Ọ̀nà 1
Wá Ìmọ̀ràn Tó Dáa Gbà
Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì? Nígbà táwọn òbí bá kọ́kọ́ gbé ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí dání, onírúurú èrò lè máa jà gùdù lọ́kàn wọn. Ọ̀gbẹ́ni Brett, baálé ilé kan tó ń gbé ní ilẹ̀ Britain, sọ pé: “Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún mi, bẹ́ẹ̀ náà sì ni mò ń ṣe kàyéfì. Àmọ́, mo tún ń wò ó pé iṣẹ́ ńlá ló já lé mi léjìká yìí, mi ò sì lérò pé mo ti ṣe tán láti tẹ́rí gba iṣẹ́ náà.” Ìyáálé ilé ni Monica tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Ajẹntínà ní tirẹ̀. Ó sọ pé: “Kò tiẹ̀ yé mi bóyá á lè ṣeé ṣe fún mi láti bójú tó jíjẹ àti mímu ọmọ mi obìnrin kékeré. Mò ń ṣe kàyéfì pé, ‘Ǹjẹ́ á ṣeé ṣe fún mi láti tọ́ ọ dàgbà kó lè di ọmọlúwàbí èèyàn?’”
Ṣé ìwọ náà gbà pẹ̀lú àwọn òbí tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí pé bí ọmọ bíbí ṣe lè fúnni láyọ̀ náà ló ṣe lè mú kí iṣẹ́ já léni léjìká? Kò sírọ́ ńbẹ̀, iṣẹ́ ńlá lọ̀rọ̀ ọmọ títọ́, àmọ́ ó máa ń gbádùn mọ́ni, wàhálà ibẹ̀ ò kéré, síbẹ̀ èrè pọ̀ ńbẹ̀. Bí bàbá kan ṣe sọ ọ́ ló rí, “ẹ̀ẹ̀kan làǹfààní àtitọ́mọ yọrí mọ.” Síbẹ̀ náà, bó ṣe jẹ́ pé ipa ribiribi làwọn òbí ń kó lórí ìlera àti ayọ̀ àwọn ọmọ wọn, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o nílò ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé lórí bó o ṣe lè jẹ́ òbí aláṣeyọrí.
Ìṣòro tó wà ńbẹ̀: Ó dà bíi pé kò sẹ́ni tí ò ṣàìmọ nǹkan kan nípa ọmọ títọ́. Látijọ́, àpẹẹrẹ táwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ bá rí kọ́ lọ́dọ̀ àwọn òbí tiwọn ni wọ́n máa ń gbára lé. Nígbà míì sì rèé, ohun tí ẹ̀sìn fi kọ́ àwọn òbí nípa ọmọ títọ́ ni wọ́n máa ń tẹ̀ lé. Àmọ́, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, tọkọ taya àtàwọn ọmọ ò gbọ́ra wọn yé mọ́, ẹ̀sìn sì ti faṣọ iyì ẹ̀ wọ́lẹ̀. Nítorí èyí, ọ̀dọ̀ àwọn ògbógi tó ń gbani nímọ̀ràn nípa ọmọ títọ́ ló kù tọ́pọ̀ àwọn òbí ń gbà lọ. Díẹ̀ lára ohun táwọn ògbógi wọ̀nyí ń sọ ni wọ́n gbé karí ìlànà tó wúlò gan-an. Ìmọ̀ràn irú àwọn ògbógi bẹ́ẹ̀ máa ń ta kora nígbà míì, kì í sì í pẹ́ táwọn èèyàn fi máa ń kà á sí èyí tí kò bágbà mu.
Ohun tó lè ràn yín lọ́wọ́: Wá ìmọ̀ràn lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó lóye jù lọ nípa ọmọ títọ́, ìyẹn ni Ẹlẹ́dàá ìwàláàyè ẹ̀dá, Jèhófà Ọlọ́run. (Ìṣe 17:26-28) Ìmọ̀ràn tààràtà àtàwọn àpẹẹrẹ tó wúlò tó lè ran ẹ̀yin òbí lọ́wọ́ láti di aláṣeyọrí wà nínú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ó ṣèlérí pé: “Èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—Sáàmù 32:8.
Ìmọ̀ràn wo ni Ọlọ́run fún àwọn òbí tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà lọ́nà tí wọ́n á fi máa láyọ̀?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]
“Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.”—Òwe 3:5