ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gf ẹ̀kọ́ 14 ojú ìwé 22-23
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Sá fún Ohun Búburú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Máa Ń Sá fún Ohun Búburú
  • Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àṣà Tí Ọlọrun Kórìíra
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Kí La Lè Ṣe Láti Mú Inú Ọlọ́run Dùn?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Apa 13
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run
  • “Ìgbà Nínífẹ̀ẹ́ àti Ìgbà Kíkórìíra”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
gf ẹ̀kọ́ 14 ojú ìwé 22-23

Ẹ̀kọ́ 14

Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Máa Ń sá Fún Ohun Búburú

Sátánì máa ń sún àwọn èèyàn ṣe ohun búburú. Ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run ní láti kórìíra ohun tí Jèhófà bá kórìíra. (Sáàmù 97:10) Díẹ̀ lára nǹkan tí àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run máa ń yẹra fún rèé:

Ara àwọn ohun tí Jèhófà kórìíra ni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀, ìmùtípara, ìṣẹ́yún, olè jíjà, irọ́ pípa, ìbínú fùfù àti tẹ́tẹ́ títa

Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀. “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.” (Ẹ́kísódù 20:14) Níní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó lòdì pẹ̀lú.—1 Kọ́ríńtì 6:18.

Ìmùtípara. “Àwọn ọ̀mùtípara [kì] yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:10.

Ìṣìkàpànìyàn, oyún ṣíṣẹ́. “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣìkà pànìyàn.”—Ẹ́kísódù 20:13.

Olè Jíjà. “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.”—Ẹ́kísódù 20:15.

Irọ́ Pípa. Jèhófà kórìíra “ahọ́n èké.”—Òwe 6:17.

Ìwà Ipá àti Ìbínú Tí A Ò Ṣàkóso. “Dájúdájú, [Jèhófà] kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) “[Apá kan] àwọn iṣẹ́ ti ara [ni] . . . ìrufùfù ìbínú.”—Gálátíà 5:19, 20.

Tẹ́tẹ́ Títa. “Ẹ jáwọ́ dídarapọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni . . . tí ó jẹ́ . . . oníwọra.”—1 Kọ́ríńtì 5:11.

Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.”—Mátíù 5:43, 44.

Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ń sọ fún wa jẹ́ fún ire wa. Kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti yẹra fún ṣíṣe ohun búburú. Pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà àti ìrànwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀, o lè yẹra fún ṣíṣe ohun tínú Ọlọ́run ò dùn sí.—Aísáyà 48:17; Fílípì 4:13; Hébérù 10:24, 25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́