ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rq ẹ̀kọ́ 10 ojú ìwé 20-21
  • Àwọn Àṣà Tí Ọlọrun Kórìíra

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Àṣà Tí Ọlọrun Kórìíra
  • Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Sá fún Ohun Búburú
    Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Yàgò Fún Ìdẹkùn Tẹ́tẹ́ Títa
    Jí!—2002
  • Tẹ́tẹ́ Títa
    Jí!—2015
  • Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Tẹ́tẹ́ Títa?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
rq ẹ̀kọ́ 10 ojú ìwé 20-21

Ẹ̀kọ́ 10

Àwọn Àṣà Tí Ọlọrun Kórìíra

Báwo ni ó ṣe yẹ kí o nímọ̀lára nípa àwọn nǹkan tí Ọlọrun sọ pé ó burú? (1)

Irú ìbálòpọ̀ wo ni kò tọ̀nà? (2)

Ojú wo ni ó yẹ kí Kristian fi wo irọ́ pípa? (3) tẹ́tẹ́ títa? (3) olè jíjà? (3) ìwà ipá? (4) ìbẹ́mìílò? (5) ìmùtípara? (6)

Báwo ni ẹnì kan ṣe lè fi àwọn àṣà búburú sílẹ̀? (7)

1. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun nífẹ̀ẹ́ ohun rere. Ṣùgbọ́n wọ́n tún gbọ́dọ̀ kọ́ láti ­kórìíra ohun búburú. (Orin Dafidi 97:10) Ìyẹ́n túmọ̀ sí yíyẹra fún àwọn àṣà kan tí Ọlọrun kórìíra. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àṣà wọ̀nyẹn?

2. Àgbèrè: Ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, panṣágà, ìbẹ́rankolòpọ̀, ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan, àti ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo lòdì sí Ọlọrun. (Lefitiku 18:⁠6; Romu 1:​26, 27; 1 Korinti 6:​9, 10) Bí tọkọtaya kan kò bá ṣègbéyàwó, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń gbé pọ̀, wọ́n ní láti pínyà tàbí kí wọ́n ṣègbéyàwó ní ìbámu pẹ̀lú òfin.​—⁠Heberu 13:⁠4.

3. Irọ́ Pípa, Tẹ́tẹ́ Títa, Olè Jíjà: Jehofa Ọlọrun kò lè purọ́. (Titu 1:⁠2) Àwọn ènìyàn tí ń wá ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ gbọ́dọ̀ yẹra fún irọ́ pípa. (Owe 6:​16-⁠19; Kolosse 3:​9, 10) Gbogbo onírúurú tẹ́tẹ́ títa ní ìwọra nínú. Nítorí náà, àwọn Kristian kì í lọ́wọ́ nínú irú tẹ́tẹ́ títa èyíkéyìí, irú bíi tẹ́tẹ́ oríire, tẹ́tẹ́ eré ẹṣin, àti bíńgò. (Efesu 5:​3-⁠5) Àwọn Kristian kì í sì í jalè. Wọn kì í mọ̀-⁠ọ́nmọ̀ ra ọjà tí a jí gbé tàbí mú nǹkan láìgba àṣẹ.​—⁠Eksodu 20:15; Efesu 4:⁠28.

4. Ìrufùfù Ìbínú, Ìwà Ipá: Ìbínú tí a kò kápá lè ṣamọ̀nà sí àwọn ìṣe oníwà ipá. (Genesisi 4:​5-⁠8) Oníwà ipá kan kò lè jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọrun. (Orin Dafidi 11:⁠5; Owe 22:​24, 25) Ó lòdì láti gbẹ̀san tàbí láti fi ibi san búburú tí àwọn ẹlòmíràn lè ṣe sí wa.​—⁠Owe 24:29; Romu 12:​17-⁠21.

5. Oògùn Onídán àti Ìbẹ́mìílò: Àwọn ènìyàn kan ń lo agbára àwọn ẹ̀mí láti lè wo àrùn sàn. Àwọn mìíràn ń sà sí àwọn ọ̀tá wọn láti mú wọn ṣàìsàn tàbí láti pa wọ́n pàápàá. Satani ni agbára tí ó wà lẹ́yìn gbogbo àwọn àṣà wọ̀nyí. Nítorí náà, àwọn Kristian kò gbọdọ̀ lọ́wọ́ nínú èyíkéyìí lára wọn. (Deuteronomi 18:​9-⁠13) Sísún mọ́ Jehofa pẹ́kípẹ́kí ni ààbò dídára jù lọ kúrò lọ́wọ́ oògùn tí àwọn ẹlòmíràn lè sà sí wa.​—⁠Owe 18:⁠10.

6. Ìmùtípara: Kò lòdì láti mu wáìnì, ọtí bíà, tàbí ọtí líle mìíràn, níwọ̀nba. (Orin Dafidi 104:15; 1 Timoteu 5:23) Ṣùgbọ́n, ìmukúmu àti ìmùtípara lòdì lójú Ọlọrun. (1 Korinti 5:​11-⁠13; 1 Timoteu 3:⁠8) Ọtí àmujù lè ba ìlera rẹ jẹ́, kí ó sì da ìdílé rẹ rú. Ó tún lè jẹ́ kí o tètè ṣubú sínú àwọn àdánwò míràn.​—⁠Owe 23:​20, 21, 29-⁠35.

7. Àwọn tí ń ṣe àwọn nǹkan tí Ọlọrun sọ pé ó burú “kì yoo jogún ìjọba Ọlọrun.” (Galatia 5:​19-⁠21) Bí o bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọrun ní tòótọ́, tí o sì fẹ́ láti mú inú rẹ̀ dùn, o lè fi àwọn àṣà wọ̀nyí sílẹ̀. (1 Johannu 5:⁠3) Kọ́ láti kórìíra ohun tí Ọlọrun sọ pé ó burú. (Romu 12:⁠9) Kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìwà-bí-Ọlọ́run. (Owe 13:20) Àwọn Kristian alábàákẹ́gbẹ́, tí wọ́n dàgbà dénú, lè jẹ́ orísun ìrànwọ́. (Jakọbu 5:14) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, gbára lé ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ àdúrà.​—⁠Filippi 4:​6, 7, 13.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Ọlọrun kórìíra ìmùtípara, olè jíjà, tẹ́tẹ́ títa, àti àwọn ìṣe oníwà ipá

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́