ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jt ojú ìwé 6-11
  • Ìdìde àti Ìdàgbàsókè Wọn Lóde Òní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdìde àti Ìdàgbàsókè Wọn Lóde Òní
  • Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ỌDÚN 1914
  • DÍDÁ TÍ ILÉ ẸJỌ́ Ń DÁ WA LÁRE
  • ÀKÀNṢE ÈTÒ ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́
  • ÀWỌN OHUN ÌTẸ̀WÉ DI PÚPỌ̀ SÍ I
  • ÀWỌN ÀPÉJỌPỌ̀ ÀGBÁYÉ
  • Bẹ́tẹ́lì Tó Wà Ní Brooklyn Ti Pé Ọgọ́rùn-ún Ọdún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Jẹ́ Aláápọn Ní Gbogbo Ilẹ̀-Ayé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Wàásù—Gbogbo Ọ̀nà La Fi Ń Mú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn
    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?
jt ojú ìwé 6-11

Ìdìde àti Ìdàgbàsókè Wọn Lóde Òní

ÌTÀN àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní bẹ̀rẹ̀ ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1870 sí 1879, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó fara sin bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Allegheny, Pennsylvania, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ní ibi tó wá di apá kan Pittsburgh báyìí. Charles Taze Russell ló ṣagbátẹrù ẹgbẹ́ náà. Ní July 1879, ẹ̀dà àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence yọjú. Nígbà tó máa fi di ọdún 1880, ọ̀pọ̀ ìjọ ló ti tàn kálẹ̀ lọ́ sí àwọn ìpínlẹ̀ àyíká ibẹ̀ láti ara àwùjọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣoṣo yẹn. Lọ́dún 1881, wọ́n dá ẹgbẹ́ Zion’s Watch Tower Tract Society sílẹ̀, nígbà tó sì di ọdún 1884, wọ́n fi í lọ́lẹ̀ lábẹ́ òfin, Russell sì jẹ́ ààrẹ rẹ̀. Nígbà tó yá wọ́n yí orúkọ Society yìí padà sí Watch Tower Bible and Tract Society. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń wàásù látilé délé, tí wọ́n ń fi ìwé tó dá lórí Bíbélì lọni. Àádọ́ta èèyàn ló ń fi àkókò kíkún ṣe èyí lọ́dún 1888, àmọ́ ní báyìí, ìpíndọ́gba iye wọn jákèjádò ayé jẹ́ nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [700,000].

Nígbà tó fi di ọdún 1909, iṣẹ́ yẹn ti gbilẹ̀ dé àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, ni wọ́n bá kó orílé iṣẹ́ Society wá sí ibi tó wà nísinsìnyí ní Brooklyn, ní New York. Wọ́n ń fi àwọn ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ gbé àwọn ọ̀rọ̀ ìwàásù tí wọ́n bá ti tẹ̀ jáde, nígbà tó sì fi di ọdún 1913, èdè mẹ́rin ni wọ́n fi ń gbé e jáde nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé ìròyìn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Kánádà, àti ní Yúróòpù. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún mílíọ̀nù àwọn ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, àtàwọn ìwé àṣàrò kúkúrú ni wọ́n pín kiri.

Lọ́dún 1912, wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá]. Ìyẹn ló fi àwọn àwòrán gbagidi àti àwòrán tí ń rìn tòun ti ohùn àti ìró tó bá a rìn ṣe àlàyé látorí ìṣẹ̀dá ilẹ̀ ayé títí fi dé òpin Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi. Ọdún 1914 ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbé e jáde fáráyé rí, ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì [35,000 ] ló sì ń wá wò ó lójoojúmọ́. Òun làkọ́kọ́ ṣe nínú gbogbo àwọn sinimá amóhùnmáwòrán.

ỌDÚN 1914

Àkókò pàtàkì kan ń sún mọ́lé. Lọ́dún 1876, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà, Charles Taze Russell, kọ àpilẹ̀kọ kan tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Àkókò Àwọn Kèfèrí: Ìgbà Wo Ni Wọ́n Dópin?” sínú ìwé ìròyìn Bible Examiner, tí wọ́n tẹ̀ ní Brooklyn, New York, èyí tó sọ ní ojú ìwé kẹtàdínlọ́gbọ̀n nínú ìtẹ̀jáde tí oṣù October pé, “Àkókò méje náà yóò dópin ní A.D. 1914.” Àkókò Àwọn Kèfèrí ni ìtumọ̀ Bíbélì mìíràn tún pè ní “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Lúùkù 21:24) Gbogbo ohun tí wọ́n retí pé kó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 1914 kọ́ ló ṣẹlẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ àmì pé Àkókò Àwọn Kèfèrí ti dópin, ó sì jẹ́ ọdún tó ṣe pàtàkì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òpìtàn àti àwọn alálàyé ló gbà pé ọdún 1914 jẹ́ ìgbà tí àwọn nǹkan dédé yí bìrí nínú ìtàn ìran ènìyàn. Àwọn àyọkà tó tẹ̀ lé e yìí fi èyí hàn:

“Ọdún 1913, tó wà ṣáájú kí Ogun Àgbáyé Kìíní tó bẹ̀rẹ̀, ni ọdún tí gbogbo nǹkan lọ ‘geerege’ kẹ́yìn nínú ìtàn.”—Ọ̀rọ̀ Olóòtú nínú ìwé ìròyìn Times-Herald, ti Washington, D.C., ti March 13, 1949.

“Ńṣe làwọn òpìtàn túbọ̀ ń ka ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75] tó wà láàárín 1914 sí 1989, nínú èyí tí ogun àgbáyé méjì ti jà, tí ọ̀tẹ̀ abẹ́lẹ̀ sì wáyé, sí sànmánì kan ṣoṣo, tó dá yàtọ̀ pátápátá, sáà àrà ọ̀tọ̀ kan tó jẹ́ pé níbi tó pọ̀ jù lọ nínú ayé, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ni pé yálà kí wọ́n máa jagun, tàbí kí àtúnṣe máa lọ lọ́wọ́ lẹ́yìn ogun, tàbí kí wọ́n máa múra láti jagun.”—Ìwé ìròyìn The New York Times, ti May 7, 1995.

“Gbogbo ayé pátá ló gbaná jẹ lórí Ogun Àgbáyé Kìíní, a ò sì tíì mọ̀dí rẹ̀ di báyìí. Ṣáájú ìgbà yẹn, ńṣe làwọn èèyàn rò pé a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ bọ́ sí àkókò alálàáfíà kẹlẹlẹ. Àlàáfíà àti aásìkí wà. Àfi bí gbẹgẹdẹ ṣe gbiná, tí gbogbo nǹkan wá dà rú. A ò sì tíì rímú mí láti ìgbà yẹn di báyìí . . . Iye àwọn èèyàn tí wọ́n ti pa nínú ọ̀rúndún yìí ju gbogbo èyí tí wọ́n ti ń pa látọjọ́ tí aláyé ti dáyé lọ.”—Dókítà Walker Percy, nínú ìwé American Medical News, ti November 21, 1977.

Ní ohun tó ju àádọ́ta ọdún lẹ́yìn 1914 ni òṣèlú ará Jámánì kan, Konrad Adenauer, kọ̀wé pé: “Ààbò àti ìfàyàbalẹ̀ ti pòórá kúrò nínú ìgbésí ayé ènìyàn láti ọdún 1914.”—The West Parker, ní Cleveland, Ohio, ti January 20, 1966.

Ààrẹ Society àkọ́kọ́, C. T. Russell, kú ní ọdún 1916, ọdún tó tẹ̀ lé e ni Joseph F. Rutherford sì rọ́pò rẹ̀. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìyípadà bá. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn tó ṣìkejì Ilé Ìṣọ́, tí wọ́n pè ní The Golden Age. (Tí a ń pè ní Jí! báyìí, iye rẹ̀ tó ń jáde déédéé ju ogún mílíọ̀nù lọ ní èdè tó ju ọgọ́rin.) Wọ́n túbọ̀ káràmáásìkí iṣẹ́ ìwàásù àtilé délé. Lọ́dún 1931, àwọn Kristẹni yìí tẹ́wọ́ gba orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà, láti fìyàtọ̀ sáàárín wọn àti àwọn ìjọ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Inú Aísáyà 43:10-12 lorúkọ yìí ti wá.

Wọ́n lo rédíò gan-an láti fi gbé ọ̀rọ̀ wọn sáfẹ́fẹ́ láàárín ọdún 1920 sí ọdún 1939. Nígbà tó máa fi di ọdún 1933, Society ti ń lo irínwó ó lé mẹ́ta [403] ilé iṣẹ́ rédíò láti fi gbé àsọyé Bíbélì wọn sáfẹ́fẹ́. Lẹ́yìn náà, lílọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí túbọ̀ ń lọ látilé délé, tí wọ́n ń lo ẹ̀rọ giramọfóònù tí wọ́n ń fà lọ́wọ́ láti fi gbé àsọyé Bíbélì tí wọ́n ti gbà sílẹ̀ jáde, wá dín lílo rédíò lọ́nà gbígbòòrò kù. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ilé wọn.

DÍDÁ TÍ ILÉ ẸJỌ́ Ń DÁ WA LÁRE

Láàárín ọdún 1930 sí ọdún 1949, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n fàṣẹ ọba mú àwọn Ẹlẹ́rìí nítorí iṣẹ́ ìwàásù yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹjọ́ sí kóòtù láti fi jà fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ, òmìnira láti tẹ̀wé jáde, òmìnira láti péjọ pọ̀, àti òmìnira láti jọ́sìn. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí àwọn Ẹlẹ́rìí pè sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láti àwọn ilé ẹjọ́ kékeré yọrí sí dídá tí wọ́n dá wọn láre nínú ẹjọ́ mẹ́tàlélógójì. Bákan náà ni wọ́n tún ṣe gba ìdáláre ní àwọn ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Ní ti àwọn ìdáláre ní ilé ẹjọ́ yìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n C. S. Braden sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí nínú ìwé rẹ̀, These Also Believe, pé: “Ohun ribiribi ni wọ́n gbé ṣe fún ètò ìjọba tiwa-n-tiwa ní bí wọ́n ṣe jà pé kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ àwọn gẹ́gẹ́ bí aráàlú du àwọn, nítorí nípa akitiyan tí wọ́n ṣe yẹn, wọ́n ti ṣe gudugudu méje tó jẹ́ kí gbogbo ẹ̀yà kéékèèké tó wà ní Amẹ́ríkà lè rí àwọn ẹ̀tọ́ yẹn gbà.”

ÀKÀNṢE ÈTÒ ÌDÁNILẸ́KỌ̀Ọ́

J. F. Rutherford kú ní ọdún 1942, N. H. Knorr sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ. Ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àjùmọ̀ṣe wá bẹ̀rẹ̀. Ní ọdún 1943, wọ́n dá ilé ẹ̀kọ́ àkànṣe fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn míṣọ́nnárì sílẹ̀, orúkọ rẹ̀ ni Watchtower Bible School of Gilead. Láti ìgbà yẹn wá ni wọ́n ti ń rán àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ jáde ní ilé ẹ̀kọ́ yìí lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ayé. Àwọn ìjọ tuntun ti wà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ti sí ìkankan tẹ́lẹ̀ rí, iye àwọn ẹ̀ka tí a sì ti ní káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè nísinsìnyí ti ju ọgọ́rùn-ún lọ. Látìgbà dégbà, wọ́n máa ń gbé àwọn àkànṣe ètò ẹ̀kọ́ kalẹ̀ fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ àwọn alàgbà ìjọ, àwọn òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda-ara-ẹni ní àwọn ẹ̀ka, àti àwọn tó ń fi àkókò kíkún ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí (gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà). Ọ̀kan-ò-jọ̀kan àkànṣe ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn òjíṣẹ́ ni wọ́n ti ṣe ní ibùdó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan tó wà ní Patterson, ní New York.

N. H. Knorr kú ní ọdún 1977. Ọ̀kan lára àyípadà tí a ṣe nínú ètò àjọ yìí, tí N. H. Knorr ti kópa kẹ́yìn kí ó tó kú ni àfikún iye àwọn tó jẹ́ Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, èyí tó máa ń wà ní orílé iṣẹ́ ní Brooklyn. Lọ́dún 1976, a pín àwọn ẹrù iṣẹ́ àbójútó, a sì yàn wọ́n fún ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìgbìmọ̀, àwọn tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, tó jẹ́ pé gbogbo wọn ló ti ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìrírí gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́, ló sì wà nínú àwọn ìgbìmọ̀ ọ̀hún.

ÀWỌN OHUN ÌTẸ̀WÉ DI PÚPỌ̀ SÍ I

Ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní kún fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bùyààrì. Látorí àwùjọ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kéréje kan tó wà ní Pennsylvania lọ́dún 1870 lọ́hùn-ún ni àwọn Ẹlẹ́rìí ti di nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́rin àbọ̀ [90,000] ìjọ kárí ayé nígbà tó fi máa di ọdún 2000. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ilé iṣẹ́ atẹ̀wétà ló ń bá wọn tẹ gbogbo ìwé wọn; àmọ́, lọ́dún 1920, àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọn tẹ àwọn ìwé mélòó kan nínú àwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n háyà. Ṣùgbọ́n láti ọdún 1927 síwájú, wọ́n ń tẹ àwọn ìwé púpọ̀ gan-an jáde látinú ilé iṣẹ́ alágbèéká mẹ́jọ kan ní Brooklyn, New York, ilé iṣẹ́ yẹn jẹ́ ti Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. Èyí ti wá gbòòrò sí i tó fi wá gba àwọn ilé iṣẹ́ mìíràn mọ́ra àti ilé ọ́fíìsì gàgàrà kan. Àwọn ilé mìíràn tún wà láfikún sí i nítòsí Brooklyn, fún ibùgbé àwọn òjíṣẹ́ tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa fi àwọn ohun ìtẹ̀wé wọ̀nyí ṣiṣẹ́. Ẹ̀wẹ̀, wọ́n tún ní ibi ìdáko tí wọ́n tún ti ń tẹ̀wé pẹ̀lú lẹ́gbẹ̀ẹ́ Wallkill, ní àgbègbè àríwá New York. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) àti Jí! (Gẹ̀ẹ́sì) ni wọ́n ń tẹ̀ níbẹ̀, àwọn oúnjẹ kan sì tún ń tibẹ̀ wá fún àwọn òjíṣẹ́ tó ń sìn ní àwọn apá ibòmíràn. Olúkúlùkù òṣìṣẹ́ olùyọ̀ǹda-ara-ẹni máa ń gba ìwọ̀nba owó kékeré kan láti fi kájú àwọn ìnáwó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.

ÀWỌN ÀPÉJỌPỌ̀ ÀGBÁYÉ

Ọdún 1893 ni àpéjọpọ̀ pàtàkì àkọ́kọ́ wáyé ní ìlú Chicago, Illinois, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Àwọn ọ̀tà-lé-lọ́ọ̀ọ́dúnrún [360] ló pésẹ̀ síbẹ̀, a sì batisí àádọ́rin [70] ẹni tuntun. Àpéjọpọ̀ àgbáyé ńlá tí a para pọ̀ ṣe ní ibì kan ṣoṣo kẹ́yìn wáyé ní Ìlú New York ní 1958. Pápá ìṣeré Yankee Stadium àti Polo Grounds ayé ijọ́un ni wọ́n ti ṣe é. Ìgbà tí iye àwọn tó wá pọ̀ jù lọ ló jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹgbàáje ó dín méjìdínlọ́gọ́rin [253,922]; iye ẹni tuntun tó ṣe batisí jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ó lé mẹ́rìndínlógóje [7,136]. Láti ìgbà yẹn ni wọ́n ti ń ṣe àwọn àpéjọpọ̀ àgbáyé ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ lórílẹ̀-èdè púpọ̀. Àpapọ̀ àpéjọpọ̀ tó wà nínú irú ọ̀wọ́ kan bẹ́ẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé lè tó ẹgbẹ̀rún.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Ohun ribiribi ni wọ́n gbé ṣe fún òmìnira àwọn aráàlú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

“Ilé Ìṣọ́,” láti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ní èdè kan ṣoṣo sí èyí tó ju mílíọ̀nù méjìlélógún [22,000,000] ní èdè tó ju méjìléláàádóje [132] lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìgbà tí nǹkan yí bìrí nínú ìtàn ìran ènìyàn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́