ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 116
  • Bá A Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ayé Tuntun Ọlọ́run, Ayé Àlàáfíà—Ìwọ Lè Wà Níbẹ̀
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Báwo Lo Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Jèhófà Fẹ́ Ká Wà Láàyè Títí Láé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Máa Nímùúṣẹ
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 116
Àwọn ọmọ mẹ́ta ń ka ìwé ‘Ìtàn Bíbélì’

ÌTÀN 116

Bá A Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé

ṢÉ O lè sọ ìwé tí ọmọbìnrin kékeré yìí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ń kà? Bẹ́ẹ̀ ni, ìwé yìí gan-an tí ìwọ náà ń kà ni, ìyẹn, Ìwé Ìtàn Bíbélì. Wọ́n sì ń ka ìtàn tó ò ń kà lọ́wọ́ báyìí gan-an, ìyẹn, “Bá A Ṣe Lè Wà Láàyè Títí Láé.”

Ṣé o mọ ohun tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, pé a gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, Jésù, bá a bá fẹ́ wà láàyè títí láé. Bíbélì sọ pé: ‘Bó o ṣe lè wà láàyè títí láé nìyí. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ náà, àti Jésù Kristi ọmọ rẹ̀ tó rán wá sí ayé.’

Báwo la ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù ọmọ rẹ̀? Ọ̀nà kan ni nípa kíka Ìwé Ìtàn Bíbélì láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin. Ó sọ púpọ̀ nípa Jèhófà àti Jésù, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ó sì tún sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ohun tí wọ́n ti ṣe àtàwọn ohun tó ṣì kù tí wọ́n máa ṣe. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ ṣe ju kíka ìwé yìí lọ.

Ṣé o rí ìwé kejì tó wà nílẹ̀ níbẹ̀? Bíbélì ni ìwé yẹn. Jẹ́ kí ẹnì kan ka orí àti ẹsẹ Bíbélì tá a ti mú àwọn ìtàn yẹn fún ọ. Bíbélì fún wa ní ìsọfúnni tó kún tá à ń fẹ́ kí gbogbo wa bàa lè sin Jèhófà ní ọ̀nà tó tọ́ ká sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ sọ ọ́ dàṣà láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà gbogbo.

Ṣùgbọ́n ká kàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù nìkan kò tó o. A lè ní ìmọ̀ tó pọ̀ gan-an nípa wọn àti ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni, síbẹ̀ ká má jèrè ìyè àìnípẹ̀kun. Ǹjẹ́ o mọ ohun tó tún béèrè?

A tún gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí ìgbésí ayé wa bá àwọn ohun tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ mu. Ṣó o rántí Júdásì Ísíkáríótù? Ọ̀kan nínú àwọn méjìlá tí Jésù yàn láti jẹ́ àpọ́sítélì rẹ̀ ni. Júdásì ní ìmọ̀ púpọ̀ nípa Jèhófà àti Jésù. Ṣùgbọ́n kí ló ṣẹlẹ̀ sí i? Nígbà tó ṣe, ó di onímọtara-ẹni-nìkan, ó sì fi Jésù han àwọn ọ̀tà rẹ̀ torí ọgbọ̀n owó fàdákà. Nítorí náà, Júdásì kò ní rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà.

Ṣó o rántí Géhásì ọkùnrin tá a kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nínú Ìtàn 69? Ó fẹ́ láti ní àwọn aṣọ àti owó tí kì í ṣe tirẹ̀. Nítorí náà, ó parọ́ láti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí gbà. Ṣùgbọ́n Jèhófà jẹ ẹ́ níyà. Òun yóò sì jẹ wá níyà pẹ̀lú bí a kò bá pa òfin rẹ̀ mọ́.

Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ èèyàn rere ló wà tí wọ́n ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà nígbà gbogbo. A fẹ́ dà bíi wọn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àpẹẹrẹ rere kan tá a lè tẹ̀ lé ni Sámúẹ́lì tó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé. Ṣó o rántí, gẹ́gẹ́ bá a ti rí i nínú Ìtàn 55, ọmọ ọdún mẹ́rin tàbí márùn-ún péré ni nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn. Nítorí náà, kò sí bó o ṣe lè kéré tó, o ò kéré jù láti sin Jèhófà.

Ẹni náà tí gbogbo wa fẹ́ láti tẹ̀ lé ní Jésù Kristi. Kódà nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé, gẹ́gẹ́ bó ti wà nínú Ìtàn 87, ó wà níbẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì tó ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Jẹ́ ká sọ fún ọ̀pọ̀ èèyàn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó nípa Jèhófà Ọlọ́run wa àgbàyanu àti ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi. Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, nígbà náà, á ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè tuntun tí Ọlọ́run máa mú wá sórí ilẹ̀ ayé.

Jòhánù 17:3; Sáàmù 145:1-21.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́