ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kc orí 14 ojú ìwé 127-140
  • Ọba Naa Jọba!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọba Naa Jọba!
  • “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • TITUMỌ ÀLÁ KAN
  • “AWỌN AKOKO TÍ A YÀNKALẸ̀ FUN AWỌN ORILẸ-EDE”
  • KI NI “JERUSALEMU” TUMỌSI?
  • “ÌTẸ̀MỌ́LẸ̀” NAA YOO TI PẸ́ TÓ?
  • IMUṢẸ ṢIṢE PATAKI JU
  • “IGBA MEJE” NAA​—⁠BAWO NI Ó TI GÙN TÓ?
  • ẸGBẸRUN ỌDUN NAA​—⁠NIGBA WO?
  • “IRAN YII”​—⁠ÈWO NI?
  • Ọdún 1914—Ọdún Pàtàkì Nínú Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Kí Ni Àwọn Ìtàn Inú Bíbélì Tó Tẹ̀ Léra Fi Hàn Nípa Ọdún 1914?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Títú Àdììtú Igi Ńlá Náà
    Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì
“Kí Ijọba Rẹ Dé”
kc orí 14 ojú ìwé 127-140

Ori 14

Ọba Naa Jọba!

1, 2. (a) Ìjẹ́pàtàkì titobiju wo ni ó wà fun ọdun naa 1914? (b) Bawo ni iwe irohin Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi) ṣe tọkasi 1914 ní ọpọlọpọ ọdun ṣaaju?

LAISI iyemeji, ọdun naa 1914 sami si iyipada pataki kan ninu àlámọ̀rí awọn orilẹ-ede ati ti araye. Ṣugbọn ó ṣe pataki pupọpupọ jù bi ọpọ julọ awọn opitan ti rò lọ. Ó jẹ́ akoko kan nigba tí awọn iṣẹlẹ amóríyágágá ṣẹlẹ tí ó nii ṣe pẹlu ‘dídé’ Ijọba Ọlọrun. Ọpọ ọdun ṣaaju, awọn akẹkọọ Bibeli olubikita ti ń fojusọna pẹlu iharagaga mímúná si ọdun yẹn. Lori ipilẹ wo?

2 Ọdun mẹrinlelọgbọn ṣaaju 1914, iwe-irohin naa Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence, ninu awọn itẹjade rẹ̀ ti December 1879 ati March 1880, tọkasi 1914 gẹgẹ bi ọdun kan tí a sami si ninu asọtẹlẹ Bibeli. Ọrọ-ẹkọ kan ninu itẹjade rẹ̀ ti June 1880 pè afiyesi si opin “Akoko awọn Keferi (Luku xxi. 24)” tí ń sunmọle. Bi ó tilẹ jẹ́ pe onkọwe naa ní akoko naa kò loye ní kíkún ohun tí awọn iṣẹlẹ tí yoo ṣẹlẹ yoo tumọsi, ó fihan lati inu itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ Bibeli pe akoko kan tí ó jẹ́ “igba meje,” tabi 2,520 ọdun, ti ijẹgaba awọn ijọba orilẹ-ede aláìgba Ọlọrun gbọ́, ti o bẹrẹ lati igba ti a kọkọ sọ Jerusalemu igbaani di ahoro, yoo dopin ní “A.D. 1914.” Oun wi pe: “Akoko gígùn ti 2520 ọdun ati . . . iriri kíkorò [ti awọn eniyan Ọlọrun] labẹ ijẹgaba ẹranko ẹhànnà naa, (iṣakoso eniyan, Dan. vii.) ni a ṣapejuwe rẹ̀ daradara ninu Dan. iv., nipasẹ ‘igba meje’ ti Nebukadnessari ati iriri rẹ̀ kíkorò laaarin awọn ẹranko-ìgbẹ́.” Nigba naa, ki ni “igba meje” naa?

TITUMỌ ÀLÁ KAN

3. Otitọ pataki wo ni a là lẹsẹẹsẹ ninu Danieli 4:⁠25?

3 Ori 4 iwe Danieli ninu Bibeli ṣapejuwe àlá alasọtẹlẹ kan tí ó pẹtẹrí. Ó ṣapejuwe pe “Ọga-ogo nii ṣe ori ní ijọba eniyan, oun a sì fi i fun ẹnikẹni tí ó wù ú.” (Danieli 4:25) Nebukadnessari, ọba Babiloni, ni o lá àlá naa ó sì rọ́ ọ fun wolii Danieli lati tumọ.

4-6. (a) Àlá wo ni Nebukadnessari lá? (b) Bawo ni Danieli ṣe tumọ rẹ̀? (c) Bawo ni ó ṣe ní imuṣẹ? (d) Nigba tí a mú un padabọsipo, ìjẹ́wọ́ wo ni Nebukadnessari ṣe?

4 Nebukadnessari ri igi gìrìwò kan ninu iran eyi ti o ṣee rí titi de ipẹkun ayé. Ó ń pese ounjẹ ati ibugbe fun gbogbogboo. Ṣugbọn “ẹni mímọ́” kan lati ọrun wá paṣẹ pe ki a ké igi naa lulẹ ki a sì fi irin ati idẹ de kùkùté rẹ̀, awọn mẹtali meji tí ó lagbara julọ ní akoko naa. “Igba meje” nilati rekọja ni akoko tí igi naa ba ṣì wà ní ipò ikalọwọko yii.

5 Ni titumọ iran alasọtẹlẹ yii, Danieli ṣalaye pe igi naa ninu ọlanla rẹ̀ duro fun Nebukadnessari. Oun ni a ó ‘ge lulẹ’ tabi rẹsilẹ. “Igba meje” yoo rekọja lákòókò tí Nebukadnessari yoo dabi ẹranko inu ìgbẹ́. Ṣugbọn gan-⁠an gẹgẹ bi a kò ti pa “igi” naa run patapata, bẹẹ gẹgẹ lẹhin “igba meje” naa a ó mú ọba naa padabọsipo.​—⁠Danieli 4:​19-27.

6 Eyi gan-⁠an ni ohun tí ó débá Nebukadnessari. A rẹ̀ ẹ́ silẹ, ó sì dabi ẹranko tí a mú kuro ní ibugbe eniyan, ó ń jẹ koriko. Dajudaju awọn “igba meje” wọnni jẹ́ ọdun meje, ní akoko tí Nebukadnessari ní ‘iriri kikoro rẹ̀ laaarin awọn ẹranko.’ Irun rẹ̀ gùn, bi ìyẹ́ idì, awọn èékánná rẹ̀ sì gùn ṣọbọlọ bi awọn èékánná ẹyẹ. Ṣugbọn nikẹhin ori rẹ̀ pé pada, a sì mú un padabọsipo si ipo-ọba rẹ̀. Nigba tí eyiini ṣẹlẹ, ó fi ìyìn ati ògo fun “Ọba ọrun” gẹgẹ bi Ẹni tí ń ṣakoso nitootọ ati ẹni tí “ijọba rẹ̀ jẹ́ lati irandiran.”​—⁠Danieli 4:​28-37.

7-9. (a) Ninu asọtẹlẹ wo ni Jesu ti tọkasi opin Akoko awọn Keferi? (b) Nitori naa awọn ibeere wo ni ó gbọdọ ṣe pataki gidi si wa?

7 Bi o ti wù ki ó rí, ki ni gbogbo eyi nii ṣe pẹlu ọdun 1914 ti Sanmani Tiwa?

“AWỌN AKOKO TÍ A YÀNKALẸ̀ FUN AWỌN ORILẸ-EDE”

8 Nigba tí ó ń ṣapejuwe ‘ami ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan’ ni Jesu Kristi wi pe:

“Awọn orilẹ-ede yoo sì tẹ̀ Jerusalemu mọ́lẹ̀, titi awọn akoko tí a yànkalẹ̀ fun awọn orilẹ-ede yoo fi kún.” (Luku 21:⁠24, NW)

“Awọn orilẹ-ede” tí Jesu tọkasi ni awọn orilẹ-ede tí kii ṣe Ju, tabi “awọn Keferi.” Itumọ Bibeli ti Yoruba tí a mọ̀ dunjú níhìn-⁠ín lò gbolohun-ọrọ naa “akoko awọn Keferi.” Nipa bayii, ọpọlọpọ ti ṣe kayefi pe, ‘Ki ni Akoko awọn Keferi? Sáà akoko wo ni Jesu nílọ́kàn? Nigba wo ni ó bẹrẹ, nigba wo ni yoo sì dopin?’

9 A ti ríi tẹlẹ pe asọtẹlẹ nla Jesu lori “ami” naa ní itumọ pataki gidi fun wa lonii. Nitori naa awa fẹ́ lati mọ̀, pẹlu, awọn idahun si awọn ibeere wọnyi.

KI NI “JERUSALEMU” TUMỌSI?

10-12. (a) Gẹgẹ bi ọmọwe kan ti wi, ki ni awọn iṣẹlẹ 29-70 C.E. ṣapẹẹrẹ? (b) Ṣugbọn ki ni itumọ titobiju tí “Jerusalemu” lè gbérù ninu Luku 21:24? (c) Bawo ni iwe agbedegbẹyọ olokiki kan ṣe ràn wa lọwọ ninu oju-iwoye yii? (d) Nipa bayii ki ni “Jerusalemu” duro fun?

10 Nigba tí ó ń sọrọ lori asọtẹlẹ Jesu, Ọjọgbọn A. T. Robertsona ṣàkíyèsí pe Jesu lò “iparun tẹmpili ati ti Jerusalemu eyi tí ó ṣẹlẹ ninu iran naa ní A.D. 70, pẹlu gẹgẹ bi ami fun wíwá rẹ̀ lẹẹkeji ati ti opin ayé tabi opin sanmani.” Nitori naa, a lè beere pe: Yatọ si ohun tí ó débá Jerusalemu ní 70 C.E., itumọ titobiju tabi eyi tí ó rìn jinna wo ni Jesu ti lè maa sopọ mọ́ “Jerusalemu” ninu Luku 21:⁠24?

11 Jesu ka Jerusalemu si olú-ìlú Israeli, nibi tí awọn ọba tí Jehofa fòróróyàn ní ìlà Dafidi jokoo “lori ìtẹ́ Oluwa,” tí wọn n ṣakoso gẹgẹ bi awọn ọba fun Jehofa Ọlọrun. Pẹlupẹlu, tẹmpili rẹ̀ jẹ́ ibi ikorijọ fun ijọsin tootọ fun gbogbo ilẹ̀-ayé. (1 Kronika 28:⁠5; 29:23; 2 Kronika 9:⁠8) Iwe gbedegbẹyọ Cyclopædia lati ọwọ M’Clintock ati Strong ṣalaye pe: “A ti sọ Jerusalemu di ibugbe ọlọ́lá ti gbogbo awọn ọba Israeli; ati Tẹmpili naa, tí a saba maa ń pè ní ‘ile Jehofa,’ lẹsẹkan naa jẹ ibugbe Ọba awọn ọba, olori patapata fun orilẹ-ede naa ti a ń dari lọna iṣakoso Ọlọrun, . . . nitootọ Jerusalemu kò ṣe pataki niti iṣelu: kii ṣe olú-ìlú ilẹ-ọba alagbara kan tí ó ń dari awọn ọ̀ràn orilẹ-ede miiran, ṣugbọn ó duro loke fiofio ninu awọn ifojusọna dídányanran tí Dafidi sọtẹlẹ nigba tí ó n kede igbagbọ rẹ̀ ninu dídé Messia kan [Orin Dafidi 2:⁠6; 110:⁠2.”​—⁠Idipọ IV, oju-iwe 838.

12 Otitọ naa pe awọn ọba ní ìlà Dafidi jokoo lori “ìtẹ́ ijọba Oluwa” tẹnumọ otitọ naa pe ijọba naa nitootọ jẹ́ ti Ọlọrun. Ijọba Israeli tí ìkòríta rẹ̀ wà ní Jerusalemu jẹ́ ijọba Ọlọrun lọna apẹẹrẹ. Nipa bayii “Jerusalemu” duro fun Ijọba Ọlọrun.

13, 14. Nigba wo ati bawo ni ‘ìtẹ̀mọ́lẹ̀’ ninu Luku 21:24 ṣe bẹrẹ?

13 Sọyèrántí, nisinsinyi, awọn ọ̀rọ̀ Jesu: “Awọn orilẹ-ede yoo sì tẹ̀ Jerusalemu mọ́lẹ̀, titi awọn akoko tí a ti yànkalẹ̀ fun awọn orilẹ-ede yoo fi kún.” (Luku 21:​24, NW) Nigba wo ni ‘ìtẹ̀mọ́lẹ̀’ naa bẹrẹ? Ní kedere, ó bẹrẹ tipẹtipẹ ṣaaju ki a tó bí Jesu ní Betlehemu, nitori pe awọn ọba eniyan ní ìlà Dafidi ti dẹkun tipẹtipẹ lati ṣakoso ní Jerusalemu. Ọba jíjẹ ní ìlà idile Dafidi wá sopin nigba tí Ọba Sedekiah di ẹni tí a mú kuro lori ìtẹ́ lati ọwọ́ awọn ara Babiloni akọluni labẹ Nebukadnessari.

14 Itan Bibeli tí ó peye sọ fun wa ohun tí ó ṣẹlẹ nitori iwa-buburu awọn eniyan naa ati ti Ọba Sedekiah. Ó wi pe: “Titi ibinu Oluwa fi ru si awọn eniyan rẹ̀, tí kò fi sí atunṣe, nitori naa ni ó ṣe mú ọba awọn ara Kaldea [Babiloni] wá bá wọn, ẹni tí ó fi idà pa awọn ọdọmọkunrin wọn . . . [Ọlọrun] fi gbogbo wọn lé [Nebukadnessari] lọwọ. Ati gbogbo ohun-eelo ile Ọlọrun, nla ati kekere, ati iṣura ile Oluwa ati iṣura ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀, gbogbo wọn ni ó mú wá si Babiloni. Ó danasun ile Ọlọrun otitọ naa ti ó sì wó odi Jerusalemu palẹ̀.” (2 Kronika 36:​11, 12, 16-20) Nibẹ ni ‘ìtẹ̀mọ́lẹ̀’ naa ti bẹrẹ.

“ÌTẸ̀MỌ́LẸ̀” NAA YOO TI PẸ́ TÓ?

15-17. (a) Ta ni ó padanu “ẹ̀tọ́ lọna ofin” si ijọba Dafidi, bawo sì ni? (b) Ta ni yoo tún jèrè ẹ̀tọ́ naa pada, bawo ni yoo sì ti pẹ́ tó? (c) Nitori naa ibeere tí ó baamu gẹ́ẹ́ wo ni ó dide? (d) Eeṣe tí yoo fi jẹ́ ohun yiyẹ fun Danieli lati dahun ibeere yii?

15 Wolii Esekieli sọtẹlẹ nipa ìrọ̀lóyè Sedekiah, eyi tí ó kẹhin ninu awọn ọba tí ńjẹ ní ìlà Dafidi tí ó ṣakoso lati Jerusalemu ti ilẹ̀-ayé, ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi:

“Bayi ni Oluwa Ọlọrun wí; Mu fila ọba kuro, sì ṣi ade kuro; eyi ko ni jẹ́ ọ̀kan naa. . . . Emi o bì ṣubu, emi o bì ṣubu, emi o bì í ṣubu, kì yoo si sí mọ́, titi igba ti ẹni ti o ni i [“ni ẹ̀tọ́ lọna ofin,” NW] ba dé; emi o si fi fun un.”​—⁠Esekieli 21:​26, 27.

16 Bi ó tilẹ jẹ́ pe Ọba Sedekiah padanu “ẹ̀tọ́ lọna ofin” si ijọba Dafidi nigba naa, Messia tí a ṣeleri naa yoo jèrè “ẹ̀tọ́” yẹn yoo sì ṣakoso ninu Ijọba Ọlọrun “titilae.” (Luku 1:​32, 33) Ṣugbọn bawo ni yoo ti pẹ́ tó ki Ijọba Messia naa​—⁠eyi tí a ti fi ijọba Israeli ilẹ̀-ayé pẹlu olú-ìlú rẹ̀ ní Jerusalemu ṣapẹẹrẹ​—⁠tó bẹrẹsii ṣakoso?

17 Jehofa Ọlọrun mọ̀, ó sì lè fi sáà akoko naa hàn ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀, gan-⁠an gẹgẹ bi ó ti sọ asọtẹlẹ ọpọlọpọ awọn ohun ọjọ-iwaju miiran. Ninu àwíyé rẹ̀ lori ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan,’ Jesu lọpọ igba tọkasi asọtẹlẹ Danieli, ninu eyi tí Ọlọrun ti fi àìtàsé sọ asọtẹlẹ ọpọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ ní ọrun ati ní ayé. (Fi Matteu 24:​3, 15, 21, 30 wera pẹlu Danieli 9:27; 11:31; 12:⁠1; 7:13.) Pẹlupẹlu, asọtẹlẹ “aadọrin ọsẹ,” ninu Danieli 9:​24-27, kò ha ti pese iṣiro akoko pipeye fun wíwá Messia lakọọkọ bi? Ko ha ni baamu fun wolii kan-naa lati pese akoko fun wíwá Messia lẹẹkeji bi? O jẹ ninu ori kẹrin iwe Danieli ni a ti rí isọfunni alasọtẹlẹ yii tí ó kàn wa ní taarata.

IMUṢẸ ṢIṢE PATAKI JU

18. (a) Eeṣe tí ó fi lè jẹ́ pe itan ayé kùnà lati mẹnukan án pe Nebukadnessari ya wèrè? (b) Eeṣe tí ó fi yẹ ki a kọbiara sí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ níhìn-⁠ín?

18 Awa ti ṣayẹwo ṣaaju nipa imuṣẹ asọtẹlẹ Danieli ti “igba meje” naa lọna iṣapẹẹrẹ, a sì ti ṣakiyesi pe ó nii ṣe pẹlu ọdun meje gidi tí Nebukadnessari fi yà wèrè. Otitọ naa pe itan ayé kò pese akọsilẹ kúlẹ̀kúlẹ̀ nipa aisi lori ìtẹ́ Nebukadnessari fun ọdun meje kò gbọdọ yanilẹnu. Awọn akọsilẹ igbaani ti Egipti, Asiria, ati ti Babiloni ní òkìkí buburu fun imukuro ohunkohun tí ó lè dojuti alakooso wọn, eyi tí ó jẹ́ idi kan tí wọn kò fi ṣeé fọkàntẹ̀ bi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a misi. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ó mú un dá wa lójú pe a mú iran àlá naa ṣẹ. Ede asọtẹlẹ naa pẹlu tún fihan pe imuṣẹ tí ó tún gbooro jù eyiini lọ yoo wà, eyiini pẹlu si ti ṣẹlẹ. Lọna wo?

19. Eeṣe, lọna ti o bọgbọnmu, tí iran yii yoo fi ràn wa lọwọ lati pinnu gígùn Akoko awọn Keferi?

19 A nilati fi i sọ́kàn pe àlá naa ni a fifun ọba Babiloni, oluṣakoso ayé naa gan-⁠an tí ó ṣeranwọ ni bíbi ijọba Ọlọrun lọna iṣapẹẹrẹ lori ilẹ̀-ayé ṣubu, ti o si tipa bayii gbe ijẹgaba iṣakoso Keferi lori ayé kalẹ. Pẹlupẹlu, iran naa dajudaju ni a funni ni awọn ọdun diẹ lẹhin tí iyipada mánigbàgbé yii ṣẹlẹ​—⁠nigba tí a mu opin bá ijọba iṣapẹẹrẹ naa nipasẹ eyi tí Jehofa ń gba lò ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀. Siwaju sii, Danieli ori 4 tẹnumọ ẹṣin-ọrọ naa leralera ‘pé Ọga-ogo ni Oluṣakoso ninu ijọba araye, oun a sì fi fun ẹni tí ó wù ú.’ (Danieli 4:​17, 26, 34, 35) Nipa bayii awa ní idi rere lati yíjúsí iran yii fun isọfunni lori gígùn akoko ijẹgaba Keferi lori ayé.

20. Ibeere wo ni a beere, nibo ni a sì lè yíjúsí fun idahun?

20 Bi a bá kà á lati akoko naa tí ijọba Ọlọrun lọna iṣapẹẹrẹ, pẹlu ọba rẹ̀ tí ó wá lati ìlà idile Dafidi, di eyi tí a bìṣubú, bawo ni yoo ti pẹ́ tó kí Ọlọrun lẹẹkan sii tó tún lo ipò ọba-aláṣẹ rẹ̀ nipasẹ ijọba kan tí ó kan ìlà idile ọlọ́ba ti Dafidi, pẹlu Messia gẹgẹ bi ọba tí ń ṣakoso? Danieli ori 4 pese ipilẹ kan fun pipinnu gígùn Akoko awọn Keferi tabi “akoko tí a ti yànkalẹ̀ fun awọn orilẹ-ede,” ninu eyi tí awọn orilẹ-ede wọnni yoo tẹ̀ “Jerusalemu,” tabi Ijọba Ọlọrun mọ́lẹ̀.​—⁠Luku 21:24.

21. Ki ni Danieli 4:​15-17 ati Jobu 14:7 tọkasi niti ipò tí ó tẹle ìrọ̀lóyè Sedekiah?

21 A bẹrẹ kika ìtẹ̀mọ́lẹ̀ yii lati ọdun tí Nebukadnessari mú Ọba Sedekiah kuro lori ìtẹ́ ní Jerusalemu. Lati igba naa lọ, lílò tí Jehofa ń lò ipò ọba-aláṣẹ gẹgẹ bi a ti ṣapẹẹrẹ rẹ̀ ninu awọn ìlà ọba ti Juda ni a ‘gé lulẹ.’ Ó wà labẹ ikalọwọko, gẹgẹ bi kùkùté igi inu àlá Nebukadnessari tí a fi irin dè. Awọn agbara ayé Keferi oníwà-bí-ẹranko ṣakoso lori gbogbo ayé. Ṣugbọn ireti ń bẹ fun “igi” naa, pe yoo “tún sọ” lẹẹkan sii. Nigba naa awọn eniyan tí ń bẹ láàyè yoo “mọ̀ pe Ọga-ogo ni ó ń ṣe olori ní ijọba eniyan.”​—⁠Danieli 4:​15-17; Jobu 14:⁠7; fiwe Isaiah 11:​1, 2; 53:⁠2.

22. Nigba wo ati lọna wo ni “igi” Ijọba naa ṣe rúwé lẹẹkan sii?

22 Ninu Ijọba tí a mú padabọsipo yii, Ọga-ogo ni ń ṣakoso nipasẹ Messia rẹ̀. Bẹẹkọ, kii ṣe nigba tí Ẹni yẹn kọ́kọ́ farahan gẹgẹ bi eniyan pípé kan lori ilẹ̀-ayé, nigba tí awọn Ju tẹ́ḿbẹ́lú rẹ̀ tí wọn sì kọ̀ ọ́ silẹ gẹgẹ bi ọba. Ṣugbọn awọn ìdè tí ń bẹ lara kùkùté igi naa ni a túsílẹ̀, “igi” Ijọba naa sì rúwé lẹẹkan sii, nigba tí “onirẹlẹ julọ” ninu araye yii dé ninu ògo rẹ̀ gẹgẹ bi Ọba ọrun fun eniyan gbogbo orilẹ-ede. Nigba naa, bi Akoko awọn Keferi ti dopin, ijọba ayé wa di ti “ijọba Oluwa wa ati ti Kristi rẹ̀.”​—⁠Ìfihàn 11:15; Danieli 4:​17, 25.

“IGBA MEJE” NAA​—⁠BAWO NI Ó TI GÙN TÓ?

23. Eeṣe tí Akoko awọn Keferi fi nilati nasẹ̀ dé ọjọ wa?

23 Dajudaju, nigba naa, “igba meje” naa gẹgẹ bi a ti lò ó fun Akoko awọn Keferi nilati gùn gan-⁠an pupọpupọ jù ọdun meje lasan lọ. Ranti pe, Jesu sọrọ nipa ‘imuṣẹ’ tabi opin Akoko awọn Keferi wọnyi ní isopọ pẹlu ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan.’ (Luku 21:​7, 24; Matteu 24:⁠3) Nitori naa wọn nilati nasẹ̀ dé ọjọ wa. Bawo ni wọn tilẹ ti gùn tó gan-⁠an?

24. Bawo ni a ṣe lè tumọ gígùn “igba meje” naa?

24 Bi a bá yíjúsí Ìfihàn ori 12, awa yoo kiyesi pe ẹsẹ 6 ati 14 fi sáà 1,260 ọjọ hàn pe ó jẹ́ ‘akoko kan ati awọn akoko ati idaji akoko,’ tabi 1 + 2 + 1/2 tí ó jẹ́ aropọ 3 1/2 akoko. Nitori naa, “akoko kan” yoo jẹ́ 360 ọdun, tabi oṣu oṣupa 12 tí ọkọọkan rẹ̀ jẹ́ 30 ọjọ ní ipindọgba. “Igba meje” yoo jẹ́ 2,520 ọjọ; iṣiro Bibeli lọna asọtẹlẹ ti “ọjọ kan fun ọdun kan, ọjọ kan fun ọdun kan,” sì fihan pe awọn wọnyi nitootọ yoo jásí 2,520 ọdun inu kalẹnda. (Numeri 14:34; Esekieli 4:⁠6) Nitori naa, eyi ni gígùn “igba meje” naa​—⁠Akoko awọn Keferi.

25. Bawo ni “aadọrin ọsẹ” ninu Jeremiah 25:11 ṣe ṣeranwọ ní pipinnu ibẹrẹ Akoko awọn Keferi?

25 A ràn wa lọwọ lati mọ akoko naa gan-⁠an fun ibẹrẹ Akoko awọn Keferi nipa ṣiṣayẹwo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Gẹgẹ bi a ti ṣakiyesi tẹlẹ, Jehofa fi àyè gba awọn ara Babiloni lati ṣẹgun awọn eniyan rẹ̀, lati pa Jerusalemu ati tẹmpili rẹ̀ run, lati mú Sedekiah kuro lori “ìtẹ́ ijọba Oluwa” ki wọn sì kó awọn Ju lọ si igbekun Babiloni. (1 Kronika 28:⁠5) Awọn iṣẹlẹ tí ó tẹle e “ní oṣu keje” mú ki awọn Ju diẹ tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ naa sálọ si Egipti, tí ó fi jẹ́ pe Juda nigba naa di ahoro patapata. (2 Ọba 25:​1-26; Jeremiah 39:​1-10; 41:​1–43:⁠7) Jeremiah wolii Jehofa ti sọtẹlẹ pe isọdahoro naa yoo jẹ́ fun 70 ọdun. (Jeremiah 25:​8-11) Lẹhin naa ni Jehofa yoo ‘ranti aiṣedeedee ọba Babiloni’ tí yoo sì ‘mú awọn eniyan Rẹ̀ pada wá sí ibi yii,’ ilẹ-ibilẹ wọn.​—⁠Jeremiah 25:12; 29:⁠10.

26. (a) Ki ni Danieli ṣe ẹlẹ́rìí olùfojúrí rẹ̀, ki ni ó si loye? (b) Bawo ni a ṣe lè mọ̀ oṣu ati ọdun tí asọtẹlẹ Danieli nipa imupadabọsipo ní imuṣẹ? (c) Ni pàtó, igba wo ni akoko yẹn?

26 Danieli fúnraarẹ̀ wà ní oko-ẹrú Babiloni fun ọpọ ọdun. Ní òru ọjọ tí Babiloni ṣubu sọ́wọ́ awọn ara Media ati Persia, oun jẹ́ ẹlẹ́rìí olufojuri si imuṣẹ asọtẹlẹ oun fúnraarẹ̀, ati ti awọn asọtẹlẹ miiran, tí a sọ lodisi ilu-nla naa. (Danieli 5:​17, 25-30; Isaiah 45:​1, 2) Awọn opitan ṣírò rẹ̀ pe Babiloni ṣubu ní ibẹrẹ October ọdun 539 B.C.E. Laipẹ laijinna lẹhin naa, Danieli loye lati inu asọtẹlẹ Jeremiah pe ìkólẹ́rú ati isọdahoro Jerusalemu ti 70 ọdun naa ti fẹrẹẹ dopin. (Danieli 9:⁠2) Ó sì tọna! Ní ọdun akọkọ Kirusi ara Persia, tí pupọ julọ ninu awọn opitan sọ pe ó bẹrẹ lati igba iruwe 538 B.C.E, Kirusi paṣẹ kan tí ó yọnda fun awọn Ju lati pada si ilẹ-ibilẹ wọn lati tún fi olugbe kún inu rẹ̀ lẹẹkan sii ati lati ṣe àtúnkọ́ tẹmpili Jehofa nibẹ. (2 Kronika 36:​20-23; Esra 1:​1-5) Irohin ọlọ́rọ̀-ìtàn tí a misi naa sọ fun wa pe awọn Ju fi pẹlu imuratan dahunpada si aṣẹ Kirusi, tobẹẹ gẹ́ẹ́ tí ó fi jẹ́ pe “nigba tí oṣu keje sì pé, awọn ọmọ Israeli [ti] wà ninu ilu wọn.” (Esra 3:⁠1) Ninu kalẹnda wa eyiini yoo jẹ́ October, 537 B.C.E., ọdun naa gan-⁠an tí ó sami si opin 70 ọdun isọdahoro tí a sọtẹlẹ.

27. (a) Nigba naa, nigba wo ni 70 ọdun naa ti gbọdọ bẹrẹ, pẹlu iṣẹlẹ wo sì ni? (b) Bawo ni “igba meje” naa ti gùn tó, nitori naa nigba wo ni wọn sì gbọdọ ti dopin? (c) Asọtẹlẹ nla miiran wo ni ó bẹrẹsi ní imuṣẹ ní akoko yẹn gan-⁠an? (d) Isọfunni wo ni Ilé-Ìṣọ́nà ti ń ṣe akọgun rẹ̀ fun 100 ọdun ati jù bẹẹ lọ?

27 Isọfunni ọlọ́rọ̀-ìtàn yẹn ṣe pataki fun wa ní pipinnu ibẹrẹ ‘awọn akoko tí a ti yànkalẹ̀ fun awọn orilẹ-ede.’ Niwọn bi 70 ọdun isọdahoro Juda ati Jerusalemu ti dopin ní 537 B.C.E., wọn bẹrẹ ní 607 B.C.E. Eyiini yoo jẹ́ ọdun tí Sedekiah dẹ́kun jijokoo sori “ìtẹ́ ijọba Oluwa” ní Jerusalemu. Nitori naa ó tún sami si akoko naa fun ibẹrẹ Akoko awọn Keferi. Bi a bá kà á lati October 607 B.C.E., “igba meje” ti 2,520 ọdun yoo mú wa wá si ibẹrẹ October 1914 C.E., nigba tí, gẹgẹ bi a ti ríi tẹlẹ, asọtẹlẹ nla ti Jesu nipa ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan’ bẹrẹsii ní imuṣẹ. Isọfunni tí ó ṣeé fọkàntẹ̀ ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ni ipilẹ fun ipari ero yii, eyi tí iwe-irohin Ilé-Ìṣọ́nà ń ṣe akọgun rẹ̀ nisinsinyi fun eyi tí ó lé ní 100 ọdun.

28, 29. (a) Ki ni ohun naa nipa awọn akọsilẹ ayé tí ó gbọdọ mú wa ṣọpẹ́ fun kúlẹ̀kúlẹ̀ tí a tọ́jú pamọ́ sinu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun? (b) Eeṣe tí idi tí ó lagbara fi wà fun yíyan October 1914 jù awọn ọjọ miiran lọ fun opin Akoko awọn Keferi?

28 Dajudaju ó yẹ ki a kún fun ọpẹ́ pe Jehofa ti tọju aworan pipeye kan nipa awọn kulẹkulẹ otitọ ti a nilo nipa awọn Ju, awọn ara Babiloni ati awọn ara Media ati Persia ní ọ̀rúndún kẹfa B.C.E. sinu Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti a misi. Bi bẹẹ kọ́, ìbá ṣoro lati ṣe akopọmọra awọn akoko gan-⁠an fun awọn iṣẹlẹ igba atijọ wọnni, nitori pe awọn akọsilẹ ti ayé igba naa kò pé rárá.

29 Bi o ti wu ki o ri, ni gbigbe iṣiro wọn kà ori irufẹ akọsilẹ ayé bẹẹ nikanṣoṣo, awọn kan ronu pe a pa Jerusalemu run ní 587 si 586 B.C.E ati pe awọn Ju bọ́ sabẹ ijẹgaba Babiloni ní ọdun tí Nebukadnessari gùn ori ìtẹ́, eyi tí wọn ṣírò pe ó jẹ́ 605 B.C.E.b Nipa bayii wọn dì 605 B.C.E mú gẹgẹ bi ọdun naa tí Jeremiah 25:11 bẹrẹsi ní imuṣẹ: “Gbogbo ilẹ naa yoo sì di ahoro; wọn yoo sì sìn laaarin awọn Keferi fun aadọrin ọdun.” (Greek Septuagint ti Bagster) Bi eyiini bá rí bẹẹ tí a sì bẹrẹ sii kà Akoko awọn Keferi lati igba naa, yoo fi opin “igba meje” alasọtẹlẹ naa saaarin ọdun Ogun Agbaye ti 1916. Sibẹ, gẹgẹ bi a ti wí, a gbagbọ pe idi tí ó lagbara pupọ jù wà fun titẹwọgba isọfunni tí ó wà ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mísí, eyi tí ó tọkasi Akoko awọn Keferi tí ó bẹrẹ ní October 607 B.C.E. tí ó sì pari ní October 1914 C.E.

30. Awọn iṣẹlẹ tí wọn parapọ wo ni wọn sami si akoko naa lati 1914 gẹgẹ bi “awọn ọjọ ikẹhin”?

30 Awa lè layọ pe tipẹtipẹ ni Ọlọrun ti ṣe akọsilẹ ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀ awọn asọtẹlẹ tí ó funni ní akoko tí ó ṣe kedere tí Jesu yoo dé gẹgẹ bi Messia ní 29 C.E., ati ti “wíwàníhìn-ín” rẹ̀ gẹgẹ bi Ọba ọrun ológo lati 1914 C.E. Nisinsinyi tí ‘ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan’ ti ń lọ si ipari rẹ̀, awa ń rí awọn ipò tí Jesu sọ fun wa lati maa wọ̀nà fun tí wọn tubọ ń gbónájanjan sii ní ayika wa. Awọn ogun agbaye, ìyàn, ajakalẹ-arun, ìsẹ̀lẹ̀, ìwà-àìlófin, ainifẹẹ, ikoriira ati ṣiṣe inunibini si awọn tí wọn duroṣinṣin tì awọn ilana-ipilẹ Bibeli​—⁠gbogbo iwọnyi lapapọ ti ràn wa lọwọ lati dá “awọn ọjọ ikẹhin” mọ̀yàtọ̀.​—⁠2 Timoteu 3:⁠1; Matteu 24:​3-12; Marku 13:​7-13.

ẸGBẸRUN ỌDUN NAA​—⁠NIGBA WO?

31. (a) Imọran wo ni Jesu pese fun ọjọ wa, eesitiṣe? (b) Ibeere wo ni a lè ní ìtẹ̀sí lati beere, kí sì ni èsì Jehofa?

31 Bawo ni ipò bibanilẹru yii yoo ti wà pẹ́ tó? Pẹlu Kristi Jesu tí a gbé gùn ori ìtẹ́ nisinsinyi gẹgẹ bi Ọba-Ajagun, idi rere wà lati gbagbọ pe kò ní pẹ́ mọ́ ki ó tó mú idajọ ṣẹ sori awọn ọ̀tá Ọlọrun. “Niti ọjọ ati wakati naa, kò sí ẹnikan tí ó mọ̀ ọ́n,” nitori pe a ki yoo jèrè ohunkohun nipa míméfò. Sibẹsibẹ, a gbọdọ ṣe igbọran si imọran Jesu naa: “Ẹ maa ṣọ́nà.” (Marku 13:32; Matteu 24:42) Bi a ti ń rí awọn ipò ayé tí ń buru sii tí a sì ń ní iriri bi awọn eniyan ní gbogbogboo ti ń ṣaibikita si ihinrere Ijọba naa, a lè ní ìtẹ̀sí lati beere, gẹgẹ bi wolii Ọlọrun kan ti ṣe, nipa iwaasu wa pe: ‘Bawo ni yoo ti pẹ́ tó, Óò Jehofa?’ Sí eyi tí Jehofa fèsì pe:

“Titi awọn ilu-nla yoo fi di ahoro, ní aisi olugbe, ati awọn ile ni aisi eniyan, ati ilẹ yoo di ahoro patapata.” (Isaiah 6:​10-12)

Ní akoko tí ó ti yàn, Jehofa yoo mú idajọ rẹ̀ ṣẹ, lakọọkọ sori Kristẹndọm ati lẹhin naa sori gbogbo apá ayé Satani yoku. Iṣakoso ẹlẹgbẹrun ọdun alalaafia ti Kristi yoo si tẹle e lẹsẹkẹsẹ.​—⁠Ìfihàn 20:​1-3, 6.

“IRAN YII”​—⁠ÈWO NI?

32. Ibeere wo ni ó dide lójú ohun tí ó wà ninu Matteu 24:34?

32 Ninu asọtẹlẹ nla rẹ̀ nipa “ami” naa, Jesu mú un dá wa lójú pe: “Loootọ ni mo wí fun yin, iran yii ki yoo rekọja, titi gbogbo nǹkan wọnyi yoo fi ṣẹ.” (Matteu 24:34) Niwọn bi oun kò ti lò gígùn akoko kan pàtó fun iran kan, ki ni a nilati loye rẹ̀ nipa “iran yii”?

33. (a) Ki ni “iran” akoko Jesu? (b) Lọna tí ó ṣerẹ́gí, ki ni a lè wí nipa “iran” 1914 si 1918?

33 Ní ọjọ Jesu, diẹ lara awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tí wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ati awọn miiran tí wọn jẹ́ ojúgbà rẹ̀, laaja lati walaaye rekọja “ipọnju” ikẹhin lori eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Ju. Awọn ni “iran” akoko Jesu. Ní akoko tí a ń kọ iwe yii, ní United States nikan ó jù 10,000,000 awọn eniyan tí wọn ṣì walaaye tí wọn dagba tó lati kíyèsí “ipilẹṣẹ ipọnju” ní 1914 si 1918. Diẹ lara awọn wọnyi ṣì lè là ọpọ ọdun sii já. Sibẹ Jesu mú un dá wa lójú pe, ki “iran yii” tó rekọja lọ, oun yoo wá gẹgẹ bi “Ọmọ eniyan” lati mú idajọ ṣẹ lori eto-igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani. (Matteu 24:​8, 21, 37-39) A gbọdọ wà lojufo, ki a sì maa reti ‘dídé ijọba naa.’​—⁠Luku 21:​31-36.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Word Pictures in the New Testament, Idipọ I, oju-iwe 188.

b Wo Ọrọ-afikun, oju-iwe 186.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 135]

ṢÍṢÍRÒ “IGBA MEJE” NAA

“igba” 7 = 7 × 360 = 2,520 ọdun

(“igba” tabi ọdun inu Bibeli jẹ́ ipindọgba laaarin ọdun ti a fi yíyọ oṣupa kà 354 ọjọ ati eyi ti a fi iyipo oorun kà ti 365 1/4 ọjọ)

607 B.C.E. si 1 B.C.E. = 606 ọdun

1 B.C.E. si 1 C.E. = 1 ọdun

1 C.E. si 1914 C.E. = 1,913 ọdun

607 B.C.E. si 1914 C.E. = 2,520 ọdun

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 140]

“IRAN TI 1914”

Ninu iwe kan tí ó ní akori oke yii, Robert Wohl “dábàá pe awọn iran ni a kò lè tumọ lọna iṣiro niti iye awọn ọdun, ṣugbọn ó rọ̀mọ́ awọn rogbodiyan pataki inu itan, eyi tí ogun agbaye kìn-ín-ní jẹ́ apẹẹrẹ titayọlọla.”​—⁠“The Economist,” March 15, 1980

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́