ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g19 No. 2 ojú ìwé 10-11
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé
  • Jí!—2019
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI JẸ́ ẸNI TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ?
  • KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÉÈYÀN ṢEÉ GBÁRA LÉ?
  • BÍ ỌMỌ RẸ ṢE LÈ DẸNI TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ
  • Iṣẹ́ Ilé Ṣe Pàtàkì
    Jí!—2017
  • Kíkọ́ Láti Yọ̀ǹda Wọn
    Jí!—1998
  • 8 Àpẹẹrẹ Rere
    Jí!—2018
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Jí!—2019
g19 No. 2 ojú ìwé 10-11
Bàbá kan ń kọ́ ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa bomi rin òdòdó

Ẹ̀KỌ́ 4

Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI JẸ́ ẸNI TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ?

Ẹni tó bá ṣeé gbára lé jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ó máa ń fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún un, ó sì máa ń parí rẹ̀ lákòókò.

Àwọn ọmọdé náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ bí wọ́n ṣe lè dẹni tó ṣeé gbára lé láìka ọjọ́ orí wọn sí. Ìwé kan tó ń jẹ́ Parenting Without Borders sọ pé: “Tí ọmọ bá wà ní ọdún kan àti oṣù mẹ́ta, ohun táwọn òbí ẹ̀ bá sọ fún un ni á máa ṣe, àmọ́ láti ọmọ ọdún kan àtààbọ̀ lọ sókè, ohun tó bá rí táwọn òbí ẹ̀ ń ṣe lòun náà á máa ṣe. Torí náà, ọ̀pọ̀ òbí ló sábà máa ń gbé àwọn iṣẹ́ kan fáwọn ọmọ tó wà ní ọdún márùn-ún sí méje. Ó sì dùn mọ́ni láti rí i pé irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún wọn.”

KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÉÈYÀN ṢEÉ GBÁRA LÉ?

Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń kúrò nílé kí wọ́n lè máa dá bójú tó ara wọn, àmọ́ wọ́n máa kó sínú ọ̀pọ̀ ìṣòro tí wọ́n á sì pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó máa ń fa ìṣòro yìí ni pé àwọn ọ̀dọ́ náà ò tíì mọ béèyàn ṣe ń ṣọ́wó ná, béèyàn ṣe ń bójú tó ilé àti béèyàn ṣe ń ṣètò ara ẹni dáadáa.

Torí náà, ohun tó máa ṣàǹfààní ni pé kó o kọ́ ọmọ ẹ ní ohun tó yẹ, kó lè ṣeé gbára lé. Ìwé náà, How to Raise an Adult sọ pé: “Kò yẹ kó jẹ́ pé ìwọ ni wọ́n máa gbára lé títí di ọmọ ọdún méjìdínlógún, tí wọ́n á wá jáde nílé tán, tí wọn ò ní lè bójú tó ara wọn.”

BÍ ỌMỌ RẸ ṢE LÈ DẸNI TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ

Yan iṣẹ́ ilé fún wọn.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.”​—Òwe 14:23.

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé ló máa ń fẹ́ bá àwọn òbí wọn ṣiṣẹ́. Ó máa dáa kó o lo àǹfààní yẹn láti yan iṣẹ́ fún wọn nínú ilé, kó o lè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́.

Àwọn òbí kan kì í fẹ́ ṣe ohun tá a sọ yìí, èrò wọn ni pé ńṣe ni àwọn á mú ayé sú àwọn ọmọ táwọn bá tún gbé iṣẹ́ ilé fún wọn, torí pé iṣẹ́ ilé ìwé táwọn ọmọ ń ṣe ti pọ̀ jù.

Àmọ́, àwọn ọmọdé tó bá máa ń ṣiṣẹ́ ilé sábà máa ń ṣàṣeyọrí nílé ìwé torí pé ó ti mọ́ wọn lára láti máa ṣiṣẹ́ táwọn òbí wọn bá fún wọn kí wọ́n sì parí ẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, ìwé Parenting Without Borders sọ pé, “tá ò bá jẹ́ káwọn ọmọ wa máa ṣiṣẹ́ ilé nígbà tí wọ́n ṣì kéré, ó lè mú kí wọ́n rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan láti máa ṣiṣẹ́ ilé . . . Tó bá wá yá, wọ́n á máa retí pé káwọn míì máa ṣe gbogbo nǹkan fún wọn.”

Bí ìwé yẹn ṣe sọ, tá a bá jẹ́ káwọn ọmọ wa máa ṣe iṣẹ́ ilé déédéé, á mọ́ wọn lára láti máa ran àwọn míì lọ́wọ́ dípò kí wọ́n máa retí pé káwọn èèyàn máa bá wọn ṣe gbogbo nǹkan. Táwọn ọmọ bá ń ṣiṣẹ́ ilé, ó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé àwọn ń kópa pàtàkì nínú ìdílé àti pé ohun tó yẹ kí àwọn máa ṣe nìyẹn.

Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ mọ̀ pé ohun tí wọ́n bá gbìn ni wọ́n máa ká.

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ìbáwí, kí o lè di ọlọ́gbọ́n ní ọjọ́ ọ̀la rẹ.”​—Òwe 19:20.

Tí ọmọ rẹ bá ṣàṣìṣe, bóyá ó ba nǹkan oní nǹkan jẹ́, má ṣe sọ pé ohun tó ṣe ò tó nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ kó gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi, kó tọrọ àforíjì tàbí kó tiẹ̀ gbìyànjú láti tún nǹkan yẹn ṣe.

Tó o bá kọ́ ọmọ rẹ láti máa gba ẹ̀bi rẹ̀ lẹ́bi:

  • á jẹ́ olóòótọ́

  • kò ní máa di ẹ̀bi ru àwọn míì

  • kò ní máa ṣe àwáwí

  • á máa tọrọ àforíjì nígbà tó bá yẹ

Bàbá kan ń kọ́ ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa bomi rin òdòdó

TÈTÈ BẸ̀Ẹ̀RẸ̀ SÍ Í KỌ́ ỌMỌ RẸ

Àwọn ọmọ tí wọ́n bá kọ́ láti jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé máa ń lè ṣètò ara wọn lọ́nà tó yẹ nígbà tí wọ́n bá dàgbà

Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere

  • Ṣé mo máa ń tẹpá mọ́ṣẹ́, ṣé mo wà létòletò, ṣé mo sì máa ń tètè dé ibi iṣẹ́?

  • Ṣé àwọn ọmọ mi máa ń rí i pé mò ń ṣiṣẹ́ ilé?

  • Ṣé mo máa ń gbà pé mo ṣàṣìṣe, ṣé mo sì máa ń tọrọ àforíjì tó bá yẹ?

Ohun Tá A Ṣe . . .

“Láti kékeré ni àwọn ọmọ mi ti máa ń ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ń dáná. Tí mo bá ń ká aṣọ, wọ́n máa ń bá mi ká a. Tí mo bá ń nu àwọn ibi tó dọ̀tí nínú ilé, wọ́n máa ń bá mi nù ún. Èyí wá jẹ́ kí wọ́n gbádùn iṣẹ́ ilé. Inú wọn máa ń dùn láti máa bá mi ṣiṣẹ́. Bí wọ́n ṣe dẹni tí mo lè gbé iṣẹ́ fún tọ́kàn mi á sì balẹ̀ nìyẹn o.” ​—Laura.

“Ìgbà kan wà tí mo sọ fún ọmọkùnrin wa pé kó pe ọ̀rẹ́ wa kan láti tọrọ àforíjì nítorí ìwà àfojúdi tó hù. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń sọ fún un pé kó tọrọ àforíjì tó bá tún ti ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, kódà tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀. Àmọ́ ní báyìí ó máa ń tọrọ àforíjì ní fàlàlà, nígbàkigbà tó bá ṣàṣìṣe.”​—Debra.

Ó ṢE PÀTÀKÌ KÉÈYÀN KỌ́GBỌ́N LÁTINÚ ÀṢÌṢE RẸ̀

Olùkọ́ kan tó ń jẹ́ Jessica Lahey sọ nínú ìwé ìròyìn Atlantic pé: “Àwọn ọmọ máa ń ṣe àṣìṣe, tí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ káwọn òbí ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè kọ́gbọ́n látinú àṣìṣe náà. Lọ́dọọdún, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan máa ń fìdí rẹmi nínú àwọn iṣẹ́ ilé ìwé kan, àmọ́ àwọn òbí wọn kì í sọ pé ká bá àwọn dọ́gbọ́n sí i káwọn ọmọ náà lè yege. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń jẹ́ kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ látinú àṣìṣe wọn, kí wọ́n sì ṣàtúnṣe. Irú àwọn ọmọ yìí ló máa ń ṣàṣeyọrí.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́