ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g22 No. 1 ojú ìwé 10-12
  • 3 | Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Tẹbítọ̀rẹ́ Dáa Sí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 3 | Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Tẹbítọ̀rẹ́ Dáa Sí I
  • Jí!—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere Àtọ̀rẹ́ Búburú
    Jí!—2004
  • Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Bá A Ṣe Lè Rẹ́ni Bá Ṣọ̀rẹ́
    Jí!—2004
  • Bá A Ṣe Lè Máa Ṣe Ọ̀rẹ́ Nínú Ayé Aláìnífẹ̀ẹ́ Yìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—2022
g22 No. 1 ojú ìwé 10-12
Inú tọkọtaya àgbàlagbà kan ń dùn bí wọ́n ṣe dì mọ́ra wọn.

AYÉ DOJÚ RÚ

3 | Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Tẹbítọ̀rẹ́ Dáa Sí I

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Torí pé nǹkan túbọ̀ ń burú sí i láyé yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ti jẹ́ kíyẹn ṣàkóbá fún àjọṣe àwọn pẹ̀lú ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn.

  • Àwọn èèyàn kan máa ń fẹ́ dá wà.

  • Àwọn tọkọtaya kan ò nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, wọ́n sì ń hùwà àìdáa síra wọn.

  • Ọ̀pọ̀ àwọn òbí ò rí tàwọn ọmọ wọn rò, wọn ò sì kíyè sí bí nǹkan ṣe rí lára wọn.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀

  • Tó o bá ní ọ̀rẹ́ tó dúró tì ẹ́ nígbà ìṣòro, inú ẹ á dùn, ara ẹ á sì yá gágá.

  • Ìgbàkigbà ni nǹkan lè yí pa dà nínú ìdílé torí bí nǹkan ṣe ń nira sí i láyé yìí.

  • Àwọn ìròyìn burúkú tí wọ́n ń gbé jáde lójoojúmọ́ lè dẹ́rù ba àwọn ọmọ ẹ, ìyẹn sì lè má jẹ́ kọ́kàn wọn balẹ̀.

Ohun Tó O Lè Ṣe Ní Báyìí

Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń nífẹ̀ẹ́ ẹni nígbà gbogbo, ó sì jẹ́ ọmọ ìyá tí a bí fún ìgbà wàhálà.”​—Òwe 17:17.

Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́, wọ́n sì lè fún ẹ ní ìmọ̀ràn táá ṣe ẹ́ láǹfààní. Tó o bá ń rántí pé ẹnì kan wà tó nífẹ̀ẹ́ ẹ, tí ò sì fọ̀rọ̀ ẹ ṣeré, ìyẹn á fún ẹ lókun kó o lè máa fara da ìṣòro èyíkéyìí tó o bá kojú.

KÍ LỌ̀NÀ ÀBÁYỌ?​—Ohun Tó O Lè Ṣe

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí nǹkan ò rí bó ṣe yẹ kó rí nílùú, o lè jẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti tẹbítọ̀rẹ́ dáa sí i tó o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí

JẸ́ KÍ ÌFẸ́ ÀÁRÍN ÌWỌ ÀTI ỌKỌ TÀBÍ AYA RẸ LÁGBÁRA SÍ I

Inú tọkọtaya àgbàlagbà kan ń dùn bí wọ́n ṣe dì mọ́ra wọn.

Jẹ́ kí ìfẹ́ àárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ lágbára sí i

Bíbélì sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan lọ . . . Torí tí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé e dìde.” (Oníwàásù 4:9, 10) Ṣe ló yẹ kí tọkọtaya dà bí àwọn agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́ kan náà, tí wọ́n sì jọ ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí wọ́n lè borí, kò yẹ kí wọ́n dà bí àwọn agbábọ́ọ̀lù tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa ń ta ko ara wọn.

  • Ẹ pinnu pé ẹ ò ní máa kanra mọ́ ẹnì kejì yín torí àwọn ìṣòro tí ẹ̀ ń kojú. Ọ̀pọ̀ ìṣòro lẹ máa yẹra fún tẹ́ ẹ bá ń mú sùúrù fúnra yín tẹ́ ẹ sì ní àmójúkúrò.

  • Ó kéré tán lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tó yẹ kẹ́ ẹ wá nǹkan ṣe sí. Ẹ rántí pé ara yín kọ́ lẹ fẹ́ bá jà, ṣe lẹ fẹ́ pawọ́ pọ̀ yanjú ìṣòro náà.

  • Ẹ máa wáyè láti wà pa pọ̀, kẹ́ ẹ lè jọ ṣe àwọn nǹkan tẹ́ ẹ máa ń fẹ́ràn láti ṣe.

  • Ẹ máa ronú nípa àwọn àsìkò tẹ́ ẹ ti jọ gbádùn ara yín. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè jọ wo fọ́tò ọjọ́ ìgbéyàwó yín àbí tàwọn àsìkò alárinrin míì tẹ́ ẹ jọ gbádùn pa pọ̀.

“Tọkọtaya lè má ní èrò kan náà lórí ohun kan, àmọ́ ìyẹn ò ní kí wọ́n má fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Àwọn méjèèjì lè jọ ṣèpinnu, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ pa pọ̀ lórí ìpinnu náà kó lè kẹ́sẹ járí.”​—David.

MÁ FI ÀWỌN Ọ̀RẸ́ RẸ SÍLẸ̀

  • Àwọn obìnrin tó wá látinú ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jókòó pa pọ̀, inú wọn ń dùn, wọ́n sì ń rẹ́rìn-ín síra.

    Má fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sílẹ̀

    O lè máa retí pé káwọn ọ̀rẹ́ ẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́ nígbà ìṣòro, àmọ́ ó yẹ kíwọ náà ronú nípa ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Tó o bá ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́, inú ẹ á dùn, ara á sì tù ẹ́.

  • Máa wáyè láti béèrè àlàáfíà díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ ẹ lójoojúmọ́.

  • Ní káwọn ọ̀rẹ́ ẹ sọ ohun tí wọ́n ṣe nígbà táwọn náà ní irú ìṣòro tó o ní.

“Tí nǹkan bá nira tá ò sì mọ ọ̀nà àbáyọ, ọ̀rẹ́ wa lè fi wá lọ́kàn balẹ̀ kó sì jẹ́ ká mọ ohun tá a lè ṣe. Ó máa fún wa nímọ̀ràn, kódà ó lè rán wa létí àwọn ohun tá a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ kíyẹn sì fún wa lókun. Àwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń dúró tì wá nígbà ìṣòro, wọ́n sì mọ̀ pé àwa náà ò ní fi wọ́n sílẹ̀.”​—Nicole.

MÁA ṢE OHUN TÁÁ JẸ́ KÍ ARA TU ÀWỌN ỌMỌ RẸ

Àwọn òbí kan àtàwọn ọmọ wọn méjì jókòó sétí omi, wọ́n sì ń wo àwọn nǹkan àrà tó wà láyìíká wọn.

Máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ara tu àwọn ọmọ rẹ

Bíbélì sọ pé: Ó yẹ kó o ‘yára láti gbọ́rọ̀, kó o sì lọ́ra láti sọ̀rọ̀.’ (Jémíìsì 1:19) Ó lè má kọ́kọ́ rọrùn fáwọn ọmọ ẹ láti máa sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára wọn, àmọ́ tó o bá ń mú sùúrù fún wọn tó o sì ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, tó bá yá wọ́n á máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn.

  • Máa ṣe ohun táá jẹ́ kí ọkàn àwọn ọmọ ẹ balẹ̀ kí wọ́n lè máa bá ẹ sọ̀rọ̀ ní fàlàlà. Ó lè má yá àwọn ọmọdé lára láti bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ ní tààràtà, àmọ́ wọ́n sábà máa ń túra ká nígbà tára bá tù wọ́n, irú bí ìgbà tí wọ́n ń jẹun, ìgbà tí wọ́n jọ wà nínú mọ́tò àbí ìgbà tí wọ́n jọ ń rìn lọ síbì kan.

  • Rí i pé àwọn ọmọ ẹ ò kì í gbọ́ ìròyìn burúkú ní gbogbo ìgbà.

  • Jẹ́ káwọn ọmọ ẹ mọ àwọn nǹkan tó o ti ṣe láti dáàbò bo ìdílé yín.

  • Pinnu ohun tí wàá ṣe tí nǹkan kan bá ṣẹlẹ̀ lójijì, kó o sì fi dánra wò pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ.

“Máa bá àwọn ọmọ ẹ sọ̀rọ̀, kó o sì jẹ́ káwọn náà máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn ní fàlàlà. Nígbà míì inú lè máa bí wọn, ọkàn wọn sì lè má balẹ̀, àmọ́ kí wọ́n má jẹ́ kó o mọ̀. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ náà nìyẹn, kó o sì ṣàlàyé àwọn nǹkan tó o ṣe kára lè tù ẹ́.”​—Bethany.

Àwòrán apá kan látinú fídíò “Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀.” Inú tọkọtaya kan ń dùn bí wọ́n ṣe dira wọn lọ́wọ́ mú, tí wọ́n sì ń rìn gba ojú ọ̀nà kan.

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I. Wo fídíò náà Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́