọ́? Ohun tó dáa jù ni pé kó o múra níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Tó o bá ń ṣiyè méjì, á kúkú dáa kó o wọ aṣọ táwọn èèyàn kò ní kọminú sí.
RÁNTÍ PÉ! Ńṣe ni ìmúra àti ìrísí rẹ dà bí àwòrán tó ń ṣe àfihàn bí inú ara èèyàn ṣe rí, òun ló ń jẹ́ kéèyàn mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.
“Bí mo bá rí àwọn èèyàn níbi àpèjẹ tí wọ́n múra lọ́nà tí kò bójú mu, ojú máa ń tì mí láti sún mọ́ wọn. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, gbogbo ohun tí mo mọ̀ nípa wọn kò ju bí wọ́n ṣe rí, ìmúra wọn sì fi hàn pé wọn kì í ṣe ọmọlúwàbí.”—Diane.
Bíbélì dábàá pé ká máa wọ “aṣọ tí ó wà létòletò,” èyí tó máa fi hàn pé o ní “ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.”—1 Tímótì 2:9.
Bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ aṣọ tí mo wọ̀ wà létòlétò, àbí ńṣe ló rí wúruwùru? Ǹjẹ́ ẹni tó ṣeé ṣe kó gbà mí síṣẹ́, ẹni tó ṣeé ṣe kó di ọ̀rẹ́ mi tàbí ẹni tí mò ń gbèrò láti fẹ́ lè ronú pé mi ò ní “ìyèkooro èrò inú” nítorí ọ̀nà tí mo gbà múra?’
Ohun tó o lè ṣe: Gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹnì kan tó o bọ̀wọ̀ fún lórí irú aṣọ tó dáa lójú rẹ̀.
2. Ọ̀rọ̀ Ẹnu Rẹ
Ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu rẹ á fi hàn bóyá o jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tàbí agbéraga, bóyá èèyàn jẹ́jẹ́ ni ẹ́ tàbí ẹni tí ara rẹ̀ kò balẹ̀. O ní láti fi èyí sọ́kàn tó o bá fẹ́ kí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan ní èrò tó dáa nípa rẹ nígbà tó bá kọ́kọ́ rí ẹ. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Valerie sọ pé: “Inú máa ń bí mi nígbà tí mo bá ń bá ọ̀dọ́kùnrin kan sọ̀rọ̀, àmọ́ tó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ló ń sọ ṣáá.” Ó fi kún un pé: “Ohun mìíràn tó tún jẹ́ ìkọjá-àyè ni bí àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe máa ń fẹ́ mọ gbogbo nǹkan nípa ọmọbìnrin tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdé lójú ẹsẹ̀. Ìyẹn máa ń sú èèyàn, ó sì máa ń mú kí ọmọbìnrin náà kọ̀ láti ṣe ohun tí ọmọkùnrin náà fẹ́.”
RÁNTÍ PÉ! Ńṣe lọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu rẹ dà bíi fèrèsé, tí àwọn ẹlòmíì lè gbà rí irú ẹni tó o jẹ́ gan-an, torí náà, rí i dájú pé ohun tó fani mọ́ra ni àwọn èèyàn rí nípa rẹ!
“Bí èmi àti ọ̀dọ́kùnrin kan bá pàdé, mi ò fẹ́ kó máa díbọ́n. Ohun tó bá ṣẹlẹ̀ nígbà àkọ́kọ́ téèyàn pàdé ẹnì kan ṣe pàtàkì. Tó bá jẹ́ pé ọ̀dọ́kùnrin kan ní láti ronú ju bó ṣe yẹ lọ kó tó sọ̀rọ̀, á jẹ́ pé kó yẹ kó sọ̀rọ̀ yẹn nìyẹn.”—Selena.
Bíbélì sọ pé: “Nínú ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀rọ̀ kì í ṣàìsí ìrélànàkọjá, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣàkóso ètè rẹ̀ ń hùwà tòyetòye.”—Òwe 10:19.
Bi ara rẹ pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè ṣe é tí mi ò fi ní máa sọ̀rọ̀ jù, tí mi ò sì ní ṣàìsọ ohun tó yẹ kí n sọ? Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà tí mò ń gbà sọ̀rọ̀ tó lè já àwọn èèyàn láyà tàbí kó bí wọn nínú?’
Ohun tó o lè ṣe: Ṣàkíyèsí àwọn tó mọ béèyàn ṣe ń fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀. Ọgbọ́n wo ni wọ́n ń dá sí i tí ọ̀rọ̀ wọn kì í fi í sú ẹni tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀? Ṣé ìwọ náà lè lo irú ọgbọ́n yẹn?
3. Ìwà Rẹ
Ìwà èèyàn sábà máa ń sọ irú ẹni téèyàn jẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ lọ. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá níwà ọmọlúwàbí, ńṣe ni ìwà rẹ ń “sọ” pé o bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíì. Èyí jẹ́ nǹkan míì tó o ní láti fi sọ́kàn nígbà tó o bá fẹ́ wá ẹni tó o máa fẹ́. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Carrie sọ pé: “Tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ bíi dídi ìlẹ̀kùn mú fún ẹni tó fẹ́ kọjá, èyí fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fúnni. Irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ ara ìwà tó dáa tó yẹ kéèyàn máa hù sáwọn èèyàn.”
RÁNTÍ PÉ! Ńṣe ni ìwà rẹ dà bíi pátákó ìpolówó ọjà tó ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an. (Òwe 20:11) Kí ni ìwà rẹ ń sọ nípa rẹ?
“Mo ronú pé ó dáa ká máa fetí sílẹ̀ táwọn ẹlòmíì bá ń bá wa sọ̀rọ. Bákan náà, ìwà ọmọlúwàbí ló jẹ́ láti má ṣe já lu ọ̀rọ̀ tí ẹnìkan ń sọ, àyàfi tó bá pọn dandan.”—Natalia.
Bíbélì sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”—Lúùkù 6:31.
Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo ní ìwà ọmọlúwàbí? Ṣé mo ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì ṣe pàtàkì sí mi lóòótọ́? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn lè fọkàn tán mi? Ṣé mi ò kì í pẹ́ lẹ́yìn?’
Ohun tó o lè ṣe: Gbìyànjú láti dé ibi tí wọ́n pè ẹ́ sí ó pẹ́ tán, ní ìṣẹ́jú mẹ́wàá ṣáájú àkókò, tó bá tiẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ pé ohun tí o kò retí ṣẹlẹ̀, wàá ṣì lè dé ibẹ̀ lákòókò. Má ṣe jẹ́ kí àwọn èèyàn fi ojú apẹ́lẹ́yìn wò ẹ́ nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n mọ̀ ẹ́!
Ohun kan tó o ní láti ṣọ́ra fún rèé o: Má torí pé o fẹ́ kí àwọn èèyàn ní èrò tó dáa nípa rẹ nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n rí ẹ, kó wá máa díbọ́n o, torí pé ńṣe nìyẹn máa sọ ẹ́ di ẹlẹ́tàn. (Sáàmù 26:4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o pinnu irú ìwà tó o fẹ́ káwọn èèyàn fi mọ̀ ẹ́, kó o sì sapá láti ní irú ìwà bẹ́ẹ̀, kó o sì máa fi ṣèwà hù láìṣe ẹ̀tàn. (Kólósè 3:9, 10) Máa rántí pé ọwọ́ ara rẹ lo máa fi tún ìwà ara rẹ ṣe. Tó o bá ń kíyè sára nípa ìrísí rẹ, ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ àti ìwà rẹ, àwọn èèyàn á máa ní èrò tó dáa nípa rẹ nígbà tí wọ́n bá kọ́kọ́ rí ẹ, ohun tó sì máa wà lọ́kàn wọ́n fún ìgbà pípẹ́ nìyẹn!
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ
“Tí èèyàn bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́, ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa lo òye. Mo ti ṣàkíyèsí pé ìwà àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń ní ipa lórí mi gan-an, torí náà àwọn tó máa ní ipá rere lórí mi ni mo máa ń gbìyànjú láti yàn lọ́rẹ̀ẹ́.”
“Kì í ṣe béèyàn ṣe rẹwà tó tàbí béèyàn ṣe lówó lọ́wọ́ tó ló máa ń jẹ́ kéèyàn lè ní ọ̀rẹ́, torí pé kò sí lọ́wọ́ rẹ láti pinnu bóyá o máa ní àwọn nǹkan wọ̀nyí tàbí o kò ní ní wọn. Àmọ́, ìwà rẹ ló máa pinnu bóyá o máa ní ọ̀rẹ́ tàbí o kò ní ní. Èyí sì jẹ́ ohun tó wà ní ipá rẹ láti ṣe!”
[Àwọn àwòrán]
Sier
Ashley
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
OHUN TÓ O LÈ ṢE TÍ ÀWỌN ÈÈYÀN Á FI NÍ ÈRÒ TÓ DÁRA NÍPA RẸ . . .
● Máa rẹ́rìn-ín músẹ́
● Bọ àwọn èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́
● Máa wà ní mímọ́ tónítóní
● Rọra wo ojú ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
MÁ ṢE ÀṢEJÙ!
Sọ̀rọ̀, ÀMỌ́ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ jù
Béèrè ìbéèrè, ÀMỌ́ má ṣe jẹ́ alátojúbọ̀
Jẹ́ kí ara rẹ yọ̀ mọ́ èèyàn, ÀMỌ́ má ṣe máa tage
Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ dá ẹ lójú, ÀMỌ́ má ṣe gbéra ga
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]
O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?
Nígbà tẹ́ ẹ wà ní ọ̀dọ́, kí lẹ kọ́ nípa béèyàn ṣe lè jẹ́ káwọn èèyàn ní èrò tó dáa nípa ẹni nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ rí ni?
․․․․․