ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 11/13 ojú ìwé 12-15
  • Ohun Mẹ́ta Tí Owó Kò Lè Rà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Mẹ́ta Tí Owó Kò Lè Rà
  • Jí!—2013
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kó o tẹ̀ lé:
  • Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó
    Jí!—2015
  • Ṣé Owó Ni Gbòǹgbò Ohun Búburú Gbogbo?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Bí Ẹ Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná
    Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
  • Owó
    Jí!—2014
Àwọn Míì
Jí!—2013
g 11/13 ojú ìwé 12-15
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

ÀPILẸ̀KỌ TÓ DÁ LÓRÍ ÀKÒRÍ Ẹ̀YÌN ÌWÉ

Ohun Mẹ́ta Tí Owó Kò Lè Rà

ÌYÀLẸ́NU gbáà ló jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ ṣì máa ń tiraka gan-an láti ra ohunkóhun àti gbogbo nǹkan tówó bá ṣáà ti lè rà, kódà kí iṣẹ́ ti fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn tàbí kí wọ́n mọ̀ pé àwọn máa tó di aláìnílélórí tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ rówó ìfẹ̀yìntì wọn gbà.

Irú àwọn yìí sì ni àwọn tó ń polówó ọjà máa ń rí mú nínú ọ̀rọ̀ dídùn tí wọ́n fi máa ń polówó ọjà pé ó yẹ kí ilé wa tóbi sí i, ó yẹ kí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wa dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ká sì máa lo àwọn aṣọ ìgbàlódé. Ká sọ pé a ò lówó lọ́wọ́ ńkọ́? Wọ́n á ní ìyẹn kì í ṣe ìṣòro, a lè rà á láwìn! Ọ̀pọ̀ ló sì máa ń kó sí wọn lọ́wọ́ torí wọn fẹ́ káyé máa yẹ àwọn bí gbèsè tiẹ̀ wọ̀ wọ́n lọ́rùn.

Àmọ́, bópẹ́ bóyá, ojú wọn máa ń já a. Ìwé kan tó n jẹ́ The Narcissism Epidemic sọ pé: “Téèyàn bá ń rajà àwìn torí pé ó fẹ́ kí ìrísí òun dára tàbí tó fi ń dá ara rẹ̀ nínú dùn ṣe ló dà bí ìgbà tẹ́nì kan ń lo oògùn olóró láti fi pàrònú rẹ́. Lóòtọ́, ó máa kọ́kọ́ dà bíi pé kò wọ́nwó, ó sì jẹ́ ọ̀nà tó rọrùn láti gbà rí nǹkan téèyàn fẹ́, àmọ́ adùn wọn kì í tọ́jọ́. Kò ní pẹ́ rárá tó o fi máa rí i pé ọjà àwìn ti gbọ́n ẹ lówó lọ. Bẹ́ẹ̀ náà sì lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú ẹni tó fi oògùn olóró pàrònú rẹ́; tí oògùn olóró bá ṣiṣẹ́ lára tán, ńṣe ni ìrẹ̀wẹ̀sì á tún wọlé dé.”

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò sí àǹfààní kankan nínú “fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòhánù 2:16) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tá a bá gbé àwọn nǹkan ìní lọ́kàn jù, kò ní jẹ́ ká lè ronú nípa àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé, ìyẹn àwọn nǹkan tí owó kò lè rà. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́ta lára wọn.

1. KÍ ÌDÍLÉ WÀ NÍṢỌ̀KAN

Ọ̀dọ́ kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Brianne,a gbà pé iṣẹ́ àtàwọn nǹkan téèyàn lè fowó rà ló gba bàbá òun lọ́kàn jù. Ó sọ pé: “A ní àwọn nǹkan tó pọ̀ gan-an, kódà a ní ju ohun tá a nílò lọ, àmọ́ dádì mi kì í gbélé tórí gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń rìnrìn-àjò. Mo mọ̀ pé iṣẹ́ wọn ló fà á, àmọ́ ó yẹ kí wọ́n rántí pé ojúṣe wọn ni láti wà pẹ̀lú ìdílé wọn!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Tó bá yá, àwọn nǹkan wó ló ṣeé ṣe kí bàbá Brianne kábàámọ̀ rẹ̀? Báwo ni bí àwọn nǹkan ìní ṣe gbà á lọ́kàn ju bó ṣe yẹ lọ kò ṣe ní jẹ́ kí àárín òun àti ọmọbìnrin rẹ̀ gún régé? Àwọn nǹkan wo ni ìdílé rẹ̀ nílò látọ̀dọ̀ rẹ̀ tó ju owó lọ?

Àwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kó o tẹ̀ lé:

  • “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí . . . àwọn kan . . . ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:10.

  • “Oúnjẹ tí a fi ọ̀gbìn oko sè, níbi tí ìfẹ́ wà, sàn ju akọ màlúù tí a bọ́ yó ní ibùjẹ ẹran tòun ti ìkórìíra.”—Òwe 15:17.

    Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Ìṣọ̀kan ìdílé kò ṣeé fowó rà. Ohun kan ṣoṣo tó lè mú kí ìdílé rẹ wà ní ìṣọ̀kan ni pé kó o máa wà pẹ̀lú wọn, kó o nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, kó o sì máa gbọ́ tiwọn.—Kólósè 3:18-21.

2. OJÚLÓWÓ ÀÀBÒ

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan tó ń jẹ́ Sarah sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mọ́mì mi máa ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ mi létí pé ọkùnrin tó lówó rẹpẹtẹ ni mo gbọ́dọ̀ fẹ́ àti pé ó yẹ kí n wá iṣẹ́ gidi kan kọ́ kí n lè gbádùn ìgbésí ayé mi.” Ó jọ pé wọn kò rí nǹkan míì rò ju bí owó á ṣe máa wọlé fún wọn lọ.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Àwọn nǹkan wo ni kì í fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ tó o bá ń ronú nípa ọjọ́ ọ̀la? Báwo la ṣe lè mọ̀ tí ẹnì kan bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn jù nípa ọjọ́ ọ̀la? Kí ló yẹ kí mọ́mì Sarah ṣe tí kò fi ní máa ṣàníyàn jù nípa bí wọ́n ṣe máa rówó ná lọ́jọ́ iwájú?

Àwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kó o tẹ̀ lé:

  • “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè.”—Mátíù 6:19.

  • “Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la.”—Jákọ́bù 4:14.

Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Owó nìkan kò tó láti fi èèyàn lọ́kàn balẹ̀ pé ọ̀la máa dáa. Ó ṣe tán, olè lè jí owó lọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé owó kò lè mú àìsàn tàbí ikú kúrò. (Oníwàásù 7:12) Ohun tí Bíbélì sọ ni pé tá a bá fẹ́ ní ojúlówó ààbò àfi ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti àwọn ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.—Jòhánù 17:3.

3. ÌTẸ́LỌ́RÙN

Ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún [24] kan tó ń jẹ́ Tanya sọ pé: “Báwọn òbí mi ṣe tọ́ mi dàgbà jẹ́ kí n mọ̀ pé a ò nílò ohun rẹpẹtẹ ká tó lè gbélé ayé. Nígbà témi àti Táyé mi ń dàgbà, ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ohun tá a máa ń ní lọ́wọ́ kì í ju ohun tá a nílò fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, síbẹ̀ inú wa máa ń dùn.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Kí nìdí tó fi lè ṣòro fún wa láti jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tá a ní tẹ́ wa lọ́rùn? Tó bá kan ọ̀rọ̀ owó, àpẹẹrẹ wo lo fi lélẹ̀ fún ìdílé rẹ?

Àwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kó o tẹ̀ lé:

  • “Bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.”—1 Tímótì 6:8.

  • “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.”—Mátíù 5:3.

Ohun tó yẹ kó o fi sọ́kàn: Àwọn nǹkan kan wà nígbèésí ayé tó ṣe pàtàkì ju owó àtàwọn ohun tí owó lè rà lọ. Bí Bíbélì ṣe sọ gan-an ló rí: “Tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ohun tó lè jẹ́ kí ọkàn ẹni balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ ni kéèyàn mọ ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bíi:

  • Kí nìdí tá a fi wà láyé?

  • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

  • Kí ni mo lè ṣe kí n bàa lè sún mọ́ Ọlọ́run?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé yìí. Inú wa máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yẹn.

a A ti yí àwọn orúkọ kan nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

Ṣé Owó Lè Fúnni Láyọ̀?

Ìwé kan tó ń jẹ́, The Narcissism Epidemic, sọ pé: “Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ owó kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀, wọ́n sì máa ń ní ìdààmú ọkàn. Kódà, ọpọlọ àwọn tó sábà máa ń ṣàníyàn nípa bí wọ́n ṣe máa túbọ̀ lówó sí i kì í fi bẹ́ẹ̀ jí pépé, wọ́n sì máa ń ní àwọn àìlera kan, irú bíi kí ọ̀nà ọ̀fun máa dùn wọ́n, ẹ̀yìn ríro àti ẹ̀fọ́rí. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń mu ọtí lámujù, wọ́n sì máa ń lo oògùn olóró. Ó ṣe kedere nígbà náà pé nǹkan máa ń dojú rú fún àwọn tó bá ń wá bí wọ́n ṣe máa rí towó ṣe lójú méjèèjì.”

“Nǹkan Ti Yí Pa Dà”

Ìwé kan tí Ọ̀mọ̀wé Madeline Levine kọ tó pè ní The Price of Privilege sọ pé: “Láàárín ọdún 1960 sí 1973 ìdí pàtàkì tí ọ̀pọ̀ fi ń lọ sí ilé ìwé gíga ni pé kí wọ́n lè ‘di ọ̀mọ̀wé láwùjọ’ tàbí ‘kí àwọn lè lóye bí ayé ṣe rí.’ Ìwọ̀nba làwọn tó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga nítorí ‘kí wọ́n lè lówó rẹpẹtẹ.’ Àmọ́ láti ọdún 1990 ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá ń sọ pé torí káwọn lè ‘rí towó ṣe’ ni ìdí pàtàkì táwọn fi ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga . . . Látìgbà tí nǹkan ti yí pa dà nípa ìdí táwọn ọ̀dọ́ fi ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga yìí ni ìṣòro ìsoríkọ́, fífọwọ́ ara ẹni gbẹ̀mí ara ẹni, àtàwọn ìṣòro míì tó ní í ṣe pẹ̀lú ọpọlọ ti ń ga sí i lọ́nà tó kàmàmà.”

“Wọ́n Ń Fi Ọjà Rírà Pàrònú Rẹ́”

Dókítà kan tó ń jẹ́ Madeline Levine sọ pé ìdílé, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ṣọ́ọ̀ṣì ti já àwọn èèyàn kulẹ̀, torí náà, wọ́n ń fi ọjà rírà pàrònú rẹ́ kí ara lè tù wọ́n. Nínú ìwé rẹ̀ tó pè ní The Price of Privilege, ó sọ pé: “Rírajà máa ń jẹ́ kéèyàn lè ṣe nǹkan bó ṣe wù ú. Ẹni tó ń rajà ló máa dúnàádúrà, òun ló sì máa pinnu ohun tó fẹ́ rà. Onítọ̀hún lè wá máa rò pé ohun tóun bá fẹ́ nìkan lòun máa rà. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé òun gan-an kọ́ ló ń ṣe ìpinnu yẹn. Àwọn ilé ìtajà ńláńlá àti àwọn tó ń bá wọn polówó ọjà ló ń pinnu ohun táwọn èèyàn máa rà. Àwọn ilé ìtajà yẹn máa ń sanwó fún àwọn tó ń bá wọn polówó ọjà kí wọ́n lè jẹ́ káwọn èèyàn rò pé ó láwọn àǹfààní àràmàǹdà kan tí wọ́n máa rí gbà tí wọ́n bá ra ọjà náà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́