ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g21 No. 1 ojú ìwé 15
  • Ẹ̀kọ́ Táá Jẹ́ Kó O Di Ọlọ́gbọ́n

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀kọ́ Táá Jẹ́ Kó O Di Ọlọ́gbọ́n
  • Jí!—2021
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Fẹ́ Kó O Jàǹfààní Látinú Ọgbọ́n Òun
  • O Lè Ní Ọgbọ́n Ọlọ́run
  • Báwo La Ṣe Lè Tẹ́tí sí Ọlọ́run?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ǹjẹ́ O Gbà Pé Ọlọ́run Wà? Tó O Bá Gbà Àǹfààní Wo Ló Máa Ṣe Ẹ́?
    Jí!—2015
  • Ohun Tó Dáa àti Ohun Tí Kò Dáa: Pinnu Ohun Tí Wàá Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
  • Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Jí!—2021
g21 No. 1 ojú ìwé 15

Ẹ̀kọ́ Táá Jẹ́ Kó O Di Ọlọ́gbọ́n

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.” (2 Tímótì 3:16) Ohun tí “mí sí” tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run Olódùmarè fi èrò rẹ̀ sọ́kàn àwọn tó kọ Bíbélì.

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀ NÍPA BÍBÉLÌ

  • Apá kan nínú ìwé kan.

    66

    Iye ìwé tó wà nínú Bíbélì.

  • Ìmọ́lẹ̀ tàn látòkè, ọwọ́ kan sì ń kọ̀wé.

    40

    Iye àwọn ọkùnrin tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì.

  • Gíláàsì tó ń ṣàpẹẹrẹ ohun tí wọ́n fi ń díwọ̀n àkókò.

    1513 Ṣ.S.K.

    Ọdún tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ Bíbélì​—ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ (3,500) ọdún sẹ́yìn!

  • Àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ lóríṣiríṣi èdè.

    3,000+

    Iye èdè tí wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì sí lódindi tàbí lápá kan.

Ọlọ́run Fẹ́ Kó O Jàǹfààní Látinú Ọgbọ́n Òun

“Èmi, Jèhófà, ni . . . Ẹni tó ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tó ń jẹ́ kí o mọ ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn. Ká ní o fetí sí àwọn àṣẹ mi ni! Àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”​—ÀÌSÁYÀ 48:17, 18.

Ńṣe ni kó o wò ó pé ìwọ gangan ni Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ yìí fún. Ó fẹ́ kó o ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ayọ̀ tòótọ́, ó sì ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ káyé ẹ lè dùn.

O Lè Ní Ọgbọ́n Ọlọ́run

“A ní láti . . . wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo orílẹ̀-èdè.”​—MÁÀKÙ 13:10.

Lára “ìhìn rere” tí ẹsẹ̀ Bíbélì yìí ń sọ ni ìlérí tí Jèhófà ṣe pé òun máa fòpin sí ìyà tó ń jẹ aráyé, pé òun máa sọ ayé di Párádísè àti pé òun máa jí àwọn èèyàn wa tó ti kú dìde. Ìhìn rere tó wá látinú Bíbélì yìí ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀ kárí ayé.

Nígbà Tí Mo Ka Bíbélì, Kò Sóhun Tó Ń Rú Mi Lójú Mọ́

“Àti kékeré làwọn nǹkan kan ti máa ń rú mi lójú. Bí àpẹẹrẹ, mo máa ń bi ara mi pé, ‘Ta tiẹ̀ ni Ẹlẹ́dàá wa?’ ‘Ṣé orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ló ní ọlọ́run tàbí ẹlẹ́dàá tiẹ̀ ni?’ Torí náà, ohun tí Bíbélì sọ ní Róòmù 3:29 wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Ó sọ pé Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ ‘Ọlọ́run àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.’ Ó tún ní orúkọ tiẹ̀, Jèhófà lorúkọ ẹ̀, ó sì fẹ́ ká di ọ̀rẹ́ òun.”​—Rakesh.

Rakesh.
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́