ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g18 No. 1 ojú ìwé 10-11
  • Ìdáríjì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdáríjì
  • Jí!—2018
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ DÁRA GAN-AN!
  • Kí Ni Ìdáríjì?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • ‘Ẹ Máa Bá a Lọ Ní Dídáríji Ara Yín Lẹ́nì Kíní Kejì’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Èéṣe tí A Fi Níláti Máa Dáríjini?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Máa Dárí Jini Látọkànwá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Jí!—2018
g18 No. 1 ojú ìwé 10-11
Obìnrin kan dárí ji ọ̀rẹ́ rẹ̀

OHUN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀

Ìdáríjì

Obìnrin kan tó ń jẹ́ Patricia sọ pé: “NÍGBÀ TÍ MO WÀ LỌ́MỌDÉ, WỌ́N MÁA Ń BÚ ARA WỌN GAN-AN NÍNÚ ÌDÍLÉ WA, WỌ́N SÌ MÁA Ń PARIWO MỌ́RA WỌN. Ìyẹn ò jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń dárí jini. Kódà nígbà tí mo dàgbà, téèyàn bá ṣẹ̀ mí, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni mo fi máa ń gbé ọ̀rọ̀ náà sọ́kàn, tí mi ò sì ní rí oorun sùn.” Tí ìgbésí ayé ẹni bá kún fún ìbínú ní gbogbo ọjọ́, téèyàn sì ń gbé ọ̀rọ̀ sọ́kàn, èèyàn ò ní láyọ̀, ìlera rẹ̀ ò sì ní dára. Ìwádìí tiẹ̀ fi hàn pé, àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kì í dárí jini:

  • Wọ́n máa ń jẹ́ kí ìbínú dá wàhálà sílẹ̀ láàárín àwọn àtàwọn míì, èyí sì lè mú kí wọ́n máa dá nìkan wà

  • Wọ́n máa ń kanra, wọ́n máa ń ṣàníyàn, wọ́n sì máa ń ní ìdààmú ọkàn

  • Wọ́n máa ń fìgbà gbogbo ronú nípa ohun tẹ́nì kan ṣe fún wọn, débi pé wọn ò ní lè gbádùn ayé wọn

  • Wọ́n máa ń mọ̀ pé àwọn ò ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́

  • Nǹkan máa ń tojú sú wọn gan-an, wọ́n sì máa ń ní onírúurú àìlera, bí ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ọkàn àti ìrora, oríkèé ara lè máa ro wọ́n tàbí kí orí máa fọ́ wọna

KÍ NI ÌDÁRÍJÌ? Ìdáríjì túmọ̀ sí pé kí èèyàn gbójú fo àìdáa tẹ́nì kan ṣe sí wa, kí èèyàn má ṣe bínú mọ́, kó má ṣe gbé e sọ́kàn, kó má sì ronú láti gbẹ̀san. Èyí kò túmọ̀ sí pé a fara mọ́ ohun tí ẹni náà ṣe, tàbí pé ohun náà kò tó nǹkan, kò sì túmọ̀ sí pé à ń díbọ́n bíi pé nǹkan kan kò ṣẹlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la dìídì pinnu láti gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wa, torí pé a fẹ́ kí àlàáfíà jọba, a ò sì fẹ́ kí àjọṣe tó wà láàárín àwa àtàwọn míì bà jẹ́.

Ẹni tó bá ní àròjinlẹ̀ ló máa ń dárí jini. Ẹni tó bá ní ẹ̀mí ìdáríjì mọ̀ pé gbogbo wa la máa ń dẹ́ṣẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe wa. (Róòmù 3:23) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”​—⁠Kólósè 3:⁠13.

Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti sọ pé, dídárí ji àwọn míì jẹ́ ara ọ̀nà pàtàkì tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn, ìfẹ́ yìí sì ni Bíbélì pè ní “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” (Kólósè 3:14) Kódà, ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì Mayo Clinic sọ pé àwọn nǹkan tó tẹ̀ lé e yìí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ń dárí jini:

  • Wọ́n máa ń ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn èèyàn, wọ́n máa ń gba ti àwọn èèyàn rò, wọ́n máa ń fi òye báni lò, wọ́n sì máa ń yọ́nú sí ẹni tó bá ṣẹ̀ wọ́n

  • Ọpọlọ wọn máa ń jí pépé, wọ́n sì máa ń sún mọ́ Ọlọ́run

  • Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣàníyàn, nǹkan kì í fi bẹ́ẹ̀ tojú sú wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í sábà kanra

  • Wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ ní ìdààmú ọkàn

DÁRÍ JI ARA RẸ. Ìwé kan tó ń jẹ́ Disability & Rehabilitation sọ pé kí èèyàn dárí ji ara rẹ̀ “ló máa ń ṣòro jù,” àmọ́ “ìyẹn ló ṣe pàtàkì jù tí èèyàn bá fẹ́ ní ìlera tó dáa,” torí pé ó máa ń jẹ́ kí ọpọlọ jí pépé kí ara sì yá gágá. Kí ló lè mú kó o máa dárí ji ara rẹ?

  • Má ṣe máa wo ara rẹ bí ẹni tí kò lè ṣe àṣìṣe rárá, àmọ́ ńṣe ni kó o gbà pé kò sẹ́ni tí kò lè ṣe àṣìṣe, ìyẹn ò sì yọ ìwọ náà sílẹ̀.​—⁠Oníwàásù 7:⁠20

  • Kọ́gbọ́n nínú àṣìṣe rẹ, kí ohun tó ṣe ẹ́ lẹ́ẹ̀kan má bàa tún ṣe ẹ́ nígbà míì

  • Máa ṣe sùúrù fún ara rẹ; fi sọ́kàn pé àwọn ìwà tàbí àṣà kan tó ti mọ́ni lára kì í lọ bọ̀rọ̀.​—⁠Éfésù 4:​23, 24

  • Àwọn tó yẹ kó o máa bá ṣọ̀rẹ́ ni àwọn tó lè fún ẹ níṣìírí láti máa ṣe ohun tó dára, tí wọ́n gbà pé nǹkan ṣì máa dára, tí wọ́n jẹ́ onínúure, tí wọ́n sì lè bá ẹ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀.​—⁠Òwe 13:⁠20

  • Tó o bá ṣẹ ẹnì kan, gbà pé o jẹ̀bi, kó o sì tètè tọrọ àforíjì. Tó o bá ń sapá láti jẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín ìwọ àtàwọn míì, ọkàn tìẹ náà á balẹ̀.​—⁠Mátíù 5:​23, 24

ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ DÁRA GAN-AN!

Nígbà tí Patricia tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó wá dẹni tó máa ń dárí jini. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe bọ́ lọ́wọ́ ìbínú burúkú tó fẹ́ bayé mi jẹ́ nìyẹn. Mi ò fi ayé ni ara mi mọ́, bẹ́ẹ̀ ni mi ò fayé ni àwọn míì lára mọ́. Àwọn ìlànà Bíbélì ń fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ohun tó dáa jù lọ ló sì ń fẹ́ fún wa.”

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ron sọ pé: “Kò sóhun tí mo lè ṣe nípa ohun táwọn míì ń rò àti ohun tí wọ́n ń ṣe. Àmọ́ mo lè ṣe nǹkan kan nípa èrò àti ìṣe tèmi. Tí mo bá fẹ́ kí àlàáfíà jọba, mi ò gbọ́dọ̀ máa di àwọn míì sínú. Mo wá rí i pé mi ò lè sọ pé ẹlẹ́mìí àlàáfíà ni mí kí n tún máa di àwọn èèyàn sínú. Ọkàn mi ti wá balẹ̀ gan-an báyìí.”

a Ibi tá a ti rí ìsọfúnni: Orí ìkànnì Mayo Clinic àti Johns Hopkins Medicine àti ìwé Social Psychiatry and Psychiatric Epidemiology.

KÓKÓ PÀTÀKÌ

“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì.”​—⁠Kólósè 3:⁠13.

Àǹfààní tó wà nínú kí èèyàn máa dárí jini:

  • A máa ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ọkàn wa á sì balẹ̀

  • A ò ní fi bẹ́ẹ̀ máa ṣàníyàn, a ò ní máa kanra, nǹkan ò sì ní máa tètè sú wa

  • Ara wa á yá gágá, ọpọlọ wa á jí pépé, àá sì túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́