ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/13 ojú ìwé 3
  • Ohun Tó Ń Lọ Láyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Ń Lọ Láyé
  • Jí!—2013
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Etíkun Ilẹ̀ Mẹ́síkò
  • Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà
  • Orílẹ̀-èdè Peru
  • Orílẹ̀-èdè Ítálì
  • Orílẹ̀-èdè South Africa
  • Epo Rọ̀bì—Báwo La Ṣe Ń Rí I?
    Jí!—2003
  • Ohun tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nílẹ̀ Áfíríkà
    Jí!—2015
  • Epo Rọ̀bì—Bí Ó Ṣe Wúlò fún Ọ
    Jí!—2003
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Jí!—2013
g 1/13 ojú ìwé 3

OHUN TÓ Ń LỌ LÁYÉ

Etíkun Ilẹ̀ Mẹ́síkò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé lóṣù April 2010 níbi tí wọ́n ti ń wa epo rọ̀bì lójú òkun ilẹ̀ Mẹ́síkò, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó odindi oṣù mẹ́ta tí epo àti gáàsì fi ń tú yàà sójú òkun. Ìwádìí kan fi hàn pé lẹ́yìn oṣù méjì àtààbọ̀, àwọn kòkòrò tín-tìn-tín inú òkun ti fa gbogbo epo àti gáàsì náà mu. Àmọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ń ṣiyè méjì lórí ọ̀rọ̀ yìí. Wọ́n sọ pé ó ṣeé ṣe káwọn kẹ́míkà náà ti ba òkun yẹn jẹ́ jìnnà.

Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà

Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fi hàn pé ẹni mẹ́fà nínú mẹ́wàá lára àwọn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún méjìdínlógún [18] sí márùndínlógójì [35] lórílẹ̀-èdè náà ló gbà pé “téèyàn bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé, kò ní máa fìgbà gbogbo hùwà ọmọlúwàbí tàbí kó máa tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere.” Ìwé ìròyìn Rossiiskaya Gazeta ló sọ bẹ́ẹ̀.

Orílẹ̀-èdè Peru

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Àwọn kùkù àgbàdo àtayébáyé tí àwọn kan rí (bí irú èyí tó wà nínú àwòrán yìí) fi hàn pé àwọn tó ń gbé ní apá àríwá ilẹ̀ Peru máa ń ṣe gúgúrú, wọ́n sì máa ń lọ àgbàdo ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta [3,000] sẹ́yìn.

Orílẹ̀-èdè Ítálì

Bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì kan ní ìpínlẹ̀ Adria-Rovigo tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lucio Soravito De Franceschi gbà pé ó yẹ káwọn lọ máa wàásù fún “àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan” ní ilé wọn. Ó sọ pé: “Ó yẹ káwa Pásítọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í lọ láti ilé dé ilé dípò ká kàn máa wàásù nínú ṣọ́ọ̀ṣì nìkan.”

Orílẹ̀-èdè South Africa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

A gbọ́ pé iye tí wọ́n ń ta ìwo ẹranko kan tí wọ́n ń pè ní Rhino (Rhinocerus) fáwọn tó fẹ́ lò ó fún ìṣègùn ti pọ̀ sí i báyìí. Ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà tí wọ́n ń ta kílò kan. Ní ọdún 2011, àkọsílẹ̀ fi hàn pé, lórílẹ̀-èdè South Africa nìkan, àwọn tó ń pa ẹranko láìgbàṣẹ ti pa Rhino tí ó pọ̀ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti méjìdínláàádọ́ta [448]. Àwọn jàǹdùkú tó ń wá ìwo ẹranko yìí ti fọ́ àwọn ibi tí wọ́n ń kó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí àtàwọn ibi tí wọ́n ti ń ta ọjà bàsá nílẹ̀ Yúróòpù. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n wá jí àwọn Rhino tó wà lọ́gbà ẹranko nílẹ̀ Yúróòpù pàápàá gbé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́