APÁ 8
Ohun Tí Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Máa Nímùúṣẹ
Kì í ṣe ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ní ìgbà àtijọ́ nìkan ni Bíbélì sọ, ṣùgbọ́n ó tún sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la. Àwọn èèyàn ò le sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la. Ìdí rẹ̀ nìyí tá a fi mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá. Kí ni Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la?
Ó sọ́ nípa ogun ńlá Ọlọ́run. Nínú ogun yìí, Ọlọ́run á mú gbogbo ìwà búburú àtàwọn tó ń hùwa búburú kúrò, ṣùgbọ́n òun á dáàbò bo àwọn tó bá sìn ín. Jésù Kristi, Ọba tí Ọlọ́run yàn á rí sí i pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbádùn àlàáfíà àti ayọ̀ àti pé wọn ò tún ní máa ṣàìsàn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì ní máa kú.
Ó yẹ kí inú wa dùn pé Ọlọ́run á mú kí Párádísè tuntun kan wà lórí ilẹ̀ ayé, àbí? Ṣùgbọ́n bá a bá máa wà nínú Párádísè yìí, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan. Nínú ìtàn tó kẹ̀yìn nínú ìwé yìí la ti máa kẹ́kọ̀ọ́ ohun tá a máa ṣe ká bàa lè gbádùn àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ní nípamọ́ fáwọn tó ń sìn ín. Nítorí náà, ka APÁ KẸJỌ kó o sì mọ ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ fún ọjọ́ ọ̀la.