ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 11/1 ojú ìwé 3
  • Ìmọ̀ràn “Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n” Kò Dúró Sójú Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìmọ̀ràn “Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n” Kò Dúró Sójú Kan
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Inú Ìwé Làwọn Òbí Kan Ti Ń Wá Ìmọ̀ràn
  • Wá Ìmọ̀ràn Tó Dáa Gbà
    Jí!—2007
  • Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lórí Ọ̀rọ̀ Ọmọ Títọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Àwọn Òbí Ń kojú Pákáǹleke
    Jí!—1997
  • Àwọn Abiyamọ Wàhálà Àṣekúdórógbó Tí Wọ́n Ń Ṣe
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 11/1 ojú ìwé 3

Ìmọ̀ràn “Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n” Kò Dúró Sójú Kan

LÁYÉ òde òní, àwọn tó láǹfààní láti wo Íńtánẹ́ẹ̀tì lórí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà lè rí ìmọ̀ràn táwọn òbí lè tẹ̀ lé láti tọ́ ọmọ wọn. Wọ́n á sì rí ohun tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ìmọ̀ràn lórí kókó ọ̀rọ̀ yìí ní kíákíá. Bó bá jẹ́ pé ìṣẹ́jú kan péré lo fi ń yẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wò tó o sì ń kà á, ọ̀pọ̀ ọdún á kọjá kó o tó kà wọ́n tán.

Kí ayé tó dayé à ń lọ wo Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí à ń lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà tó ń tọ́jú ọmọ wẹ́wẹ́, tàbí àwọn onímọ̀ nípa ìrònú àti ìṣesí ọmọdé, ibo làwọn òbí ti máa ń gbàmọ̀ràn láyé ọjọ́un? Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn mọ̀lẹ́bí wọn ni wọ́n máa ń tọ̀ lọ. Àwọn ìyá, bàbá, àtàwọn ẹbí wọn yòókù ti wà ní sẹpẹ́ láti fún wọn ní ìmọ̀ràn. Àwọn wọ̀nyí máa ń fi owó ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n tún máa ń bá wọn tọ́jú ọmọ tí wọn ò bá sí nílé. Àmọ́ lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn ló ń ṣí kúrò ní àrọko lọ sí àwọn ìlú ńlá, èyí sì ti mú kí irú àjọṣe tímọ́tímọ́ tó máa ń wà láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí yìí dohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí mọ́. Lónìí, bàbá àti ìyá tó bímọ ló sábà máa ń dá bójú tó iṣẹ́ ọmọ títọ́, èyí kò sì rọrùn rárá.

Kò sí àní-àní pé èyí wà lára ohun tó mú káwọn tó ń ṣiṣẹ́ wo-ọmọ-dèmí láyé òde òní wá pọ̀ jaburata. Ìdí mìíràn táwọn òbí tún fi ń dá tọ́ ọmọ wọn ni pé, wọ́n ti wá nígbàgbọ́ gan-an pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lè ran àwọn lọ́wọ́. Nígbà tó fi máa di ìparí àwọn ọdún 1800, àwọn ará ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti ń gbà pé kò sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ẹ̀dá tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè mú dára sí i. Wọ́n wá ronú pé, kí ló dé tí kò ní lè mú kí ọ̀nà téèyàn ń gbà tọ́mọ náà dára sí i? Nípa bẹ́ẹ̀, lọ́dún 1899, nígbà tí àjọ kan tó ń jẹ́ Ẹgbẹ́ Àwọn Ìyá Ọlọ́mọ Nílẹ̀ Amẹ́ríkà sọ pé “àwọn òbí ò kúnjú ìwọ̀n,” kíá ni ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó ka ara wọn sí ọ̀jọ̀gbọ́n lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́ sọ pé ìrànlọ́wọ́ wà. Wọ́n láwọn lè ṣèrànwọ́ fáwọn ìyá àti bàbá tí kò mọ bí wọ́n ṣe lè tọ́ ọmọ wọn.

Inú Ìwé Làwọn Òbí Kan Ti Ń Wá Ìmọ̀ràn

Síbẹ̀, kí làwọn ọ̀jọ̀gbọ́n wọ̀nyí ti gbé ṣe? Ṣé àwọn òbí ayé òde òní kò wá dààmú mọ́ bíi tàwọn òbí ayé ọjọ́un ni, ṣé wọ́n sì ti wá mọ ọ̀nà tó dára gan-an báyìí láti gbà tọ́mọ? Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì láìpẹ́ yìí fi hàn pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Ìwádìí náà fi hàn pé, tá a bá kó ọgọ́rùn-ún òbí jọ, nǹkan bí márùndínlógójì nínú wọn tó ní ọmọ kéékèèké ló ṣì ń wá ìmọ̀ràn tí wọ́n lè gbára lé. Àwọn mìíràn sì gbà pé kò sóhun táwọn lè ṣe ju káwọn máa tẹ̀ lé ohunkóhun tọ́kàn àwọn bá ti sọ pé káwọn ṣe.

Nínú ìwé kan tí ìyáàfin Ann Hulbert ṣe jáde lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́, èyí tó pè ní Raising America: Experts, Parents, and a Century of Advice About Children, ó fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò onírúurú ìwé táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ti kọ lórí ọ̀rọ̀ ọmọ títọ́. Ìyáàfin Hulbert, tóun fúnra rẹ̀ lọ́mọ méjì wá sọ pé, ìwọ̀nba díẹ̀ lára ohun táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n náà kọ ló bá ohun tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ mú. Ó jọ pé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn fúnra wọn làwọn ìmọ̀ràn wọn dá lé dípò kí wọ́n gbé e karí ohun tó dìídì jẹ́ òótọ́. Tá a bá wo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n kọ ló ta kora, ló dá lórí àṣà ìgbàlódé, tó sì máa ń ṣeni ní kàyéfì nígbà míì pàápàá.

Ipò wo lèyí wá fi àwọn òbí sí lónìí? Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ọ̀pọ̀ òbí ni kò mọ ohun tí wọn ì bá ṣe, nítorí pé ńṣe ni onírúurú ìmọ̀ràn, èrò, àti àìfohùnṣọ̀kan túbọ̀ ń pọ̀ sí i ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Àmọ́, àwọn òbí kan wà tó gbà pé àwọn lóhun tó ń tọ́ àwọn sọ́nà. Níbi gbogbo láyé, àwọn òbí ń jàǹfààní látinú ìwé àtayébáyé kan tó kún fún ọgbọ́n, tí ìmọ̀ràn inú rẹ̀ sì ṣeé gbára lé títí dòní. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jẹ́ ká mọ ìwé náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́