ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ws orí 13 ojú ìwé 106-112
  • “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Yíjú Sí Awọn Wọnni Tí Wọn Wà Lẹ́hìn-Òde Majẹmu Titun Naa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Yíjú Sí Awọn Wọnni Tí Wọn Wà Lẹ́hìn-Òde Majẹmu Titun Naa
  • Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Fi “Awọn Agutan Miiran” Kun Agbo Kan
  • Ninawọ Ikesini naa: “Maa Bọ” Jade
  • Majẹmu Titun Ti Ọlọrun Ń Súnmọ́ Àṣeparí Rẹ̀
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Lẹhin Majẹmu Titun Naa—Ijọba Ẹlẹgbẹrun Ọdun
    Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
  • Ẹ̀yin Yóò Di “Ìjọba Àwọn Àlùfáà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Ìbùkún Púpọ̀ Sí I Nípasẹ̀ Májẹ̀mú Tuntun
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia”
ws orí 13 ojú ìwé 106-112

Ori 13

“Ọmọ-Aládé Alaafia” naa Yíjú Sí Awọn Wọnni Tí Wọn Wà Lẹ́hìn-Òde Majẹmu Titun Naa

1. Eeṣe ti awọn Ju ti oni kò lè sẹ́ pe majẹmu Mose ti a ṣe pẹlu awọn babanla wọn yoo wa si opin?

AWỌN Ju abinibi lonii, awọn wọnni ti wọn jẹ́ atọmọdọmọ nipa ti ara fun babanla naa Abrahamu, kò lè sẹ pe majẹmu Ofin Mose ogbologboo ni a o fi majẹmu titun didara ju kan rọpo rẹ̀. Wọn kò lè yọ awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun naa kuro ninu awọn ikọwe Iwe Mímọ́ lede Heberu bi a ṣe kọ ọ ninu Jeremiah 31:31 pe: “Wò ó, ọjọ ń bọ, ni Oluwa wi, ti emi o bá ile Israeli ati ile Juda dá majẹmu titun.”

2. Bawo ni ibeere nipa ta ni yoo jẹ́ Alarina majẹmu titun naa ṣe di eyi ti a ṣipaya nikẹhin?

2 Ẹni ti alarina majẹmu titun naa yoo jẹ́ ni Jeremiah kò sọ asọtẹlẹ rẹ̀. Ṣugbọn ní alẹ Nisan 14, 33 C.E., nigba ti Jesu Kristi ń fi ago waini Irekọja lé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọwọ, o fihan pe oun ni yoo jẹ́ Alarina yẹn. (Luku 22:20) Ninu Heberu 7:22 a sọ fun wa pe oun ni ìdógò, “onigbọwọ,” tabi oniduro, fun iru “majẹmu” titun “ti o dara ju” bẹẹ.

3. Ipo miiran wo niha ọdọ Ọlọrun ni Jesu Kristi dì mú, o ha si jẹ́ nipasẹ ìlà idile ni bi?

3 Nipasẹ irubọ nitori majẹmu titun naa, Jesu wá di Olori Alufaa ti Jehofa. Oun kò dà bẹẹ nipasẹ titi ọdọ Aaroni, olori alufaa akọkọ fun Israeli wá lọna abinibi. A búra fun un sinu ipo Olori Alufaa nipasẹ ìbúra Ọlọrun Ọga-Ogo, Jehofa, Afi-Alufaa-Jẹ naa. Awọn ọ̀rọ̀ Orin Dafidi 110:4 ní imuṣẹ si Jesu lara pe: “Oluwa ti búra, ki yoo si yi ọkan pada pe, iwọ ni alufaa titilae nipa ẹsẹ ti Melkisedeki!”​—⁠Heberu 7:​20, 21.

4. (a) Pẹlu iru “Israeli” wo ni Jehofa bá dá majẹmu titun ti a ṣeleri rẹ̀ naa, eesitiṣe? (b) Awọn wọnni ti a mú wọ inu majẹmu titun naa di awọn ọmọkunrin awọn òbí wo?

4 Yatọ si àṣẹ́kù kekere kan, orilẹ-ede Israeli abinibi kọ Jesu Kristi bi Alarina majẹmu titun naa. Nipa bayii “ile Israeli” eyi ti Ọlọrun ba dá majẹmu titun ti a sọtẹlẹ naa ni ẹri fihan pe o jẹ́ Israeli tẹmi, “Israeli Ọlọrun.” (Galatia 6:16) A bí Israeli tẹmi yẹn ní ọjọ Pentekosti, 33 C.E. Niwọn bi oun ti jẹ́ ti ẹmi, o lè gba awọn onigbagbọ ti kii ṣe Ju, tabi awọn Keferi bi ọmọ ilu rẹ̀. (Iṣe 15:14) Peteru darukọ rẹ̀ bii “iran ti a yàn, olualufaa, orilẹ-ede mímọ́, eniyan ọ̀tọ̀.” (1 Peteru 2:9) “Orilẹ-ede mímọ́” yii jẹ́ ikojọpọ awọn ọmọkunrin tẹmi ti Abrahamu Gigaju naa, Jehofa, Oluṣe ati Olumu majẹmu Abrahamu ṣẹ. Nitori naa, wọn tun jẹ́ “awọn ọmọkunrin” ètò-àjọ bi iyawo Jehofa ní ọ̀run lẹsẹkan naa, eyi ti Sara, aya Abrahamu jẹ awojiji rẹ̀. Láì ṣee yẹsilẹ, majẹmu titun ti Abrahamu Gigaju naa fún ètò-àjọ ti ọ̀run yẹn gẹgẹ bi iya “iru-ọmọ” ti a ṣeleri naa, tí Isaaki jẹ́ awojiji rẹ̀, ní afiyesi ti ó yẹ.

A Fi “Awọn Agutan Miiran” Kun Agbo Kan

5. Ki ni majẹmu titun naa ń beere fun nihin-⁠in lori ilẹ̀-ayé?

5 Majẹmu titun yẹn nilo awọn ojiṣẹ alaapọn nihin-⁠in lori ilẹ̀-ayé, awọn mẹmba àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo si ti sìn gẹgẹ bi awọn ti ó kun iwọn titootun bi awọn “iranṣẹ majẹmu titun” ti ó ti rọpo majẹmu Ofin Mose ti ó ti gbó naa. (2 Korinti 3:6) Wọn kii ṣe awọn ojiṣẹ alufaa ti wọn wà ninu ọgọrọọrun awọn ẹya-isin Kristẹndọm, apa ti ó gbajumọ julọ ninu Babiloni Nla ti ode-oni. Wọn ti ṣegbọran si aṣẹ Ìfihàn 18:4 wọn si ti jade wá lati inu ilẹ-ọba isin eke agbaye yẹn.

6. (a) Iye wo ni a fi awọn ojiṣẹ majẹmu titun naa mọ si? (b) Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Oluṣọ-Agutan Rere naa yoo yi afiyesi rẹ̀ si awọn wọnni ti wọn wà lẹhin ode majẹmu titun naa?

6 Iye awọn ojiṣẹ majẹmu titun yẹn ni a o fimọ si 144,000. (Ìfihàn 7:1-⁠8; 14:1-⁠5) Nitori naa akoko yẹn nilati de nigba ti Oluṣọ-Agutan Rere naa yoo yi afiyesi rẹ̀ rekọja iha ọ̀dọ̀ awọn ojiṣẹ majẹmu titun naa. Olori Ojiṣẹ Jehofa ti ri eyi tẹ́lẹ̀ ó si tọkasi eyi nigba ti ó sọ, ninu Johannu 10:16, wi pe oun ní “awọn agutan miiran,” ti kii ṣe ti “agbo kekere” ti 144,000 yii.​—⁠Luku 12:32.

7. (a) Eeṣe ti awọn mẹmba “awọn agutan miiran” naa kii ṣe awọn ojiṣẹ majẹmu titun naa? (b) Bawo ni àṣẹ́kù awọn wọnni ti wọn ti wà ninu majẹmu titun naa ṣe di ibukun fun awọn idile ati orilẹ-ede ilẹ̀-ayé?

7 Bi o tilẹ jẹ pe “awọn agutan miiran” ki yoo jẹ́ apakan “agbo kekere,” wọn yoo jẹ́ ojiṣẹ Ọlọrun, pẹlu, ṣugbọn kii ṣe awọn ojiṣẹ majẹmu titun naa. Ati otitọ naa pe “awọn agutan miiran” yẹn yoo di “agbo kan” pẹlu iyoku awọn “iranṣẹ majẹmu titun” yoo fi ohun nla kan han. Ki ni? Eyi: Ṣaaju ki a to ṣe wọn logo ninu Ijọba ọ̀run, àṣẹ́kù naa bi ẹnikọọkan yoo darapọ pẹlu “awọn agutan miiran” naa lori ilẹ̀-ayé. Ní ọna yii àṣẹ́kù iru-ọmọ ẹmi ti Abrahamu yoo bẹrẹsii jẹ́ ibukun fun gbogbo idile ayé ati awọn orilẹ-ede ṣaaju “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” ní Armageddoni ati ṣaaju igba ibẹrẹ ijọba Ẹgbẹrun Ọdun naa.​—⁠Galatia 3:29; Ìfihàn 16:​14, 16.

8. Nigba wo ni Oluṣọ-Agutan Rere naa yi afiyesi rẹ̀ si awọn wọnni ti wọn wà lẹhin ode majẹmu titun naa, igbesẹ akọkọ wo si ni “awọn agutan miiran” wọnyi ti gbé?

8 Bayii ni ọran ti ri gan-⁠an, paapaa ní pataki lati 1935. Lati igba naa, araadọta ọkẹ “awọn agutan miiran” wọnyẹn ti darapọ mọ́ ẹgbẹẹgbẹrun awọn ijọ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yíká-ayé wọn sì ti ya araawọn si mímọ́ fun Oluṣọ-Agutan Onipo ajulọ naa, Jehofa Ọlọrun. A si tipa bayii gbà wọn wọle sinu “agbo kan” ti Oluṣọ-Agutan Rere naa, Jesu Kristi.

9. Njẹ imugbooro afiyesi Alarina majẹmu titun naa ha tumọsi pe iṣẹ-ojiṣẹ majẹmu titun naa ti pari lori ilẹ̀-ayé bi?

9 Njẹ otitọ naa pe Alarina majẹmu titun naa, lati igba naa lọ, ti ń mu ki afiyesi rẹ̀ gbooro titikan “awọn agutan miiran” pẹlu ha tumọsi pe iṣẹ-ojiṣẹ majẹmu titun naa pari si 1935 bi? Bẹẹkọ, nitori àṣẹ́kù awọn ojiṣẹ majẹmu titun naa ṣi kù lori ilẹ̀-ayé, wọn si nilati pari iṣẹ-ojiṣẹ yẹn.

10. Awọn wo lonii ni wọn ń janfaani lati inu iṣẹ-ojiṣẹ majẹmu titun naa bi awọn onkọwe Iwe Mímọ́ Kristian Lede Griki mẹjọ naa ti kọ ọ silẹ?

10 Lonii, àṣẹ́kù “agbo kekere” naa pẹlu “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti Oluṣọ-Agutan Rere naa ti iye wọn tubọ ń pọ̀ sii ń janfaani lati inu iṣẹ-ojiṣẹ awọn miiran ti wọn ti wà ṣaaju wọn, iru bii aposteli Paulu. Ní fifi iṣotitọ mú iṣẹ-ojiṣẹ majẹmu titun naa ṣẹ titi de oju iku rẹ̀ ní Romu ní akoko kan ṣaaju ki a tó pa Jerusalemu run ní 70 C.E., a misi Paulu lati kọ 14 ninu 27 awọn iwe ti Iwe Mímọ́ Kristian Lede Griki. Ẹ wo bi àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo ati “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti yẹ ki wọn kun fun ọpẹ tó pe awọn ọkunrin oluṣotitọ ọrundun kìn-ín-ní, iru bii aposteli Paulu ati awọn onkọwe Iwe Mímọ́ Kristian Lede Griki meje miiran, mu ẹru-iṣẹ majẹmu titun wọn ṣẹ titi de opin igbesi-aye wọn lori ilẹ̀-ayé! Ati pẹlu ní akoko wa, araadọta ọkẹ “awọn agutan miiran” ni wọn ti ń janfaani lati inu iṣẹ-ojiṣẹ majẹmu titun naa bayii, bi àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo naa ti ń mu un ṣe labẹ idari Alarina naa, Jesu Kristi. “Ọmọ-Aládé Alaafia” naa ní bayii ti yi afiyesi rẹ̀ si “awọn agutan miiran” ẹni ọ̀wọ́n wọnyi, ti iye wọn tubọ ń yara roke sii.

11. (a) Bawo ni o ti pẹ́ tó ti majẹmu titun naa ti wà lẹnu iṣẹ, ki ni eyi si fihan? (b) Ninu ipo wo ni àṣẹ́kù awọn ojiṣẹ majẹmu titun naa ti ń ṣiṣẹsin lonii?

11 Bi o ti wu ki o ri, akoko ti nilati maa tan lọ nisinsinyi! Majẹmu titun naa ti wà lẹnu iṣẹ fun eyi ti o ju 1,950 ọdun lọ nisinsinyi, ti ó fi eyi ti o lé ní 400 ọdun wà pẹ ju majẹmu Ofin Mose ti oun rọpo, iye awọn ojiṣẹ majẹmu titun naa si ń diku sii bi awọn mẹmba ti ń fi oju iran ilẹ̀-ayé silẹ ninu iku. Ṣugbọn àṣẹ́kù awọn ojiṣẹ wọnni lonii ń baa lọ lati maa ṣiṣẹsin bii “ẹru oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu naa” ẹni ti Oluwa rẹ̀, Jesu Kristi, yàn ṣe “olori gbogbo ohun-ini rẹ̀.”​—⁠Matteu 24:​45-⁠47, NW.

Ninawọ Ikesini naa: “Maa Bọ” Jade

12. Ní ibamu pẹlu Ìfihàn 22:17, ikesini wo ni ẹgbẹ “iyawo” naa nawọ rẹ̀ jade, ati si awọn wo?

12 Ẹ wo bi iṣẹ-isin ti awọn ojiṣẹ majẹmu titun wọnni ń ṣe ti jẹ́ onifẹẹ to! Fun apẹẹrẹ, ninu Ìfihàn 22:17 a kà pe: “Ati ẹmi ati iyawo wi pe, Maa bọ̀. Ati ẹni ti ó ń gbọ ki ó wi pe, Maa bọ̀. Ati ẹni ti oungbẹ ń gbẹ ki ó wá. Ẹnikẹni ti ó ba si fẹ, ki o gba omi iye naa lọfẹẹ.” Ẹgbẹ “iyawo” naa, ní ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu agbara iṣiṣẹ Jehofa, tabi ẹmi rẹ̀, ń nawọ ikesini yẹn jade si awọn ti wọn wà lẹhin ode majẹmu titun naa. A nawọ ikesini naa, kii ṣe sí awọn wọnni ti wọn ti ku nisinsinyi ninu iboji iranti ti a o fi ajinde kuro ninu iku jinki, ṣugbọn si awọn eniyan ti wọn walaaye nisinsinyi, ti wọn wà ninu ewu iparun ní Armageddoni ṣugbọn ti wọn ní eti igbọran.

13. (a) Ikesini ti ẹgbẹ “iyawo” naa nawọ rẹ̀ jade ha ti jẹ́ lasan bi? Ṣalaye. (b) Ki ni awọn wọnni ti wọn ti tẹwọgba ikesini naa ń ṣe ní igbọran si Ìfihàn 22:17? (c) Ki ni ọran naa gbọdọ ti ri pẹlu akoko ti ó ṣẹku fun ninawọ ikesini naa jade?

13 Kii ṣe lasan ni a ti nawọ ikesini onifẹẹ yii jade kárí-ayé ní pataki lati 1935. Eyi ti ó ju igba ọ̀kẹ́ ni wọn ti dahunpada si ikesini alaaanu naa lati wá mu omi. Bí awọn wọnni ti wọn ti fetisilẹ pẹlu imọriri, wọn ń fi tìgbọràn-tìgbọràn sọ fun awọn araadọta ọkẹ pupọ sii ti oungbẹ ń gbẹ fun iwalaaye ailopin ninu paradise ori ilẹ̀-ayé pe, “Maa bọ.” Ṣugbọn akoko fun ninawọ ikesini alaaanu yii jade si “awọn agutan miiran” ní ààlà. Lẹhin ṣiṣe inawọ rẹ̀ sini fun eyi ti ó ju aadọta ọdun, akoko ti ó ṣẹku fun un nisinsinyi ti nilati kuru gidi gan-⁠an ni, niwọn bi ogun Ọlọrun ní Armageddoni ti ń rọdẹdẹ pẹlu ami ikilọ buburu lori “iran” eniyan yii.​—⁠Matteu 24:⁠34.

14. Ki ni ohun ti a gbọdọ maa dupẹ ki a si maa yin Jehofa fun?

14 Nitori naa, nisinsinyi, ọpẹ ni fun Jehofa fun pipese Alarina titootun ẹni ti ó ṣaṣeyọri ṣiṣe aṣepari ète majẹmu titun naa ní pipese awọn eniyan kan, 144,000 ní iye, fun orukọ Rẹ̀! Iyin ni, pẹlu, fun Jehofa pe Alarina rẹ̀ gẹgẹ bi Oluṣọ-Agutan Rere kan ti ń mu araadọta ọkẹ “awọn agutan miiran” ti wọn tubọ ń pọ sii wọnú “agbo kan” naa, nibi ti wọn ti bẹrẹsii janfaani awọn ibukun ti ń ṣan wá sọdọ awọn iran eniyan lati inu majẹmu titun naa!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 111]

Araadọta ọkẹ “awọn agutan miiran” ti wá sinu ètò-àjọ Jehofa ti a le fojuri ní awọn ọjọ ikẹhin wọnyi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́