ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kc orí 1 ojú ìwé 4-13
  • “Kí Ijọba Rẹ Dé”!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Kí Ijọba Rẹ Dé”!
  • “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KI NI IJỌBA YẸN JẸ́?
  • OTITỌ-GIDI NAA LONII
  • ORÍSUN AYỌ̀ TOOTỌ
  • Ìjọba Ọlọrun Ń Ṣàkóso
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ìjọba Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2020
  • Ohun Ti Ijọba Ọlọrun Lè Tumọsi Fun Ọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
“Kí Ijọba Rẹ Dé”
kc orí 1 ojú ìwé 4-13

Ori 1

“Kí Ijọba Rẹ Dé”!

1. Kí ni Ijọba Ọlọrun yoo tumọsi fun ọ, bi ó bá mú awọn ipò tí a yàwòrán rẹ̀ níhìn-ín wá laipẹ?

IWỌNBA awọn ọ̀rọ̀ adura diẹ ni a ti sọ ní àsọtúnsọ nigba gbogbo ju ti oke yii lọ. Boya iwọ onkawe ti gba adura yii. Dajudaju awa ń fẹ́ Ijọba Ọlọrun! Bawo ni yoo ti tóbilọ́lá tó lati gbé labẹ awọn ipò tí a yaworan rẹ̀ si awọn oju-iwe yii! Eyi sì ni ireti naa tí Ijọba Ọlọrun nawọ́ rẹ̀ jade si wa: Alaafia ati iṣọkan ní gbogbo ilẹ̀-ayé. Awọn ẹya-iran araye tí a sopọṣọkan ninu ojulowo ìdè ifẹ. Olukuluku ń ní inudidun lati ṣe iṣẹ́ tí ń mú èso jade tí ó sì ń gbadun eso iṣẹ aṣekara rẹ̀. Afẹfẹ tí ó kún fun ohùn-orin iṣẹda ati orin ati ẹ̀rín awọn eniyan alayọ. Ẹgbẹ-awujọ araye onilera yíká ilẹ́-ayé ninu eyi tí ẹnikan kò darugbo tabi ṣaisan. Igbadun alaafia pẹlu awọn ẹranko, òórùn dídùn awọn òdòdó, ẹwà oju-ilẹ aláwọ̀ mèremère ati awọn ìgbà tí ń yipada nigba gbogbo. Bẹẹni, gbogbo eyi, ati pupọ sii, ni a ṣeleri fun ilẹ̀-ayé wa lẹhin tí Ijọba Ọlọrun bá dé, gẹgẹ bi awa yoo ti ríi.

2, 3. Awọn iyipada wo ní awọn ọdun lọwọlọwọ yii ni ó tẹnumọ aini naa fun Ijọba Ọlọrun?

2 Bi ó ti wù ki ó rí, awọn nǹkan yatọ gan-an nisinsinyi. Nitori pe awa ń la akoko naa kọja eyi tí Bibeli ṣapejuwe gẹgẹ bi eyi tí ó jẹ́ “ìgbà ewu.” (2 Timoteu 3:1) Iwọ mọ̀ bi awọn akoko oníyánpọnyánrin wọnyi ṣe kàn igbesi-aye iwọ funraarẹ tó. Ọpọ awọn tí yoo ka awọn oju-iwe wọnyi ti padanu awọn olólùfẹ́ wọn ninu awọn ogun ati ìwà-ipá miiran ní ọ̀rúndún yii. Sibẹ awọn orilẹ-ede ti kówọnú igbokegbodo eré-ìje ohun ija kikankikan ju ti igbakigba rí lọ. Ní bayii, wọn ti ní awọn ohun ija tí ó pọ̀ lápọ̀jù lọwọ lati mú iparun yán-án-yán-án iran eniyan wá.

3 Awọn iṣoro miiran, tí ó ń ṣẹlẹ layika ile, tún kàn wa pẹlu. Pẹlu ìlunijanilólè, ipaniyan ati ìfipá-banilòpọ̀ tí ń gasoke sii, pupọ ninu wa ríi pe ó lewu paapaa lati rìn ní òpópónà. Awa kò ha sì gbọ́ nipa ìkọ̀sílẹ̀ tí ń pọ̀ sii, awọn idile tí ń túká ati ìyapòkíì ju ti tẹlẹri? Ninu sanmani yii tí ó kún fun ìwà-àìníjàánu niti ibalopọ takọtabo ati ìjoògùnyó, ọpọlọpọ eniyan ni rírán awọn ọmọ wọn lọ si awọn ile-ẹkọ gbogbogboo ń kọlóminú. Bi iwọ bá ń gbé ní adugbo kan tabi ni orilẹ-ede nibi tí irúfẹ́ awọn iṣoro bẹẹ kò ì tíì yọjú, ó yẹ ki o kún fun ọpẹ́ nitootọ!

4, 5. (a) Awọn iṣoro miiran wo ni ó kàn igbesi-aye wa? (b) Awọn itẹsi wo ninu ayé ni ó fihan pe ó jẹ́ kanjukanju pe ‘kí ijọba Ọlọrun dé’?

4 Éèló ni ó ń ná ọ lati gbé ounjẹ kalẹ sori tabili rẹ ní awọn ọjọ wọnyi? Éèló ni ó sì ń ná ọ lati bojuto ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ? Bi owó ounjẹ ati ti epo mọto ti ń fosoke sii, ipò ayé tí ó ń mì yọ́gẹyọ̀gẹ ń ṣe kilọkilọ pe rẹ́rẹ́ fẹ́ rún ní ọjọ-iwaju. Nibo ni ayé wa forílé? Ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ kan ninu U.S.News & World Report ti August 4, 1980, tẹnumọ ijẹpataki yánpọnyánrin naa. Ó wi pe: “Ayafi bi a bá gbé awọn igbesẹ titun tí ó ṣe pataki, ayé, ní 20 ọdun sí akoko yii yoo jẹ́ planẹti ẹlẹgbín ati aláìdúrósójúkan pẹlu ọpọ billion òtòṣì eniyan tí ń jà kìràkìtà fun awọn ohun àmúsọrọ̀ tí ó gbówólórí tí ó sì ṣọ̀wọ́n. Ikilọ yẹn jade ní July 24 lati ọ̀dọ̀ igbimọ ijọba apapọ kan tí ń pari ẹkọ iwadii ọlọdun-mẹta kan.” Laaarin awọn nǹkan miiran, ẹkọ iwadii yii ṣipaya pe nigba tí yoo bá fi di ọdun 2000 àròpọ̀ iye eniyan ayé yoo dé 6.3 billion, pé​—⁠láì tíì mẹnukan ifosoke owó-ọjà⁠—​owó ounjẹ yoo di ìlọ́po-méjì, awọn aṣálẹ̀ yoo gbooro sii, awọn ẹgàn yoo sì pòórá, ati pe ó keretan idaji epo agbaye ni a ó ti fàgbẹ. Eyiini ni, bi eto-igbekalẹ isinsinyi yoo bá tilẹ laaja titi di igba naa!

5 Kí ni orilẹ-ede kọọkan, tabi Iparapọ Awọn Orilẹ-ede paapaa, ti ṣe nipa yánpọnyánrin yii? Lọwọlọwọ, iwọnba diẹ péré ni wọn ti ṣe. Gbogbo eyi fihan bi a ti nílò Ijọba Ọlọrun ní kanjukanju tó!

KI NI IJỌBA YẸN JẸ́?

6. Eeṣe tí ijakulẹ yoo fi tọ́ si wá bi Ijọba Ọlọrun bá wà ninu kìkì ọkàn-àyà awọn eniyan?

6 Ó ha wulẹ jẹ́ ipò kan tí a fi mọ sinu ọkàn-àyà awọn onigbagbọ bi? Lédè miiran, nigba tí a bá yí awọn eniyan tí ó pọ̀ tó lọ́kàn pada si isin Kristian, Ijọba Ọlọrun yoo ha ti wà nihin-in nigba naa bi? Awọn eniyan kan ti ronú lọna bẹẹ, tí wọn si tọkasi Luku 17:21 ninu Bibeli ti King James Version, tabi Authorized Version (lédè Gẹẹsi), eyi tí ó wi pe: “Ijọba Ọlọrun ń bẹ ninu yin.” Ṣugbọn bi ipari ero wọn bá tọ̀nà, Ijọba Ọlọrun tubọ ń lọ jinna sii ni. Eeṣe? Nitori pe ipindọgba iye awọn tí wọn fẹnujẹ́wọ́ pe wọn jẹ Kristian ní ifiwera pẹlu awọn tí ń bẹ ninu ayé lonii kò tó ìpín 25 ninu ọgọrun-un, ó sì ń dinku sii. Pẹlupẹlu, ọgọrọọrun lọna araadọta-ọkẹ awọn mẹmba ṣọọṣi wà tí ó jẹ́ pe o ṣọwọn ki wọn to wọnu ṣọọsi kan.

7, 8. Bawo ni àyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ ṣe ràn wa lọwọ lati dé ori itumọ tootọ nipa Luku 17:⁠21?

7 Ronu, pẹlu, nipa eyi: Ta ni Jesu ń bá sọrọ nigba tí ó wi pe, “Ijọba Ọlọrun ń bẹ ninu yin”? O jẹ si awọn Farisi alágàbàgebè ti Jesu lò ọ̀rọ̀ Ọlọrun lati ẹnu wolii Isaiah fun pe: “Ọkàn wọn jinna si mi.” (Matteu 15:​1, 8, AV; Isaiah 29:13) Bawo ni Ijọba naa ṣe lè wọ̀ inu awọn ọkàn-àyà líle wọnyẹn? Nigba naa, kí ni itumọ ọ̀rọ̀ Jesu? Ẹri atọnisọna kan ń bẹ ninu awọn itẹjade King James Version tí ó ní awọn alaye etí-ìwé. Nibẹ ni a ti pese kíkà miiran pe: “Ijọba Ọlọrun ń bẹ laaarin yin.” Eyi sì ni ọna tí ọpọlọpọ awọn itumọ Bibeli miiran, gẹgẹ bi Jerusalem Bible ti Katoliki ati The New English Bible, gbà sọ ọ pẹlu.

8 Nitori naa, Jesu nihin-in ń sọrọ nipa araarẹ̀, Ọba ti a yànsípò, gẹgẹ bi ẹni tí ó wà laaarin wọn. Niti gàsíkíá oun wà nibẹ laaarin wọn, gẹgẹ bi eniyan tootọ gidi kan. Eyi sì nilati mú un wá si ọkàn-àyà wa, pẹlu, pe Ijọba naa jẹ́ ijọba tootọ gidi kan, akoso tootọ kan, àní gẹgẹ bi Ọba rẹ̀ ti jẹ́ eniyan gidi kan.

OTITỌ-GIDI NAA LONII

9, 10. Kí ni ijọba tootọ gidi kan, bawo ni o ṣe le ṣe awọn ọmọ abẹ rẹ̀ ni anfaani?

9 Lonii, awọn ilẹ ọlọba diẹ ṣi ṣẹ́kù lori ilẹ̀-ayé yii. Ijọba tootọ gidi ni wọn, ti o ni ninu Norway, United Kingdom, Jordan ati Nepal, ki a mẹnukan diẹ ninu wọn. Ninu awọn wọnyi ni ọba (tabi ọbabìnrin) wà, pẹlu awọn alajumọ ṣakoso tí wọn ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi igbimọ aṣofin, ìgbìmọ̀ àpérò tabi ẹgbẹ alakoso miiran. Labẹ ẹgbẹ olùṣàkóso tí ó kere ní ifiwera yii, ni awọn ara-ilu ti ń báa lọ lati maa gbé igbesi-aye wọn ojoojumọ. Wọn jẹ́ awọn ọmọ abẹ ijọba naa.

10 Nibi tí ọba ati awọn alájùmọ̀ ṣakoso rẹ̀ bá ti ní aniyan jijinlẹ fun ire awọn eniyan, ijọba kan lè pese ọpọlọpọ anfaani. Ó rí bẹẹ ninu ijọba Solomoni igbaani, nigba tí awọn eniyan “pọ̀ gẹgẹ bi iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun ní ọpọlọpọ, wọn ń jẹ, wọn sì ń mu, wọn sì ń ṣe àríyá.”​—⁠1 Ọba 4:20; 10:1-⁠9.a

11. Ní awọn ọna wo ni Ijọba Ọlọrun gbà farajọra pẹlu awọn ijọba ori ilẹ̀-ayé?

11 Ǹjẹ́ otitọ naa pe Ijọba Ọlọrun ń ṣakoso lati ọrun ha mú ki ó dínkù ní jíjẹ́ tootọ-gidi bi? Họwu, bẹẹkọ! Lakọọkọ ná, ó ní ọba kan tí ó walaaye tí ó sì jẹ́ alaapọn. Oun ni ẹni ti Ọlọrun fúnraarẹ̀ yansipo, Jesu Kristi Oluwa, ẹni tí Bibeli wí nipa rẹ̀ pe: “Oun ni awọn [orilẹ-ede, NW] yoo ni ireti si.” (Romu 15:12) Gẹgẹ bi awọn akoso ori ilẹ̀-ayé, Ijọba ọrun naa ní ẹgbẹ oluṣakoso alápá pupọ kan. Bibeli fi eyi hàn pe ó jẹ́ apapọ iye awọn àjùmọ̀ jọba kan tí a diwọn, tí wọn ti fẹ̀rí ìwàtítọ́ wọn hàn si Ọlọrun gẹgẹ bi awọn ọkunrin ati obinrin lori ilẹ̀-ayé yii. Fun awọn wọnyi, ni Jesu wi pe: “Má bẹru, agbo kekere; nitori dídùn inu Baba yin ni lati fi ijọba fun yin.” (Luku 12:32; Ìfihàn 5:9, 10; 20:⁠4) Ijọba naa ní ọla-aṣẹ lati ọrun. Lati ibi àyè ìríran rẹ̀ tí ó wà lókèlókè ní ọrun, akoso Ijọba naa lè nà agbara aṣẹ rẹ̀ jade​—⁠nipasẹ ohun-àmúlò tí ó lagbara pupọpupọ ju ti redio tabi irin-iṣẹ amútànṣán àràmàǹdà jade​—⁠si ibikibi lori ilẹ̀-ayé.

12, 13. Ijọba Ọlọrun ní iru (a) awọn ofin, (b) ìṣètò fun idanilẹkọọ, (c) itolẹsẹẹsẹ ìlera wo?

12 Nipa ti awọn ofin ń kọ́? Bẹẹni, Ijọba Ọlọrun ń gbéṣẹ́ṣe nipasẹ awọn ofin​—⁠awọn ofin tí ó dara julọ, tí Ọlọrun ṣe fun ire eniyan. Iwọ lè kà nipa wọn ninu Bibeli. (Deuteronomi 6:​4-⁠9; Marku 12:​28-⁠31) Ijọba naa ha ní eto-igbekalẹ idanilẹkọọ kan bi? Dajudaju ó ní in! Nisinsinyi gan-an, itolẹsẹẹsẹ idanilẹkọọ rẹ̀ ń tẹsiwaju lati ran awọn eniyan olotìítọ́-inú lọwọ ní gbogbo orilẹ-ede ati awọn eniyan ati èdè, lati mura wọn silẹ fun ìyè àìnípẹ̀kun labẹ ìṣàkóso ododo Ijọba naa. Ninu orilẹ-ede yoowu tí iwọ lè maa gbé lori ilẹ̀-ayé, iwọ bi ẹnikan le mu araarẹ wà larọwọto fun ilana ẹkọ itọni yii.​—⁠Matteu 24:14; Ìfihàn 7:​9, 10; Isaiah 54:⁠13.

13 Ijọba naa ha ní itolẹsẹẹsẹ fun ilera bi? Ó ní eyi tí ó ṣeé múlò julọ ninu gbogbo itolẹsẹẹsẹ ilera​—⁠eyi tí a gbekari ẹbọ irapada Jesu Kristi Oluwa. Itolẹsẹẹsẹ yii yoo wẹ awọn eniyan mọ́ kuro ninu awọn òjòjò wọn ati ailera nipa ti ara, ki ọwọ́ wọn baa lè tẹ̀ ìyè ainipẹkun ninu ẹkunrẹrẹ ilera didara. (Isaiah 25:8; Johannu 10:10) Nigba tí ó wà lori ilẹ̀-ayé, Jesu ṣe ọpọ iṣẹ iyanu, tí ó fihan pe oun yoo ní aṣẹ ati agbara lati wo awọn alaisan sàn, ki ó lajú afọju, ki ó mú arọ láradá, àní ki ó tilẹ mú awọn òkú padabọ si ìyè. (Luku 7:​20-⁠23) Nigba tí itolẹsẹẹsẹ Ijọba yii ṣì jẹ́ ti ọjọ iwaju sibẹ, awọn wọnni tí ń kẹkọọ nipa rẹ̀ lonii ń kẹkọọ pẹlu lati gbé igbesi-aye ọ̀nà ìwàhíhù mímọ́ tónítóní, a sì ń mú wọn padabọsipo nisinsinyi gan-an sinu ilera didara tẹmi. Ireti wọn jẹ́ tootọ-gidi.​—⁠Isaiah 65:14; Romu 10:⁠11.

14. Nigba tí ó wà lori ilẹ̀-ayé, kí ni Jesu tẹnumọ ninu ìkọ́ni rẹ̀?

14 Nigba tí Jesu jẹ́ eniyan lori ilẹ̀ ayé, ó kọni ní ohun pupọ nipa Ijọba Ọlọrun ati, nitootọ, ó pèsè apẹẹrẹ àkọ́wò ti igbesi-aye labẹ iṣakoso rẹ̀. (Luku 4:43; Matteu 12:​22-⁠28) Ó kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nipa Ọlọrun, ki wọn baa lè fà sunmọ Ọlọrun ninu ipò ibatan ọmọkunrin pẹlu baba onifẹẹ kan. Ó pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó yekooro fun wọn lati lè kojú awọn ọran tí a ń bá pade ninu igbesi-aye pẹlu iyọrisirere.​—⁠Johannu 1:18; 14:⁠6.

ORÍSUN AYỌ̀ TOOTỌ

15. Eeṣe tí awọn eniyan ọjọ Jesu fi dabi wa lonii nínú nínílò itunu?

15 Adura naa pe ‘kí ijọba Ọlọrun dé’ jẹ́ apakan Iwaasu lori Oke, eyi tí Jesu ṣe lori oke tí ó dojukọ Òkun Galili. Awọn olùtẹ́tísílẹ̀ rẹ̀ ni awọn ọmọ-ẹhin tí ó yàn, papọ pẹlu ogunlọgọ awọn eniyan miiran. Awọn wọnyi ni a ti “jẹ kan eegun,” ti a si “túkáàkiri” lati ọwọ́ awọn eniyan onímọtara ẹni níkan. (Matteu 9:​36, NW) Ohun tí Jesu sọ mú itunu wá fun awọn olùgbọ́ rẹ̀, bẹẹ gẹgẹ ni awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì lè jẹ́ itunu fun awa naa lonii.

16. Awọn wo ni o ń rí ayọ tootọ, bawo sì ni?

16 Jesu bẹrẹ iwaasu rẹ̀ nipa titọkasi orisun ayọ tootọ. A ha lè rí eyi ninu ọrọ̀ ohun ìní ti ara, ninu eré-ìnàjú, ninu irusoke imọlara ati ìmóríyá bi? Bẹẹkọ, nitori pe Jesu fi itẹnumọ naa sori awọn nǹkan tẹmi. Ó fihan pe awọn eniyan tí wọn “tòṣì ni ẹmi” ati awọn “tí ebi ń pa ati tí oungbẹ ń gbẹ sipa ododo” ni yoo rí ayọ pipẹtiti ní isopọ pẹlu Ijọba Ọlọrun. (Matteu 5:​3, 6; Luku 8:​1, 4-⁠15) Iwọ ha ń mú irúfẹ́ ifẹ-ọkan tẹmi bẹẹ dàgbà bi?

17, 18. (a) Kí ni awa nilati ṣe lati di ẹni ti Ọlọrun tẹwọgba? (b) Bawo ni imudaniloju Jesu ninu Matteu 6:​26-⁠33 ṣe fà ọ mọra?

17 Bi oun ti ń bá iwaasu rẹ̀ lọ, Jesu mú un ṣe kedere pe, lati di ẹni ti Ọlọrun tẹwọgba, awa nilati kẹkọọ lati jẹ́ alafarawe Baba wa ọrun. Awa gbọdọ gbé awọn animọ rẹ̀ yọ ki a sì hùwà ní ibamu pẹlu awọn ọpa idiwọn rẹ̀. (Matteu 5:​43-⁠48; Efesu 5:​1, 2) Lati wù ú ijọsin wa kò gbọdọ jẹ́ ètò àṣà kan lasan tí a ń múṣe lẹẹkan tabi lẹẹmeji lọ́sẹ̀. Ó nilati jẹ́ ijọsin tí ó walaaye, tí ó kún fun akitiyan iṣẹ́, tí o ń jẹyọ ninu igbesi-aye wa ojoojumọ ati ninu aniyan wa onifẹẹ fun awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa.

18 Bi ó ti wù ki ó rí, bi awa bá fi awọn iniyelori tẹmi si ipò kìn-ní-ní ninu igbesi-aye wa, eyi ki yoo ha ṣamọna wa si jíjìyà àìní ninu awujọ oníwọra ati oniwa temi-nikan-ṣaa yii bi? Bẹẹkọ rárá! Bi awa bá ‘ń wá ijọba Ọlọrun ati ododo rẹ̀ lakọọkọ,’ nigba naa gbogbo ohun miiran tí ó pọndandan fun igbesi-aye ni a ó fi kún un fun wa. Jesu ṣalaye eyi daradara ninu Matteu 6:​26-⁠33, eyi tí ó yẹ ki o kà.

19, 20. (a) Eeṣe tí ó fi ṣe pataki lati mọ̀ ojú tí Ọlọrun fi ń wò ijọsin wa? (b) Bawo ni a ṣe lè ràn wa lọwọ lati fun Ijọba Ọlọrun ní ijẹpataki ninu igbesi-aye wa? (c) Eeṣe tí yoo fi ṣanfaani lati ṣe atunyẹwo “Adura Oluwa”?

19 Nigba naa, bawo ni awa yoo ṣe ‘wá ijọba naa lákọ̀ọ́kọ̀’? Ó ha tumọsi pe bi awa bá ‘ń lọ si ṣọọṣi tí awa yàn’ dajudaju awa yoo rí ibukun Ọlọrun bi? Tabi o ha beere pe ki awa ṣawari iru ijọsin tí Ọlọrun yàn fun wa bi? Ṣakiyesi ohun tí Jesu wi nipa eyi: “Kii ṣe gbogbo ẹni tí ń pè mi ní Oluwa, Oluwa, ni yoo wọle ijọba ọrun; bikoṣe ẹni tí ń ṣe ifẹ ti Baba mi tí ń bẹ ní ọrun.” Oun mú un ṣe kedere pe awọn kan tí wọn jẹ́wọ́ pe wọn ‘sọtẹlẹ ní orukọ rẹ̀ tí wọn sì ti ṣe ọpọ iṣẹ iyanu nla ní orukọ rẹ̀’ niti gàsíkíá ni yoo jẹ́ “oníṣẹ́ ẹṣẹ” ni oju-iwoye Ọlọrun. (Matteu 7:​21-⁠23; tún wò 7:13, 14 pẹlu.) Bawo ni awa ṣe lè mọ̀ daju oju tí Ọlọrun fi ń wò ijọsin wa? Kìkì nipa didi ojúlùmọ̀ daradara pẹlu ohun tí ó wà ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli.

20 Ayẹwo Bibeli yoo ràn wa lọwọ lati fun Ijọba Ọlọrun ní ijẹpataki tí ó tọ́ síi ninu igbesi-aye wa, ati lọna tí ó ṣe deedee pẹlu ipò olukuluku wa. Yoo ràn wa lọwọ lati bojúwo igbesi-aye lakọtun, ati lati mọriri ohun ti awọn ohun tí ó ṣe pataki julọ jẹ́. Nitori naa ẹ jẹ ki a jiroro apá tí ó kàn ninu Iwaasu Jesu lori Oke tí a mọ̀ si “Adura Oluwa.” (Matteu 6:​9-⁠13) Atunyẹwo Adura Àwòṣe yii yoo ràn wa lọwọ lati ní oju-iwoye tí ó tọ́ lori ohun tí Ọlọrun ń beere lọwọ wa bi awa yoo bá rí ayọ tootọ. Yoo sì tún fihan wa pe ẹṣin-ọrọ alayọ naa tí ń bẹ ninu Bibeli jẹ́ yíya orukọ Ọlọrun si mímọ́ nipasẹ Ijọba rẹ̀ lọwọ Jesu Kristi.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ayafi bi a bá fihàn pe omiran ni, gbogbo awọn ẹsẹ iwe mimọ ti a fayọ lapakan tabi lapapọ ninu iwe yii jẹ lati inu Bibeli Mimọ ni èdè Yoruba, itẹjade ti 1960, ni àkọtọ́ ti ode-oni.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

ARAYE HA NILO IJỌBA ỌLỌRUN BI?

“Bi ẹ̀rọ atọmiki oní mẹgatọn-kan bá bú gbàù sori New York City, yoo fẹrẹẹ pa 2.25 million eniyan lẹsẹkẹsẹ, ti 3.6 million miiran yoo sì farapa yánnayànna, . . . ni awujọ awọn oniṣegun ati onimọ ijinlẹ nipa ẹ̀rọ atọmiki wí lánàá. . . . Ìgbàgbọ́ wọn ni pe ayé yoo ní iriri irúfẹ́ ogun kan bẹẹ ki ọ̀rúndún yii tó pari ati pe yoo mú ki wíwà eniyan titilọ di alaiṣeeṣe.”​—⁠New York “Times,” September 27, 1980

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

ÌJÓÒÓTỌ́ IJỌBA ỌLỌRUN

ỌBA: Jesu, pẹlu ọla-aṣẹ lati ṣakoso fun 1,000 ọdun.

AWỌN ALAJUMỌṢAKOSO NÍ ỌRUN: Ni Ọlọrun yàn lati inu awọn ẹda eniyan olùṣòtítọ́.

ILẸ AKOSO RẸ̀: Ilẹ̀-ayé wa pẹlu paradise tí ó kárí ayé ni a o mú padabọ.

AWỌN ADUROṢINṢIN ỌMỌ ABẸ: Ọpọ billion, ti yoo ni ninu awọn oku tí a jí dide.

AWỌN OFIN: Ní a gbeka ori ododo Ọlọrun, olu ofin ti ifẹ.

ITOLẸSẸẸSẸ ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́: Ríran awọn eniyan gbogbo ẹya-iran lọwọ lati gbadun igbesi-aye alayọ nisinsinyi, ati mímúra wọn sílẹ̀ fun ìyè ainipẹkun ninu paradise ilẹ̀-ayé.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́