APÁ 3
Láti Ìgbà Ìdáǹdè Kúrò ní Íjíbítì sí Àkókò Ọba Àkọ́kọ́ ní Ísírẹ́lì
Mósè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ìgbèkùn ní Íjíbítì wá sí Òkè Sínáì, níbi tí Ọlọ́run ti fún wọn ní àwọn òfin rẹ̀. Nígbà tó ṣe, Mósè rán ọkùnrin méjìlá láti lọ ṣe amí ilẹ̀ Kénáánì. Ṣùgbọ́n mẹ́wàá nínú wọn mú ìròyìn búburú padà wá. Wọ́n mú kí àwọn èèyàn náà fẹ́ láti padà lọ sí Íjíbítì. Nítorí àìní ìgbàgbọ́ wọn, Ọlọ́run jẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyà nípa mímú kí wọ́n máa rìn káàkiri fún ogójì [40] ọdún ní aginjù.
Níkẹyìn, Ọlọ́run yan Jóṣúà láti ṣe aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ ilẹ̀ Kénáánì. Láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè gba ilẹ̀ náà, Jèhófà mú kí àwọn iṣẹ́ ìyanu ṣẹlẹ̀. Ó mú kí Odò Jọ́dánì má ṣàn mọ́, ó mú kí odi Jẹ́ríkò wó lulẹ̀, ó sì mú kí oòrùn dúró sójú kan fún odindi ọjọ́ kan. Lẹ́yìn ọdún mẹ́fà, wọ́n gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ará Kénáánì.
Bá a bá bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jóṣúà, ọ̀ọ́dúnrún ó lé mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [356] ọdún làwọn onídàájọ́ fi ṣàkóso Ísírẹ́lì. A óò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀pọ̀ nínú wọn, títí kan Bárákì, Gídíónì, Jẹ́fútà, Sámúsìnì àti Sámúẹ́lì. A ó sì tún kà nípa àwọn obìnrin bíi Ráhábù, Dèbórà, Jáẹ́lì, Rúùtù, Náómì àti Dèlílà. Ní àkópọ̀, ìtàn irínwó ọdún ó dín mẹ́rin [396] ló wà ní Apá KẸTA.