ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • dg apá 6 ojú ìwé 12-14
  • Idi Ti Ọlọrun Ti Fi Fayegba Ijiya

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Idi Ti Ọlọrun Ti Fi Fayegba Ijiya
  • Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ariyanjiyan ti Ipo Ọba-Alaṣẹ Agbaye
  • Ìṣọ̀tẹ̀ ti Awọn Ẹda Ẹmi
  • Ariyanjiyan Meji
  • Ijọba naa—Eeṣe Tí Ó Fi Pẹ́ Tobẹẹ Ní ‘Dídé’?
    “Kí Ijọba Rẹ Dé”
  • Ìjìyà Ẹ̀dá Ènìyàn—Èéṣe Tí Ọlọrun Fi Fàyègbà Á?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ọ̀ràn Tó Kan Gbogbo Wa
    Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà
  • Ìdí Tí Ìwà Ibi Ṣì Fi Wà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
Àwọn Míì
Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
dg apá 6 ojú ìwé 12-14

Apa 6

Idi Ti Ọlọrun Ti Fi Fayegba Ijiya

1, 2. Bawo ni awọn obi wa akọkọ ṣe ba ibẹrẹ didara ti Ọlọrun fi fun wọn jẹ?

KI NI ṣaitọna? Ki ni ṣẹlẹ ti o ba ibẹrẹ daradara tí Ọlọrun fi fun awọn obi wa akọkọ ninu Paradise ni Edeni jẹ? Eeṣe, kàkà ti ìbá fi jẹ alaafia ati iṣọkan inu Paradise, ti iwa buburu ati ijiya fi bori fun ẹgbẹẹgbẹrun ọdun?

2 Idi naa ni pe Adamu ati Efa ṣi ominira ifẹ-inu tiwọn lò. Wọn padanu oju-iwoye otitọ naa pe a kò dá wọn lati ni aásìkí lọtọ laisi Ọlọrun ati awọn ofin rẹ̀. Wọn pinnu lati wà lominira kuro lọdọ Ọlọrun, ni rironu pe eyi yoo mu ki igbesi-aye wọn sunwọn sii. Nitori naa wọn tayọ ààlà ominira ifẹ-inu ti Ọlọrun ti palaṣẹ.​—⁠Genesisi, ori 3.

Ariyanjiyan ti Ipo Ọba-Alaṣẹ Agbaye

3-5. Eeṣe ti Ọlọrun kò fi wulẹ pa Adamu ati Efa run ki o sì tun bẹrẹ lẹẹkan sii?

3 Eeṣe ti Ọlọrun kò fi wulẹ pa Adamu ati Efa run ki o sì bẹrẹ lẹẹkan sii pẹlu eniyan meji miiran? Nitori pe ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀, iyẹni pe, ẹ̀tọ́ rẹ̀ lati ṣakoso ti a kò lè já gbà kuro, ni a ti penija.

4 Ibeere naa ni pe: Ta ni o ni ẹ̀tọ́ lati ṣakoso, akoso ta si ni o tọna? Jijẹ ti oun jẹ olodumare ati Ẹlẹdaa gbogbo iṣẹda fun Ọlọrun ni ẹ̀tọ́ lati ṣakoso lori wọn. Niwọn bi oun ti jẹ ọlọgbọn gbogbo, akoso rẹ̀ ni o dara julọ fun gbogbo iṣẹda. Ṣugbọn iṣakoso Ọlọrun ni a ti penija bayii. Pẹlupẹlu, ohun kan ha ṣaitọ pẹlu iṣẹda rẹ̀​—⁠eniyan bi? Awa yoo ṣayẹwo bi ibeere nipa iwatitọ eniyan ṣe wemọ ọran naa ni iwaju.

5 Pe eniyan di ominira kuro lọdọ Ọlọrun, tun dọgbọn gbe ibeere miiran yọ: Eniyan ha lè ṣe daradara jù ti Ọlọrun kò bá ṣakoso wọn bi? Dajudaju Ẹlẹdaa mọ idahun naa, ṣugbọn ọna ti o daju kan fun eniyan lati ṣawari idahun naa ni lati yọnda ominira patapata ti wọn ń fẹ fun wọn. Wọn yan ipa-ọna yẹn lati inu ominira ifẹ-inu araawọn, nitori naa Ọlọrun fayegba a.

6, 7. Eeṣe ti Ọlọrun ti fi yọnda ominira patapata fun eniyan fun ìgbà pipẹ titi tobẹẹ?

6 Nipa yiyọnda akoko ti o pọ̀ tó fun awọn eniyan lati ṣe idanrawo pẹlu ominira patapata, Ọlọrun yoo fi idi rẹ̀ mulẹ titi lọ gbere boya eniyan lè ṣe daradara ju labẹ akoso ti Ọlọrun tabi ti ara wọn. Akoko ti a si yọnda gbọdọ nilati gun to lati fun awọn eniyan laaye lati de ibi ti wọn kasi otente awọn ohun ti wọn lè ṣaṣeyọri rẹ̀ lọna ti iṣelu, ọgbọn imọ-ẹrọ, imọ ijinlẹ, ati ilana iṣegun.

7 Nitori naa, Ọlọrun ti gba eniyan laaye ni kikun titi di ọjọ wa lati fihan rekọja iyemeji boya akoso eniyan laigbara lé e lè ṣaṣeyọri. Nipa bayi o ṣeeṣe fun eniyan lati yàn laaarin inurere ati iwa òṣìkà, laaarin ifẹ ati ikoriira, laaarin ododo ati aiṣododo. Ṣugbọn oun ni abajade yiyan ti oun ṣe dojukọ pẹlu: rere ati alaafia tabi buburu ati ijiya.

Ìṣọ̀tẹ̀ ti Awọn Ẹda Ẹmi

8, 9. (a) Bawo ni ìṣọ̀tẹ̀ ṣe bẹsilẹ ni ilẹ-ọba ẹmi? (b) Ta ni yàtọ̀ si Adamu ati Efa ni Satani sún lati ṣọ̀tẹ̀?

8 Koko miiran wà lati gbeyẹwo. Kii ṣe kiki awọn obi wa akọkọ nikan ni wọn ṣọtẹ lodisi akoso Ọlọrun. Ṣugbọn awọn miiran wo ni o tun wà ni akoko naa? Awọn ẹda ẹmi. Ṣaaju ki Ọlọrun to ṣẹda awọn eniyan, oun ti ṣẹda oriṣi iwalaaye gigaju kan, iye awọn angẹli ti wọn pọ̀ lọ rẹpẹtẹ, lati gbe ni ilẹ akoso ti ọrun. Awọn pẹlu ni a dá pẹlu ominira ifẹ-inu ati bakan naa pẹlu aini naa lati wà ni itẹriba fun akoso Ọlọrun.​—⁠Jobu 38:⁠7; Orin Dafidi 104:⁠4; Ìfihàn 5:⁠11.

9 Bibeli fihan pe ìṣọ̀tẹ̀ kọkọ bẹsilẹ ni ilẹ̀-ọba ẹmi. Ẹda ẹmi kan ń fẹ ominira patapata. Oun tilẹ ń fẹ ki awọn eniyan maa jọsin oun. (Matteu 4:​8, 9) Ọlọ̀tẹ̀ ẹda ẹmi yii wa di koko ipilẹ kan ninu lilo agbara-idari lori Adamu ati Efa lati ṣọ̀tẹ̀, ni fifi eke sọ pe Ọlọrun ń fawọ ohun didara kan sẹhin kuro lọdọ wọn. (Genesisi 3:​1-⁠5) Nitori naa a ń pe e ni Eṣu (Abanijẹ) ati Satani (Alatako). Nigba ti o ya, oun sún awọn ẹda ẹmi miiran lati ṣọ̀tẹ̀. A wá mọ wọn si awọn ẹmi eṣu.​—⁠Deuteronomi 32:⁠17; Ìfihàn 12:⁠9; 16:⁠14.

10. Ki ni àbárèbábọ̀ ìṣọ̀tẹ̀ awọn eniyan ati ti awọn ẹda ẹmi?

10 Awọn eniyan, nipa ṣíṣọ̀tẹ̀ lodisi Ọlọrun, ṣi araawọn paya si agbara-idari ti Satani ati awọn ẹmi eṣu rẹ̀. Idi niyẹn ti Bibeli fi pe Satani ni “ọlọrun aye yii,” ẹni ti o “ti sọ ọkan awọn ti kò gbagbọ di afọju.” Nipa bẹẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pe “gbogbo ayé wà labẹ agbara ẹni buburu nì.” Jesu funraarẹ̀ pe Satani ni “alade aye yii.”​—⁠2 Korinti 4:⁠4; 1 Johannu 5:⁠19; Johannu 12:⁠31.

Ariyanjiyan Meji

11. Nipa ariyanjiyan miiran wo ni Satani pe Ọlọrun nija?

11 Satani gbe ariyanjiyan miiran dide ti o pe Ọlọrun nija. Ni ọna yii, oun fẹ̀sùn kàn pe Ọlọrun ṣàṣìṣe nì ọna ti Oun gbà ṣẹda awọn eniyan ati pe kò si ẹni ti yoo fẹ ṣe ohun ti o tọ́ ti a bá fi wọn sabẹ ikimọlẹ. Ni ṣàkó, oun sọ pe labẹ idanwo wọn yoo tilẹ fi Ọlọrun bú. (Jobu 2:​1-⁠5) Ni ọna yii Satani gbe ibeere dide si iwatitọ ti awọn ẹda eniyan.

12-14. Bawo ni akoko yoo ṣe ṣi otitọ nipa awọn ariyanjiyan mejeeji ti Satani gbe dide paya?

12 Nitori naa, Ọlọrun ti yọnda akoko ti o pọ̀ tó fun gbogbo awọn ẹda olóye lati rii bi a o ṣe yanju ariyanjiyan yii ati bakan naa ariyanjiyan ti ipo ọba-alaṣẹ ti Ọlọrun. (Fiwe Eksodu 9:⁠16.) Àbárèbábọ̀ iriri itan eniyan ni yoo ṣipaya otitọ nipa awọn ariyanjiyan mejeeji wọnyi.

13 Lakọọkọ naa, ki ni akoko yoo ṣipaya nipa ti ipo ọba-alaṣẹ agbaye, ẹ̀tọ́ ti Ọlọrun lati ṣakoso? Njẹ awọn eniyan lè ṣakoso araawọn daradara ju ti Ọlọrun lọ bi? Njẹ eto-igbekalẹ ti akoso eniyan eyikeyii ni iyasọtọ kuro lọdọ Ọlọrun lè mu ayé alalaafia kan ti o bọ lọwọ ogun, iwa ọdaran, ati aisedajọ ododo wọle wá bi? Eyikeyii yoo ha lè mu òṣì kuro ki o sì pese aásìkí fun gbogbo eniyan bi? Eyikeyii yoo ha lè ṣẹgun aisan, ọjọ ogbo, ati iku bi? Iṣakoso Ọlọrun ni a wéwéè-gbekalẹ lati ṣe gbogbo iyẹn.​—⁠Genesisi 1:​26-⁠31.

14 Nipa ti ariyanjiyan keji, ki ni akoko yoo ṣipaya niti ọran itoye ẹda eniyan? O ha jẹ àṣìṣe fun Ọlọrun lati ṣẹda eniyan ni ọna ti oun gba ṣe e bi? Njẹ eyikeyii ninu wọn yoo ṣe ohun ti o tọ́ labẹ idanwo bi? Awọn eniyan eyikeyii yoo ha fihan pe awọn ń fẹ iṣakoso Ọlọrun dipo ti iṣakoso olominira ti eniyan bi?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ọlọrun ti yọnda akoko fun awọn eniyan lati de otente awọn ohun ti wọn lè ṣaṣeyọri rẹ̀

[Credit Line]

Ọkọ̀ ìrìn-àjò si gbangba ojude ofurufu: A gbekari fọto ti NASA

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́