ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ie ojú ìwé 28-29
  • Òtítọ́ Nípa Ọkàn Ṣe Pàtàkì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òtítọ́ Nípa Ọkàn Ṣe Pàtàkì
  • Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òmìnira Kúrò Nínú Ìbẹ̀rù àti Àìnírètí
  • Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú—Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Rẹ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ǹjẹ́ Ẹ̀mí Èèyàn Máa Ń Kú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • ‘Òtítọ́ Yóò Sọ Yín Di Òmìnira’—Lọ́nà Wo?
    Jí!—2012
  • Ọkàn Gẹ́gẹ́ Bí Bíbélì Ṣe Fi Í Hàn
    Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
Àwọn Míì
Kí Ní Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?
ie ojú ìwé 28-29

Òtítọ́ Nípa Ọkàn Ṣe Pàtàkì

“Ẹ ó . . . mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—JÒHÁNÙ 8:32.

1. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a gbé ìgbàgbọ́ wa nípa ọkàn àti ikú yẹ̀ wò?

Ẹ̀SÌN ẹni àti àṣà ìbílẹ̀ ẹni látilẹ̀wá ní ń pinnu ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ohun tí ènìyàn gbà gbọ́ nípa ikú àti Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú. Bí a ti ṣe rí i, wọ́n yàtọ̀ látorí ìmúdánilójú pé kìkì lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àtúnbí jáǹrẹrẹ ni ọkàn ṣẹ̀ṣẹ̀ lè lé góńgó rẹ̀ bá títí dórí èrò náà pé ìgbé ayé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ń pinnu kádàrá ẹni títí láé. Látàrí èyí, ìdánilójú ti ẹnì kan lè jẹ́ ti pé òun yóò di ọ̀kan pẹ̀lú ẹni atóbijù níkẹyìn bí òun bá kú, tí ti ẹlòmíràn lè jẹ́ dídé ipò Nirvana, síbẹ̀ ti òmíràn lè jẹ́ fífi ọ̀run ṣèrè jẹ. Kí wá ló jẹ́ òtítọ́? Níwọ̀n bí àwọn ohun tí a gbà gbọ́ ti nípa lórí ìwà wa, ìṣesí wa àti àwọn ìpinnu wa, kò ha yẹ kí rírí ìdáhùn sí ìbéèrè náà jẹ wá lógún bí?

2, 3. (a) Èé ṣe tí a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọkàn? (b) Bí a ṣe kọ ọ́ sínú Bíbélì, kí ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa ọkàn?

2 Bíbélì, ìwé tí ó lọ́jọ́ lórí jù lọ láyé, tọpasẹ̀ ìtàn ènìyàn lọ sẹ́yìn dé ìgbà ìṣẹ̀dá ọkàn àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ kò ní àwọn ọgbọ́n èrò orí àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn nínú. Bíbélì sọ òtítọ́ nípa ọkàn kedere pé: Ìwọ fúnra rẹ ni ọkàn rẹ, òkú kò sí níbikíbi rárá, àti pé àwọn tí wọ́n wà nínú ìrántí Ọlọ́run ni a óò jí díde ní àkókò tirẹ̀. Kí ni ohun tí mímọ̀ tí o bá mọ èyí yóò ṣe fún ọ?

3 Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” (Jòhánù 8:32) Bẹ́ẹ̀ ni, òtítọ́ máa ń túni sílẹ̀. Ṣùgbọ́n inú kí ni òtítọ́ nípa ọkàn yóò ti dá wa sílẹ̀?

Òmìnira Kúrò Nínú Ìbẹ̀rù àti Àìnírètí

4, 5. (a) Ẹ̀rù wo ni òtítọ́ nípa ọkàn máa ń lé jáde? (b) Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe fún ọ̀dọ́langba kan tí àìsàn rẹ̀ ti dójú ikú nígboyà?

4 Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ló bẹ̀rù ikú, wọ́n sì máa ń gbìyànjú láti yẹra fún ríronú nípa rẹ̀.” Òpìtàn kan sọ pé: “Ní Ìwọ̀ Oòrùn, ọ̀rọ̀ náà ‘ikú’ pàápàá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ohun àìgbọ́dọ̀ sọ.” Nínú àwọn àwùjọ kan, àwọn àdàpè bí “jáde láyé” àti “papò dà” ni a sábà máa fi ń júwe pé ẹnì kan kú. Ní ti gidi, ìbẹ̀rù ikú yìí jẹ́ ìbẹ̀rù ohun àìmọ̀, níwọ̀n bí ikú ti jẹ́ àdììtú lójú ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn. Ìmọ̀ nípa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ síni tí a bá kú máa ń dín ìbẹ̀rù yìí kù.

5 Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ipò ọkàn Michaelyn, ọmọ ọdún 15 kan. Ọmọbìnrin náà ní àrùn àpọ̀jù sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀, ikú burúkú kan sì dojú kọ ọ́. Ìyá rẹ̀, Paula, rántí pé: “Michaelyn sọ pé òun kò bẹ̀rù àtikú nítorí òun mọ̀ pé ikú jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ lásán. A sọ̀rọ̀ gan-an nípa ayé tuntun Ọlọ́run àti gbogbo àwọn tí a óò jí dìde nínú rẹ̀. Michaelyn ní ìgbàgbọ́ tí ó kàmàmà nínú Jèhófà Ọlọ́run àti àjíǹde—kò ṣiyèméjì rárá.” Ìrètí àjíǹde mú kí ọmọdébìnrin onígboyà yìí bọ́ lọ́wọ́ gbígbọ̀n jìnnìjìnnì nítorí ikú.

6, 7. Òtítọ́ nípa ọkàn máa ń jẹ́ kí a bọ́ lọ́wọ́ irú àìnírètí wo? Ṣàkàwé.

6 Ipa wo ni òtítọ́ ní lórí àwọn òbí Michaelyn? Baba rẹ̀, Jeff, sọ pé: “Ikú ọmọdébìnrin wa jẹ́ ohun tí ń dunni jù lọ tí ó tíì ṣẹlẹ̀ sí wa rí. Ṣùgbọ́n, a gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí Jèhófà nípa àjíǹde láìṣiyèméjì, a sì ń wọ̀nà fún ọjọ́ náà tí a óò lè gbá Michaelyn olólùfẹ́ wa mọ́ra lẹ́ẹ̀kan sí i. Wíwà pa pọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i yẹn yóò mà kọyọyọ o!”

7 Bẹ́ẹ̀ ni, òtítọ́ nípa ọkàn máa ń túni sílẹ̀ kúrò nínú àìnírètí burúkú tí ikú olólùfẹ́ ẹni má ń kó báni. Lóòótọ́, kò sí ohun tí ó lè mú ẹ̀dùn àti ìrora tí ó máa ń báni tí olólùfẹ́ ẹni bá kú kúrò pátápátá. Àmọ́, ìrètí àjíǹde máa ń mú kí ṣíṣọ̀fọ̀ mọ níwọ̀n, ó sì ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn gan-an láti fara da ìrora náà.

8, 9. Òtítọ́ nípa ipò àwọn òkú máa ń jẹ́ kí a bọ́ lọ́wọ́ irú ẹ̀rù wo?

8 Òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ nípa ipò àwọn òkú tún máa ń múni bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù òkú. Ọ̀pọ̀ tí ààtò ṣíṣe tìtorí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán nípa àwọn òkú ti fìgbà kan rí gbé dè ni ó jẹ́ pé, láti ìgbà tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ yìí, wọn kò tún bẹ̀rù àsàsí, àwọn àpẹẹrẹ abàmì, ońdè, àti ohun tí ó lágbára idán mọ́, wọn kò sì ṣèrúbọ onínàáwó rẹpẹtẹ láti fi tu àwọn baba ńlá wọn lójú kí wọ́n má bàa padà wá máa yọ àwọn alààyè lẹ́nu. Ní tòótọ́, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá,” irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ kò já mọ́ nǹkan kan rárá.—Oníwàásù 9:5.

9 Òtítọ́ nípa ọkàn, bí ó ṣe wà nínú Bíbélì, máa ń dáni nídè, ó sì ṣeé fọkàn tẹ̀. Àmọ́ o, ṣàgbéyẹ̀wò ìrètí àrà ọ̀tọ̀ kan tí Bíbélì nawọ́ rẹ̀ sí ọ.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

Òtítọ́ nípa ọkàn yóò dá ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìbẹ̀rù ikú, ìbẹ̀rù àwọn òkú, àìnírètí tí ikú olólùfẹ́ ẹni máa ń fà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́