OHUN TÓ Ń FÚNNI LÁYỌ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ Sí i
ṢÓ O MÁA Ń RONÚ LÓRÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ?
Báwo ni ìdílé mi ṣe lè láyọ̀?
Báwo ni mo ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ kí èmi náà sì jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi?
Ṣé àwọn èèyàn mi tó ti kú ṣì lè jíǹde?
Ṣé ìyà lè dópin?
Ṣé àwọn èèyàn ló máa pa ayé yìí run?
Ṣé gbogbo ẹ̀sìn ni inú Ọlọ́run dùn sí?
O LÈ RÍ ÌDÁHÙN SÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ ÀTÀWỌN ÌBÉÈRÈ MÍÌ
Lọ sí ìkànnì jw.org. Ó wà ní èdè tó ju 900 lọ. Wàá rí àwọn ìṣọfúnni tó máa wúlò fún ẹ nípa àwọn kókó ọ̀rọ̀ tó yàtọ̀ síra.
Wàá tún rí fídíò àwọn èèyàn káàkiri ayé tí wọ́n ti rí ọ̀nà ayọ̀, tí wọn ò sì bojú wẹ̀yìn mọ́! Oògùn olóró tiẹ̀ ti di bárakú fún àwọn kan lára wọn nígbà kan, bẹ́ẹ̀ làwọn míì sì jẹ́ àkòtagìrì ẹlẹ́wọ̀n tẹ́lẹ̀. Àwọn tó kàwé gan-an àtàwọn ọ̀jọ̀gbọ́n tún wà lára wọn, títí kan àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì.
Tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org/yo, o lè ka Bíbélì àtàwọn ìwé míì tó ń ṣàlàyé Bíbélì tàbí kó o wà wọ́n jáde lọ́fẹ̀ẹ́. Díẹ̀ lára àwọn ìwé náà ni:
Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!