Àìleèkú Ọkàn—Bí Ẹ̀kọ́ Náà Ṣe Bẹ̀rẹ̀
“Kò tún sí kókó ìjíròrò mìíràn nípa ẹ̀dá ẹni nínú lọ́hùn-ún tí ó máa ń gba ènìyàn lọ́kàn bí ti ipò tí ó máa ń wà lẹ́yìn ikú.”—Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ “ENCYCLOPÆDIA OF RELIGION AND ETHICS.”
1-3. Báwo ni Socrates àti Plato ṣe gbé èrò náà pé ọkàn jẹ́ aláìleèkú jáde?
AFẸ̀SÙN ìwà àìtọ́ àti kíkọ́ àwọn ọmọdé ní ìkọ́kúkọ̀ọ́ kan ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan, ẹni 70 ọdún, tí ó jẹ́ olùkọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣàlàyé ara rẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ẹlẹ́tanú dá a lẹ́bi, wọ́n sì dájọ́ ikú fún un. Ní wákàtí díẹ̀ péré kí wọ́n tó pa á, arúgbó olùkọ́ náà ṣe onírúurú àlàyé fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó pé yí i ká, láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọkàn jẹ́ aláìleèkú àti pé ikú kì í ṣe ohun tí a ń bẹ̀rù.
2 Ọkùnrin tí a dájọ́ ikú fún náà ni Socrates, gbajúmọ̀ ọlọ́gbọ́n èrò orí, ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ti ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, kì í ṣe ẹlòmíràn. Plato ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ kọ ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí sínú àwọn àròkọ náà, Apology àti Phaedo. Socrates àti Plato ni a sọ pé ó kọ́kọ́ gbé èrò náà pé ọkàn jẹ́ aláìleèkú jáde. Ṣùgbọ́n àwọn kọ́ ni wọ́n pilẹ̀ ẹ̀kọ́ yìí.
3 Bí a ó ṣe padà rí i, ìpilẹ̀ṣẹ̀ èrò náà pé ènìyàn jẹ́ aláìleèkú lọ jìnnàjìnnà dé ìgbà láéláé. Àmọ́, Socrates àti Plato ni ó tún èrò náà ṣàlàyé mọ́nránmọ́rán, tí wọ́n sì sọ ọ́ di ẹ̀kọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí, tí ó fi tipa báyìí di ohun tí ó fa àwùjọ àwọn ọ̀mọ̀wé ìgbà ayé wọn àti ré kọjá ìgbà náà mọ́ra.
Láti Ìgbà Pythagoras Títí Dé Ìgbà Àwọn Òkìtì Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀
4. Ṣáájú Socrates, kí ni ojú ìwòye àwọn Gíríìkì nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú?
4 Àwọn ará Gíríìkì tí ó wà ṣáájú Socrates àti Plato pẹ̀lú gbà gbọ́ pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú. Ojú ìwòye Pythagoras, gbajúmọ̀ onímọ̀ ìṣirò, ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì ti ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, ni pé ọkàn jẹ́ aláìleèkú, ó sì máa ń papò dà. Ṣáájú rẹ̀, Thales ti Mílétù, tí a rò pé ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n èrò orí ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tí a kọ́kọ́ mọ̀, rò pé kì í ṣe inú ènìyàn, ẹranko, àti àwọn ewéko nìkan ni ọkàn aláìleèkú wà, ṣùgbọ́n pé ó tún wà nínú àwọn nǹkan bí mágínẹ́ẹ̀tì, níwọ̀n bí wọ́n ti lè fa irin mọ́ra. Àwọn Gíríìkì ìgbàanì sọ pé ṣe ni a máa ń fi ọkọ̀ ojú omi gbé ọkàn àwọn òkú kọjá odò Styx wọnú àgbègbè abẹ́lẹ̀ salalu kan tí wọ́n ń pè ní ayé àwọn òkú. Níbẹ̀, àwọn adájọ́ a máa rán àwọn ọkàn lọ sínú ẹ̀wọ̀n kan tí ògiri rẹ̀ ga tàbí kí wọ́n rán an lọ sínú ipò ayọ̀ pípé ní Elysium.
5, 6. Kí ni àwọn ará Páṣíà ka ọkàn sí?
5 Ní ilẹ̀ Iran, tàbí Páṣíà, níhà ìlà-oòrùn, wòlíì kan tí a ń pè ní Zoroaster yọjú ní ọ̀rúndún keje ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó dá ọ̀nà ìjọsìn kan sílẹ̀ tí a wá mọ̀ sí ẹ̀sìn Zoroaster. Èyí ni ẹ̀sìn Ilẹ̀ Ọba Páṣíà tí ó jọba lé ayé lórí kí Gíríìsì tó di agbára ayé pàtàkì kan. Ìwé Mímọ́ àwọn ẹlẹ́sìn Zoroaster sọ pé: “Nínú àìleèkú ni ọkàn Olódodo yóò ti máa wà nínú Ìdùnnú láéláé, ṣùgbọ́n inú ìdálóró ni ọkàn Òpùrọ́ yóò wà dájúdájú. Àwọn Òfin wọ̀nyí sì ni Ahura Mazda [tí ó túmọ̀ sí “ọlọ́run ọlọ́gbọ́n”] ti fi ọlá àṣẹ ipò ọba rẹ̀ pa láṣẹ.”
6 Ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn tún jẹ́ apá kan nínú àwọn ẹ̀sìn ilẹ̀ Iran tí ó ti wà ṣáájú ẹ̀sìn Zoroaster. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀yà ìgbàanì ní ilẹ̀ Iran máa ń ṣètọ́jú ọkàn àwọn tí ó ti papò dà nípa pípèsè ọrẹ oúnjẹ àti aṣọ tí yóò ṣe wọ́n láǹfààní nínú ayé àwọn òkú fún wọn.
7, 8. Kí ni àwọn ará Íjíbítì ìgbàanì gbà gbọ́ nípa pé ọkàn ń la ikú ara já?
7 Ìgbàgbọ́ nínú ìwàláàyè lẹ́yìn ikú jẹ́ òpómúléró nínú ẹ̀sìn àwọn ará Íjíbítì. Àwọn ará Íjíbítì gbà gbọ́ pé Osiris, olú ọlọ́run ayé àwọn òkú, yóò ṣèdájọ́ fún ọkàn òkú. Bí àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ kan tí ó wà nínú ìwé tí a fi òrépèté ṣe, tí a sọ pé ó ti wà láti ọ̀rúndún kẹrìnlá ṣááju Sànmánì Tiwa, fi Anubis, ọlọ́run àwọn òkú, hàn bí ó ṣe ń ṣamọ̀nà ọkàn akọ̀wé náà, Hunefer, lọ sọ́dọ̀ Osiris. Ọkàn-àyà akọ̀wé náà, tí ó dúró fún ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀, ni a ń fi ìyẹ́ kan, tí abo ọlọ́run òtítọ́ àti àìṣègbè fi sórí, díwọ̀n lórí ìwọ̀n onígaméjì. Thoth, ọlọ́run mìíràn, ní ń ṣàkọsílẹ̀ àbájáde rẹ̀. Níwọ̀n bí ọkàn Hunefer kò ti wúwo nítorí ẹ̀bi, kò wúwo tó ìyẹ́ náà, a sì jẹ́ kí Hunefer wọnú ilẹ̀ ọba Osiris kí ó sì gba àìleèkú. Ìwé òrépèté náà tún fi abàmì abo kan hàn, ó dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ìwọ̀n náà, ó ṣe tán láti gbé olóògbé náà mì bí ọkàn rẹ̀ bá fìdí rẹmi nínú ìdánwò náà. Àwọn ará Íjíbítì tún máa ń kun òkú wọn lọ́ṣẹ, wọn a sì pa òkú àwọn fáráò mọ́ sínú àwọn òkìtì aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ńláńlá, níwọ̀n bí wọ́n ti rò pé wíwàláàyè nìṣó ọkàn sinmi lórí pípa tí wọ́n bá pa ara òkú náà mọ́.
8 Nígbà náà, ẹ̀kọ́ kan náà—àìleèkú ọkàn—ni àwọn ará ìgbàanì lónírúurú jọ gbà gbọ́. Ṣé orísun kan náà ni wọ́n ti gba ẹ̀kọ́ yìí ni?
Ibi Tí Ó ti Pilẹ̀
9. Ẹ̀sìn wo ni ó nípa lórí àwọn ènìyàn Íjíbítì, Páṣíà àti Gíríìsì ìgbàanì?
9 Ìwé náà, The Religion of Babylonia and Assyria, sọ pé: “Ní ayé ìgbàanì, ẹ̀sìn àwọn ará Bábílónì nípa lórí àwọn ará Íjíbítì, Páṣíà, àti Gíríìsì.” Ìwé yìí ń bá àlàyé rẹ̀ lọ pé: “Nítorí ìfarakanra tí ó wà láàárín Íjíbítì àti Bábílónì nígbà àtijọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn wàláà El-Amarna ṣe fi hàn, ó dájú pé àyè tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ ṣí sílẹ̀ fún ojú ìwòye àti àṣà àwọn ará Bábílónì láti wọnú ẹgbẹ́ awo àwọn ará Íjíbítì. Ní Páṣíà, ipa tí àwọn ìrònú àwọn ará Bábílónì ní hàn lára ẹgbẹ́ awo Mithra . . . Àdàlù ẹ̀kọ́ àwọn Semite àti ìtàn àròsọ ti àwọn Gíríìkì àti ẹgbẹ́ awo ilẹ̀ Gíríìsì ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ní gbogbogbòò ti wá tẹ́wọ́ gbà báyìí débi pé kò tún béèrè àlàyé síwájú sí i mọ́. Dé ìwọ̀n gíga, àwọn ẹ̀kọ́ Semite wọ̀nyí jẹ́ ti Bábílónì ní pàtàkì.”a
10, 11. Kí ní ojú ìwòye àwọn ará Bábílónì nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú?
10 Ṣùgbọ́n ojú ìwòye àwọn ará Bábílónì nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú kò ha yàtọ̀ gidigidi sí ti àwọn ará Íjíbítì, Páṣíà, àti ti àwọn Gíríìkì bí? Bí àpẹẹrẹ, gbé ìtàn akọni Epic of Gilgamesh ti Bábílónì yẹ̀ wò. Akọni Gilgamesh, tí ó ti ń darúgbó, ni ìdààmú bá nítorí mímọ̀ tí ó mọ̀ pé lóòótọ́ ni ikú wà, ó bá gbéra láti wá àìleèkú lọ ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ kò tẹ̀ ẹ́. Omidan kan tí ń ta wáìnì tí ó bá pàdé nígbà ìrìn àjò rẹ̀ tilẹ̀ fún un níṣìírí pé kí ó jayé ìsinsìnyí tẹ́rùn, pé ọwọ́ rẹ̀ kò lè tẹ ìwàláàyè gbére tí ó ń wá kiri. Ohun tí ìtàn akọni náà fi kọ́ni ni pé ikú kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ àti pé ríretí láti di aláìleèkú jẹ́ ìtànjẹ. Èyí yóò ha fi hàn pé àwọn ará Bábílónì kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú bí?
11 Ọ̀jọ̀gbọ́n Morris Jastrow, Kékeré, ti Yunifásítì Pennsylvania, U.S.A., kọ̀wé pé: “Àti àwọn ènìyàn àti àwọn aṣáájú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn [Babilóníà], kò sí èyí tí ó retí pé kí ohun tí a bá ti mú wá sí ìyè di èyí tí a óò tún pa rẹ́ ráúráú. [Lójú tiwọn], ikú jẹ́ ọ̀nà láti ré kọjá sínú irú ayé mìíràn, tí ó sì jẹ́ pé ńṣe ni kíkọ̀ láti gbà pé àìleèkú wà kàn túbọ̀ ń mú un ṣe kedere pé àyípadà tí ikú ń mú bá ìwàláàyè kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Bábílónì pẹ̀lú gbà gbọ́ pé irú ìwàláàyè kan, bákan ṣá, ń bá a lọ lẹ́yìn ikú. Wọ́n ń fi èyí hàn nípa sísin àwọn nǹkan èlò pọ̀ mọ́ àwọn òkú kí wọ́n lè lò wọ́n nígbà Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú.
12-14. (a) Lẹ́yìn Ìkún Omi, ibo ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ti bẹ̀rẹ̀? (b) Báwo ni ẹ̀kọ́ náà ṣe tàn káàkiri ilẹ̀ ayé?
12 Ní kedere, ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn lọ jìnnà sẹ́yìn dé Bábílónì ìgbàanì. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì, ìwé kan tí ẹ̀rí wà kedere pé ó péye ní ti ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀, ti wí, Nímírọ́dù, ọmọ ọmọ Nóà, ló tẹ ìlú Bábélì, tàbí Bábílónì, dó.b Lẹ́yìn Ìkún Omi kárí ayé lọ́jọ́ Nóà, èdè kan àti ẹ̀sìn kan péré ni ó wà. Nípa títẹ̀ tí Nímírọ́dù tẹ ìlú náà dó tí ó sì kọ́ ilé gogoro kan síbẹ̀, ẹ̀sìn mìíràn ló dá sílẹ̀. Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé, lẹ́yìn tí a da èdè rú ní Bábélì, àwọn tí ń mọ ilé gogoro tí kò kẹ́sẹ járí náà tú ká, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ àkọ̀tun ìgbésí ayé, wọ́n sì mú ẹ̀sìn wọn dání lọ. (Jẹ́nẹ́sísì 10:6-10; 11:4-9) Bí àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Bábílónì ṣe tàn ká ilẹ̀ ayé nìyẹn.
13 Ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ sọ pé ikú gbígbóná ni Nímírọ́dù kú. Lẹ́yìn ikú rẹ̀, ó bọ́gbọ́n mú pé kí àwọn ará Bábílónì fẹ́ láti gbé e gẹ̀gẹ̀ nítorí pé òun ló tẹ ìlú wọn dó, tí ó kọ́ ọ, tí ó sì kọ́kọ́ jọba níbẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọlọ́run Marduk (Méródákì) ni a kà sí ẹni tí ó tẹ Bábílónì dó, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan dábàá pé Nímírọ́dù tí wọ́n sọ di àkúnlẹ̀bọ ni wọ́n ń pè ní Marduk. Bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé èrò náà pé ènìyàn ní ọkàn kan tí ó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú yóò ti wà lóde ó kéré tán nígbà ikú Nímírọ́dù. Bí ó ti wù kí ó rí, àkọsílẹ̀ ìtàn fi hàn pé lẹ́yìn Ìkún Omi, Bábélì, tàbí Bábílónì ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ti bẹ̀rẹ̀.
14 Báwo wá ni ẹ̀kọ́ náà ṣe di òpómúléró nínú ọ̀pọ̀ ju lọ ẹ̀sìn ní ọjọ́ wa? Apá tí ó tẹ̀ lé e yóò gbé bí ó ṣe wọnú àwọn ẹ̀sìn Ìlà-Oòrùn yẹ̀ wò.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a El-Amarna ni ibi tí àwókù ìlú àwọn ará Íjíbítì náà, Akhetaton, wà, èyí tí a sọ pé wọ́n kọ́ ní ọ̀rúndún kẹrìnlá ṣááju Sànmánì Tiwa.
b Wo ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s?, ojú ìwé 37 sí 54, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ojú ìwòye àwọn ará Íjíbítì nípa àwọn ọkàn ní inú ayé àwọn òkú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Socrates ṣàlàyé pé ọkàn jẹ́ aláìleèkú