ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gt orí 47
  • Omijé Yípadà di Ayọ̀ Ńlá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Omijé Yípadà di Ayọ̀ Ńlá
  • Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Jí Ọmọbìnrin Kan Dìde!
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jésù Jí Òkú Dìde
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • A Lè Jí Dìde Kúrò Nínú Ikú!
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Jésù Ṣe Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìyanu
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
gt orí 47

Orí 47

Omijé Yípadà di Ayọ̀ Ńlá

NIGBA ti Jairu ríi pe a mú obinrin onísun ẹ̀jẹ̀ naa láradá, ìgbọ́kànlé rẹ̀ ninu agbára iṣẹ́-ìyanu Jesu láìsí àníàní pọ̀sí i. Ṣaaju ní ọjọ́ naa, Jairu ti beere pe kí Jesu wá kí ó sì ṣe ìrànwọ́ fun ọmọbinrin oun ààyò olùfẹ́ ọlọ́dún-12, tí ó dùbúlẹ̀ ní bèbè ikú. Nisinsinyi, bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí Jairu bẹ̀rù julọ wáyé. Nigba tí Jesu ṣì ńsọ̀rọ̀ pẹlu obinrin naa, awọn ọkunrin kan dé wọn sì sọ fun Jairu lọna jẹ́jẹ́ pe: “Ọmọbinrin rẹ ti kú! Eeṣe tí iwọ tún fi ńkó iyọnu bá olùkọ́ni?”

Bawo ni ìròhìn naa ti ńbanininujẹ tó! Tilẹ̀ ronú ná: Ọkunrin yii, ẹni tí a bọ̀wọ̀ ńlá fun ní àdúgbò di aláìnírànlọ́wọ́ patapata nisinsinyi bí ó ti gbọ́ ikú ọmọbinrin rẹ̀. Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, fetíkọ́ ìbánisọ̀rọ̀pọ̀ naa. Nitori naa, o yíjú sí Jairu, o sì fun un ni iṣiri wipe: “Má bẹ̀rù: ṣá lo ìgbàgbọ́.”

Jesu bá ọkunrin tí ẹ̀dùn-ọkàn kọlù naa pada lọ sí ilé rẹ̀. Nigba ti wọn dé ibẹ̀, wọn rí ìrúkèrúdò ẹkún sísun ati ìpohùnréré ẹkún ńlá. Ogunlọgọ kóra jọ, wọn sì ńlu araawọn ninu ẹ̀dùn-ọkàn. Nigba ti Jesu wọlé, ó beere pe: “Eeṣe tí ẹyin fi ńdá ìdàrúdàpọ̀ aláriwo ati ẹkún silẹ̀? Ọmọ kekere naa kò tíì kú, ṣugbọn ó ńsùn ni.”

Ní gbígbọ́ eyi, awọn eniyan naa bẹrẹsii fi Jesu rẹ́rìn-ín ẹlẹya nitori wọn mọ̀ pe ọmọbinrin naa ti kú niti gidi. Jesu, bí ó ti wù kí ó rí, sọ pe ó wulẹ ńsùn ni. Nipasẹ lílo awọn agbára tí Ọlọrun fifun un, oun yoo fihàn pe awọn eniyan ni a lè mú padà lati inú ikú lọna tí ó rọrùn bi a ṣe lè jí ẹnikan lati ojú oorun àsùnwọra.

Nisinsinyi Jesu mú kí olukuluku eniyan jáde àyàfi Peteru, Jakọbu, Johanu, ati ìyá ọmọbinrin tí ó ti kú naa ati baba rẹ̀. Lẹhin naa ni ó mú awọn márùn-ún wọnyi pẹlu rẹ̀ lọ sí ibi tí ọmọbinrin naa dùbúlẹ̀ sí. Ní gbígbá ọwọ́ ọmọbinrin naa mú ṣinṣin, Jesu wipe: “Talʹi·tha cuʹmi,” eyi tí itumọ rẹ̀ jẹ́: “Omidan, mo wí fun ọ, Dìde!” Lójúkan-náà ọmọbinrin naa dìde ó sì bẹrẹsii rìn kaakiri! Ìran naa fẹrẹẹ mú kí ayọ̀ ńlá ṣe awọn òbí rẹ̀ ní ìrànrán.

Lẹhin fífúnni ní ìtọ́ni pe kí a fi ohun kan fun ọmọ naa lati jẹ, Jesu pàṣẹ fun Jairu ati iyawo rẹ̀ lati maṣe sọ ohun ti o ti ṣẹlẹ fun ẹnikẹni. Ṣugbọn láìka ohun tí Jesu wí sí, ọ̀rọ̀ nipa rẹ̀ tànkálẹ̀ lọ sí gbogbo ẹ̀kún ilẹ̀ yẹn. Eyi ni ajinde keji tí Jesu ṣe. Matiu 9:18-26; Maaku 5:35-43; Luuku 8:41-56.

▪ Ìròhìn wo ni Jairu gbà, bawo sì ni Jesu ṣe fun un ní ìṣírí?

▪ Ki ni ipò naa ti jẹ́ nigba ti wọn dé ilé Jairu?

▪ Eeṣe tí Jesu fi wipe ọmọ tí ó kú naa wulẹ ńsùn ni?

▪ Awọn márùn-ún wo ní nbẹ lọ́dọ̀ Jesu tí wọn fojúrí ajinde naa?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́