ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g20 No. 2 ojú ìwé 8-9
  • 2. Ṣé Àwa La Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2. Ṣé Àwa La Lẹ̀bi Ìyà Tó Ń Jẹ Wá?
  • Jí!—2020
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì
  • Ronú Lórí Èyí
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2020
  • Ìbéèrè Kẹta: Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Jẹ́ Kí Ìyà Máa Jẹ Mí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • 4. Ṣé Látìbẹ̀rẹ̀ Ni Ọlọ́run Ti Dá Wa Pé Ká Máa Jìyà?
    Jí!—2020
Àwọn Míì
Jí!—2020
g20 No. 2 ojú ìwé 8-9
Ọkùnrin kan jókòó sínú ilé rẹ̀, ó fọwọ́ kan di sìgá mú, ó sì fọwọ́ kejì gbé bíà dání.

2. Ṣé Àwa La Lẹ̀bi Ìyà Tó ń jẹ Wá?

Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yìí Fi Ṣe Pàtàkì

Tó bá jẹ́ pé àwa la lẹ̀bi, á jẹ́ pé a lè mú àwọn ìyà kan tó ń jẹ wá kúrò.

Ronú Lórí Èyí

Èwo lára àwọn ohun tó ń fa ìyà wọ̀nyí làwa èèyàn jẹ̀bi rẹ̀?

  • Àwòrán ọwọ́ tó di ẹ̀ṣẹ́, ó ṣàpẹẹrẹ ìwà ìkà.

    Ìwà Ìkà.

    Àjọ Ìlera Àgbáyé fojú bù ú pé èèyàn kan nínú mẹ́rin ni wọ́n ti hùwà ìkà sí nígbà tó wà lọ́mọdé. Bákan náà, ọ̀kan nínú obìnrin mẹ́ta ni wọ́n ti hùwà ìkà sí tàbí tí wọ́n ti fipá bá lò pọ̀ rí.

  • Àwòrán ibojì, ó ṣàpẹẹrẹ itẹ́ òkú.

    Ọ̀fọ̀.

    Ìròyìn kan tí Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé jáde sọ pé: “Kárí ayé, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́rin (477,000) èèyàn ni wọ́n pa lọ́dún 2016.” Èyí sì jẹ́ àfikún sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́sàn-án (180,000) tí wọ́n gbà pé wọ́n kú sínú ogun àti ìjà lọ́dún yẹn.

  • Àwòrán ọkàn tó ní ilà, ó ṣàpẹẹrẹ àìléra.

    Àìlera.

    Nínú àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn National Geographic, òǹkọ̀wé Fran Smith sọ pé: “Àwọn tó ń mu sìgá ju bílíọ̀nù kan lọ, sìgá sì jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń fa àrùn márùn-ún tó ń pa èèyàn jù lọ. Àwọn àrùn náà ni: àrùn ọkàn, àrùn rọpárọsẹ̀, àìsàn èémí, àìsàn tó ń mú kí òpó ẹ̀jẹ̀ dí àti jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró.”

  • Àwòrán òṣùwọ̀n tí kò dọ́gba, ó ṣàpẹẹrẹ kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́.

    Kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́.

    Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jay Watts tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìrònú ẹ̀dá sọ pé: “Ipò òṣì, fífojú pa àwọn èèyàn rẹ́, kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, èrò pé ọkùnrin lọ̀gá obìnrin, lílé àwọn èèyàn kúrò nílùú àti gbígbé àṣà ìbílẹ̀ kan ga ju ìkejì lọ máa ń kó ìdààmú ọkàn bá èèyàn.”

    TÓ O BÁ FẸ́ MỌ̀ SÍ I

    Wo fídíò Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé? Ó wà lórí ìkànnì jw.org.

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Ọkùnrin tó di sìgá mú yẹn ti wà lórí ibùsùn nílé ìwòsàn. Ìyàwò rẹ̀ gbójú sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan bí dókítà ṣe ń sọ ìròyìn burúkú nípa àìlera ọkọ rẹ̀.

Àwa èèyàn la lẹ̀bi ọ̀pọ̀ lára ìyà tó ń jẹ wá.

Àwọn ìjọba tó ń fìyà jẹ aráàlú ti mú kí ayé nira fáwọn èèyàn tí wọ́n sọ pé àwọn ń bójú tó.

“Èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára rẹ̀.” ​—ONÍWÀÁSÙ 8:9.

A lè mú àwọn ìyà kan kúrò.

Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, ìlera wa á dáa sí i, àá sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn.

“Ìbàlẹ̀ ọkàn ń mú kí ara lókun, àmọ́ owú dà bí àìsàn tó ń mú kí egungun jẹrà.”​—ÒWE 14:30.

“Ẹ mú gbogbo inú burúkú, ìbínú, ìrunú, ariwo àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín, títí kan gbogbo ohun tó lè ṣeni léṣe.”​—ÉFÉSÙ 4:31.

Ṣé àwa la lẹ̀bi ìyà tó ń jẹ wá?

Bíbélì sọ pé: “Ohun tí èèyàn bá gbìn, òun ló máa ká.” (Gálátíà 6:⁠7) Nígbà míì, àwọn ìpinnu tá a bá ṣe ló máa ń fìyà jẹ wá. Ìdí nìyẹn táwọn dókítà fi gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kí wọ́n máa ṣeré ìmárale, kí wọ́n sì jáwọ́ nínú àwọn àṣà tó léwu bíi mímu sìgá. Àmọ́ kò tọ̀nà tá a bá sọ pé àwa èèyàn la lẹ̀bi gbogbo ìyà tó ń jẹ wá. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni jàǹbá ń ṣẹlẹ̀ sí, táwọn àjálù ń dé bá tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ míì, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn kọ́ ló fà á.

Kí nìdí táwọn èèyàn rere fi ń jìyà?

Wo ìbéèrè 3.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́