Bẹ́tẹ́lì Tó Wà Ní Brooklyn Ti Pé Ọgọ́rùn-ún Ọdún
ỌDÚN mánigbàgbé lọdún 1909 nílùú New York. Ọdún yẹn ni wọ́n ṣí afárá tó wà lágbègbè Queens, afárá yìí ló so àgbègbè Queens pọ̀ mọ́ àgbègbè Manhattan, lọ́dún yẹn kan náà ni wọ́n ṣí afárá míì tó wà lágbègbè Manhattan tó so àgbègbè Manhattan pọ̀ mọ́ Brooklyn.
Ọdún mánigbàgbé lọdún yẹn jẹ́ fáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà. Ṣáájú ọdún yẹn, Arákùnrin Charles Taze Russell, tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Bible and Tract Society nígbà yẹn, ìyẹn àjọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé kalẹ̀ lábẹ́ òfin, ti kíyè sí pé iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣì máa gbòòrò. (Mátíù 24:14) Ó rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn gbé oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìlú Pittsburgh ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania tẹ́lẹ̀ lọ sí Brooklyn ní ìpínlẹ̀ New York. Látọdún 1908 la ti bẹ̀rẹ̀ sí í palẹ̀ mọ́, nígbà tó sì di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1909 la kó lọ.
Kí Nìdí Tá A Fi Kó Lọ sí Brooklyn?
Àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù nígbà yẹn mọ̀ pé wíwàásù nínú àwọn ìwé ìròyìn jẹ́ ọ̀nà tó gbẹ́ṣẹ́ gan-an láti jẹ́ káwọn èèyàn tètè gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Nígbà tó fi máa di ọdún 1908, inú oríṣi ìwé ìròyìn mọ́kànlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìwàásù Arákùnrin Russell ti máa ń jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àròpọ̀ gbogbo ìwé ìròyìn yìí tó máa ń jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé méjì [402,000].
Arákùnrin Russell kọ̀wé pé: “Àwọn ará tó mọ̀ nípa báwọn ìwé ìròyìn ṣe máa ń gbé àpilẹ̀kọ jáde . . . fi dá wa lójú pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà á máa ka ìwàásù ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tá a bá lè máa gbé e jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n ń tẹ̀ láwọn [ìlú ńlá], wọ́n sọ pé láàárín ọdún kan ó ṣeé ṣe ká rí àìmọye àwọn ìwé ìròyìn táá máa gbé ìwàásù yìí jáde nígbà gbogbo.” Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá ibi tó máa dáa jù lọ láti jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù lè máa gbòòrò síwájú.
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Brooklyn ni wọ́n kó lọ? Arákùnrin Russell sọ pé: “Lẹ́yìn tá a gbàdúrà nípa rẹ̀, a parí èrò sí pé Brooklyn ní ìpínlẹ̀ New York ló máa dáa jù lọ fún iṣẹ́ ìwàásù torí pé èèyàn pọ̀ nílùú náà . . . àwọn èèyàn sì tún mọ ìlú náà sí ‘Ibùjókòó Àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì.’” Àbájáde ẹ̀ fi hàn pé ohun tí wọ́n ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ìwé ìròyìn fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìwàásù Arákùnrin Russell jáde.
Ìdí míì tún wà tí ìpínlẹ̀ New York fi dáa gan-an fún ibi tó yẹ kí oríléeṣẹ́ wa wà. Nígbà tó fi máa di ọdún 1909, a ti ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, orílẹ̀-èdè Jámánì àti ilẹ̀ Ọsirélíà, a sì retí pé àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì ṣì tún máa wà. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kí oríléeṣẹ́ wa lágbàáyé wà nílùú tó ní etíkun tó sì tún láwọn ọ̀nà tó pọ̀ àtàwọn ọ̀nà ọkọ̀ ojú irin téèyàn lè gbà dé àwọn ìlú míì.
Kí Nìdí Tá A Fi Ń Pè É Ní Bẹ́tẹ́lì?
A kọ́kọ́ dá oríléeṣẹ́ wa, ìyẹn Watch Tower Bible and Tract Society sílẹ̀ láàárín ọdún 1880 sí 1889 nílùú Allegheny (tó ti wá di apá kan ìlú Pittsburgh báyìí), ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania. Ilé Bíbélì là ń pè é nígbà yẹn, èèyàn méjìlá ló sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lọ́dún 1896.
Nígbà tá a kó lọ sí Brooklyn lọ́dún 1909, a bẹ̀rẹ̀ sí í pe ilé tá a kó lọ náà ní Bẹ́tẹ́lì.a Kí nìdí tá a fi ń pè é ní Bẹ́tẹ́lì? Olórí ìsìn kan tó gbajúmọ̀ dáadáa tó ń jẹ́ Henry Ward Beecher ló ni Ilé tí Watch Tower Society rà ní ojúlé 13 sí 17 ní Òpópónà Hicks, àwọn èèyàn sì sábà máa ń pe ilé yẹn ní ‘Beecher Bethel.’ A tún ra ilé tí Beecher ń gbé tẹ́lẹ̀ tó wà ní ojúlé 124 òpópónà Columbia Heights. Ilé Ìṣọ́ March 1, 1909 ti èdè Gẹ̀ẹ́sì ròyìn pé: “Ohun mánigbàgbé ni pé, láìrò ó tì tẹ́lẹ̀, a ra ilé Ọ̀gbẹ́ni Beecher, a sì tún ra ilé tó ń gbé nígbà kan rí. . . . Ilé tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ rà yìí la ó máa pè ní ‘Bẹ́tẹ́lì,’ a ó sì máa pe ọ́fíìsì tuntun àti gbọ̀ngàn ńlá yìí ní ‘Brooklyn Tabernacle,’ [ìyẹn, Àgọ́ Ìjọsìn Ìlú Brooklyn], àwọn orúkọ yìí ló máa rọ́pò ‘Ilé Bíbélì’ tá à ń pe ilé wa tẹ́lẹ̀.”
Ní báyìí, Bẹ́tẹ́lì la wá ń pe oríléeṣẹ́ wa tó wà ní Brooklyn tó ti wá fẹ̀ gan-an báyìí àtàwọn èyí tó wà ní Wallkill, Patterson àti ìpínlẹ̀ New York títí kan àwọn ilé gbígbé, ibi ìtẹ̀wé àtàwọn ọ́fíìsì tó wà níbẹ̀. Kódà, orílẹ̀-èdè mẹ́tàléláàádọ́fà [113] kárí ayé la ti ní àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì báyìí. Àwọn òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó ń jẹ́ kí òtítọ́ Bíbélì lè máa dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn sì ju ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlógún [19,000] lọ.
Tọwọ́tẹsẹ̀ La Fi Gbàlejò
January 31, ọdún 1909 la ya oríléeṣẹ́ wa yìí sí mímọ́. Ọjọ́ Monday September 6, ọdún 1909 la sì yà sọ́tọ̀ láti fi gbàlejò níbẹ̀. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bá a ṣe máa ń pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, ló wá fójú lóúnjẹ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló gba àpéjọ Kristẹni kan tí wọ́n lọ ṣe nílùú Saratoga Springs wá sí Bẹ́tẹ́lì lọ́jọ́ náà, ìyẹn sì tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogún [320] kìlómítà sílùú New York. Arákùnrin Charles Taze Russell ló fúnra ẹ̀ kí àwọn àlejò káàbọ̀.b
A ṣì ń gbàlejò ní Bẹ́tẹ́lì títí dòní olónìí. Kódà, àwọn èèyàn tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì [40,000] lọ ló máa ń wá ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn lọ́dọọdún. Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ṣì ń kó ipa pàtàkì nínú bí ìhìn rere nípa Ìjọba Jèhófà ṣe ń gbòòrò sí i, ìyẹn sì ń bù kún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù tó ń jẹ́ “Bẹ́tẹ́lì” túmọ̀ sí “Ilé Ọlọ́run.” Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ìlú kan tó lókìkí ní Ísírẹ́lì ni wọ́n ń pè ní Bẹ́tẹ́lì. Àmọ́, ìlú Jerúsálẹ́mù nìkan ni Bíbélì dárúkọ léraléra.
b Tó o bá fẹ́ ka púpọ̀ sí i nípa ìtàn yìí, wo ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, lédè Gẹ̀ẹ́sì, ojú ìwé 718 sí 723. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
KÍ LO MỌ̀ NÍPA WATCH TOWER BIBLE and TRACT SOCIETY?
Ọdún 1884 la dá àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania sílẹ̀ lábẹ́ òfin, orúkọ tá a sì ń pè é nígbà yẹn ni Zion’s Watch Tower Tract Society. Ìdí tá a fi dá àjọ yìí sílẹ̀ ni láti jẹ́ káwọn èèyàn kárí ayé mọ òtítọ́ nípa Bíbélì, pàápàá nípasẹ̀ àwọn ìwé tá à ń tẹ̀ jáde. Àjọ Watch Tower Bible and Tract Society ṣì jẹ́ ọkàn lára àwọn àjọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò kárí ayé lábẹ́ òfin.c—Fílípì 1:7.
Àjọ yìí ti tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé míì tó dá lórí Bíbélì jáde ní irínwó lé mẹ́tàléláàádọ́rin [473] èdè. Wọ́n ti tẹ ohun tó lé ní àádọ́jọ [150] mílíọ̀nù Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lódindi tàbí lápá kan ní èdè méjìléláàádọ́rin [72]. Yàtọ̀ sí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, àjọ yìí tún ti tẹ àwọn Bíbélì kan jáde fúnra wọn, wọ́n sì tún ṣètò pé káwọn ilé ìtẹ̀wé míì bá wọn tẹ àwọn Bíbélì kan lédè Gẹ̀ẹ́sì, irú bíi: American Standard Version, The Bible in Living English, The Emphatic Diaglott, Holman’s Linear Parallel Edition, King James Version (títí kan Bible Students Edition), àti The New Testament Newly Translated and Critically Emphasized, Àtúnṣe Kejì.
Yàtọ̀ sáwọn Bíbélì tá a ti tẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti gbé ìwé ńlá, ìwé ìròyìn, ìwé àṣàrò kúkúrú, àwo CD, àwo DVD àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tó ju ogún [20] bílíọ̀nù jáde láàárín ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, gbogbo ẹ̀ ló sì dá lórí Bíbélì.d Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìtẹ̀jáde yìí la tẹ̀, tá a dì, tá a sì kó ránṣẹ́ látàwọn Ilé Bẹ́tẹ́lì tó wà láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Ajẹntínà, Amẹ́ríkà, Brazil, Finland, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Íńdíà, Ítálì, Jámánì, Japan, Kánádà, Kòríà, Kòlóńbíà, Lẹ́bánónì, Mẹ́síkò, Myanmar, Nàìjíríà, Ọsirélíà, Philippines, Sípéènì, Gúúsù Áfíríkà.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Lọ́dún 2008, mílíọ̀nù méje, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà ó lé mẹ́rin àti irínwó lé mẹ́tàlélógójì [7,124,443] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà ní igba àti mẹ́rìndínlógójì [236] ilẹ̀. Wọ́n wà nínú ìjọ ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàlélọ́gọ́rùn, igba ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin [103,267].
d A kì í ta àwọn ìtẹ̀jáde wọ̀nyí. Ọrẹ àtinúwá làwọn èèyàn fi ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe.
[Àtẹ Ìsọfúnnni]
ÌTẸ̀JÁDE WA LỌ́DÚN 1998 SÍ 2008
Ìwé Ńlá 458,230,708
Ìwé Ìròyìn 11,292,413,199
Àṣàrò Kúkúrú 7,996,906,376
Ìwé Pẹlẹbẹ 862,050,233
Àwo CD àti MP3 34,621,130
Àwo DVD 13,500,125
Àwọn míì 129,083,031
Àròpọ̀ 20,786,804,802
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ilé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ojúlé 122 sí 124 Òpópónà Columbia Heights
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ojúlé 13 sí 17 Òpópónà Hicks (ọdún 1909 sí 1918)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Ìwé ìròyìn tó ń gbé àwọn ọ̀rọ̀ Arákùnrin Russell jáde
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Ojúlé 35 Òpópónà Myrtle (ọdún 1920 sí 1922)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ojúlé 18 Òpópónà Concord (ọdún 1922 sí 1927)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ojúlé 117 Òpópónà Adams (látọdún 1927 títí dòní)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ojúlé 25 sí 30 Òpópónà Columbia Heights
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ilé ìtẹ̀wẹ́ wa nílùú Wallkill
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ibùdó Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa nílùú Patterson