ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 41
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Íṣímáẹ́lì pa Gẹdaláyà (1-10)

      • Íṣímáẹ́lì fẹsẹ̀ fẹ bó ṣe rí Jóhánánì (11-18)

Jeremáyà 41:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “látinú èso ìjọba náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:23; Jer 40:14
  • +2Ọb 25:25

Jeremáyà 41:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:1
  • +Joṣ 18:1
  • +1Ọb 16:23, 24
  • +Le 19:27, 28; Di 14:1
  • +Le 2:1

Jeremáyà 41:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíìtì.”

Jeremáyà 41:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:22; 2Kr 16:6

Jeremáyà 41:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 40:12
  • +Jer 40:7
  • +Jer 40:14

Jeremáyà 41:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 40:13; 43:2

Jeremáyà 41:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “odò ńlá.”

Jeremáyà 41:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 40:6

Jeremáyà 41:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 41:2

Jeremáyà 41:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 35:19
  • +2Ọb 25:26; Jer 42:14; 43:7

Jeremáyà 41:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 41:2

Àwọn míì

Jer. 41:12Ọb 25:23; Jer 40:14
Jer. 41:12Ọb 25:25
Jer. 41:51Ọb 12:1
Jer. 41:5Joṣ 18:1
Jer. 41:51Ọb 16:23, 24
Jer. 41:5Le 19:27, 28; Di 14:1
Jer. 41:5Le 2:1
Jer. 41:91Ọb 15:22; 2Kr 16:6
Jer. 41:10Jer 40:12
Jer. 41:10Jer 40:7
Jer. 41:10Jer 40:14
Jer. 41:11Jer 40:13; 43:2
Jer. 41:14Jer 40:6
Jer. 41:16Jer 41:2
Jer. 41:17Jẹ 35:19
Jer. 41:172Ọb 25:26; Jer 42:14; 43:7
Jer. 41:18Jer 41:2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 41:1-18

Jeremáyà

41 Ní oṣù keje, Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Netanáyà ọmọ Élíṣámà, tó wá láti ìdílé ọba,* tó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn sàràkí-sàràkí ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá míì sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ní Mísípà.+ Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Mísípà, 2 Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dìde, wọ́n sì fi idà pa Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó pa ẹni tí ọba Bábílónì yàn ṣe olórí ilẹ̀ náà. 3 Íṣímáẹ́lì tún pa gbogbo àwọn Júù tó wà pẹ̀lú Gẹdaláyà ní Mísípà àti àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà níbẹ̀.

4 Ní ọjọ́ kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti pa Gẹdaláyà, kí ẹnikẹ́ni tó mọ̀ nípa rẹ̀, 5 ọgọ́rin (80) ọkùnrin wá láti Ṣékémù,+ láti Ṣílò+ àti láti Samáríà.+ Wọ́n fá irùngbọ̀n wọn, wọ́n ti fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n sì ti kọ ara wọn lábẹ,+ ọrẹ ọkà àti oje igi tùràrí+ sì wà ní ọwọ́ wọn tí wọ́n mú wá sí ilé Jèhófà. 6 Torí náà, Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà jáde kúrò ní Mísípà láti lọ pàdé wọn, ó ń sunkún bó ṣe ń rìn lọ. Nígbà tó pàdé wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù.” 7 Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe wọnú ìlú náà, Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti àwọn ọkùnrin tó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, ó sì sọ òkú wọn sínú kòtò omi.

8 Ṣùgbọ́n mẹ́wàá lára àwọn ọkùnrin náà sọ fún Íṣímáẹ́lì pé: “Má pa wá, nítorí pé a ní àlìkámà,* ọkà bálì, òróró àti oyin ní ìpamọ́ nínú oko.” Torí náà, ó dá wọn sí, kò sì pa wọ́n pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn. 9 Íṣímáẹ́lì wá sọ òkú gbogbo àwọn ọkùnrin tó pa sínú kòtò omi ńlá kan tí Ọba Ásà ṣe nítorí Ọba Bááṣà ti Ísírẹ́lì.+ Inú kòtò omi yìí ni Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà kó òkú àwọn tó pa sí títí ó fi kún.

10 Íṣímáẹ́lì mú gbogbo àwọn tó kù ní Mísípà lẹ́rú,+ títí kan àwọn ọmọbìnrin ọba àti gbogbo èèyàn tó ṣẹ́ kù ní Mísípà, àwọn tí Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ ti fi sí ìkáwọ́ Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù. Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà mú wọn lẹ́rú, ó sì lọ láti sọdá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì.+

11 Nígbà tí Jóhánánì+ ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ gbogbo ohun búburú tí Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà ti ṣe, 12 wọ́n kó gbogbo ọkùnrin, wọ́n sì lọ láti bá Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà jà, wọ́n rí i lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi ńlá* tó wà ní Gíbíónì.

13 Inú gbogbo àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú Íṣímáẹ́lì dùn nígbà tí wọ́n rí Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀. 14 Ni gbogbo àwọn tí Íṣímáẹ́lì ti mú lẹ́rú láti Mísípà bá yíjú pa dà,+ wọ́n sì bá Jóhánánì ọmọ Káréà pa dà. 15 Àmọ́ Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà àti mẹ́jọ lára àwọn ọkùnrin rẹ̀ sá mọ́ Jóhánánì lọ́wọ́, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì.

16 Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó àwọn èèyàn tó ṣẹ́ kù ní Mísípà, ìyẹn àwọn tó gbà sílẹ̀ lọ́wọ́ Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà, lẹ́yìn tó ti pa Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù. Wọ́n kó àwọn ọkùnrin, àwọn ọmọ ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pa dà dé láti Gíbíónì. 17 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lọ, wọ́n sì dé sí ibùwọ̀ Kímúhámù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù+ láti lọ sí Íjíbítì+ 18 torí àwọn ará Kálídíà. Ẹ̀rù wọn ń bà wọ́n, nítorí Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà ti pa Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù, ẹni tí ọba Bábílónì yàn ṣe olórí ilẹ̀ náà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́