Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn Jẹ́ Gbajúmọ̀?
Kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú àlàfo yìí:
․․․․․ kéèyàn jẹ́ gbajúmọ̀.
A. Ìgbà gbogbo ló dára
B. Kì í ṣe ìgbà gbogbo ló dára
D. Kò dára
ÌDÁHÙN tó tọ̀nà ni “B.” Kí nìdí? Ìdí ni pé, bí èèyàn kan bá jẹ́ gbajúmọ̀, ó lè túmọ̀ sí pé ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ràn irú ẹni bẹ́ẹ̀, kì í ṣe ìgbà gbogbo ni ìyẹn sì burú! Bíbélì sọ pé àwọn Kristẹni yóò jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” àwọn èèyàn yóò sì máa wá sọ́dọ̀ wọn. (Aísáyà 42:6; Ìṣe 13:47) Tá a bá fojú ìyẹn wò ó a lè sọ pé gbajúmọ̀ làwọn Kristẹni.
Ǹjẹ́ O Mọ̀? Gbajúmọ̀ ni Jésù náà. Kódà, nígbà tó ṣì wà ní ọmọdé, ó rí “ojú rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.” (Lúùkù 2:52) Bíbélì sì tún sọ pé nígbà tí Jésù dàgbà, “ogunlọ́gọ̀ ńlá tẹ̀ lé e láti Gálílì àti Dekapólì àti Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà àti láti ìhà kejì Jọ́dánì.”—Mátíù 4:25.
Kí nìdí tí kò fi burú bí Jésù ṣe jẹ́ gbajúmọ̀? Ìdí ni pé kì í ṣe pé Jésù ń wá ògo tàbí pé ó ń wá bó ṣe máa di gbajúmọ̀, kì í sì í ṣe pé ó ń wá bí àwọn èèyàn ṣe máa gba tiẹ̀ lọ́nàkọnà. Jésù kàn ń ṣe ohun tó dára ní tiẹ̀ ni, ìyẹn sì máa ń mú kí àwọn èèyàn gba tiẹ̀ láwọn ìgbà míì. (John 8:29, 30) Ṣùgbọ́n, Jésù mọ̀ pé nǹkan rere yòówù kí àwọn èèyàn sọ nípa òun, fún ìgbà díẹ̀ ni. Ó mọ̀ pé nígbà tó bá yá, àwọn èèyàn máa pa òun!—Lúùkù 9:22.
Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Ńṣe ni jíjẹ́ gbajúmọ̀ dà bíi kí èèyàn jẹ́ olówó. Kì í ṣe ìgbà gbogbo ló burú kí èèyàn ní owó. Ibi tí ìṣòro wà ni ohun tí àwọn èèyàn máa ń ṣe nítorí àtidolówó àti ohun tí wọ́n máa ń ṣe kí ọlá wọn lè máa ròkè.
Ṣọ́ra o! Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló jẹ́ pé kò sí ohun tí wọn kò lè ṣe kí wọ́n lè di gbajúmọ̀. Àwọn kan gbà pé ibi tí ayé bá yí sí ni àwọn á bá wọn yí sí. Ìpátá ni àwọn kan, wọ́n máa ń fipá mú àwọn èèyàn kí wọ́n lè gba tiwọn, bí kò tiẹ̀ ti ọkàn àwọn èèyàn náà wá.a
Nínú àwọn ojú ìwé tí ó tẹ̀ lé èyí, a máa jíròrò ọ̀nà méjì tó léwu tí èèyàn lè gbà di gbajúmọ̀. Lẹ́yìn náà, a máa jíròrò ọ̀nà tó dára téèyàn lè gbà di gbajúmọ̀.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìpátá kan tí wọ́n jẹ́ “Néfílímù,” ó tún pè wọ́n ní “àwọn ọkùnrin olókìkí.” Ohun tí wọ́n fẹ́ ni pé kí àwọn èèyàn ṣáà máa gbé ògo fún wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 6:4.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
ÀWỌN Ọ̀NÀ TÍ ÈÈYÀN LÈ GBÀ DI GBAJÚMỌ̀
ÀWỌN TÓ MÁA Ń ṢE OJÚ AYÉ
Mo fẹ́ kí àwọn èèyàn máa gba tèmi.
Kí àwọn èèyàn lè gba tèmi, mo gbọ́dọ̀ máa hùwà bíi tiwọn.
“Mo máa ń gbìyànjú láti yí ìwà mi pa dà kí ó lè bá ti àwọn míì mu. Ó kọ́kọ́ dà bíi pé ó dára. Àmọ́, nígbà tó yá, mo wá rí i pé kì í ṣe ohun tó dáa rárá pé kí ẹnì kan yí ìwà ẹ̀ pa dà torí kí àwọn èèyàn lè gba tiẹ̀.”—Nicole.
Ìlànà Bíbélì: “Iwọ kò gbọdọ tọ̀ ọ̀pọlọpọ enia lẹhin lati ṣe ibi.”—Ẹ́kísódù 23:2, Bíbélì Mímọ́.
ÌPÁTÁ
Àwọn èèyàn ti gba tèmi dáadáa tẹ́lẹ̀, bí mo sì ṣe fẹ́ kí wọ́n máa gba tèmi lọ́jọ́kọ́jọ́ nìyẹn.
Gbogbo ohun tó bá gbà ni màá ṣe kí àwọn èèyàn lè máa wárí fún mi, tó bá tiẹ̀ gba pé kí n máa gun àwọn èèyàn gàràgàrà.
“Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń hùwà ìkà sí ara wọn, nígbà tó sì jẹ́ pé àwọn ìpátá gbajúmọ̀ dáadáa, ńṣe ni ẹni tí kò bá láyà á gbà pé ohunkóhun tí wọ́n bá ṣe náà ló dára.”—Raquel.
Ìlànà Bíbélì: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”—Lúùkù 6:31.
Ọ̀NÀ TÓ DÁRA
1 Mọ ohun tó yẹ kó o ṣe. Bíbélì sọ pé àwọn tó dàgbà dénú ti “kọ́ agbára ìwòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.”—Hébérù 5:14.
2 Di ohun tó o gbà gbọ́ mú. Ńṣe ni kó o ṣe bíi Jóṣúà tó fi ìdánilójú sọ pé: “Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín . . . Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”—Jóṣúà 24:15.
3 Má ṣiyèméjì nípa ọ̀nà tí o yàn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán Tímótì létí pé: “Kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọ́run fún wa bí kò ṣe ti agbára.”—2 Tímótì 1:7.
Tó o bá ń fi àwọn kókó mẹ́ta tó wà ní apá òsì yìí sílò, èyí lè mú kó o má ṣe gbayì lójú àwọn kan mọ́, ṣùgbọ́n o máa dẹni tó gbayì lójú àwọn èèyàn gidi!
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ RẸ SỌ
Melissa—Òótọ́ ni pé o lè gbìyànjú láti máa ṣe bí àwọn ọmọ iléèwé rẹ kan ṣe ń ṣe. Àmọ́ ńṣe nìyẹn máa ń fi ayé súni! Ti pé o jẹ́ Kristẹni á mú kí o dá yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọlúwàbí. Ìyẹn ò sì túmọ̀ sí pé o kò dákan mọ̀. Ńṣe ló máa mú káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ.
Ashley—Nígbà tí mo bá wà ní iléèwé, ó máa ń ṣe mí bíi pé àwọn èèyàn ò gba tèmi, àmọ́ tí mo bá lọ sí ìpàdé Kristẹni, mo máa ń wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ mi, tí wọ́n sì mọyì mi. Èyí máa ń mú kí n rí i pé, kò sídìí fún mi láti máa wá bí àwọn ọmọ iléèwé mi ṣe máa gba tèmi.
Phillip—Ohun kan tó o lè ṣe tí àwọn èèyàn fi lè máa gba tìẹ ni pé kí ìwọ náà máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ ọ́ lógún. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo ti ń gbìyànjú láti máa ṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi, èyí sì ti mú kí á túbọ̀ sún mọ́ra.