Ojú Ìwé Kejì
Bí Àwọn Òbí Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọmọ Yanjú
Ohun kan wà tí àwọn òbí kì í sábà ronú nípa rẹ̀ tí wọ́n bá ń wo ọmọ wọn jòjòló. Àmọ́ òótọ́ pọ́ńbélé ni pé: Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ ọmọ wọn jòjòló yìí máa dàgbà di géńdé, ó sì máa wà láyè ara rẹ̀. Bí Ọlọ́run sì ṣe fẹ́ kó rí gan-an nìyẹn, torí Bíbélì sọ pé ‘ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀.’ (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa ń rí fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin.
Síbẹ̀, ní ọjọ́ ayọ̀ tí ojú sábà máa ń roni yẹn, ìyẹn ní ọjọ́ tí ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin tó ti dàgbà bá fi ilé sílẹ̀, ọ̀pọ̀ òbí sábà máa ń ronú pé: ‘Ǹjẹ́ mo tọ́ ọmọ mi bó ṣe tọ́?’ ‘Ṣé ó máa lè fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ rẹ̀, ṣé á mọ ilé tọ́jú, ṣé kò sì ní máa ná ìnákúnàá?’ Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù ni pé, ‘Ṣé ọmọ mi á lè máa tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere tá a ti kọ́ ọ?’—Òwe 22:6; 2 Tímótì 3:15.
Àkànṣe ìwé ìròyìn Jí! yìí ṣàlàyé bí ìmọ̀ràn Bíbélì ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ọmọ wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà.