ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 29
ORIN 87 Ẹ Wá Gba Ìtura
Bá A Ṣe Lè Gba Àwọn Èèyàn Nímọ̀ràn
“Màá fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—SM. 32:8.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Bá a ṣe lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó dáa.
1. Ta ló yẹ kó gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn? Ṣàlàyé.
ṢÉ Ó máa ń wù ẹ́ láti gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn? Àwọn kan máa ń fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, àwọn míì kì í fẹ́ gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n. Èyí ó wù ó jẹ́, gbogbo wa ló yẹ ká máa gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nígbà tó bá yẹ. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù sọ pé ohun tá a máa fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀ ni pé wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Jòh. 13:35) Bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ni pé ká gbà wọ́n nímọ̀ràn nígbà tó bá pọn dandan. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá fẹ́ ‘jadùn ọ̀rẹ́,’ a gbọ́dọ̀ máa gba ọ̀rẹ́ wa ní “ìmọ̀ràn àtọkànwá.”—Òwe 27:9.
2. Kí ló yẹ káwọn alàgbà máa ṣe, kí sì nìdí? (Tún wo àpótí náà “Ìmọ̀ràn Tí Alága Máa Ń Gba Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Nípàdé Àárín Ọ̀sẹ̀.”)
2 Ó yẹ káwọn alàgbà mọ bí wọ́n ṣe lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó dáa. Jèhófà àti Jésù ló yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n yìí láti máa bójú tó ìjọ. (1 Pét. 5:2, 3) Ọ̀kan lára ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n máa ń fi Bíbélì gba àwọn ará nímọ̀ràn tí wọ́n bá ń sọ àsọyé. Wọ́n tún máa ń gba ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ nímọ̀ràn, wọ́n sì máa ń rọ àwọn tó fi Jèhófà sílẹ̀ pé kí wọ́n pa dà. Báwo làwọn alàgbà àti ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣe lè gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó dáa?
3. (a) Báwo la ṣe lè jẹ́ agbani-nímọ̀ràn tó dáa? (Àìsáyà 9:6; tún wo àpótí náà “Fara Wé Jésù Tó O Bá Ń Gba Àwọn Èèyàn Nímọ̀ràn.”) (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Tá a bá fẹ́ jẹ́ agbani-nímọ̀ràn tó dáa, ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ lára àwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, ní pàtàkì Jésù Kristi. Ọ̀kan lára orúkọ oyè ẹ̀ ni “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn.” (Ka Àìsáyà 9:6.) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tá a lè ṣe tẹ́nì kan bá ní ká gba òun nímọ̀ràn àtohun tá a lè ṣe tá a bá rí i pé ó yẹ ká gba ẹnì kan nímọ̀ràn. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nígbà tó yẹ àti lọ́nà tó tọ́.
TẸ́NÌ KAN BÁ NÍ KÁ GBA ÒUN NÍMỌ̀RÀN
4-5. Tẹ́nì kan bá sọ pé ká gba òun nímọ̀ràn, ìbéèrè wo ló yẹ ká kọ́kọ́ bi ara wa? Sọ àpẹẹrẹ kan.
4 Tẹ́nì kan bá sọ pé ká gba òun nímọ̀ràn, kí ló yẹ ká kọ́kọ́ ṣe? Inú wa lè dùn, a sì lè fẹ́ gba ẹni náà nímọ̀ràn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Àmọ́ ó yẹ ká kọ́kọ́ bi ara wa pé, ‘Ṣé èmi ló yẹ kí n gba ẹni náà nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ yìí?’ Nígbà míì, tá a bá rí i pé a ò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà dáadáa, á dáa ká sọ fún un pé kó lọ bá ẹni tó mọ̀ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tá á lè gbà á nímọ̀ràn.
5 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ yìí. Ká sọ pé ọ̀rẹ́ ẹ tímọ́tímọ́ ń ṣàìsàn tó le gan-an. Ó sọ fún ẹ pé òun ti ń ṣèwádìí nípa ìtọ́jú lóríṣiríṣi tóun lè gbà, ó sì ní kó o sọ èrò ẹ nípa èyí tó dáa jù. Lóòótọ́, o lè fẹ́ kó gba ìtọ́jú kan tó o fẹ́, àmọ́ o kì í ṣe dókítà, o ò sì mọ nǹkan kan nípa bí wọ́n ṣe ń tọ́jú irú àìsàn yẹn. Torí náà, ohun tó dáa jù tó o lè ṣe láti ran ọ̀rẹ́ ẹ lọ́wọ́ ni pé kó o bá a wá dókítà tó lè tọ́jú irú àìsàn yẹn.
6. Kí nìdí tó fi yẹ ká ní sùúrù ká tó gba ẹnì kan nímọ̀ràn?
6 Tẹ́nì kan bá ní ká gba òun nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ kan tá a sì rí i pé a kúnjú ìwọ̀n láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè gba pé ká ní sùúrù díẹ̀ ká tó gba ẹni náà nímọ̀ràn. Kí nìdí? Ìdí ni pé Òwe 15:28 sọ pé “olódodo máa ń ṣe àṣàrò kí ó tó dáhùn.” Tá a bá rò pé a mọ ìdáhùn náà ńkọ́? Ó ṣì yẹ ká lọ ṣèwádìí, ká gbàdúrà, ká sì ṣàṣàrò nípa ọ̀rọ̀ náà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á túbọ̀ dá wa lójú pé ohun tí Jèhófà fẹ́ la sọ fún ẹni náà. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Nátánì ṣe.
7. Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wòlíì Nátánì?
7 Nígbà tí Ọba Dáfídì sọ fún wòlíì Nátánì pé ó wu òun láti kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún Jèhófà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Nátánì gbà á nímọ̀ràn pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó yẹ kí Nátánì kọ́kọ́ bi Jèhófà kó tó sọ ohun tó máa ṣe fún un. Kí nìdí? Ìdí ni pé Dáfídì kọ́ ni Jèhófà fẹ́ kó kọ́ tẹ́ńpìlì náà. (1 Kíró. 17:1-4) Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kọ́ wa? Tẹ́nì kan bá ní ká gba òun nímọ̀ràn, á dáa tá a bá “lọ́ra láti sọ̀rọ̀,” ìyẹn ni pé ká ronú dáadáa ká tó sọ̀rọ̀.—Jém. 1:19.
8. Kí nìdí míì tó fi yẹ ká ṣọ́ra tá a bá fẹ́ gba ẹnì kan nímọ̀ràn?
8 Ẹ jẹ́ ká wo ìdí míì tó fi yẹ ká ṣọ́ra tá a bá fẹ́ gba ẹnì kan nímọ̀ràn. Tí ìmọ̀ràn tá a gba ẹnì kan bá mú kó ṣe ìpinnu tí kò tọ́, àwa náà lè jẹ̀bi. Torí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká ronú jinlẹ̀ ká tó gba ẹnì kan nímọ̀ràn.
TÁ A BÁ RÍ I PÉ Ó YẸ KÁ GBA ẸNÌ KAN NÍMỌ̀RÀN
9. Káwọn alàgbà tó gba ẹnì kan nímọ̀ràn, kí ló gbọ́dọ̀ dá wọn lójú? (Gálátíà 6:1)
9 Táwọn alàgbà bá rí i pé ó yẹ káwọn gba arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó “ṣi ẹsẹ̀ gbé” nímọ̀ràn, wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ látìgbàdégbà. (Ka Gálátíà 6:1.) Àlàyé tá a ṣe lórí ẹsẹ yìí nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì ni pé ẹni tó ṣi ẹsẹ̀ gbé “ti ń ṣe àwọn ìpinnu tí kò dáa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì dẹ́ṣẹ̀ ńlá.” Ojúṣe àwọn alàgbà ni láti ran ẹni náà lọ́wọ́ kó lè máa rìn lọ́nà ìyè. (Jém. 5:19, 20) Táwọn alàgbà bá fẹ́ kí ẹnì kan gba ìmọ̀ràn àwọn, kí wọ́n tó lọ, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ẹni náà ti ṣe ìpinnu tí ò dáa. Jèhófà fún gbogbo wa láǹfààní láti ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn wa mu. (Róòmù 14:1-4) Àmọ́ tí ẹnì kan bá ti ń ṣe ohun tí ò dáa àmọ́ tí kò tíì dẹ́ṣẹ̀ ńlá, táwọn alàgbà sì rí i pé ó yẹ kí wọ́n gbà á nímọ̀ràn ńkọ́?
10-12. Táwọn alàgbà bá fẹ́ gba ẹnì kan nímọ̀ràn tẹ́ni náà ò sì sọ pé kí wọ́n gba òun nímọ̀ràn, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe? Ṣàpèjúwe. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
10 Kì í rọrùn fáwọn alàgbà láti gba ẹnì kan nímọ̀ràn tí ẹni náà ò bá sọ pé kí wọ́n gba òun nímọ̀ràn. Kí nìdí tó fi máa ń rí bẹ́ẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ẹni náà lè má mọ̀ pé òun ti ṣe ohun tí ò dáa. Torí náà káwọn alàgbà tó gba ẹni náà nímọ̀ràn, àwọn nǹkan kan wà tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe kẹ́ni náà lè gba ìmọ̀ràn náà.
11 Tí àgbẹ̀ kan bá fẹ́ gbin nǹkan sórí ilẹ̀ tó le, á kọ́kọ́ wú ilẹ̀ náà kó lè rọ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn lá wá gbin nǹkan tó fẹ́ gbìn, á sì máa bomi rin ín kó lè hù. Lọ́nà kan náà, kí alàgbà kan tó gba ẹnì kan nímọ̀ràn, àmọ́ tí kì í ṣe ẹni náà ló ní kó gba òun nímọ̀ràn, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kó ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ó yẹ kó wá àsìkò tó rọrùn láti bá a sọ̀rọ̀, kó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an àti pé nǹkan kan wà tóun fẹ́ bá a sọ. Táwọn ará bá mọ̀ pé onínúure ni alàgbà kan tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ó máa rọrùn fún wọn láti gba ìmọ̀ràn tó bá fún wọn.
12 Tí alàgbà náà bá ń bá ẹni náà sọ̀rọ̀, ó yẹ kó fi í lọ́kàn balẹ̀ kó sì jẹ́ kó mọ̀ pé gbogbo wa la máa ń ṣàṣìṣe, a sì nílò ìmọ̀ràn látìgbàdégbà. (Róòmù 3:23) Ó yẹ kó fohùn jẹ́jẹ́ bá a sọ̀rọ̀, kó bọ̀wọ̀ fún un, kó wá jẹ́ kó rí i látinú Ìwé Mímọ́ pé ó ti ṣàṣìṣe. Tí arákùnrin náà bá ti gbà pé òun ṣàṣìṣe, á rọrùn fún alàgbà náà láti ràn án lọ́wọ́. Bíi ti àgbẹ̀ tó ‘gbin nǹkan,’ alàgbà náà á ṣàlàyé àwọn nǹkan tó máa ṣe kó lè ṣàtúnṣe. Paríparí ẹ̀, bíi ti àgbẹ̀ tó ‘bomi rin’ nǹkan tó gbìn, alàgbà náà máa gbóríyìn fún arákùnrin yẹn tọkàntọkàn, á sì gbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀.—Jém. 5:15.
Ìfẹ́ ló ń mú káwọn alàgbà gba ẹnì kan nímọ̀ràn bí ẹni náà ò tiẹ̀ ní kí wọ́n gba òun nímọ̀ràn, wọ́n sì máa ń fọgbọ́n ṣe é (Wo ìpínrọ̀ 10-12)
13. Kí làwọn alàgbà lè ṣe kó lè dá wọn lójú pé ohun táwọn ń sọ yé ẹni náà?
13 Nígbà míì, ọ̀tọ̀ lohun tẹ́ni tó gbani nímọ̀ràn ń sọ, àmọ́ ọ̀tọ̀ ni nǹkan tẹ́ni tí wọ́n ń gbà nímọ̀ràn máa lóye. Táwọn alàgbà ò bá fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀, kí ló yẹ kí wọ́n ṣe? Tí wọ́n bá fẹ́ kóhun táwọn sọ yé ẹni náà dáadáa, ó yẹ kí wọ́n fọgbọ́n bi í láwọn ìbéèrè táá jẹ́ kó mọ ohun tí wọ́n ń sọ, kí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. (Oníw. 12:11) Ohun tẹ́ni tí wọ́n gbà nímọ̀ràn bá sọ ló máa jẹ́ káwọn alàgbà yẹn mọ̀ bóyá ohun táwọn sọ ti yé e.
BÁ A ṢE LÈ GBA ÀWỌN ÈÈYÀN NÍMỌ̀RÀN NÍGBÀ TÓ YẸ ÀTI LỌ́NÀ TÓ TỌ́
14. Ṣó yẹ ká gba ẹnì kan nímọ̀ràn tínú bá ń bí wa? Ṣàlàyé.
14 Torí pé aláìpé ni wá, a máa ń sọ tàbí ṣe nǹkan tó máa ń bí àwọn míì nínú. (Kól. 3:13) Kódà, Bíbélì sọ pé ẹnì kan lè ṣe nǹkan tó máa múnú bí wa. (Éfé. 4:26) Àmọ́ kò yẹ ká gba ẹnì kan nímọ̀ràn tínú bá ń bí wa. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé “ìbínú èèyàn kì í mú òdodo Ọlọ́run wá.” (Jém. 1:20) Tá a bá gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nígbà tínú ń bí wa, ó lè pa ẹni náà lára dípò kó ṣe é láǹfààní. Àmọ́ ìyẹn ò ní ká má sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún ẹni tó múnú bí wa. Síbẹ̀, tá a bá jẹ́ kí inú tó ń bí wa rọlẹ̀ ká tó sọ̀rọ̀, ohun tá a bá sọ máa ṣe ẹni náà láǹfààní. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tá a lè kọ́ lára Élíhù tó gba Jóòbù nímọ̀ràn tó dáa.
15. Kí la kọ́ lára Élíhù? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
15 Ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni Élíhù fi dákẹ́ nígbà tí Jóòbù ń gbèjà ara ẹ̀ níṣojú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ mẹ́ta tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án. Àánú Jóòbù ṣe Élíhù, àmọ́ inú bí i nígbà tí Jóòbù sọ nǹkan tí ò jóòótọ́ nípa Jèhófà tó sì ń wí àwíjàre. Síbẹ̀, Élíhù ní sùúrù dìgbà tó yẹ kó sọ̀rọ̀, kò kanra mọ́ Jóòbù nígbà tó ń gbà á nímọ̀ràn, ó sì bọ̀wọ̀ fún un. (Jóòbù 32:2; 33:1-7) Ohun pàtàkì tá a kọ́ lára Élíhù ni pé: Ó ṣe pàtàkì ká máa gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn nígbà tó yẹ àti lọ́nà tó tọ́, ká fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, ká sì bọ̀wọ̀ fún wọn.—Oníw. 3:1, 7.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú kọ́kọ́ bí Élíhù, àmọ́ nígbà tó fẹ́ gba Jóòbù nímọ̀ràn, ó bọ̀wọ̀ fún un, kò sì kàn án lábùkù (Wo ìpínrọ̀ 15)
MÁA GBA ÀWỌN ÈÈYÀN NÍMỌ̀RÀN KÓ O SÌ MÁA GBÀMỌ̀RÀN LỌ́DỌ̀ ÀWỌN ÈÈYÀN
16. Kí lo kọ́ nínú Sáàmù 32:8?
16 Ẹsẹ Bíbélì tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé sọ pé ‘Jèhófà máa fún wa nímọ̀ràn pẹ̀lú ojú ẹ̀ lára wa.’ (Ka Sáàmù 32:8.) Ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà á máa gbà wá nímọ̀ràn, á sì máa ràn wá lọ́wọ́. Kì í ṣe pé Jèhófà máa ń gbà wá nímọ̀ràn nìkan ni, ó tún máa ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe máa lò ó. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká fara wé Jèhófà! Torí náà, tá a bá láǹfààní láti gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn, ó yẹ ká fara wé Jèhófà, ká má fi wọ́n sílẹ̀, ká sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí.
17. Táwọn alàgbà bá ń gba àwọn ará nímọ̀ràn látinú Bíbélì, kí nìyẹn máa fi hàn pé wọ́n jẹ́? Ṣàlàyé. (Àìsáyà 32:1, 2)
17 Àsìkò tá a wà yìí ló ṣe pàtàkì jù ká máa gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó dáa, ká sì tún máa gbàmọ̀ràn tó dáa lọ́dọ̀ àwọn èèyàn. (2 Tím. 3:1) Àwọn alàgbà dà “bí omi tó ń ṣàn ní ilẹ̀ tí kò lómi” torí wọ́n máa ń gbà wá nímọ̀ràn látinú Bíbélì ká lè máa sin Jèhófà nìṣó. (Ka Àìsáyà 32:1, 2.) Àwọn ọ̀rẹ́ tó mọ ohun tá a fẹ́, síbẹ̀ tí wọ́n máa sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ fún wa dà bí “èso ápù oníwúrà tó wà nínú abọ́ fàdákà.” (Òwe 25:11) Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún wa lọ́gbọ́n táá jẹ́ ká lè máa gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tó dáa, táá sì jẹ́ káwa náà máa gbàmọ̀ràn tó dáa lọ́dọ̀ àwọn èèyàn.
ORIN 109 Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá