ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 28
ORIN 88 Mú Mi Mọ Àwọn Ọ̀nà Rẹ
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Gbàmọ̀ràn Lọ́dọ̀ Àwọn Èèyàn?
“Ọgbọ́n jẹ́ ti àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn.”—ÒWE 13:10.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Ohun tó máa jẹ́ kí ìmọ̀ràn táwọn èèyàn fún wa ṣe wá láǹfààní.
1. Kí ni ò ní jẹ́ ká ṣi ìpinnu ṣe? (Òwe 13:10; 15:22)
GBOGBO wa la máa ń fẹ́ ṣèpinnu tó dáa, a sì máa ń fẹ́ kí ohun tá a fẹ́ ṣe yọrí sí rere. Torí náà, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé tá a bá ń gbàmọ̀ràn, àá ṣèpinnu tó dáa, ohun tá a fẹ́ ṣe á sì yọrí sí rere.—Ka Òwe 13:10; 15:22.
2. Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún wa?
2 Ó dájú pé ọ̀dọ̀ Jèhófà Bàbá wa ọ̀run la ti lè rí ọgbọ́n àti ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ. Ó ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́, ó ní: “Màá fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sm. 32:8) Ìyẹn fi hàn pé kì í ṣe pé Jèhófà máa ń fún wa nímọ̀ràn nìkan ni, ọ̀rọ̀ wa tún jẹ ẹ́ lógún, ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè fi àwọn ìmọ̀ràn ẹ̀ sílò.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè mẹ́rin yìí: (1) Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ kí n ní tí mo bá fẹ́ jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn tó dáa táwọn èèyàn bá fún mi? (2) Ọ̀dọ̀ ta ni mo ti lè gbàmọ̀ràn tó dáa? (3) Báwo ni mo ṣe lè fi hàn pé òótọ́ ni mo fẹ́ gbàmọ̀ràn? (4) Kí nìdí tí ò fi yẹ kí n sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣèpinnu fún mi?
ÀWỌN ÀNÍMỌ́ WO LÓ YẸ KÍ N NÍ?
4. Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ ká ní tá a bá fẹ́ jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn tó dáa táwọn èèyàn bá fún wa?
4 Tá a bá fẹ́ jàǹfààní nínú ìmọ̀ràn tí wọ́n fún wa, a gbọ́dọ̀ nírẹ̀lẹ̀, ká sì mọ̀wọ̀n ara wa. Ó yẹ ká gbà pé àwọn nǹkan kan wà tá ò mọ̀ tàbí tá ò ṣe rí. Torí náà, àfi káwọn èèyàn ràn wá lọ́wọ́. Àmọ́, tá ò bá nírẹ̀lẹ̀, tá ò sì mọ̀wọ̀n ara wa, Jèhófà ò ní ràn wá lọ́wọ́. Kódà, tá a bá rí ìmọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní nígbà tá à ń ka Bíbélì, a lè má fi sílò, á sì wá dà bí ìgbà tá à ń yín àgbàdo sẹ́yìn igbá. (Míkà 6:8; 1 Pét. 5:5) Àmọ́ tá a bá nírẹ̀lẹ̀, tá a sì mọ̀wọ̀n ara wa, àá tètè máa fi ìmọ̀ràn Bíbélì tá a gbọ́ sílò, á sì ṣe wá láǹfààní.
5. Àwọn nǹkan wo ni Ọba Dáfídì gbé ṣe tó lè mú kó máa gbéra ga?
5 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ lára Ọba Dáfídì. Àwọn àṣeyọrí tó ti ṣe lè mú kó máa gbéra ga. Ọ̀pọ̀ ọdún kó tó jọba làwọn èèyàn ti mọ̀ ọ́n sẹ́ni tó morin kọ dáadáa. Kódà, wọ́n ní kó wá kọrin fún ọba. (1 Sám. 16:18, 19) Lẹ́yìn tí Jèhófà fòróró yan Dáfídì pé òun ni ọba kàn, Jèhófà fún un ní ẹ̀mí mímọ́ kó lè lágbára. (1 Sám. 16:11-13) Bákan náà, ó di olókìkí láàárín àwọn èèyàn ẹ̀ torí pé ó pa àwọn ọ̀tá tó pọ̀ títí kan Gòláyátì ará Filísínì. (1 Sám. 17:37, 50; 18:7) Tó bá jẹ́ pé agbéraga èèyàn kan ló gbé irú àwọn nǹkan ńlá báyìí ṣe, kò ní gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹnì kankan mọ́. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Dáfídì ò rí bẹ́ẹ̀.
6. Báwo la ṣe mọ̀ pé Dáfídì máa ń gbàmọ̀ràn? (Tún wo àwòrán.)
6 Lẹ́yìn tí Dáfídì di ọba, àwọn ọkùnrin tó máa gbà á nímọ̀ràn tó dáa ló mú lọ́rẹ̀ẹ́. (1 Kíró. 27:32-34) Kò yà wá lẹ́nu torí pé Dáfídì ti máa ń gbàmọ̀ràn táwọn èèyàn bá fún un. Ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin nìkan kọ́ ni Dáfídì ti máa ń gbàmọ̀ràn, ó tún gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ obìnrin kan tó ń jẹ́ Ábígẹ́lì. Ìyàwó Nábálì ni Ábígẹ́lì, Nábálì kì í bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, kò moore, ó sì tún jọra ẹ̀ lójú. Àmọ́ torí pé Dáfídì nírẹ̀lẹ̀, ó gba ìmọ̀ràn tó dáa tí Ábígẹ́lì fún un, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kó ṣàṣìṣe ńlá.—1 Sám. 25:2, 3, 21-25, 32-34.
Ọba Dáfídì nírẹ̀lẹ̀ torí pé ó gba ìmọ̀ràn tó dáa tí Ábígẹ́lì fún un, ó sì fi sílò (Wo ìpínrọ̀ 6)
7. Àwọn nǹkan wo la lè kọ́ lára Dáfídì? (Oníwàásù 4:13) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Àwọn nǹkan kan wà tá a lè kọ́ lára Dáfídì. Bí àpẹẹrẹ, a lè mọ àwọn nǹkan kan ṣe dáadáa tàbí ká wà nípò àṣẹ. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kò yẹ ká máa rò pé gbogbo nǹkan la mọ̀, a ò sì nílò ìmọ̀ràn ẹnikẹ́ni. Bíi Dáfídì, ó yẹ ká máa gbàmọ̀ràn táwọn èèyàn bá fún wa, ì báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà ló fún wa. (Ka Oníwàásù 4:13.) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ò ní ṣàṣìṣe ńlá tó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwa àtàwọn ẹlòmíì.
Ó yẹ ká máa gbàmọ̀ràn táwọn èèyàn bá fún wa, ì báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbàlagbà ló fún wa (Wo ìpínrọ̀ 7)c
Ọ̀DỌ̀ TA NI MO TI LÈ GBÀMỌ̀RÀN TÓ DÁA?
8. Kí ló mú kí Jónátánì lè fún Dáfídì nímọ̀ràn tó dáa?
8 Ẹ jẹ́ ká wo nǹkan míì tá a lè kọ́ lára Dáfídì. Ó gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà àtàwọn tó mọ ìṣòro tó ní dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Dáfídì fẹ́ wá ojúure Ọba Sọ́ọ̀lù, ó gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù. Kí ló mú kí Jónátánì lè fún Dáfídì nímọ̀ràn tó dáa? Ohun tó mú kó lè ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ó sì mọ Sọ́ọ̀lù bàbá ẹ̀ dáadáa. (1 Sám. 20:9-13) Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí?
9. Ta ló yẹ ká lọ bá tá a bá fẹ́ gbàmọ̀ràn? Ṣàlàyé. (Òwe 13:20)
9 Tá a bá fẹ́ gbàmọ̀ràn, á dáa ká lọ bá ẹni tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, tó sì mọ̀ nípa ohun tó ń ṣe wá.a (Ka Òwe 13:20.) Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká sọ pé ọ̀dọ́kùnrin kan ń wá ẹni tó dáa tó máa fẹ́. Ta lẹ rò pé ó máa lè gbà á nímọ̀ràn tó dáa jù? Ọ̀rẹ́ ẹ̀ kan tí ò tíì ṣègbéyàwó lè gbà á nímọ̀ràn tó dáa tó bá lo àwọn ìlànà inú Bíbélì. Àmọ́ tí ọ̀dọ́kùnrin náà bá lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ tọkọtaya tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, tí wọ́n mọ̀ ọ́n dáadáa, tó sì ti pẹ́ díẹ̀ tí wọ́n ṣègbéyàwó, wọ́n á gbà á nímọ̀ràn tó wúlò, tó sì máa ṣe é láǹfààní.
10. Kí la máa jíròrò báyìí?
10 A ti sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ méjì tó yẹ ká ní àti ẹni tó lè fún wa nímọ̀ràn tó dáa. Ní báyìí, a máa jíròrò bá a ṣe lè fi hàn pé òótọ́ la fẹ́ gbàmọ̀ràn àti ìdí tí ò fi yẹ ká sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣèpinnu fún wa.
BÁWO NI MO ṢE LÈ FI HÀN PÉ ÒÓTỌ́ NI MO FẸ́ GBÀMỌ̀RÀN?
11-12. (a) Kí ni kò yẹ ká máa ṣe? (b) Kí ni Ọba Rèhóbóámù ṣe nígbà tó fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì kan?
11 Nígbà míì, ó lè jọ pé ẹnì kan fẹ́ gbàmọ̀ràn, àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé ó ti pinnu ohun tó fẹ́ ṣe, ó kàn fẹ́ káwọn míì fọwọ́ sí i ni. Ṣé a lè sọ pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ fẹ́ gbàmọ̀ràn lóòótọ́? Rárá. Ó yẹ kó kẹ́kọ̀ọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọba Rèhóbóámù.
12 Rèhóbóámù ló jọba lẹ́yìn Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì. Nǹkan ń lọ dáadáa ní Ísírẹ́lì nígbà tí Rèhóbóámù jọba, àmọ́ àwọn ará ìlú sọ pé ohun tí bàbá ẹ̀ ní káwọn ṣe ti pọ̀ jù. Torí náà, àwọn èèyàn náà wá bá Rèhóbóámù, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ṣe ohun tó máa rọ àwọn lọ́rùn. Rèhóbóámù wá sọ fún wọn pé kí wọ́n ní sùúrù díẹ̀ kóun lè pinnu ohun tóun máa ṣe. Ó ṣe dáadáa níbẹ̀rẹ̀ torí àwọn àgbà ọkùnrin tó bá Sólómọ́nì bàbá ẹ̀ ṣiṣẹ́ ló kọ́kọ́ ní kí wọ́n gba òun nímọ̀ràn. (1 Ọba 12:2-7) Àmọ́ kò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn táwọn àgbà ọkùnrin yẹn fún un. Kí nìdí tí ò fi gbàmọ̀ràn wọn? Ó lè jẹ́ pé Rèhóbóámù ti pinnu ohun tó máa ṣe, àmọ́ tó kàn fẹ́ kí ẹlòmíì fọwọ́ sí i. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ìdí nìyẹn tó fi gba ìmọ̀ràn àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́. (1 Ọba 12:8-14) Torí náà, ìmọ̀ràn táwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ gbà á ló sọ fún àwọn ará ìlú. Àtìgbà yẹn ni orílẹ̀-èdè náà ti pín sí méjì, ìgbà gbogbo sì ni wàhálà ń dé bá Rèhóbóámù.—1 Ọba 12:16-19.
13. Báwo la ṣe lè mọ̀ pé a ṣe tán láti gbàmọ̀ràn?
13 Kí la kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Rèhóbóámù? Tá a bá ní kẹ́nì kan gbà wá nímọ̀ràn, ó yẹ ká fi hàn pé òótọ́ la fẹ́ gbàmọ̀ràn. Báwo la ṣe lè mọ̀ pé a ṣe tán láti gbàmọ̀ràn? Ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Tí mo bá lọ gbàmọ̀ràn, ṣé kì í ṣe ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo máa ń kọ ìmọ̀ràn náà torí pé kì í ṣe ohun tí mo fẹ́ ni wọ́n sọ?’ Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan.
14. Tí wọ́n bá gbà wá nímọ̀ràn, kí ló yẹ ká máa rántí? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Ká sọ pé arákùnrin kan rí iṣẹ́ kan táá máa mówó ńlá wọlé. Àmọ́ kó tó gba iṣẹ́ náà, ó ní kí alàgbà kan gba òun nímọ̀ràn. Arákùnrin náà sọ fún alàgbà yẹn pé iṣẹ́ náà máa gba pé kóun máa fi ìdílé òun sílẹ̀, á sì máa pẹ́ díẹ̀ kóun tó pa dà dé. Alàgbà náà rán arákùnrin yẹn létí pé ojúṣe tó ṣe pàtàkì jù tí Jèhófà gbé fáwọn olórí ìdílé ni pé kí wọ́n jẹ́ kí ìdílé wọn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. (Éfé. 6:4; 1 Tím. 5:8) Tí arákùnrin náà bá kọ ìmọ̀ràn alàgbà yẹn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ńkọ́, tó sì lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin míì títí tó fi dé ọ̀dọ̀ àwọn tó sọ ohun tó fẹ́ gbọ́? Ṣé a lè sọ pé arákùnrin yẹn fẹ́ gbàmọ̀ràn lóòótọ́ àbí ó ti pinnu ohun tó fẹ́ ṣe, ó kàn ń wá ẹni tó máa fọwọ́ sí i ni? Ó yẹ ká rántí pé ọkàn wa lè tàn wá jẹ. (Jer. 17:9) Nígbà míì, wọ́n lè gbà wá nímọ̀ràn tá ò fẹ́, ó sì lè jẹ́ pé ìmọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní jù nìyẹn.
Ṣé a fẹ́ gbàmọ̀ràn lóòótọ́ àbí a ti pinnu ohun tá a fẹ́ ṣe, a kàn ń wá ẹni tó máa fọwọ́ sí i ni? (Wo ìpínrọ̀ 14)
ṢÉ Ó YẸ KÍ N SỌ FÁWỌN ÈÈYÀN PÉ KÍ WỌ́N ṢÈPINNU FÚN MI?
15. Kí ni ò yẹ ká ṣe, kí sì nìdí?
15 Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni láti pinnu ohun tó máa ṣe. (Gál. 6:4, 5) Ohun tá a ti jíròrò ti jẹ́ ká rí i pé ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń jẹ́ kí Bíbélì tọ́ òun sọ́nà, ó sì máa ń gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn kó tó ṣèpinnu. Àmọ́ kò yẹ ká sọ fáwọn èèyàn pé kí wọ́n ṣèpinnu fún wa. Àwọn kan lè bi ẹni tí wọ́n fọkàn tán pé, “Kí lẹ máa ṣe tó bá jẹ́ ẹ̀yin ni?” Àwọn míì kì í sọ pé kí wọ́n ṣèpinnu fáwọn, àmọ́ nǹkan táwọn ẹlòmíì ṣe làwọn náà máa ṣe láìro ọ̀rọ̀ náà dáadáa.
16. Kí ló ṣẹlẹ̀ níjọ Kọ́ríńtì nípa ẹran tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà, ta ló sì máa pinnu bóyá kẹ́nì kan jẹ ẹ́ tàbí kó má jẹ ẹ́? (1 Kọ́ríńtì 8:7; 10:25, 26)
16 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níjọ Kọ́ríńtì nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀. Ẹran tó ṣeé ṣe kí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà ló dá àríyànjiyàn sílẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà sáwọn ará ìjọ yẹn pé: “A mọ̀ pé òrìṣà kò jẹ́ nǹkan kan nínú ayé àti pé kò sí Ọlọ́run míì àfi ọ̀kan ṣoṣo.” (1 Kọ́r. 8:4) Torí náà, àwọn kan nínú ìjọ yẹn pinnu pé àwọn lè jẹ ẹran tó ṣeé ṣe kí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà àmọ́ tí wọ́n wá tà lọ́jà. Àwọn míì sì sọ pé táwọn bá jẹ ẹran yẹn, ó máa da ẹ̀rí ọkàn àwọn láàmú. (Ka 1 Kọ́ríńtì 8:7; 10:25, 26.) Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó máa ṣe. Pọ́ọ̀lù ò sọ pé káwọn ará Kọ́ríńtì máa ṣèpinnu fáwọn ẹlòmíì, kò sì sọ pé ohun táwọn ẹlòmíì bá ṣe làwọn náà gbọ́dọ̀ ṣe. Kálukú wọn ló máa “jíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Róòmù 14:10-12.
17. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tó bá jẹ́ pé ohun táwọn kan ṣe làwa náà ṣe láìrò ó dáadáa? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
17 Ṣé irú ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ lónìí? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn èròjà kéékèèké inú ẹ̀jẹ̀. Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu bóyá òun máa gba àwọn èròjà kéékèèké náà tàbí òun ò ní gbà á.b Ọ̀rọ̀ náà lè má yé wa dáadáa, àmọ́ Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tóun máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. (Róòmù 14:4) Tó bá jẹ́ pé ohun táwọn kan ṣe làwa náà ṣe láìrò ó dáadáa, ẹ̀rí ọkàn wa ò ní lágbára mọ́. Tá a bá fẹ́ kọ́ ẹ̀rí ọkàn wa, tá a sì fẹ́ kó máa ṣiṣẹ́ dáadáa, àfi ká máa lò ó. (Héb. 5:14) Torí náà, ìgbà wo ló yẹ ká lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú ẹ̀? Ó yẹ ká ṣèwádìí fúnra wa, àmọ́ tá ò bá mọ bá a ṣe lè lo ìlànà Bíbélì tá a rí, ìgbà yẹn ló yẹ ká lọ gbàmọ̀ràn.
Ẹ̀yìn tá a bá ti ṣèwádìí fúnra wa la lè lọ gbàmọ̀ràn (Wo ìpínrọ̀ 17)
MÁA GBÀMỌ̀RÀN
18. Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ṣe fún wa?
18 Jèhófà fọkàn tán wa pátápátá torí ó gbà wá láyè láti máa ṣèpinnu fúnra wa. Ó fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bákan náà, ó fún wa láwọn ọ̀rẹ́ ọlọgbọ́n tí wọ́n ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe yìí fi hàn pé Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa ni. (Òwe 3:21-23) Àmọ́ kí làwa náà lè ṣe láti fi hàn pé a mọyì ohun tó ṣe fún wa?
19. Báwo la ṣe lè máa múnú Jèhófà dùn?
19 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Àwọn òbí máa ń fẹ́ káwọn ọmọ wọn dàgbà, kí wọ́n gbọ́n, kí wọ́n sì di ìránṣẹ́ Jèhófà tó ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Lọ́nà kan náà, inú Jèhófà máa ń dùn tó bá rí i pé òtítọ́ ń jinlẹ̀ sí i nínú wa, tó rí i pé à ń gbàmọ̀ràn, a sì ń ṣèpinnu tó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀.
ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́
a Nígbà míì, àwa Kristẹni lè gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bí àwọn dókítà, àwọn tó mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ owó tàbí àwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì.
b Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa ọ̀rọ̀ yìí, wo ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 39, kókó 5 àti apá “Ṣèwádìí.”
c ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Alàgbà kan ń fún alàgbà míì nímọ̀ràn nípa bó ṣe sọ̀rọ̀ nípàdé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe.