ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rq ẹ̀kọ́ 11 ojú ìwé 22-23
  • Àwọn Èrò Ìgbàgbọ́ àti Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Tí Inú Ọlọrun Kò Dùn Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Èrò Ìgbàgbọ́ àti Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Tí Inú Ọlọrun Kò Dùn Sí
  • Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Easter tàbí Ìṣe Ìrántí Èwo ni Ó Yẹ Kí O Ṣe?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Pinnu Láti Jọ́sìn Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Ṣayẹyẹ Ọdún Àjíǹde?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àwọn Ayẹyẹ Tí Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
Àwọn Míì
Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
rq ẹ̀kọ́ 11 ojú ìwé 22-23

Ẹ̀kọ́ 11

Àwọn Èrò Ìgbàgbọ́ àti Àṣà Ìṣẹ̀dálẹ̀ Tí Inú Ọlọrun Kò Dùn Sí

Irú àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wo ni ó lòdì? (1)

Ó ha yẹ kí Kristian gbà gbọ́ pé Ọlọrun jẹ́ Mẹ́talọ́kan? (2)

Èé ṣe tí àwọn Kristian tòótọ́ kì í fi í ṣayẹyẹ Keresimesi, Easter, tàbí ọjọ́ ìbí? (3, 4)

Òkú ha lè pa alààyè lára bí? (5)

Jesu ha kú sórí àgbélébùú bí? (6)

Báwo ni ó ti ṣe pàtàkì tó láti mú inú Ọlọrun dùn? (7)

1. Kì í ṣe gbogbo èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ni ó burú. Ṣùgbọ́n, Ọlọrun kò tẹ́wọ́ gbà wọ́n bí wọ́n bá wá láti inú ìsìn èké tàbí bí wọ́n bá lòdì sí àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli.​—⁠Matteu 15:⁠6.

2. Mẹ́talọ́kan: Jehofa ha jẹ́ Mẹ́talọ́kan​—⁠ẹni mẹ́ta nínú Ọlọrun kan ṣoṣo bí? Rárá o! Jehofa, Baba, ni “Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo.” (Johannu 17:⁠3; Marku 12:29) Jesu jẹ́ Ọmọkùnrin Rẹ̀ àkọ́bí, ó sì wà ní ìtẹríba fún Ọlọrun. (1 Korinti 11:⁠3) Baba tóbi ju Ọmọkùnrin lọ. (Johannu 14:28) Ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan; ó jẹ́ ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun.​—⁠Genesisi 1:⁠2; Ìṣe 2:⁠18.

3. Keresimesi àti Easter: Kì í ṣe December 25 ni a bí Jesu. A bí i ní nǹkan bí October 1, àkókò kan nínú ọdún nígbà tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń da àwọn agbo ẹran wọn lọ sínú pápá ní òru. (Luku 2:​8-⁠12) Jesu kò pàṣẹ fún àwọn Kristian rí láti ṣayẹyẹ ìbí rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa ṣèrántí, tàbí rántí, ikú rẹ̀. (Luku 22:​19, 20) Keresimesi àti àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ̀ wá láti inú àwọn ìsìn èké ìgbàanì. Ohun kan náà jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Easter, irú bíi lílo ẹyin àti ehoro. Àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣayẹyẹ Keresimesi tàbí Easter, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn Kristian tòótọ́ lónìí kì í ṣe wọ́n.

4. Ọjọ́ ìbí: Àwọn ènìyàn tí kò jọ́sìn Jehofa ni ó ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjì péré tí a ròyìn nínú Bibeli. (Genesisi 40:​20-⁠22; Marku 6:​21, 22, 24-⁠27) Àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ṣíṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí wá láti inú àwọn ìsìn èké ìgbàanì. Àwọn Kristian tòótọ́ ń fi ẹ̀bùn tọrẹ, wọ́n sì ń gbádùn ara wọn ní àwọn àkókò míràn láàárín ọdún.

5. Ìbẹ̀rù Àwọn Òkú: Àwọn òkú kò lè ṣe ohunkóhun tàbí nímọ̀lára ohunkóhun. A kò lè ràn wọ́n lọ́wọ́, wọn kò sì lè pa wá lára. (Orin Dafidi 146:⁠4; Oniwasu 9:​5, 10) Ọkàn ń kú; kì í wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. (Esekieli 18:⁠4) Ṣùgbọ́n nígbà míràn, àwọn áńgẹ́lì búburú, tí a ń pè ní ẹ̀mí èṣù, máa ń díbọ́n bí ẹ̀mí àwọn òkú. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ èyíkéyìí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ̀rù tàbí ìjọsìn àwọn òkú lòdì.​—⁠Isaiah 8:⁠19.

6. Àgbélébùú: Jesu kò kú sórí àgbélébùú. Orí òpó, tàbí igi dídúró ṣánṣán kan, ni ó kú sí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà tí a tú sí “àgbélébùú” nínú ọ̀pọ̀ Bibeli túmọ̀ sí ẹyọ igi kan ṣoṣo. Àmì àgbélébùú wá láti inú àwọn ìsìn èké ìgbàanì. Àwọn Kristian àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kò lo àgbélébùú tàbí jọ́sìn rẹ̀. Nítorí náà, ìwọ́ ha rò pé yóò tọ̀nà láti lo àgbélébùú nínú ìjọsìn bí?​—⁠Deuteronomi 7:26; 1 Korinti 10:⁠14.

7. Ó lè ṣòro gan-⁠an láti kọ díẹ̀ nínú àwọn èrò ìgbàgbọ́ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọ̀nyí sílẹ̀. Àwọn ìbátan àti ọ̀rẹ́ lè gbìyànjú láti yí ọ lérò padà láti má ṣe yí àwọn èrò ìgbàgbọ́ rẹ padà. Ṣùgbọ́n, mímú inú Ọlọrun dùn ṣe pàtàkì ju mímú inú ènìyàn dùn.​—⁠Owe 29:⁠25; Matteu 10:​36, 37.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ọlọrun kì í ṣe Mẹ́talọ́kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Keresimesi àti Easter wá láti inú àwọn ìsìn èké ìgbàanì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kò sí ìdí láti jọ́sìn àwọn òkú tàbí láti bẹ̀rù wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́