ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • dg apá 7 ojú ìwé 14-17
  • Ki Ni ti Jẹ Abajade Ìṣọ̀tẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ki Ni ti Jẹ Abajade Ìṣọ̀tẹ̀?
  • Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ipo-Ọran naa Lonii
  • Ohun Ti Akoko Ti Fihan
  • Oju-iwoye Gígùn ti Ọlọrun
  • Àyè Tí Ọlọ́run Fi Gba Ìjìyà Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dópin
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Eeṣe Tí Ijiya Ati Aisi Idajọ Òdodo Fi Pọ̀ Tobẹẹ?
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!
    Gbogbo Ìpọ́njú Máa Dópin Láìpẹ́!
  • Idi Ti Ọlọrun Ti Fi Fayegba Ijiya
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
Àwọn Míì
Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
dg apá 7 ojú ìwé 14-17

Apa 7

Ki Ni ti Jẹ Abajade Ìṣọ̀tẹ̀?

1-3. Bawo ni akoko ti ṣe fẹri han pe Jehofa tọna?

NIPA ti ariyanjiyan ẹ̀tọ́ ti Ọlọrun lati ṣakoso, ki ni ti jẹ abajade gbogbo awọn ọrundun wọnyi ti iṣakoso eniyan laisi ọwọ Ọlọrun nibẹ? Awọn eniyan ha ti fi ẹri hàn pe wọn jẹ oluṣakoso ti o sanju Ọlọrun lọ bi? Bi a bá fi akọsilẹ iwa òṣìkà ti eniyan si eniyan ṣedajọ rẹ̀, dajudaju bẹẹkọ.

2 Nigba ti awọn obi wa akọkọ kọ iṣakoso Ọlọrun silẹ, ijaba tẹlee. Wọn mu ijiya wa sori araawọn ati gbogbo idile eniyan ti o wá lati ọdọ wọn. Wọn kò si lè dẹbi fun ẹnikẹni ayafi araawọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pe: “Wọn ti ba araawọn jẹ lọdọ rẹ̀, wọn kii ṣe ọmọ rẹ̀, àbuku wọn ni.”​—⁠Deuteronomi 32:⁠5.

3 Itan ti fi itọna ikilọ Ọlọrun fun Adamu ati Efa han pe bi wọn bá jade kuro labẹ awọn ipese Ọlọrun, wọn yoo dibajẹ wọn yoo sì ku lẹhin-o-rẹhin. (Genesisi 2:⁠17; 3:⁠19) Wọn jade kuro labẹ iṣakoso Ọlọrun loootọ, ati laipẹ wọn dibajẹ wọn sì ku loootọ.

4. Eeṣe ti a fi bí gbogbo wa ni alaipe, ti o lè ṣaisan ki o si ku?

4 Ohun ti o ṣẹlẹ lẹhin naa si gbogbo atọmọdọmọ wọn jẹ gẹgẹ bi Romu 5:⁠12 ti ṣalaye: “Ẹ̀ṣẹ̀ ti . . . ipa ọdọ eniyan kan [Adamu, olori idile araye] wọ ayé, ati iku nipa ẹ̀ṣẹ̀; bẹẹni iku si kọja sori eniyan gbogbo.” Nitori naa nigba ti awọn obi wa akọkọ ṣọ̀tẹ̀ lodisi jijẹ ti Ọlọrun jẹ alabojuto, wọn di ẹlẹṣẹ ti o labuku. Ni ibamu pẹlu awọn ofin ti tita àtaré animọ-ẹda nipaṣẹ ọna ìbímọ, ogún ti aipe ti o jẹyọ lati ibẹ wà ni ohun ti wọn lè pin fun awọn atọmọdọmọ wọn. Idi niyẹn ti a fi bí gbogbo wa ni alábùkù, ti o lè saisan ki o sì ku.

5, 6. Ki ni itan ti fihan nipa isapa eniyan lati mu alaafia ati aásìkí tootọ wa?

5 Ọpọ ọrundun ni o ti kọja lọ. Awọn iṣakoso olu-ọba ti wá wọn si ti lọ. Gbogbo oniruuru ijọba ti a lè ronu kàn ni a ti danwo. Sibẹ, leralera, awọn ohun afonilaya ti ṣẹlẹ si idile eniyan. Lẹhin ẹgbẹrun ọdun mẹfa, ẹnikan lè rò pe awọn eniyan yoo ti tẹsiwaju de bi pe wọn yoo gbe alaafia, idajọ ododo, ati aásìkí kalẹ kárí ilẹ̀-ayé ati pe ní bayii wọn yoo ti loye iniyelori inurere, ìyọ́nú, ati ifọwọsowọpọ ni kikun.

6 Bi o ti wu ki o ri, odikeji ni ohun ti o ń ṣẹlẹ. Kò si iru ijọba ti a tíì pete ti o tíì mu alaafia ati aásìkí tootọ wá fun gbogbo eniyan. Ninu ọrundun 20 yii nikanṣoṣo, a ti ri ìṣìkàpa araadọta ọkẹ raurau lọna ti a wéwèé ṣe latokedelẹ nigba Ipanirundeeru ati ipakupa eyi ti o ju 100 million ninu awọn ogun. Ni akoko tiwa ọkẹ aimọye eniyan ni a ti daloro, ṣìkàpa, ti a sì ju sẹ́wọ̀n nititori airi-ara-gbankan-si ati iyatọsira niti ọran iṣelu.

Ipo-Ọran naa Lonii

7. Bawo ni a ṣe lè ṣapejuwe ipo idile eniyan lonii?

7 Ni afikun sii, gbe apapọ ipo idile eniyan lonii yẹwo. Iwa ọdaran ati iwa ipa wọpọ. Ìlòkúlò oogun oloro gbodekan. Àkóràn aisan lọna ti ibalopọ takọtabo gbilẹ̀gbòde. Aisan ti a foya rẹ̀ naa AIDS ń nipa lori araadọta ọkẹ eniyan. Araadọta ọkẹ lọna mẹwa mẹwa eniyan ń ku lọwọ ebi tabi aisan lọdọọdun, nigba ti iwọnba eniyan ni ọrọ̀ rẹpẹtẹ. Awọn eniyan ń ba ilẹ̀-ayé jẹ́ wọn si ń jẹ ẹ run. Iniyelori ti idile ati iwarere ti wolulẹ nibi gbogbo. Niti tootọ, igbesi-aye lonii ń fi iṣakoso buruku jai ti Satani, “ọlọrun aye yi” han. Ayé ti oun jẹ́ ọ̀gá fun tutu jọ̀bọ̀lọ̀, kò loju aanu, o sì kun bamubamu fun iwà ibajẹ.​—⁠2 Korinti 4:⁠4.

8. Eeṣe ti a kò fi lè pe awọn aṣeyọri araye ni itẹsiwaju tootọ?

8 Ọlọrun ti yọnda akoko ti o pọ̀ tó fun awọn eniyan lati de otente itẹsiwaju wọn lori imọ ijinlẹ ati ọrọ̀ alumọni. Ṣugbọn o ha jẹ itẹsiwaju tootọ gidi nigba ti a fi ibọn arọ̀jò-ọta, ọkọ̀ agba ologun nla, ọkọ̀ ofurufu ayara-bi-aṣa ti a fi ń ju bọmbu, ati awọn ohun ija atọmiki oloro dipo ọrun ati ọfà bi? O ha jẹ itẹsiwaju nigba ti awọn eniyan bá lè rinrin ajo lọ si gbangba ojude ofurufu ṣugbọn ti wọn kò lè gbe papọ ni alaafia nihin in lori ilẹ̀-ayé bi? O ha jẹ itẹsiwaju nigba ti awọn eniyan bá ń bẹru lati rin loju pópó ni alẹ, tabi koda lọsan gangan ni awọn ibomiran bi?

Ohun Ti Akoko Ti Fihan

9, 10. (a) Ki ni awọn ọrundun akoko ti o ti kọja ti fihan ni kedere? (b) Eeṣe ti Ọlọrun ki yoo fi gba ominira ifẹ-inu kuro?

9 Ohun ti ayẹwo akoko ọpọ ọrundun ti fihan ni pe kò ṣeeṣe fun awọn eniyan lati dari awọn iṣisẹ wọn pẹlu aṣeyọri laigbarale iṣakoso Ọlọrun. Kò ṣeeṣe fun wọn lati ṣe iyẹn gan an bi kò ti ṣeeṣe fun wọn lati walaaye laisi jijẹun, mimu omi, ati mimi atẹgun sinu. Ẹri naa ṣe kedere: A wéwèé gbe wa kalẹ lati gbarale itọsọna Ẹlẹdaa wa gan an gẹgẹ bi o ti daju pe a ṣẹda wa lati gbara le ounjẹ, omi, ati atẹgun.

10 Nipa fifayegba iwa buburu, Ọlọrun lẹẹkan ati fun gbogbo ìgbà ti ṣaṣefihan abayọri bibani-ninujẹ ti àṣìlò ominira ifẹ-inu. Ominira ifẹ-inu sì jẹ ẹbun iyebiye tobẹẹ ti kàkà ki Ọlọrun gbà a kuro lọwọ awọn eniyan, o yọnda fun wọn lati ri ohun ti àṣìlò rẹ̀ tumọ si. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ otitọ nigba ti o wi pe: “Kò sì ni ipá eniyan ti ń rin, lati tọ́ iṣisẹrẹ.” O tun kun fun otitọ pẹlu nigba ti o wi pe: “Ẹnikan ń ṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.”​—⁠Jeremiah 10:⁠23; Oniwaasu 8:⁠9.

11. Iru iṣakoso eniyan eyikeyii ha tíì mu ijiya kuro bi?

11 Gbigba ti Ọlọrun gba iṣakoso eniyan láàyè fun ẹgbẹrun ọdun mẹfa fi tagbara-tagbara ṣapejuwe pe eniyan kò lè fi opin si ijiya. Kò tíì figba kankan ṣe bẹẹ rí. Fun apẹẹrẹ, ni ìgbà ayé rẹ̀, Ọba Solomoni ti Israeli, pẹlu gbogbo ọgbọn, ọrọ̀, ati agbara rẹ̀, kò lè mu òṣì ati arè ti o jẹyọ lati inu iṣakoso eniyan kuro. (Oniwaasu 4:​1-⁠3) Lọna kan-naa ni ọjọ tiwa, awọn aṣaaju ayé, koda pẹlu ọna igbaṣe ti o de kẹhin, kò lè mu ijiya kuro. Eyi ti o buru julọ sibẹ, itan ti fihan pe awọn eniyan ti kò gbarale iṣakoso Ọlọrun ti fikun ijiya kàkà ti wọn ìbá fi mu un kuro.

Oju-iwoye Gígùn ti Ọlọrun

12-14. Awọn anfaani ọlọjọ gígùn wo ni o de gẹgẹ bi abajade gbigba ti Ọlọrun gba ijiya láàyè?

12 Gbigba ti Ọlọrun gba ijiya láàyè ti kun fun irora fun wa. Ṣugbọn oun lo oju-iwoye gígùn, ni mímọ̀ abayọri rere ti yoo de lẹhin-o-rẹhin. Oju-iwoye Ọlọrun yoo ṣanfaani fun awọn iṣẹda, kii ṣe fun kiki ọdun diẹ kan tabi ẹgbẹrun melookan, ṣugbọn fun araadọta ọkẹ ọdun, bẹẹni, titi lọ gbere.

13 Bi ipo naa bá tun dide ni akoko ọjọ iwaju eyikeyii pe ẹnikan ṣi ominira ifẹ-inu lò lati gbe ibeere dide si ọna ti Ọlọrun gba ń ṣe awọn nǹkan, kì yoo tun beere pe ki a fun un ni ààyè lati gbiyanju lati fẹri oju-iwoye rẹ̀ mulẹ. Pe oun ti yọnda fun awọn ọlọ̀tẹ̀ fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun, Ọlọrun ti fi idi àwòṣe lọna ofin lelẹ̀ eyi ti a lè maa mu lò titi fáàbàdà nibikibi ni agbaye.

14 Nitori pe Jehofa ti fayegba iwa ibi ati ijiya ni akoko yii, a o ti fẹri rẹ̀ han daradara pe kò si ohun ti o bá ṣe alaiwa ni iṣọkan pẹlu rẹ̀ ti o lè ṣaṣeyọri. A o ti fi i han rekọja iyemeji pe kò si ipete rikiṣi olominira ti awọn eniyan tabi awọn ẹda ẹmi ti o lè mu anfaani wiwa pẹ titi wa. Nipa bayii, Ọlọrun ni a o dalare ni kikun ni titẹ ọlọ̀tẹ̀ eyikeyii ni àtẹ̀rẹ̀ ni kíámọ́sá. “Awọn eniyan buburu ni yoo parun.”​—⁠Orin Dafidi 145:⁠20; Romu 3:⁠4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Lẹhin ti awọn obi wa akọkọ yan ominira kuro lọdọ Ọlọrun, wọn dagba wọn si ku ni gbẹ̀hìngbẹ́hín

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Iṣakoso eniyan laisi ọwọ Ọlọrun ninu rẹ̀ ti jẹ ti oníjàbá

[Credit Line]

Fọto U.S. Coast Guard

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́