APÁ 13
Kí La Lè Ṣe Láti Mú Inú Ọlọ́run Dùn?
Máa sá fún ohun tó burú. 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10
Tí a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní ṣe àwọn ohun tó kórìíra.
Jèhófà ò fẹ́ ká jalè, kò fẹ́ ká mutí para, kò sì fẹ́ ká máa lo oògùn nílòkulò.
Ọlọ́run kórìíra ìpànìyàn, ìṣẹ́yún àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀. Kò fẹ́ ká jẹ́ olójúkòkòrò, kò sì fẹ́ ká máa jà.
A ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn ère tàbí ká lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò.
Kò ní sáyè fún àwọn tó ń hùwà burúkú nínú Párádísè tó ń bọ̀.
Máa ṣe ohun tó dára. Mátíù 7:12
Tí a bá fẹ́ mú inú Ọlọ́run dùn, a gbọ́dọ̀ sapá ká lè fìwà jọ ọ́.
Tí o bá jẹ́ onínúure àti ọ̀làwọ́, èyí máa fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn.
Jẹ́ olóòótọ́.
Máa ṣàánú, kí o sì máa dárí jini.
Máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fún àwọn èèyàn àtàwọn ohun tó ń ṣe.—Àìsáyà 43:10.